ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/1 ojú ìwé 9-14
  • “Awa Ti Rí Messia”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Awa Ti Rí Messia”!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlà-Ìran Jesu
  • Awọn Asọtẹlẹ Nipa Messia
  • Dídé Rẹ̀ Ni A Sọtẹlẹ
  • A Dá A Fihàn Yatọ Lati Òkè Wá
  • Eeṣe Ti Awọn Ju Kò Fi Tẹwọgba Jesu?
  • Idi ti Messia Fi Nilati Kú
  • “Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jesu Kristi Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìmọ̀ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Wọ́n Retí Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/1 ojú ìwé 9-14

“Awa Ti Rí Messia”!

“Oun [Anderu] tètèkọ́ rí Simoni arakunrin oun tikaraarẹ, ó sì wí fun un pe, Awa ti rí Messia, itumọ eyi ti ijẹ Kristi.”—JOHANNU 1:41.

1. Ẹ̀rí wo ni Johannu Arinibọmi jẹ́ nipa Jesu ará Nasareti, kí sì ni Anderu pari èrò sí nipa rẹ̀?

ANDERU wo ọkunrin Ju naa ti a ń pe ni    Jesu ará Nasareti ní àwòfín, fun ìgbà    pipẹ. Kò ní irisi ọba, tabi ọkunrin amòye, tabi rabbi kan. Kò ni aṣọ ìgúnwà, tabi ori ewú, tabi ọwọ́ ti ó dẹ̀ múlọ́múlọ́ ati àwọ̀ ara mímọ́lóló. Jesu jẹ́ ọ̀dọ́—nǹkan bii ẹni 30 ọdun—pẹlu awọn àtẹ́lẹwọ́ nínípọn ati àwọ̀ ara aláwọ̀ amọ̀ ti ó jẹ́ ti oniṣẹ àfọwọ́ṣe. Nitori naa kò lè ya Anderu lẹnu lati mọ pe gbẹ́nàgbẹ́nà ni. Sibẹ, Johannu Arinibọmi sọ nipa ọkunrin yii pe: “Wò ó, Ọdọ-agutan Ọlọrun!” Ni ọjọ ti ó ṣaaju, Johannu ti sọ ohun kan ti o tilẹ tubọ yanilẹnu: “Eyi ni Ọmọ Ọlọrun.” Eyi ha lè jẹ́ otitọ bi? Anderu lo akoko diẹ lati fetisilẹ si Jesu ni ọjọ yẹn. Awa kò mọ ohun ti Jesu sọ; a mọ pe awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yí igbesi-aye Anderu pada. Ó yára wá arakunrin rẹ̀, Simoni rí, ó sì fi ìtara kigbe pe, “Awa ti rí Messia”!—Johannu 1:34-41.

2. Eeṣe tí ó fi ṣe pataki lati ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí niti pe boya Jesu ni Messia ti a ṣeleri naa?

2 Anderu ati Simoni (ẹni ti Jesu tún orukọ rẹ̀ sọ ni Peteru) lẹhin naa di aposteli Jesu. Lẹhin ohun ti ó ju ọdun meji lọ gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin rẹ̀, Peteru sọ fun Jesu pe: “Kristi [Messia], Ọmọ Ọlọrun alaaye ni iwọ iṣe.” (Matteu 16:16) Awọn aposteli ati ọmọ-ẹhin oluṣotitọ naa fẹ̀rí imuratan hàn nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín lati kú fun igbagbọ yẹn. Lonii, araadọta-ọkẹ awọn eniyan oloootọ-ọkan ni wọn ń fọkansin bakan-naa. Ṣugbọn lori ẹ̀rí wo? Ó ṣetan, ẹ̀rí, ni ó fi iyatọ hàn laaarin igbagbọ ati igbagbọ-laiwadii lasan. (Wo Heberu 11:1.) Nitori naa ẹ jẹ ki a gbé awọn ìlà mẹta ti o wọ́pọ̀ nipa ẹ̀rí ti ó fihàn pe Jesu ni Messia naa nitootọ yẹwo.

Ìlà-Ìran Jesu

3. Kí ni Ihinrere Matteu ati Luku sọ kulẹkulẹ rẹ̀ nipa ìlà-ìran Jesu?

3 Ìlà-ìran Jesu ni ẹ̀rí akọkọ ti Iwe Mimọ Kristian Lede Griki fi funni ni itilẹhin ipo Messia rẹ̀. Bibeli sọtẹlẹ ṣaaju pe Messia naa yoo wá lati ìlà idile Ọba Dafidi. (Orin Dafidi 132:11, 12; Isaiah 11:1, 10) Ihinrere Matteu bẹrẹ pe: “Iwe ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu.” Matteu ti ìjẹ́wọ́ tí ó fi ìgboyà sọ yii lẹhin nipa títọpa ipilẹ-iran Jesu gba ìlà baba alágbàtọ́ rẹ̀ Josefu. (Matteu 1:1-16) Ihinrere Luku tọpa ìlà-ìran Jesu gba ọ̀dọ̀ Maria, ìyá rẹ̀ nipa ti ara, pada sẹhin gba ọ̀dọ̀ Dafidi ati Abrahamu si Adamu. (Luku 3:23-38)a Nipa bayii awọn onkọwe iwe Ihinrere ṣe akọsilẹ ìjẹ́wọ́ wọn fínnífínní pe Jesu jẹ́ ajogun Dafidi, ni èrò itumọ ti ofin ati niti àdánidá.

4, 5. (a) Ǹjẹ́ awọn alájọgbáyé Jesu ha pe ipilẹ-iran rẹ̀ lati ọdọ Dafidi nija bi, eesitiṣe ti eyi fi ṣe pataki? (b) Bawo ni awọn itọkasi ti kìí ṣe ara Bibeli ṣe ti ìlà-ìran Jesu lẹhin?

4 Àní alátakò aṣiyemeji julọ nipa ipo Messia Jesu paapaa kò lè sẹ́ ìjẹ́wọ́ Jesu fun jíjẹ́ ọmọkunrin Dafidi. Eeṣe? Idi meji ni ó wà. Ekinni, ìjẹ́wọ́ yẹn ni a sọ ni asọtunsọ lọna gbigbooro ni Jerusalemu fun ọpọ ẹwadun ṣaaju ki a tó pa ilu naa run ni 70 C.E. (Fiwe Matteu 21:9; Iṣe 4:27; 5:27, 28.) Bi ijẹwo naa bá jẹ́ èké ni, eyikeyii ninu awọn alátakò Jesu—ó sì kúkú ní pupọ wọn—ìbá ti fi Jesu hàn ni ayédèrú nipa wiwulẹ ṣayẹwo ìlà-ìran rẹ̀ ninu awọn akọsilẹ ìtàn-ìran ti o wà ninu ibi ìkóhun-ìṣẹ̀m̀báyé pamọ́ sí ti gbogbogboo.b Ṣugbọn ìtàn kò ni akọsilẹ nipa ẹnikẹni ti ń pe ipilẹ-iran Jesu lati ọdọ Ọba Dafidi níjà. Lọna ti o ṣe kedere, ìjẹ́wọ́ naa ni kò ṣee fipa kọlu. Kò sí iyemeji pe Matteu ati Luku ṣadakọ awọn orukọ ti o ṣe pataki fun awọn akọsilẹ wọn taarata lati inu awọn akọsilẹ gbogbogboo.

5 Ekeji, awọn orisun ẹhin ode Bibeli jẹrii si itẹwọgba gbogbogboo nipa ìlà-ìran Jesu. Fun apẹẹrẹ, Talmud ṣakọsilẹ rabbi ọrundun kẹrin bi ẹni ti ń sọ awọn ọ̀rọ̀ alailẹkọọ tí ń runnininu nipa Maria, ìyá Jesu, fun ‘híhùwà aṣẹwo pẹlu gbẹ́nàgbẹ́nà’; ṣugbọn àyọkà-ọ̀rọ̀ kan-naa gbà pe “ó jẹ́ iran àtẹ̀lé awọn ọmọ-aládé ati oluṣakoso.” Apẹẹrẹ ti ó tubọ gba iwaju ni ti opitan ọrundun keji naa Hegesippus. Ó sọ pe nigba ti Domitian, Kesari Romu, fẹ́ lati pa ìran àtẹ̀lé Dafidi eyikeyii run, diẹ ninu awọn ọ̀tá Kristian ijimiji bu ẹnu àtẹ́ lu awọn ọmọ-ọmọ Juda, iyèkan Jesu, “bi awọn ti o ti idile Dafidi wá.” Bi Juda bá jẹ́ ìran àtẹ̀lé Dafidi ti a mọ daradara, Jesu kò ha jẹ́ bẹẹ bakan-naa bi? Ó rí bẹẹ láìṣeéjáníkoro!—Galatia 1:19; Juda 1.

Awọn Asọtẹlẹ Nipa Messia

6. Bawo ni awọn asọtẹlẹ nipa Messia ti pọ̀ yanturu tó ninu Iwe Mimọ Lede Heberu?

6 Ìlà ẹ̀rí miiran pe Jesu ni Messia ni asọtẹlẹ ti o ní imuṣẹ. Awọn asọtẹlẹ ti ó kan Messia pọ̀ jaburata ninu Iwe Mimọ Lede Heberu. Ninu iwe rẹ̀ The Life and Times of Jesus the Messiah, Alfred Edersheim ṣe akopọ awọn ẹsẹ 456 ninu Iwe Mimọ Lede Heberu tí awọn rabbi igbaani kàsí ti messia. Bi o ti wu ki o ri, awọn rabbi naa ní ọpọlọpọ èrò òdì nipa Messia naa; ọpọ ninu awọn àyọkà-ọ̀rọ̀ ti wọn tọka sí kìí ṣe ti messia rárá. Sibẹ, o keretan ọgọọrọ awọn asọtẹlẹ ti ó dá Jesu mọ gẹgẹ bi Messia naa ni ó wà.—Fiwe Ìfihàn 19:10.

7. Kí ni diẹ lara awọn asọtẹlẹ ti Jesu muṣẹ ni akoko ìṣàtìpó rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé?

7 Lara wọn ni: ilu ti a ti bí i (Mika 5:2; Luku 2:4-11); àjálù-ibi ti pípa ọpọ awọn ọmọ-ọwọ́ ti ó wáyé lẹhin ìbí rẹ̀ (Jeremiah 31:15; Matteu 2:16-18); a o pè é jade lati Egipti (Hosea 11:1; Matteu 2:15); awọn oluṣakoso orilẹ-ede yoo pawọ́pọ̀ lati pa á run (Orin Dafidi 2:1, 2; Iṣe 4:25-28); ìfinihàn rẹ̀ fun 30 owó idẹ wẹ́wẹ́ (Sekariah 11:12; Matteu 26:15); àní ọ̀nà ikú rẹ̀ paapaa.—Orin Dafidi 22:16, alaye ẹsẹ-iwe; Johannu 19:18, 23; 20:25, 27.c

Dídé Rẹ̀ Ni A Sọtẹlẹ

8. (a) Asọtẹlẹ wo ni o tọka si ìgbà ti Messia naa yoo dé ni pàtó? (b) Awọn kókó abajọ meji wo ni a gbọdọ mọ̀ ki a baà lè loye asọtẹlẹ yii?

8 Ẹ jẹ ki a wulẹ kó afiyesi jọ sori asọtẹlẹ kanṣoṣo. Ni Danieli 9:25, awọn Ju ni a sọ fun nipa ìgbà ti Messia naa yoo dé. Ó kà pe: “Nitori naa ki iwọ ki o mọ̀, ki ó sì yé ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ̀ naa lati tún Jerusalemu ṣe, ati lati tun un kọ́, titi de ìgbà ọmọ-alade [Messia] Ẹni-ororo naa, yoo jẹ́ ọsẹ meje, ati ọsẹ mejilelọgọta.” Ní ìwòfìrí akọkọ, asọtẹlẹ yii lè dabii ohun ijinlẹ kan. Ṣugbọn ni èrò itumọ gbigbooro kan, ó ń beere lọwọ wa pe ki a wá kìkì ẹyọ isọfunni meji: ọgangan ibẹrẹ kan ati gígùn akoko. Lati ṣakawe, bi o bá ni aworan ilẹ kan tí ó tọka si iṣura kan ti a rì mọ́lẹ̀ sibi ti ó wà ni “50 òpó-wáyà si ila-oorun kanga ti ó wà ninu ọgbà ilu,” iwọ lè ri awọn apejuwe naa bi eyi ti o tojú sú ọ—ni pataki bi iwọ kò bá mọ ibi ti kanga yii wà, tabi bi ‘òpó-wáyà’ kan ti gùn tó. Iwọ kò ha ni wá awọn otitọ meji wọnni láwàárí ki o ba lè mọ ibi ti iṣura naa wà bí? Ó dara, asọtẹlẹ Danieli rí bakan-naa gan-an, ayafi pe a ń fẹ mọ ibẹrẹ akoko naa kí a sì ka sáà akoko ti ó tẹle e.

9, 10. (a) Kí ni ọgangan ibẹrẹ naa lati ibi ti a ti ka awọn ọsẹ 69 naa? (b) Bawo ni awọn ọsẹ 69 naa ti gùn tó, bawo ni a sì ṣe mọ eyi?

9 Lakọọkọ, a nilo ọgangan ibẹrẹ wa, deeti ọjọ naa ti ‘ọ̀rọ̀ naa lati tun Jerusalemu ṣe ati lati tun un kọ́ jade lọ.’ Tẹle e, a nilati mọ gígùn rẹ̀ lati ọgangan ibẹrẹ yẹn, àní bi ọsẹ 69 (7 mọ́ 62) wọnyi ti gùn tó. Kò sí eyikeyii ninu ẹyọ isọfunni naa ti ó ṣoro lati rí. Nehemiah sọ fun wa ni kedere gan-an pe ọ̀rọ̀ naa jade lọ lati tún ogiri ti ó yi Jerusalemu kọ́, ó keretan lati sọ ọ́ di ilu kan ti a tunṣe, “ni ogún ọdun Artasasta ọba.” (Nehemiah 2:1, 5, 7, 8) Iyẹn fi ọgangan ibẹrẹ wa sí 455 B.C.E.d

10 Wàyí o niti awọn ọsẹ 69 wọnyi, wọn ha lè jẹ́ ọsẹ gidi ti ọlọjọ meje bi? Bẹẹkọ, nitori pe Messia kò farahan ni ohun ti ó wulẹ ju ọdun kan lẹhin 455 B.C.E. Nipa bayii ọpọ julọ awọn ọmọwe Bibeli ati aimọye awọn itumọ (ti ó ní ninu Tanakh ti awọn Ju ni akiyesi ẹsẹ-iwe si ẹsẹ yii) fohunṣọkan pe iwọnyi jẹ́ awọn ọsẹ “ọdun.” Èrò yii nipa ‘ọsẹ ọlọdun,’ tabi iyipoyipo ọdun meje kan, ni awọn Ju igbaani mọ̀ daradara. Gan-an gẹgẹ bi wọn ti ń ṣakiyesi ọjọ isinmi ni gbogbo ọjọ keje, wọn ń ṣakiyesi ọdun isinmi ni gbogbo ọdun keje. (Eksodu 20:8-11; 23:10, 11) Nitori naa ọsẹ 69 ti ọlọdun yoo papọ jẹ́ 69 ọdun lọna 7, tabi 483 ọdun. Gbogbo ohun ti ó ṣẹku fun wa lati ṣe ni lati kà á. Lati 455 B.C.E., kíka 483 ọdun mú wa dé ọdun naa 29 C.E.—ọdun naa gan-an ti a baptisi Jesu ti ó sì di ma·shiʹach, Messia naa!—Wo “Seventy Weeks,” Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 899.

11. Bawo ni a ṣe lè dá awọn wọnni ti wọn sọ pe eyi wulẹ jẹ́ ọ̀nà igbalode fun ṣiṣetumọ asọtẹlẹ Danieli ni lóhùn?

11 Awọn kan lè ṣatako pe eyi wulẹ jẹ́ ọ̀nà igbalode lasan kan fun titumọ asọtẹlẹ naa lati bá ìtàn mu ni. Bi ó bá ri bẹẹ, eeṣe ti awọn eniyan ni awọn ọjọ Jesu fi ń reti Messia naa lati farahan ni akoko yẹn? Luku opitan Kristian, Tacitus ati Suetonius, awọn opitan Romu, Josephus opitan Ju, ati Philo ọmọran Ju gbogbo wọn gbé ni ohun ti kò jinna si akoko yii ti wọn sì jẹrii si ipo ireti yii. (Luku 3:15) Awọn ọmọwe kan loni rinkinkin mọ́ ọn pe ininilara lati ọwọ Romu ni o mú ki awọn Ju yánhànhàn fun ki wọn sì reti Messia ni awọn ọjọ wọnni. Bi o ti wu ki o ri, eeṣe, ti awọn Ju fi reti Messia nigba naa ti kìí ṣe ni akoko inunibini Griki rírorò ni ọpọ ọrundun ṣaaju? Eeṣe ti Tacitus fi sọ pe ó jẹ́ “awọn asọtẹlẹ ti o jinlẹ” ti ó ṣamọna awọn Ju lati reti awọn oluṣakoso lilagbara lati wá lati Judea ki wọn sì “gba ilẹ-ọba gbogbogboo”? Abba Hillel Silver, ninu iwe rẹ̀ A History of Messianic Speculation in Israel, gbà pe “Messia naa ni a reti ni nǹkan bii ìdámẹ́rin keji ọrundun kìn-ín-ní C.E.,” kìí ṣe nitori inunibini Romu, ṣugbọn nitori “itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ ti ó gbajúmọ̀ nipa ọjọ yẹn,” ti a fàyọ ni apakan lati inu iwe Danieli.

A Dá A Fihàn Yatọ Lati Òkè Wá

12. Bawo ni Jehofa ṣe dá fi Jesu hàn yatọ gẹgẹ bi Messia naa?

12 Iru ẹ̀rí kẹta nipa ipo Messia Jesu ni ẹ̀rí Ọlọrun funraarẹ. Gẹgẹ bi Luku 3:21, 22 ti sọ, lẹhin ti a ti baptisi Jesu, oun ni a fororo yan pẹlu ipá ti ó jẹ́ mimọ ti ó sì lagbara julọ ni gbogbo agbaye, ẹmi mimọ Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀. Ati pẹlu ohùn tirẹ̀ fúnraarẹ̀, Jehofa fihàn pe oun ti fọwọsi Ọmọkunrin oun, Jesu. Ni awọn akoko iṣẹlẹ meji miiran, Jehofa sọrọ ni taarata si Jesu lati ọrun wá, ní titipa bayii fi ifọwọsi Rẹ̀ hàn: lẹẹkan rí, niwaju mẹta ninu awọn aposteli Jesu, ati ni akoko miiran, niwaju ogunlọgọ onworan. (Matteu 17:1-5; Johannu 12:28, 29) Siwaju sii, awọn angẹli ni a rán lati òkè wá lati jẹrii si ipo Jesu gẹgẹ bi Kristi, tabi Messia.—Luku 2:10, 11.

13, 14. Bawo ni Jehofa ṣe ṣàṣefihàn ifọwọsi Jesu gẹgẹ bi Messia rẹ̀?

13 Jehofa fi ẹ̀rí fifọwọsi ẹni-ami-ororo rẹ̀ hàn nipa fifi agbara fun un lati ṣaṣepari awọn iṣẹ ńláǹlà. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ awọn asọtẹlẹ ti o fi kulẹkulẹ ìtàn hàn ṣaaju—ti awọn kan nasẹ̀ dé ọjọ wa.e Ó tun ṣe awọn iṣẹ iyanu, iru bii fifounjẹ bọ́ ogunlọgọ ati wíwo awọn alaisan sàn. Ó tilẹ jí awọn òkú dide paapaa. Ǹjẹ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ wulẹ humọ ìtàn awọn iṣe alagbara wọnyi lẹhin iṣẹlẹ naa ni bi? Ó dara, Jesu ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu rẹ̀ niṣoju awọn ti ọ̀ràn ṣoju wọn, nigba miiran ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan lẹẹkan-naa. Àní awọn ọ̀tá Jesu paapaa kò lè sẹ́ pe ó ṣe awọn nǹkan wọnyi niti gidi. (Marku 6:2; Johannu 11:47) Yatọ si iyẹn, bi awọn ọmọlẹhin Jesu bá ni itẹsi-ọkan lati humọ iru awọn akọsilẹ iṣẹlẹ bẹẹ, nigba naa eeṣe ti wọn yoo fi jẹ alaifọrọ-sabẹ-ahọ́n-sọ tobẹẹ nigba ti ọ̀ràn bá kan awọn ìkùna tiwọn funraawọn? Nitootọ, ǹjẹ́ wọn ìbá ti muratan lati kú fun igbagbọ ti a gbekari àlọ́ lásánlàsàn kan ti wọn ti funraawọn humọ rẹ̀ bi? Bẹẹkọ. Awọn iṣẹ iyanu Jesu jẹ́ otitọ inu ìtàn.

14 Ẹ̀rí Ọlọrun nipa Jesu gẹgẹ bi Messia lọ siwaju sii. Nipasẹ ẹmi mimọ ó rí sí i pe ẹ̀rí nipa ipo Messia Jesu ni a kọ silẹ ti ó sì di apakan iwe ti a tumọ ti a sì pínkiri lọna gbigbooro julọ ninu gbogbo ìtàn.

Eeṣe Ti Awọn Ju Kò Fi Tẹwọgba Jesu?

15. (a) Bawo ni awọn ẹ̀rí ti a fi dá Jesu mọ̀ gẹgẹ bi Messia ṣe gbooro tó? (b) Ireti awọn Ju wo ni o ṣamọna ọpọlọpọ ninu wọn lati kọ Jesu tì gẹgẹ bi Messia naa?

15 Lapapọ, nigba naa, awọn ìsọ̀rí ẹ̀rí mẹta wọnyi ní ọgọrọọrun awọn otitọ gidi ninu ti wọn fi Jesu hàn gẹgẹ bi Messia naa. Iyẹn kò ha tó bi? Wulẹ ronuwoye kikọwe beere fun iwé-àṣẹ iwakọ tabi kaadi ìrajà àwìn kí á sì sọ fun ọ pe ẹyọ ìdánimọ̀ mẹta kò tó—pe iwọ gbọdọ mú ọgọrọọrun-un wá. Ẹ wo bi iyẹn yoo ti jẹ́ alaibọgbọmu tó! Dajudaju, nigba naa, Jesu ni a dá fihàn yatọ lọna tí ó pọ̀ tó ninu Bibeli. Bi o ti wu ki o ri, eeṣe, ti ọpọ ninu awọn eniyan Jesu gangan fi sẹ́ gbogbo ẹ̀rí yii pe oun ni Messia naa? Idi ni pe ẹ̀rí, bi ó ti ṣe pataki tó fun ojulowo igbagbọ, kò mú igbagbọ daju. Lọna ti o banininujẹ, ọpọlọpọ gbagbọ ninu ohunkohun ti wọn fẹ́ lati gbagbọ, àní ni oju ẹ̀rí ti o pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ paapaa. Nigba ti ó bá kan ọ̀ràn Messia, ọpọ julọ awọn Ju ní awọn èrò pàtó nipa ohun ti wọn ń fẹ́. Wọn fẹ́ messia oṣelu kan, ọ̀kan ti yoo fopin si ininilara Romu ti yoo sì mú Israeli padabọ si ipo ògo kan ti ó jọ ti awọn ọjọ Solomoni ni ọ̀nà ohun-ìní ti ara. Bawo, nigba naa, ni wọn ṣe lè tẹwọgba ọmọkunrin gbẹnagbẹna onirẹlẹ yii, ará Nasareti yii ti kò fi ìfẹ́-ọkàn hàn ninu oṣelu tabi ọrọ̀? Bawo, ni pataki, ni oun fi lè jẹ́ Messia lẹhin ti ó ti jiya ti ó sì kú lọna itiju lori òpó-igi ìdálóró?

16. Eeṣe ti awọn ọmọlẹhin Jesu fi nilati ṣe àtúnṣebọ̀sípò ireti wọn nipa Messia naa?

16 Awọn ọmọ-ẹhin Jesu fúnraarẹ̀ ni ikú rẹ̀ da jìnìnjìnìn bò. Lẹhin ajinde ologo rẹ̀, o hàn gbangba pe wọn ń reti pe yoo ‘mu ijọba pada bọ̀ si Israeli’ loju-ẹsẹ. (Iṣe 1:6) Ṣugbọn wọn kò kọ Jesu gẹgẹ bi Messia kìkì nitori pe ireti adání yii kò ni imuṣẹ. Wọn lo igbagbọ ti a gbekari ẹ̀rí ti o pọ̀ tó ti o wa larọọwọto ninu rẹ̀, ti òye wọn sì dagba sii ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀; awọn ohun riruniloju ni a mú kuro. Wọn wá rí i pe Messia naa kò lè mú gbogbo awọn asọtẹlẹ nipa rẹ̀ ṣẹ ni akoko kukuru ti ó lò gẹgẹ bi eniyan lori ilẹ̀-ayé. Eeṣe, asọtẹlẹ kan sọrọ nipa dídé rẹ̀ lọna irẹlẹ, ní gigun agódóńgbó kẹtẹkẹtẹ kan, nigba ti o jẹ pe omiran sọrọ nipa wíwá rẹ̀ ninu ògo lori awọsanma! Bawo ni mejeeji ṣe lè jẹ́ otitọ? Ni kedere oun nilati wá lẹẹkeji.—Danieli 7:13; Sekariah 9:9.

Idi ti Messia Fi Nilati Kú

17. Bawo ni asọtẹlẹ Danieli ṣe mú un ṣe kedere pe Messia naa nilati kú, fun idi wo ni yoo sì fi kú?

17 Siwaju sii, awọn asọtẹlẹ nipa Messia mú un ṣe kedere pe Messia naa nilati kú. Fun apẹẹrẹ, asọtẹlẹ naa gan-an ti ó sọ ìgbà ti Messia naa yoo dé sọtẹlẹ ni awọn ẹsẹ ti ó tẹle pe: “Lẹhin ọsẹ mejilelọgọta [eyi ti o tẹle ọsẹ meje] naa ni a o ké [Messia] Ẹni-ororo naa kuro.” (Danieli 9:26) Ọ̀rọ̀ Heberu naa ka·rathʹ ti a lò nihin-in fun “ké kuro” jẹ́ ọ̀rọ̀ kan-naa ti a lò fun idajọ ikú labẹ Ofin Mose. Laisi iyemeji kankan Messia naa nilati kú. Eeṣe? Ẹsẹ 24 fun wa ni idahun naa pe: “Lati fi edidi di ẹṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedeedee ati lati mú ododo ainipẹkun wá.” Awọn Ju mọ̀ daradara pe kìkì irubọ kan, ikú kan, ni ó lè ṣe etutu fun ẹṣẹ.—Lefitiku 17:11; fiwe Heberu 9:22.

18. (a) Bawo ni Isaiah ori 53 ṣe fihàn pe Messia naa gbọdọ jiya ki ó sì kú? (b) Ohun ti ó farajọ itakora wo ni asọtẹlẹ yii gbé dide?

18 Isaiah ori 53 sọrọ nipa Messia gẹgẹ bi akanṣe Iranṣẹ Jehofa ẹni ti yoo nilati jiya kí ó sì kú lati bo ẹṣẹ awọn ẹlomiran. Ẹsẹ 5 sọ pe: “A ṣá a ni ọgbẹ́ nitori irekọja wa, a pa á ni ara nitori aiṣedeedee wa.” Asọtẹlẹ kan-naa, lẹhin sisọ fun wa pe Messia yii gbọdọ kú gẹgẹ bi ‘ẹbọ ẹṣẹ,’ fihàn pe Ẹni yii kan-naa “yoo mú ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yoo ṣẹ ni ọwọ́ rẹ̀.” (Ẹsẹ 10) Iyẹn kìí ha ṣe itakora bi? Bawo ni Messia naa ṣe lè kú, ki ó sì tun “mú ọjọ rẹ̀ gùn”? Bawo ni a ṣe lè fi rubọ gẹgẹ bi ẹbọ kan ki ó sì tun sọ ‘ifẹ Oluwa di eyi ti ó ṣẹ ni ọwọ́ rẹ̀’ lẹhin naa? Bawo, nitootọ, ni ó ṣe lè kú kí ó sì wà ni òkú titilọ laimu awọn asọtẹlẹ ti wọn ṣe pataki julọ nipa rẹ̀ ṣẹ, iyẹn ni ṣiṣakoso titilae gẹgẹ bi Ọba ti yoo sì mú alaafia ati ayọ wá si gbogbo ayé?—Isaiah 9:6, 7.

19. Bawo ni ajinde Jesu ṣe yanju ohun ti ó farajọ itakora awọn asọtẹlẹ nipa Messia?

19 Ohun tí ó farajọ itakora yii ni iṣẹ iyanu kanṣoṣo, ti o gbafiyesi yanju. Jesu ni a jí dide. Ọgọrọọrun awọn Ju alailabosi-ọkan di ẹni ti ọ̀ràn otitọ ologo yii ṣoju rẹ̀. (1 Korinti 15:6) Aposteli Paulu lẹhin naa kọwe pe: “Ọkunrin yii [Jesu Kristi] rú ẹbọ kan fun ẹṣẹ títílọ-kánrin ó sì jokoo ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, lati ìgbà naa lọ ó ń duro titi a o fi gbé awọn ọ̀tá rẹ̀ kalẹ bi apoti itisẹ rẹ̀.” (Heberu 10:10, 12, 13, NW) Bẹẹni, lẹhin ìgbà ti a jí Jesu dide si iwalaaye ti òkè ọ̀run, ati lẹhin sáà akoko ‘diduro,’ ni oun yoo tó di ẹni ti a gbé ka ori ìtẹ́ nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín gẹgẹ bi Ọba ti yoo sì gbegbeesẹ lodisi awọn ọ̀tá Baba rẹ̀, Jehofa. Ninu ìlà iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba, Jesu Messia naa nipa lori igbesi-aye gbogbo eniyan ti ó walaaye nisinsiyi. Ni ọ̀nà wo? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti o tẹle e yoo gbé eyi yẹwo.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nigba ti Luku 3:23 sọ pe: “Josefu, tíí ṣe ọmọ Eli,” ó ṣe kedere pe ó tumọsi “ọmọ” ni èrò itumọ ti “ọkọ-ọmọbinrin,” niwọn bi Eli ti jẹ́ baba Maria nipa ti ara.—Insight on the Scriptures, Idipọ 1, oju-iwe 913 si 917.

b Josephus opitan Ju, nigba ti ó ń gbe ìlà-ìran tirẹ kalẹ, mú un ṣe kedere pe iru awọn akọsilẹ bẹẹ wà larọọwọto ṣaaju 70 C.E. Awọn akọsilẹ wọnyi ni ó hàn gbangba pe a parun pẹlu ilu Jerusalemu, ní mímú gbogbo ìjẹ́wọ́ ipo Messia lẹhin naa jẹ́ eyi ti kò ṣeé fẹ̀rí rẹ̀ hàn.

c Wo Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 387.

d Ẹ̀rí tí ó lagbara wà lati orisun ti Griki, Babiloni, ati Paṣia igbaani ti ń tọka pe ọdun kìn-ín-ní iṣakoso Artasasta jẹ́ 474 B.C.E. Wo Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 614 si 616, 900.

e Ninu ọ̀kan lara iru asọtẹlẹ bẹẹ, ó sọtẹlẹ pe awọn messia èké yoo dide lati ọjọ rẹ̀ lọ siwaju. (Matteu 24:23-26) Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti ó ṣaaju.

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Eeṣe ti a fi nilati ṣayẹwo ẹ̀rí niti boya Jesu ni Messia ti a ṣeleri naa?

◻ Bawo ni ìlà-ìran Jesu ṣe ti ipo Messia rẹ̀ lẹhin?

◻ Bawo ni awọn asọtẹlẹ Bibeli ṣe ṣeranwọ lati fẹ̀rí hàn pe Jesu ni Messia naa?

◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni Jehofa fúnraarẹ̀ gbà jẹrii si ìdáfihàn yatọ Jesu gẹgẹ bi Messia naa?

◻ Eeṣe ti ọpọlọpọ awọn Ju fi kọ Jesu silẹ gẹgẹ bi Messia naa, eesitiṣe ti awọn idi wọnyi kò fi yè kooro?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọkọọkan ninu ọpọlọpọ iṣẹ iyanu Jesu pese ẹ̀rí siwaju sii nipa ipo Messia rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́