ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 2/15 ojú ìwé 4-7
  • “Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹ̀rí Tá A Máa Fi Mọ Ẹni Tí Í Ṣe Mèsáyà Náà
  • Àwọn Ohun Tó Para Pọ̀ Di Ẹ̀rí Náà
  • Bí Ìtàn Ìdílé Ṣe Fi Mèsáyà Hàn
  • Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Kàn Ṣèèṣì Ṣẹ sí Jésù Lára Ni?
  • Bí Mèsáyà Ṣe Dé
  • Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Awa Ti Rí Messia”!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Wọ́n Retí Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jesu Kristi Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìmọ̀ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 2/15 ojú ìwé 4-7

“Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”

“ÀWA ti rí Mèsáyà náà.” “Àwa ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin, àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀.” Àwọn Júù olùfọkànsìn méjì kan ní ọ̀rúndún kìíní ló sọ ọ̀rọ̀ tó yani lẹ́nu yẹn. Mèsáyà táwọn Júù ń retí ti dé wàyí. Ó dá àwọn méjèèjì lójú hán-ún pé òun ni!—Jòhánù 1:35-45.

Tó o bá wo ọ̀ràn náà dáadáa, tó o ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú àti nínú ẹ̀sìn láyé ìgbà yẹn, wàá rí i pé bó ṣe dá wọn lójú pé Mèsáyà ni wọ́n rí yìí ṣe pàtàkì gan-an ni. Àwọn kan ń polongo ara wọn pé àwọn ló máa dá àwọn Júù nídè, wọ́n sì ń ṣe oríṣiríṣi ìlérí àmọ́ kò pẹ́ táwọn èèyàn fi rí i pé ibi táwọn fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀, torí pé àwọn tó ń polongo ara wọn yìí kò lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù tó ń fojú wọn gbolẹ̀.—Ìṣe 5:34-37.

Àmọ́, kò sí iyèméjì kankan lọ́kàn àwọn Júù méjì yìí, ìyẹn Áńdérù àti Fílípì, pé Mèsáyà náà gan-an làwọn rí. Dípò ìyẹn, bọ́dún ṣe ń gorí ọdún ló túbọ̀ ń dá wọn lójú sí i bí wọ́n ṣe ń fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àrà tí ọkùnrin yìí ń ṣe, èyí tó jẹ́ pé ó bá àwọn ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò ṣe mu.

Kí ló mú káwọn méjì yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, tó sì dá wọn lójú pé ọkùnrin yìí kì í ṣe èké Mèsáyà tàbí afàwọ̀rajà kan lásán? Kí làwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó hàn gbangba gbàǹgbà pé òun gan-an ni Mèsáyà lóòótọ́?

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn Bíbélì ṣe fi hàn, Áńdérù àti Fílípì sọ pé Jésù ará Násárétì, tó ń ṣiṣẹ́ káfíńtà tẹ́lẹ̀, ni Mèsáyà náà tí Ọlọ́run ṣèlérí táwọn èèyàn sì ti ń retí látọdún pípẹ́. (Jòhánù 1:45) Òpìtàn kan láyé ìgbà yẹn tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbára lé, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lúùkù, sọ pé “ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì” ni Mèsáyà dé. (Lúùkù 3:1-3) Ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù bẹ̀rẹ̀ ní oṣù September ọdún 28 Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní oṣù September ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Lúùkù tún sọ pé àwọn Júù ti “ń fojú sọ́nà” pé kí Mèsáyà dé láàárín àkókò yẹn. (Lúùkù 3:15) Kí nìdí tí wọ́n fi ń wọ̀nà pé kó dé lákòókò yẹn? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

Àwọn Ẹ̀rí Tá A Máa Fi Mọ Ẹni Tí Í Ṣe Mèsáyà Náà

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipa pàtàkì ni Mèsáyà yóò kó, ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá, pèsè àwọn ẹ̀rí kan pàtó tó máa jẹ́ káwọn tó bá wà lójúfò àtàwọn olóòótọ́ èèyàn lè mọ ẹni tí Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí náà jẹ́ gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé, tí ẹ̀rí bá wà, àwọn afàwọ̀rajà ò ní lè rí àwọn tó bá wà lójúfò tàn jẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ.

Nígbà tí aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè kan bá fẹ́ fi ara rẹ̀ han ìjọba orílẹ̀-èdè mìíràn, ó gbọ́dọ̀ fi ìwé ẹ̀rí hàn wọ́n níbẹ̀ láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé orílẹ̀-èdè rẹ̀ ló rán an wá gẹ́gẹ́ bí aṣojú lóòótọ́. Bákan náà, tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti lo àwọn kan láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí Mèsáyà yóò ṣe àtàwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ni Mèsáyà náà lóòótọ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Mèsáyà, “Olórí Aṣojú” náà, bá dé, ńṣe ló máa dà bíi pé ó wá tòun ti ìwé ẹ̀rí.—Hébérù 12:2.

Àwọn ohun tí Mèsáyà yóò ṣe àtàwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i tó máa fi í hàn pé òun ni Mèsáyà náà lóòótọ́ wà nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí wọ́n ti kọ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Mèsáyà yóò ṣe wá, bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe rí, ìyà táwọn èèyàn yóò fi jẹ ẹ́, àti irú ikú tó máa kú. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé gbára lé yìí tún sọ nípa àjíǹde rẹ̀, bí yóò ṣe dépò ńlá ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, àti ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Ìjọba rẹ̀ yóò mú wá fún aráyé. Ńṣe ni Bíbélì sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí lọ́nà tó jẹ́ pé kò sí ẹlòmíràn tó máa bá mu yàtọ̀ sí ẹni tó jẹ́ Mèsáyà náà nìkan ṣoṣo.

Òótọ́ ni pé nígbà tí Jésù dé lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, kì í ṣe gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ló ṣẹ lákòókò náà. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò tíì pa á, kò sì tíì jíǹde. Síbẹ̀, Áńdérù àti Fílípì àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn gba Jésù gbọ́ nítorí àwọn nǹkan tó kọ́ni àtàwọn nǹkan tó ṣe. Wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tó mú kó dá wọn lójú pé òun ni Mèsáyà náà. Ká ní o wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tó o sì yẹ àwọn ẹ̀rí wọ̀nyẹn wò fúnra rẹ láìṣe lámèyítọ́ kankan nípa rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé Jésù ni Mèsáyà.

Àwọn Ohun Tó Para Pọ̀ Di Ẹ̀rí Náà

Kí ni ì bá mú kó o gbà pé Jésù ni Mèsáyà? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú kí Jésù tó dé làwọn wòlíì tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì ti sọ àwọn ohun kan pàtó tí Mèsáyà ní láti ṣe tó máa fi í hàn pé òun gan-an ni Mèsáyà. Bí àwọn wòlíì ṣe ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí ni àwòrán ẹni tí Mèsáyà náà í ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i hàn kedere. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Henry H. Halley sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká fojú inú wò ó pé àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọn ò mọra rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò jọ sọ̀rọ̀ rí. Ká ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú apá kan òkúta mábìlì tí wọ́n gbẹ́ mèremère wá sínú yàrá kan, tí wọ́n sì to gbogbo òkúta mábìlì tí olúkúlùkù wọn mú wá náà pọ̀ tó wá já sì àwòrán èèyàn kan, báwo nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣeé ṣe tí kì í bá ṣe pé ẹnì kan ló kọ́kọ́ gbẹ́ àwòrán ẹni náà tó sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní apá kan rẹ̀?” Halley wá béèrè pé: “Báwo ni gbogbo onírúurú nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Jésù àtèyí tó gbélé ayé ṣe, èyí tí onírúurú òǹkọ̀wé tó gbé lákòókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ nípa rẹ̀, kó tiẹ̀ tó di pé Jésù wá sáyé pàápàá, ṣe ṣẹ gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe kọ ọ́ tí kì í bá ṣe pé ẹnì kan tí ọgbọ́n rẹ̀ ga ju tèèyàn lọ fíìfíì ló darí àwọn tó kọ ọ́?” Nígbà tí Halley ro ọ̀rọ̀ náà lọ tó rò ó bọ̀, ó ní: “Iṣẹ́ ìyanu ńlá gbáà ni!”

Inú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ni ohun tí òpìtàn yìí pè ní iṣẹ́ ìyanu yẹn ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tẹ́ni tó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì kọ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì sílẹ̀, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa ipa tí Mèsáyà yóò kó, ó tún kọ ọ́ pé ìran Ábúráhámù ni Mèsáyà yóò ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:15-18) Ohun mìíràn tó sọ fi hàn pé ìran Júdà ni Mèsáyà yóò ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Ọlọ́run ní kí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ipa tí Mèsáyà yóò kó gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ àti olùdáǹdè yóò ju ti Mósè alára lọ.—Diutarónómì 18:18.

Nígbà ìjọba Dáfídì, àsọtẹ́lẹ̀ fi hàn pé Mèsáyà náà ni yóò jogún ìtẹ́ Dáfídì àti pé ńṣe ni ìjọba Rẹ̀ yóò “fìdí . . . múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Sámúẹ́lì 7:13-16) Ìwé Míkà sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí í ṣe ìlú ìbílẹ̀ Dáfídì ni a óò ti bí Mèsáyà náà. (Míkà 5:2) Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wúńdíá ló máa bí i. (Aísáyà 7:14) Málákì wòlíì sì sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹnì kan bí Èlíjà ni yóò kéde dídé Mèsáyà.—Málákì 4:5, 6.

Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Mèsáyà tún wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ọdún náà gan-an tí Mèsáyà yóò dé, ó ní: “Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta. Òun yóò padà, a ó sì tún un kọ́ ní ti gidi, pẹ̀lú ojúde ìlú àti yàrà ńlá, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà kíkangógó.”—Dáníẹ́lì 9:25.

Atasásítà ọba Páṣíà sọ “ọ̀rọ̀ náà” pé kí wọ́n lọ tún Jerúsálẹ́mù kọ́ ní ọdún ogún ìjọba rẹ̀. Ọdún 474 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, nítorí náà ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ọdún ogún ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́. (Nehemáyà 2:1-8) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin tó jẹ́ ọ̀sẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ (ìyẹn àròpọ̀ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta) ló máa wà láàárín ìgbà tí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò kí wọ́n sì tún un kọ́ àti ìgbà tí Mèsáyà yóò dé. Tá a bá ṣírò ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin yìí, yóò fún wa ní ọ̀rìnlénírínwó ọjọ́ ó lé mẹ́ta [483], èyí tí kò pé ọdún méjì. Àmọ́ tá a bá lo ìlànà àsọtẹ́lẹ̀ ti “ọjọ́ kan fún ọdún kan,” a óò rí i pé ọ̀rìnlénírínwó ọdún ó lé mẹ́ta [483] sígbà yẹn ni Mèsáyà náà yóò dé, ìyẹn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni.—Ìsíkíẹ́lì 4:6.a

Òótọ́ ni pé láwọn ọdún kan tàbí òmíràn, àwọn kan ń sọ pé àwọn ni Mèsáyà, àmọ́ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù ará Násárétì nìkan ṣoṣo ló fara hàn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà. (Lúùkù 3:1, 2) Ọdún yẹn gan-an ni Jésù lọ bá Jòhánù Olùbatisí pé kó batisí òun, Jòhánù sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbà yẹn ni Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù pé òun ni Mèsáyà. Nígbà tó yá, Jòhánù, ẹni tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò pa ọ̀nà mọ́ bíi ti Èlíjà, fi Jésù han Áńdérù àti ọmọlẹ́yìn mìíràn, ó sọ fún wọn pé Jésù ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”—Jòhánù 1:29; Lúùkù 1:13-17; 3:21-23.

Bí Ìtàn Ìdílé Ṣe Fi Mèsáyà Hàn

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìdílé àwọn Júù kan ní pàtó ni Mèsáyà yóò ti wá. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé Ẹlẹ́dàá tó mọ ohun gbogbo yóò ṣètò kí Mèsáyà dé lásìkò tí ìwé àkọsílẹ̀ ìdílé ṣì wà, káwọn èèyàn lè rí ohun tí wọ́n máa fi mọ ìdílé tí Mèsáyà ti wá lóòótọ́.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí McClintock àti Strong ṣe sọ pé: “Àfàìmọ̀ ni ò ní jẹ́ pé ìgbà ìparun Jerúsálẹ́mù [lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni] ni àwọn ìwé àkọsílẹ̀ nípa ẹ̀yà àti ìdílé àwọn Júù pa run, kì í ṣe ṣáájú ìgbà yẹn.” Ẹ̀rí tó dájú wà pé ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Kristẹni ni Mátíù àti Lúùkù ti kọ àwọn Ìwé Ìhìn Rere wọn. Nítorí náà, wọ́n á ti yẹ àwọn ìwé wọ̀nyẹn wò lákòókò tí wọ́n fẹ́ ṣe àkọsílẹ̀ ìdílé tí Jésù ti wá. (Mátíù 1:1-16; Lúùkù 3:23-38) Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ yìí sì ti ṣe pàtàkì tó, ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nígbà ayé Mátíù àti Lúùkù yóò fẹ́ ṣèwádìí fúnra wọn láti mọ ìdílé tí Jésù ti wá lóòótọ́.

Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Kàn Ṣèèṣì Ṣẹ sí Jésù Lára Ni?

Síbẹ̀, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mèsáyà kàn ṣèèṣì ṣẹ sí Jésù lára? Nígbà tí wọ́n bi ọ̀mọ̀wé kan ní ìbéèrè yẹn, ìdáhùn rẹ̀ ni pé: “Rárá o, kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ jaburata ẹ̀rí ló fi hàn pé kì í ṣe pé ó ṣèèṣì ṣẹ sí i lára. Ẹnì kan tiẹ̀ fi ìṣirò ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà, ó ní bá a bá kó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù èèyàn jọ, agbára káká ni a óò fi rí ẹyọ kan nínú wọn tí mẹ́jọ lára àsọtẹ́lẹ̀ Mèsáyà yóò ṣèèṣì ṣẹ sí lára.” Ọ̀mọ̀wé náà ṣe àpèjúwe kan láti fi ṣàlàyé ohun tí gbogbo ìyẹn túmọ̀ sí, ó ní: “Tá a bá kó owó idẹ dọ́là tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù lọ́nà bílíọ̀nù jọ, yóò bo gbogbo ìpínlẹ̀ Texas [tó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárùn-ún (690,000) kìlómítà tá a bá rìn ín yí po], gbogbo owó náà yóò sì ga tó ẹsẹ̀ bàtà méjì látilẹ̀. Tá a bá wá sàmì sí ọ̀kan lára owó náà tá a sì ní kí ẹnì kan tó fi nǹkan bojú rìn yí ká gbogbo ìpínlẹ̀ náà kó sì mú ọ̀kan nínú owó idẹ náà, kí ló fi hàn pé owó tá a sàmì sí yẹn gan-an ló máa mú?” Ọ̀mọ̀wé yìí wá sọ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe máa rí gan-an nìyẹn “tá a bá sọ pé mẹ́jọ péré lára àsọtẹ́lẹ̀ nípa [Mèsáyà] kàn lè ṣẹ sí ẹnì kan ṣáá lára.”

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ṣẹ sí Jésù lára láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kì í kàn án ṣe àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́jọ péré. Nítorí ẹ̀rí tó fakíki yìí, ọ̀mọ̀wé yẹn wá sọ pé: “Nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé ayé yìí rí, Jésù nìkan ṣoṣo ló mú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, kò tún sí ẹlòmíràn.”

Bí Mèsáyà Ṣe Dé

Kò sí àní-àní pé Jésù ará Násárétì tó dé lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni ni Mèsáyà. Bó ṣe dé wẹ́rẹ́ nìyẹn gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà onírẹ̀lẹ̀ táwọn èèyàn yóò fìyà jẹ. Dídé tó sì dé kì í ṣe láti di Ọba ajagunṣẹ́gun tó máa fòpin sí ìyà tí ìjọba Róòmù fi ń jẹ àwọn Júù, gẹ́gẹ́ bó ṣe jọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ń retí, títí kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pàápàá. (Aísáyà, orí 53; Sekaráyà 9:9; Iṣe 1:6-8) Àmọ́, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tó bá tún máa padà dé lọ́jọ́ iwájú, ńṣe ni yóò wá pẹ̀lú agbára àti ọlá àṣẹ tó ga lọ́lá.—Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14.

Nígbà táwọn olóye èèyàn jákèjádò ayé fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó dá wọn lójú pé Mèsáyà ti dé ní ọ̀rúndún kìíní, àti pé ó tún máa padà wá. Ẹ̀rí sì fi hàn pé ọdún 1914 tí í ṣe ìbẹ̀rẹ̀ “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ ni àkókò tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó padà wá.b (Mátíù 24:3-14) Ọdún yẹn ni Ọlọ́run fi Jésù jẹ Ọba Ìjọba Rẹ̀ lókè ọ̀run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn ò lè fojú rí i. Láìpẹ́ láìjìnnà, Jésù yóò gbé ìgbésẹ̀ láti mú gbogbo ohun tí ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì fà kúrò. Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e yóò bù kún gbogbo àwọn tí wọ́n bá fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé òun ni Irú Ọmọ náà tí í ṣe Mèsáyà, ẹni “tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”—Jòhánù 1:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti jíròrò ẹ̀rí yìí pẹ̀lú rẹ, a ó sì tún fi àwọn ohun tí ìjọba Mèsáyà yóò ṣe fún ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ hàn ọ́ nínú Bíbélì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ ka àlàyé síwájú sí i nípa Dáníẹ́lì 9:25, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ kejì, ojú ìwé 899 sí 904, àti ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, ojú ìwé 186 sí 191. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì.

b Tó o bá ń fẹ́ àlàyé sí i, wo orí 10 àti 11 nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Ọdún 455 ṣáájú Ọdún 29 Ọdún 1914, Mèsáyà máa tó

Sànmánì Kristẹni, Sànmánì Kristẹni, Mèsáyà di fòpin sí ìwà

“ọ̀rọ̀ náà láti mú Mèsáyà dé ọba ní ọ̀run búburú, yóò

Jerúsálẹ́mù padà sì sọ ilẹ̀ ayé

bọ̀ sípò” di Párádísè

Ọ̀rìnlénírínwó ó lé

mẹ́ta [483] ọdún

(ọ̀sẹ̀ 69 tó jẹ́ ọ̀sẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀)—Dáníẹ́lì 9:25

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́