Àǹfààní Wo Ni Mèsáyà Máa Ṣe fún Wa?
ÌWỌ náà lè máa béèrè pé, “Àǹfààní wo ni Mèsáyà máa ṣe fún wa?” Bẹ́ẹ̀ ni, ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn fẹ́ mọ̀ bóyá Mèsáyà máa ṣàǹfààní kankan fún òun.
Àwọn kan tó o lè gbára lé ọ̀rọ̀ wọn lè máa sọ fún ọ pé ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn rọrùn, ó sì ṣe kedere. Òun ni pé, Mèsáyà máa ṣe ọ́ láǹfààní, kódà, kò sẹ́ni tí kò ní ṣe láǹfààní. Ẹnì kan tó jẹ́ ògbógi nínú òfin àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìíní kọ àwọn ọ̀rọ̀ kan nípa Mèsáyà, ó ní: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí jẹ́ ká mọ ipa pàtàkì tí Mèsáyà yóò kó nínú ohun tí Ẹlẹ́dàá pinnu láti ṣe, ìyẹn láti bù kún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. (2 Kọ́ríńtì 1:20) Ipa tí Mèsáyà yóò kó ṣe pàtàkì gan-an débi pé bó ṣe máa wá sáyé àti ọ̀nà tó máa gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì dá lé lórí. Nínú ìwé kan tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ti ń lò láti àádọ́rin ọdún sẹ́yìn, Henry H. Halley sọ pé: “Ìdí tí wọ́n fi kọ Májẹ̀mú Láéláé ni pé wọ́n fẹ́ fi fojú àwọn èèyàn sọ́nà fún dídé [Mèsáyà], kí wọ́n sì fi pa ọ̀nà mọ́ fún dídé rẹ̀.” Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ pọn dandan kí Mèsáyà náà dé? Kí nìdí tó fi yẹ kí dídé rẹ̀ jẹ ọ́ lọ́kàn?
“Mèsáyà” túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró,” ohun tí orúkọ tá a mọ̀ dunjú náà “Kristi” sì túmọ̀ sí nìyẹn. Ó di dandan kí Mèsáyà, tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, ẹ̀dà ti ọdún 1970, sọ pé ó jẹ́ “olùràpadà gíga jù lọ,” wá nítorí ìwà àfojúdi tí Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́ náà, hù. Pípé ni Ọlọ́run dá wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n máa gbádùn títí láé nínú Párádísè, àmọ́ wọ́n gbé àǹfààní yẹn sọ nù. Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù ń fi yé wọn pé Ẹlẹ́dàá wọn ti mú nǹkan le fún wọn jù, ó ní nǹkan á túbọ̀ dáa fún wọn tó bá jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ló ń pinnu ohun tó dára àtohun tó burú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.
Sátánì tan Éfà, òun náà sì gba irọ́ Sátánì gbọ́. Ó hàn gbangba pé Ádámù ka àjọṣe tó wà láàárín òun àti aya rẹ̀ sí pàtàkì ju ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run lọ, ìyẹn ló fi bá Èṣù dìtẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6; 1 Tímótì 2:14) Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú kí wọ́n pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè, kì í sì í ṣe ìyẹn nìkan ni àkóbá tí wọ́n ṣe. Wọ́n tún jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àtohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀, ìyẹn ikú.—Róòmù 5:12.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa, ti pinnu nǹkan tóun máa ṣe láti mú gbogbo ìṣòro tí ọ̀tẹ̀ náà dá sílẹ̀ kúrò. Ọlọ́run fẹ́ jẹ́ kó ṣeé ṣe fọ́mọ èèyàn láti padà sọ́dọ̀ òun. Ìlànà kan tó bófin mu tí Ọlọ́run fi sínú Òfin Mósè ni yóò sì lò láti mú kí èyí ṣeé ṣe, ìyẹn ìlànà tó sọ pé ojú fún ojú, eyín fún eyín àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Diutarónómì 19:21; 1 Jòhánù 3:8) Gbogbo nǹkan gbọ́dọ̀ lọ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tó bófin mu yìí kí èyíkéyìí nínú àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ tó lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ṣe pinnu pé kó rí fún aráyé látìbẹ̀rẹ̀. Èyí ló fà á tá a fi nílò Mèsáyà.
Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ Èṣù, ohun tó sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì ni pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé “gbólóhùn [yìí] ló jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn nípa àwọn ìlérí tó dá lórí Mèsáyà gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ ọ́.” Ọ̀mọ̀wé mìíràn sọ pé Mèsáyà ni ẹni tí Ọlọ́run máa lò “láti mú gbogbo àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn àkọ́kọ́ fà kúrò,” tí yóò sì wá rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé.—Hébérù 2:14, 15.
Àmọ́, o lè máa sọ pé kò sí ìbùkún kankan fún aráyé báyìí. Òótọ́ ni torí pé dípò ìbùkún, ńṣe ni ipò nǹkan túbọ̀ ń dojú rú fún aráyé tí wọn ò sì mọ ọ̀nà àbáyọ. Abájọ tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia fi sọ pé “ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ṣì ń retí pé kí Mèsáyà dé,” wọ́n ní tó bá dé “yóò tún ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe, yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá aráyé.” Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ pé Mèsáyà ti dé. Ǹjẹ́ ìdí wà tó fi yẹ ká gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.