‘Mo Ha Nilati Ṣe Iribọmi Bi?’
NINU gbogbo awọn ipinnu ti a beere pe ki a ṣe ninu igbesi-aye, boya ni ọ̀kan ṣe pataki ju eyi: ‘Mo ha nilati ṣe iribọmi bi?’ Eeṣe ti eyiini fi ṣe pataki tobẹẹ? Nitori pe ipinnu wa nigba ti ó bá kan ibeere yii ní ipa taarata kìí ṣe kìkì lori ipa-ọna igbesi-aye wa isinsinyi ṣugbọn lori ire alaafia ayeraye wa pẹlu.
Ipinnu yii ha dojukọ ọ́ bi? Boya iwọ ti ń kẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun akoko kan. Tabi awọn obi rẹ ti lè maa kọ́ ọ lẹkọọ Iwe Mimọ lati ìgbà ọmọ-ọwọ́. Nisinsinyi iwọ ti dori koko naa nibi ti iwọ ti nilati ṣe ipinnu nipa ohun ti o nilati ṣe. Ki iwọ baa lè ṣe ipinnu ti ó tọna, iwọ nilati loye ohun ti iribọmi ní ninu ati ẹni ti o nilati ṣe iribọmi.
Ohun Tí Iribọmi Ní Ninu
Lọna kan ti o dabii ayẹyẹ igbeyawo, iribọmi jẹ́ ayẹyẹ kan ti ń sàmì sí ipo ibatan kan. Niti ọ̀ràn igbeyawo, ọkunrin ati obinrin ti ọ̀ràn kàn ti mú ipo ibatan sisunmọra pẹkipẹki kan dagba tẹlẹtẹlẹ. Ayẹyẹ igbeyawo naa kàn wulẹ ń fi ohun ti wọn ti fohunṣọkan lé lori nikọkọ hàn ni gbangba ni, iyẹn ni pe, awọn mejeeji ń kowọnu ìdè igbeyawo gan-an. Ó tún ṣí awọn anfaani ti tọkọtaya naa yoo gbadun silẹ ó sì mú awọn ẹrù-iṣẹ́ ti wọn nilati kunju iwọn rẹ̀ ninu igbesi-aye wọn wá.
Ipo ọ̀ràn naa jọra pẹlu iribọmi. Bi a ti ń kẹkọọ Bibeli, a ń kẹkọọ nipa awọn ohun didara tí Jehofa ti ṣe fun wa. Oun ti fun wa ní kìí ṣe kìkì iwalaaye wa ati ohun gbogbo ti a nilo lati gbe e ró nikan ni bikoṣe Ọmọkunrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo pẹlu lati ṣí ọ̀nà silẹ fun iran eniyan ẹlẹṣẹ lati lè wá sinu ipo ibatan pẹlu Rẹ̀ ati lati jere iye ayeraye lori paradise ilẹ̀-ayé. Nigba ti a bá ronu lori gbogbo eyi, a kò ha sún wa lati gbegbeesẹ bi?
Kí ni ohun ti a lè ṣe? Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi, sọ fun wa pe: “Bi ẹnikan ba ń fẹ́ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé [òpó-igi ìdálóró, NW] rẹ̀, ki o sì maa tọ mi lẹhin.” (Matteu 16:24) Bẹẹni, a lè di ọmọ-ẹhin Jesu Kristi, ni titẹle apẹẹrẹ rẹ̀ ni ṣiṣiṣẹsin fun awọn ohun ti o dùn mọ́ Baba rẹ̀, Jehofa lọ́kàn. Bi o ti wu ki o ri, lati ṣe bẹẹ, beere fun ‘sísẹ́’ araawa, iyẹn ni pe, fifinnufindọ pinnu lati fi ifẹ-inu Ọlọrun ṣiwaju tiwa; eyi ni ninu fifi araawa rubọ, tabi yiya igbesi-aye wa si mímọ́ fun ṣiṣe ifẹ-inu rẹ̀. Lati sọ ipinnu ti a funra-ẹni ṣe nikọkọ yii di mímọ̀, ààtò akanṣe itagbangba kan ni a ó ṣe. Iribọmi ni ààtò akanṣe yẹn lati fi apẹẹrẹ iyasimimọ wa si Ọlọrun hàn ni gbangba.
Ta Ni Ó Nilati Ṣe Iribọmi?
Jesu Kristi fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nitọọni pe ‘ki wọn lọ, kọ́ orile-ede gbogbo, ki wọn baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti ọmọ, ati ni ti ẹmi mimo, ki wọn kọ́ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti oun ti pa ni aṣẹ fun wọn.’ (Matteu 28:19, 20) Ni kedere, ìwọ̀n idagbadenu niti ero-inu ati ọkàn-àyà ni a beere lọwọ awọn ti a o baptisi. Nipasẹ ikẹkọọ ti ara-ẹni wọn ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọn ti mọriri aini naa lati ‘ronupiwada ki wọn si tun yipada’ kuro ninu ipa-ọna igbesi-aye wọn tẹlẹri. (Iṣe 3:19) Nigba naa, wọn ti rí aini naa lati tẹwọgba iṣẹ ajihinrere naa ti Jesu Kristi ṣe, ni didi ọmọ-ẹhin rẹ̀. Gbogbo iwọnyi ni a ti ṣe ṣaaju igbesẹ iribọmi.
Iwọ ha ti dé ipo yii ninu idagbasoke rẹ nipa tẹmi bi? Iwọ ha fọkanfẹ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun bi? Bi o ba jẹ́ bẹẹ, fi taduratadura gbé akọsilẹ Bibeli nipa ìwẹ̀fà ara Ethiopia naa yẹwo, gẹgẹ bi a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ninu Iṣe ori 8. Nigba ti awọn asọtẹlẹ nipa Jesu gẹgẹ bii Messia naa di eyi ti a ṣalaye fun ọkunrin yii, o ṣayẹwo ọkàn ati àyà rẹ̀ ó sì beere pe: “Kí ni ó dá mi duro lati baptisi?” Ni kedere kò si ohunkohun ti ń da a duro; nitori naa a ṣe iribọmi fun un.—Iṣe 8:26-38.
Lonii ọpọlọpọ ni ń beere iru ibeere kan-naa: “Kí ni ó dá mi duro lati baptisi?” Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, 300,945 awọn olùṣèyàsímímọ́ titun ni a baptisi ni 1991. Eyi mú ayọ titobi wá fun gbogbo awọn eniyan Jehofa, awọn alagba ti wọn sì wà ninu ijọ ni wọn layọ lati ṣeranwọ fun awọn ẹni ọlọkan títọ́ miiran lati tẹsiwaju ki wọn sì kunju ohun abeere-fun fun iribọmi.
Bi o ti wu ki o ri, ó lè jẹ́ pe awọn alagba ninu ijọ rẹ dabaa pe ki o ṣì duro ná. Tabi, bi iwọ ba jẹ́ ọ̀dọ́ kan, awọn obi rẹ le sọ pe ki o duro ná. Kí ni nigba naa? Maṣe di ẹni ti a mú rẹwẹsi. Fi í sọkan pe kikowọnu ipo ibatan pẹlu Ẹni Gigajulọ naa jẹ́ ọ̀ràn wiwuwo kan. Ọ̀pá ìdiwọ̀n giga ni a nilati bá ṣedeede ti a sì nilati rọ̀ mọ́. Nitori naa fetisilẹ si awọn idabaa ti a fifun ọ ki o si fi wọn silo tọkantọkan. Bi iwọ kò ba loye idi ti a fifunni naa lẹkun-unrẹrẹ, maṣe tijú, ṣugbọn beere awọn ibeere titi di ìgbà ti iwọ yoo loye iru imurasilẹ ti o nilati ṣe niti gidi.
Ni ọwọ́ keji èwẹ̀, awọn eniyan kan le lọ́tìkọ̀ lati gbe igbeṣe ńlá naa, gẹgẹ bi wọn ti pè é. Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan lara wọn bi? Niti tootọ, awọn idi ṣiṣe gunmọ lè wa ti iwọ fi nilati sún ṣiṣe iyasimimọ ati iribọmi siwaju. Ṣugbọn bi iwọ ba ti kunju oṣuwọn sibẹ ti o ṣi ń tàdí mẹ́hìn, ó dara ki o beere lọwọ araarẹ pe: “Kí ni ó dá mi duro lati baptisi?” Fi taduratadura ṣayẹwo ipo rẹ ki o si wò ó boya idi gidi kan wà niti tootọ fun sísún idahunpada si ikesini Jehofa lati wọnu ipo ibatan ara-ẹni pẹlu rẹ̀ siwaju.
‘Mo Ṣì Kéré’
Bi iwọ ba jẹ́ ọ̀dọ́ kan, iwọ le maa ronu pe, ‘Mo ṣì kéré.’ Otitọ ni pe niwọn bi awọn ọ̀dọ́ ba ṣì ń baa lọ bi onigbọran ti wọn sì ń dahunpada si awọn obi wọn Kristian ti wọn si ń fi Iwe Mimọ silo debi ti agbara wọn gbé e dé, wọn le ni igbọkanle pe Jehofa ń wò wọn gẹgẹ bi “mimọ.” Niti tootọ, Bibeli sọ fun wa pe itẹwọgba atọrunwa fun awọn obi oloootọ nasẹ dori awọn ọmọ ti wọn ṣì gbarale wọn. (1 Korinti 7:14) Bi o ti wu ki o ri, kò si iye idiwọn ọjọ-ori ti a fifunni ninu Bibeli nipa ìgbà ti gbigbaraleni yii yoo dopin. Nitori naa, o ṣe pataki fun awọn ọ̀dọ́ Kristian lati ronu gidigidi lori ibeere naa pe: ‘Mo ha nilati ṣe iribọmi bi?’
Bibeli fun awọn èwe niṣiiri lati ‘ranti Ẹlẹdaa wọn nigba èwe.’ (Oniwasu 12:1) Ni ìhà yii, awa ni apẹẹrẹ ti Samueli ọ̀dọ́, ẹni ti “ń ṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde.” Apẹẹrẹ ti Timoteu tun wà pẹlu, ẹni ti ó fi otitọ tí ìyá rẹ̀ ati iya rẹ̀ àgbà kọ́ ọ sọkan lati ìgbà ọmọ-ọwọ́.—1 Samueli 2:18; 2 Timoteu 1:5; 3:14, 15.
Bakan-naa lonii, ọpọ awọn ọ̀dọ́ ni wọn ti ya igbesi-aye wọn si mimọ lati ṣiṣẹsin Jehofa. Akifusa, ọmọ ọdun 15 kan, sọ pe apakan ninu Ipade Iṣẹ-isin ran oun lọwọ lati ṣe ipinnu rẹ̀ lati ṣe iribọmi. Ayumi ṣe iribọmi nigba ti ó wà ni ọmọ ọdun mẹwaa. Ó fẹ́ lati ṣiṣẹsin Jehofa nitori pe ó ti wá fẹran rẹ̀ niti gidi. Nisinsinyi oun jẹ́ ọmọ ọdun 13 ó sì ṣẹṣẹ ní iriri ti rírí akẹkọọ Bibeli rẹ̀, ti oun naa ti wá nifẹẹ Jehofa pẹlu, ti o ṣe iribọmi ni ọmọ ọdun 12. Hikaru, aburo Ayumi ọkunrin pẹlu, ṣe iribọmi ni ọmọ ọdun mẹwaa. Ó ranti pe, “Awọn kan sọ pe mo ti kéré jù, ṣugbọn Jehofa mọ bi mo ṣe nimọlara. Mo pinnu lati ṣe iribọmi ni gbàrà ti mo bá ti pinnu lati ya igbesi-aye mi sí mímọ́ lati ṣiṣẹsin in pẹlu gbogbo ohun ti mo ní.”
Apẹẹrẹ ti awọn obi tun jẹ́ kókó kan, gẹgẹ bi a ti le rii ninu iriri arabinrin ọ̀dọ́ kan. Baba rẹ̀ kaleewọ fun ìyá rẹ̀ lati bá oun ati arakunrin ati arabinrin rẹ̀ ṣe ikẹkọọ Bibeli. Oun yoo lù wọn ti yoo si sun iwe wọn níná. Ṣugbọn nitori iforiti ati igbagbọ iya naa, awọn ọmọ naa le rí ijẹpataki ṣiṣiṣẹsin Jehofa Ọlọrun. Ọdọmọbinrin yii ni a baptisi ni ọmọ ọdun 13, ti aburo rẹ̀ ọkunrin ati obinrin si ti tẹle apẹẹrẹ rẹ̀.
‘Mo Ti Dàgbà Jù’
Olorin naa sọ pe: “Awọn arugbo eniyan ati awọn ọmọde . . . yin orukọ Oluwa.” (Orin Dafidi 148:12, 13) Bẹẹni, awọn agbalagba bakan-naa gbọdọ mọ ijẹpataki didi iduro wọn mu ni ìhà ọdọ Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, awọn agbalagba kan tẹ̀ siha kíkọ̀ lati ṣe iyipada. Wọn nimọlara pe “ẹja gbígbẹ kò ṣee ká.” Sibẹ, ranti pe Abrahamu oloootọ jẹ́ ẹni ọdun 75 nigba ti Jehofa sọ fun un pe: “Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ará rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi yoo fi hàn ọ́.” (Iṣe 7:3; Genesisi 12:1, 4) Mose jẹ́ ẹni 80 ọdun nigba ti Jehofa yan iṣẹ fun un: “Mú awọn eniyan mi, . . . lati Egipti jade wa.” (Eksodu 3:10) Awọn ọkunrin wọnyi ati awọn miiran ni gbogbo wọn ti fidimulẹ ninu ọ̀nà igbesi-aye wọn nigba ti Jehofa ní kí wọn ṣàṣehàn ifẹ ati iyasimimọ wọn sí i. Wọn kò lọ́tìkọ̀ lati dahunpada si ìpè Jehofa.
Lonii ń kọ? Shizumu ti jẹ́ onisin Buddha fun ọdun 78 nigba ti o bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli. Idile rẹ̀ tako o, ti wọn kò tilẹ gbà á láàyè lati kẹkọọ ninu ile araarẹ. Lẹhin ọdun kan pere, ó ri aini naa lati ya araarẹ si mimọ fun Jehofa, ó sì ṣe iribọmi. Eeṣe ti oun fi ṣe iyipada? Ó wi pe: “Fun ọpọlọpọ ọdun ni isin eke ti fi tàn mi jẹ, mo si fẹ́ lati maa baa lọ ni gbigba otitọ lati ọdọ Jehofa titilae.”
“Eyi ti Ń Gbà Yin Là Nisinsinyi”
Akoko ń tán lọ. Iwalaaye, titikan tirẹ, wà ninu ewu. Ó jẹ kanjukanju pe ki o ronu gidigidi lori ọ̀ràn nipa yiya araàrẹ si mimọ fun Jehofa ati fifẹrii rẹ̀ hàn nipa iribọmi. Aposteli Peteru tẹnumọ eyi nipa sisọ pe: “Eyi ti ń gbà yin là nisinsinyi pẹlu, ani baptismu.” Ó tun ṣalaye siwaju sii pe iribọmi “kìí ṣe [ìwẹ̀] èérí ti ara nù” (ẹnikan yoo ti nilati ṣe iyẹn tẹlẹtẹlẹ ṣaaju ki o tó tootun fun iribọmi) “bikoṣe idahun ọkàn rere sipa Ọlọrun.”—1 Peteru 3:21.
Lẹhin kikun oju oṣuwọn awọn ohun ti Jehofa beere fun, ọmọ-ẹhin ti o ti ṣe iribọmi naa wá lati ní ẹri-ọkan rere. Nipa bibaa lọ lati ṣe bi ó ti lè ṣe daradara tó ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa, oun ń gbadun alaafia ọkàn ati itẹlọrun. (Jakọbu 1:25) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, oun lè fi igbọkanle fojusọna fun awọn ibukun alailopin lati ọ̀dọ̀ Jehofa ninu eto igbekalẹ titun ti ń bọ̀. Ǹjẹ́ ki eyiini jẹ́ ipin rẹ bi iwọ ti ń dahunpada lọna títọ́ si ibeere naa: ‘Mo ha nilati ṣe iribọmi bi?’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Gẹgẹ bi ọdọmọdekunrin kan Samueli ṣe iranṣẹ niwaju Jehofa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Mose jẹ́ ẹni 80 ọdun nigba ti Jehofa yan iṣẹ fun un
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lonii tọmọdetagba ti wọn ti ṣe iribọmi le fojusọna fun awọn ibukun alailopin ninu eto igbekalẹ titun Ọlọrun