ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/1 ojú ìwé 5-8
  • Messia naa—Ireti Tootọ kan Ha ni Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Messia naa—Ireti Tootọ kan Ha ni Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Messia Ọrundun Lọna 20
  • Ireti Tootọ kan Ha Ni Bi?
  • Olùgbàlà Araye
  • Messia naa ati Iṣakoso
  • Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Awa Ti Rí Messia”!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Wọ́n Retí Mèsáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/1 ojú ìwé 5-8

Messia naa—Ireti Tootọ kan Ha ni Bi?

Ó pe araarẹ̀ ni Mose. Bi o ti wu ki o ri, orukọ rẹ̀ gan-an, ni a ti gbàgbé ninu ìtàn. Ni ọrundun karun C.E., ó rinrin-ajo jakejado erekuṣu Krete, ní mímú un dá awọn Ju ti wọn wà nibẹ loju pe oun ni messia naa ti wọn ń reti. Ó sọ fun wọn pe laipẹ inilara, ìgbèkùn ati oko-òǹdè wọn yoo dopin. Wọn gbagbọ. Nigba ti ọjọ isọdominira wọn dé, awọn Ju tẹle “Mose” lọ si pepele ilẹ ti o wọnu òkun ti ó dojukọ Òkun Mediterranean. Ó sọ fun wọn pe wọn kàn nilati gbé araawọn sọ sinu òkun nikan ni ti omi naa yoo sì pín sí meji niwaju wọn. Ọpọlọpọ ṣegbọran, ní kíkán lu òkun tí kò pínyà. Ọpọ jantirẹrẹ ni o rì sinu omi; awọn atukọ̀-òkun ati apẹja gba diẹ là ninu wọn. Mose, bi o ti wu ki o ri, ni a kò rí. Messia yẹn pòórá.

KI NI messia tumọsi? Awọn ọ̀rọ̀ naa “olugbala,” “olùdáǹdè,” ati “aṣaaju” lè wá sọ́kàn. Ọpọlọpọ lérò pe messia jẹ́ sàràkí-ẹ̀dá kan ti ń tannáran ireti ati ifọkansin ninu awọn ọmọlẹhin rẹ̀, ni ṣiṣeleri lati ṣamọna wọn kuro ninu inilara lọ sinu ominira. Niwọn bi eyi ti o pọ julọ ninu ìtàn eniyan ti jẹ́ ti ininilara, kò yani lẹnu pe ọpọ ninu iru awọn messia bẹẹ ti farahan la awọn ọrundun já. (Fiwe Oniwasu 8:9.) Ṣugbọn bii ẹni naa ti ó pe araarẹ̀ ni Mose ti Krete, awọn messia wọnyi ti sábà maa ń ṣamọna awọn alátẹ̀lé wọn si ijakulẹ ati ìjábá ju isọdominira lọ.

“Eyi ni Messia Ọba naa!” Bẹẹ ni rabbi ti a gbeniyi gidigidi naa Akiba ben Joseph ṣe kí Simeon Bar Kokhba ni ọdun naa 132 C.E. Bar Kokhba jẹ́ ọkunrin alagbara kan ti o dari ẹgbẹ́ ọmọ-ogun lilagbara kan. Ọpọlọpọ Ju ronu pe, ọkunrin kan ti yoo fopin si inilara ìgbà pípẹ́ wọn ní ọwọ́ Agbara Ayé Romu, ti dé nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín. Bar Kokhba kùnà; ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ-ibilẹ rẹ̀ fi iwalaaye wọn dí ikuna yẹn.

Ni ọrundun kejila, messia Ju miiran farahan, ni akoko yii o jẹ́ Yemen. Nigba ti caliph, tabi oluṣakoso, beere lọwọ rẹ̀ fun àmì kan nipa ipo messia rẹ̀, messia yii dábàá pe ki caliph bẹ́ oun lori ki ó sì jẹ́ ki ajinde oun loju-ẹsẹ jẹ́ àmì naa. Caliph fohunṣọkan pẹlu ìwéwèé naa—iyẹn sì ni opin messia Yemen. Ní ọrundun yẹn kan-naa, ọkunrin kan ti a ń pe ni David Alroy sọ fun awọn Ju ni Aarin Gbungbun Ila-oorun pe ki wọn mura lati tẹle oun lori ìyẹ́-apá awọn angẹli pada si Ilẹ Mímọ́. Ọpọlọpọ gbagbọ pe oun ni messia naa. Awọn Ju ti wọn wà ni Baghdad fi suuru duro lori òrùlé wọn, wọn fi aibikita ṣaifiyesi awọn olè ti wọn ń kó awọn ohun ìní wọn lọ.

Sabbatai Zevi dide ni ọrundun 17 lati Smirna. Ó polongo ipo messia rẹ̀ fun awọn Ju jakejado Europe. Awọn Kristian, pẹlu, fetisilẹ si i. Zevi ṣeleri isọdominira fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀—ó dabi ẹni pe nipa jijẹ ki wọn sọ ẹṣẹ dàṣà laisi ikalọwọko. Awọn ọmọlẹhin rẹ̀ timọtimọ julọ ṣe awọn ariya-ẹhanna, àṣà wíwà ni ìhòòhò-goloto, àgbèrè, ati ibalopọ laaarin ibatan ti ó sunmọra, lẹhin naa wọn a fiya jẹ araawọn nipa nínà araawọn lọ́rẹ́, nipa yíyí gbirigbiri kaakiri níhòòhò ninu yìnyín, ati nipa ríri araawọn mọlẹ dé ọrùn ninu ilẹ tútù. Nigba ti ó rinrin-ajo lọ si Turkey, Zevi ni a gbámú ti a sì sọ fun pe ó gbọdọ yipada yala si Islam tabi ki ó kú. Ó yipada. Ọpọlọpọ ninu awọn olufọkansin rẹ̀ ni a dáníjì. Sibẹ, fun ọrundun meji ti ó tẹle e, Zevi ni awọn eniyan kan ṣì ń pè ni messia.

Kristẹndọm ti mú ipin awọn messia tirẹ̀ jade bakan-naa. Ni ọrundun 12, ọkunrin kan ti ń jẹ́ Tanchelm kó ògídìgbó awọn ọmọ-ẹhin jọ ó sì jẹ gàba lori ilu Antwerp. Messia yii pe araarẹ̀ ni ọlọrun kan; ó tilẹ ta omi-ìwẹ̀ rẹ̀ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati mu gẹgẹ bi sakramẹnti! Messia “Kristian” miiran ni Thomas Müntzer ọmọ ilẹ Germany ọrundun 16. Ó ṣaaju irukerudo lodisi awọn alaṣẹ ilu, ni sisọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe eyi jẹ́ ìjà Armageddoni. Ó ṣeleri pe oun yoo wọ́n ọta abúgbàù awọn ọ̀tá pẹlu apá ẹ̀wù oun. Kaka bẹẹ, awọn eniyan rẹ̀ ni a pa ni ipakupa, ti a sì bẹ́ Müntzer lori. Ọpọlọpọ iru awọn messia miiran bẹẹ farahan ninu Kristẹndọm la awọn ọrundun já.

Awọn isin miiran, pẹlu, ní sàràkí-ẹ̀dá ti o jẹ́ messia wọn. Islam tọka si Mahdi, tabi ẹni ti a tọsọna lọna títọ́, ti yoo mú sanmani idajọ-ododo wọle. Ninu isin Hindu, awọn kan ti jẹwọ jíjẹ́ ìmárawọ̀ awọn ọlọrun Hindu, tabi àtúnwá, awọn oniruuru ọlọrun. Ati, gẹgẹ bi iwe gbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica sì ti sọ, “isin alaini-messia kan bii ti Buddha paapaa ti pese igbagbọ, laaarin awọn awujọ Mahāyāna, ninu Buddha Maitreya ọjọ iwaju naa ẹni ti yoo sọkalẹ wá lati ibugbe rẹ̀ ọ̀run ti yoo sì mu awọn oluṣotitọ wá si paradise.”

Awọn Messia Ọrundun Lọna 20

Ni ọrundun tiwa, aini naa fun ojulowo messia ti di kanjukanju ju ti igbakigbari lọ; kò yanilẹnu, nigba naa, pe ọpọlọpọ ti jẹwọ orukọ oyè yẹn. Ni ilu Congo ti Africa ni awọn ọdun 1920, 1930, ati 1940, Simon Kimbangu ati agbapò rẹ̀ Andre “Jesus” Matswa ni a kokiki yin gẹgẹ bi messia. Wọn kú, ṣugbọn awọn ọmọlẹhin wọn ṣì reti wọn lati padabọ ki wọn sì mú ẹgbẹrundun Africa wá.

Ọrundun yii tún ti rí idide “igbokegbodo isin onidan” ni New Guinea ati Melanesia. Awọn mẹmba reti pe ki ọkọ̀-òkun tabi ọkọ̀-òfuurufú kan ti awọn ọkunrin aláwọ̀ funfun bii-messia yoo darí balẹ ti yoo mú ki wọn di ọlọ́rọ̀ ti yoo sì mú sanmani ayọ wa nigba ti awọn òkú yoo dide paapaa.

Awọn orilẹ-ede onile iṣẹ ẹ̀rọ ti ní messia tiwọn pẹlu. Awọn kan jẹ́ aṣaaju isin, iru bii Sun Myung Moon, ẹni ti o polongo araarẹ̀ gẹgẹ bi agbapò Jesu Kristi ti ó ní-in lọ́kàn lati fọ ayé mọ́ nipasẹ awọn olufọkansin rẹ̀ ti o jẹ́ idile olusopọṣọkan. Awọn aṣaaju oṣelu ti tún gbiyanju lati fi araawọn si ipo messia, Adolf Hitler ti jẹ́ apẹẹrẹ buburu jai julọ ni ọrundun yii pẹlu ọ̀rọ̀ gigagiga rẹ̀ nipa Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun kan.

Awọn ìmọ̀-ọ̀ràn ati eto-ajọ oṣelu ti de ipo messia bakan-naa. Fun apẹẹrẹ, iwe gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pe ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn Marx-oun-Lenin ní o jọ bi ẹni pe o dábàá jíjẹ́ messia. Ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ Ede, ti a kokiki yin gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun alaafia ayé, jọbi pe o ti di iru afidipo messia kan ninu èrò ọpọlọpọ.

Ireti Tootọ kan Ha Ni Bi?

Akopọ àlàyé kukuru yii mú un ṣe kedere daradara pe ìtàn awọn ajọ-igbokegbodo nipa messia fi pupọpupọ jẹ́ ìtàn ìtànjẹ, ti awọn ireti ti o jásí pàbó ati awọn àlá ti kò fidimulẹ. Kò lè yanilẹnu pupọ, nigba naa, pe ọpọlọpọ eniyan lonii ti di alainigbẹkẹle ninu ireti fun messia kan.

Ṣaaju ki a tó pa ireti nipa messia rẹ́ patapata, bi o ti wu ki o ri, a nilati kọ́kọ́ mọ ibi ti ó ti wá ná. Niti tootọ, “messia” jẹ́ ọ̀rọ̀ Bibeli. Ọ̀rọ̀ Heberu naa ni ma·shiʹach, tabi “ẹni-ami-ororo.” Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli, awọn ọba ati alufaa ni a ń yànsípò wọn nigba miiran nipasẹ ayẹyẹ ìfòróró-yànni, ninu eyi ti a ti ń da ororo atasánsán sori wọn. Fun idi yii èdè isọrọ naa ma·shiʹach ni a lò fun wọn lọna títọ́. Awọn ọkunrin kan tun wà pẹlu ti a fòróró-yàn, tabi yàn sí ipò akanṣe kan, laisi ayẹyẹ ifororoyanni eyikeyii. Mose ni a pè ni “Kristi,” tabi “ẹni-ami-ororo,” ni Heberu 11:24-26, nitori pe oun ni a yàn gẹgẹ bi wolii ati aṣoju Ọlọrun.

Itumọ messia yii gẹgẹ bi “ẹni-ami-ororo” ya messia ti inu Bibeli sọtọ gédégbé kuro lara awọn èké messia ti a ti jiroro. Awọn messia inu Bibeli kìí ṣe ayanra-ẹni sipo; bẹẹ ni kìí ṣe àgbájọ awọn ọmọlẹhin tí ń jọsin wọn ni ó yàn wọn. Bẹẹkọ, ìyànsípò wọn pilẹṣẹ lati òkè wá, lati ọdọ Jehofa funraarẹ.

Nigba ti Bibeli sọrọ nipa ọpọlọpọ messia, ó gbé ọ̀kan ga fiofio ju awọn ti ó kù lọ. (Orin Dafidi 45:7) Messia yii ni sàràkí-ẹ̀dá ti o ṣepataki julọ ninu asọtẹlẹ Bibeli, kọkọrọ naa sí imuṣẹ awọn ileri Bibeli tí ń funni ní iṣiri julọ. Messia yii sì jijakadi pẹlu awọn iṣoro ti a ń dojukọ lonii.

Olùgbàlà Araye

Messia ti Bibeli dari afiyesi si awọn iṣoro araye nipa lilọ si awọn gbongbo wọn. Nigba ti awọn obi wa akọkọ, Adamu ati Efa, ṣọ̀tẹ̀ lodisi Ẹlẹdaa nitori ti a sún wọn lati ọwọ́ ẹ̀dá ẹmi ọlọtẹ naa Satani, ní iyọrisi rẹ̀ wọn fi agbara ẹ̀tọ́ iṣakoso patapata laikusibikan sọ́wọ́ araawọn. Wọn fẹ́ lati jẹ́ ẹni naa ti yoo pinnu ohun ti ó tọ́ ati ohun tí kò tọ́. Wọn tipa bẹẹ rìn jade kuro labẹ iṣakoso onifẹẹ, ati aláàbò ti Jehofa wọn sì ri idile eniyan bọ inu rudurudu ati ibanujẹ ti iṣakoso ara-ẹni, aipe, ati ikú.—Romu 5:12.

Ẹ wo bi o ti jẹ́ onifẹẹ tó, nigba naa, pe Jehofa Ọlọrun yàn akoko ṣiṣokunkun yẹn ninu ìtàn eniyan lati pese ireti fírífírí kan fun gbogbo araye. Ni pipolongo aṣẹ idajọ lori awọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan naa, Ọlọrun sọtẹlẹ pe iru ọmọ wọn yoo ní oludande kan. Bi a tọka sí i gẹgẹ bi “iru-ọmọ,” Olugbala yii yoo wá mu iyọrisi iṣẹ buburu ti Satani ti ṣe nibẹ ni Edeni kuro; Iru-ọmọ naa yoo gún “ejo” naa, Satani fọ́, ní ori, ni fífọ́ ọ túútúú kuro ni iwalaaye.—Genesisi 3:14, 15.

Lati ìgbà laelae, ni awọn Ju ti rí asọtẹlẹ yii gẹgẹ bii ti Messia. Ọpọ awọn Targum, akopọ Iwe Mimọ tí awọn Ju ṣe ti a sábà maa ń lò ni ọrundun kìn-ín-ní, ṣalaye pe asọtẹlẹ yii yoo ni imuṣẹ “ni ọjọ Messia Ọba.”

Abajọ, nigba naa, ti o fi jẹ́ pe lati ibẹrẹpẹpẹ gan-an, ni ileri dídé Iru-ọmọ, tabi Olugbala, yii ti dùn mọ́ awọn ọkunrin onigbagbọ. Ṣá ronuwoye imọlara Abrahamu nigba ti Jehofa sọ fun un pe Iru-ọmọ naa yoo wá nipasẹ ìlà ìran tirẹ̀, ati pe “gbogbo orilẹ-ede ayé”—kìí wulẹ ṣe awọn ìran àtẹ̀lé tirẹ̀ nikan—ni yoo ‘bukun araawọn’ nipasẹ Iru-ọmọ yẹn.—Genesisi 22:17, 18.

Messia naa ati Iṣakoso

Awọn asọtẹlẹ ẹhin ìgbà naa so ireti yii pọ̀ mọ́ ifojusọna fun iṣakoso rere. Ni Genesisi 49:10, Judah ọmọ ọmọ-ọmọ Abrahamu ni a sọ fun pe: “Ọ̀pá-aládé kì yoo ti ọwọ́ Judah kuro, bẹẹ ni olofin kì yoo kuro laaarin ẹsẹ rẹ̀, titi Ṣiloh yoo fi dé; oun ni awọn eniyan yoo gbọ́ tirẹ̀.” Ni kedere, “Ṣiloh” yii ni yoo ṣakoso—yoo sì ṣakoso kìí ṣe kìkì awọn Ju nikan ṣugbọn “awọn eniyan.” (Fiwe Danieli 7:13, 14.) Ṣiloh ni awọn Ju igbaani mọ̀ mọ́ Messia; niti tootọ, diẹ lara awọn Targum Ju wulẹ fi ọ̀rọ̀ naa “Messia” rọpo “Ṣiloh” tabi “Messia ọba.”

Gẹgẹ bi imọlẹ asọtẹlẹ ti a mísí ṣe ń baa lọ lati mọlẹ sii, pupọ sii ni a ṣipaya nipa iṣakoso Messia yii. (Owe 4:18) Ni 2 Samueli 7:12-16, Ọba Dafidi, ìran àtẹ̀lé Judah, ni a sọ fun pe Iru-ọmọ naa yoo wá lati ìlà rẹ̀. Siwaju sii pẹlu, Iru-ọmọ yii ni yoo jẹ́ Ọba ara-ọtọ kan. Ìtẹ́, tabi ipo iṣakoso rẹ̀, yoo wà titilae! Isaiah 9:6, 7 ti kókó yii lẹhin pe: “A bí ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yoo sì wà ni ejika rẹ̀: . . . Ijọba yoo bí sii, alaafia kì yoo ní ipẹkun: lori ìtẹ́ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati maa tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isinsinyi lọ, àní titilae. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yoo ṣe eyi.”

Iwọ ha lè ronuwoye iru ijọba kan bẹẹ bi? Oluṣakoso aduroti idajọ-ododo, olododo kan ti o fi idi alaafia mulẹ ti ó sì ń ṣakoso titilae. Ẹ wo bi o ti yatọ gédégédé tó si awọn itotẹlera aṣenilaanu ti awọn èké messia inu ìtàn! Yatọ gédégédé si aṣaaju atannijẹ, ti ó yan araarẹ̀, Messia ti Bibeli jẹ́ oluṣakoso ayé pẹlu gbogbo agbara ati ọla-aṣẹ ti o pọndandan lati yí awọn ipo ayé pada.

Ifojusọna yii nitumọ lọna jijinlẹ ni awọn akoko oniwahala wa. Araye kò tíì fi ìgbékútà nilo iru ireti kan bẹẹ rí. Bi o ti wu ki o ri, niwọn bi ó ti rọrun lati loye ireti èké, ó ṣekoko pe ki ẹnikọọkan wa ṣe ayẹwo kínníkínní nipa ibeere yii: Ǹjẹ́ Jesu ti Nasareti ni Messia ti a sọtẹlẹ naa bi ọpọlọpọ ti gbagbọ bí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o tẹle e yoo gbé ọ̀ràn yii yẹwo.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Messia kan ní Brooklyn Kẹ̀?

Awọn iwe àlẹ̀mọra-ogiri, awọn patako ipolowo-ọja, ati awọn iná ipolowo-ọja ní Israeli lẹnu aipẹ yii polongo pe “Murasilẹ fun dídé Messia naa.” Ipolongo itagbangba oní $400,000 yii ni a ti gbejade lati ọwọ́ awọn Lubavitcher, ẹya isin Hasidic Jew ti o ní itẹwọgba gbogbogboo gigalọla. Igbagbọ titankalẹ naa wà laaarin ẹgbẹ́ ti o ni mẹmba 250,000 yẹn pe rabbi wọn titobilọla, Menachem Mendel Schneerson ti Brooklyn, New York, ni Messia naa. Eeṣe? Schneerson kọni niti gidi pe Messia yoo de ninu iran yii. Ati gẹgẹ bi iwe-irohin Newsweek ṣe sọ, awọn oṣiṣẹ Lubavitcher tẹpẹlẹmọ pe rabbi ẹni 90 ọdun naa kì yoo kú ki Messia tó dé. Fun ọpọ ọrundun ẹya-isin yii ti kọni pe iran eniyan kọọkan ń mu ọkunrin kan o keretan jade ti o tootun lati jẹ́ Messia. Schneerson dabi iru ọkunrin bẹẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀, kò si tii yan olugbapo kankan. Sibẹ, awọn Ju ti o pọ julọ kò tẹwọgba a gẹgẹ bii Messia naa, ni iwe-irohin Newsweek sọ. Gẹgẹ bi iwe-irohin ojoojumọ naa Newsday ṣe sọ, Eliezer Schach rabbi alabaadije rẹ̀ ẹni ọdun 96 naa ti pe e ni “èké messia.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Igbagbọ naa pe Mose ti Krete ni messia naa ná ọpọlọpọ eniyan ni iwalaaye wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́