ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/15 ojú ìwé 30-31
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Alààyè Tọ́ Ẹ Sọ́nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/15 ojú ìwé 30-31

Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Bawo ni awọn Kristian ṣe nilati daniyan tó nipa pe awọn èròjà inu ẹ̀jẹ̀, bii plasma gbígbẹ, ni o ti ṣeeṣe ki a pòpọ̀ mọ awọn ounjẹ kan ti a ń mújáde?

Bi idi ti o fẹsẹmulẹ bá wà lati gbagbọ pe ẹ̀jẹ̀ ẹranko (tabi èròjà rẹ̀) ni a ń lo dajudaju ninu awọn ohun eelo ounjẹ ni adugbo, awọn Kristian nilati lo iṣọra gidigidi. Sibẹ, yoo jẹ́ iwa-omugọ lati di ẹni ti a dà lọ́kàn rú nipasẹ ìfura lasan tabi gbe igbesi-aye pẹlu idaamu ti kò fidimulẹ.

Ni ibẹrẹ ìtàn eniyan, Ẹlẹdaa wa ṣofin pe awọn eniyan kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Genesisi 9:3, 4) Ó sọ pe ẹ̀jẹ̀ duro fun iwalaaye, eyi ti o jẹ́ ẹbun lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ẹ̀jẹ̀ ti a dà jade kuro lara ẹ̀dá kan ni a lè lò kìkì ninu irubọ, bii lori pẹpẹ. Bi kò ṣe bẹẹ, ẹ̀jẹ̀ lati ara ẹ̀dá kan ni a nilati dà sori ilẹ, ni èrò itumọ ti fififun Ọlọrun pada. Awọn eniyan rẹ̀ ni wọn gbọdọ yẹra fun gbigbe iwalaaye ró nipa gbigba ẹ̀jẹ̀ sara. Ó paṣẹ pe: “Ẹyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹrankẹran: nitori pe ẹ̀jẹ̀ ni ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti ó bá jẹ ẹ ni a o ké kuro.” (Lefitiku 17:11-14) Ìkàléèwọ̀ Ọlọrun lori jíjẹ ẹ̀jẹ̀ ni a sọ ni asọtunsọ fun awọn Kristian. (Iṣe 15:28, 29) Nipa bẹẹ awọn Kristian ijimiji nilati yẹra fun ounjẹ ti ó ni ẹ̀jẹ̀ ninu, bii ẹran lati inu ẹranko ti a lọ́ lọ́rùn pa tabi sọ́sééjì ẹlẹ́jẹ̀.

Bi o ti wu ki o ri, ni èrò ti ó lọgbọn-ninu, bawo ni awọn Kristian wọnyẹn yoo ṣe gbé igbesẹ lori ipinnu wọn lati ‘pa araawọn mọ kuro ninu ẹ̀jẹ̀’? (Iṣe 21:25) Wọn ha wulẹ nilati fi awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu silo ni ṣakala pe: “Ohunkohun ti a bá ń tà ni ọja ni ki ẹ maa jẹ, laibeere ohun kan nitori ẹ̀rí-ọkàn”?

Bẹẹkọ. Awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn ni 1 Korinti 10:25 tọkasi awọn ẹran ti ó ti lè wá lati ara ẹranko kan ti a fi rubọ ni tẹmpili oriṣa. Nigba naa lọhun-un, aṣẹku ẹran lati inu awọn tẹmpili ni wọn maa ń pamọ kuro nipa títà wọn fun awọn oniṣowo, ti wọn lè fẹ́ lati fi wọn kún awọn ipese ẹran ti wọn ní fun títà ni ìsọ̀ wọn. Kókó ọ̀rọ̀ Paulu ni pe ẹran lati inu tẹmpili kò buru ninu araarẹ tabi ni abaawọn. Ni kedere ó jẹ́ aṣa lati gbà ki wọn si lo ẹ̀jẹ̀ awọn ẹranko ti a fi rubọ nibẹ lori pẹpẹ abọriṣa. Nitori naa bi a bá ta diẹ lara awọn aṣẹku ẹran naa lọja, laisi isopọ híhàn gbangba pẹlu tẹmpili tabi aṣiloye awọn abọriṣa, awọn Kristian lè rà á gẹgẹ bi ẹran ori àtẹ ti ó mọ́ ti a sì ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ danu daradara.

Bi o ti wu ki o ri, ó nilati yatọ, bi awọn Kristian wọnyẹn bá mọ pe ẹran lati inu awọn ẹranko ti a ti lọ́ lọ́rùn pa (tabi sọ́sééjì ẹlẹ́jẹ̀) jẹ́ ọ̀kan ninu awọn yíyàn ti ó wà ni ile itaja adugbo. Wọn nilati lo iṣọra ninu yíyan iru ẹran wo ni wọn nilati rà. Ó lè ṣeeṣe fun wọn lati dá awọn ẹran ti ó ni ẹ̀jẹ̀ ninu mọ̀ bi iru bẹẹ bá ni àwọ̀ yiyatọ (àní gẹgẹ bi o ti ṣeeṣe lati dá sọ́sééjì ẹlẹ́jẹ̀ mọ̀ lonii ni awọn ilẹ ti ó wọ́pọ̀). Tabi awọn Kristian lè wadii lọwọ awọn alapata ti a bọwọ fun tabi oniṣowo ẹran kan. Bi wọn kò bá ní idi lati gbagbọ pe ẹran kan ni ẹ̀jẹ̀ ninu, wọn wulẹ lè rà á ki wọn sì jẹ ẹ́.

Paulu tun kọwe pe: “Ẹ jẹ ki ilọgbọn-ninu yin di mímọ̀ fun gbogbo eniyan.” (Filippi 4:5, NW) Iyẹn lè kan ọ̀ràn ẹran rírà. Kìí ṣe Ofin Israeli bẹẹ sì ni kìí ṣe àṣẹ ẹgbẹ oluṣakoso awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní ni ó tọka pe awọn eniyan Ọlọrun nilati lọ jinna ninu ṣiṣe iwadii nipa ẹran, àní ní didi olùjẹ ewébẹ̀ nikan bi iyemeji kekere bá wà nipa wíwà ẹ̀jẹ̀ ninu ẹran ti o wà larọọwọto.

Ọmọ Israeli kan ti ó jẹ́ ọdẹ ti ó pa ẹranko kan yoo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ silẹ. (Fiwe Deuteronomi 12:15, 16.) Bi idile rẹ̀ kò bá lè jẹ gbogbo ẹran naa tán, oun lè ta diẹ. Àní ninu òkú ẹranko kan ti a ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ daradara, iwọn ẹ̀jẹ̀ kekere yoo ṣẹku sinu ẹran naa, ṣugbọn kò sí ohunkohun ninu Bibeli ti o dabaa pe Ju kan ti ń ra ẹran nilati ṣe àṣerégèé ninu wiwadii iru awọn kulẹkulẹ bii iye iṣẹju ti ó wà laaarin pipa ati ríro ẹ̀jẹ̀ dànù, kaṣan ti ẹ̀jẹ̀ ń gbà jade tabi iṣan ti ẹ̀jẹ̀ ń gbà pada wo ni a gé lati jẹ́ ki ẹ̀jẹ̀ naa tú jade, ati bawo ni a ṣe so ẹran naa rọ̀ ati bi akoko sísorọ̀ naa ti gùn tó. Siwaju sii, ẹgbẹ oluṣakoso kò kọwe pe awọn Kristian nilati lo iṣọra ara-ọtọ ninu ọ̀ràn yii, bi ẹni pe wọn nilo òkodoro idahun ṣaaju ki wọn tó jẹ ẹran eyikeyii.

Ni ọpọ ilẹ lonii, ofin, aṣa, tabi aṣa isin ni pe awọn ẹran ti a pa (ayafi bii awọn ṣiṣajeji, bii sọ́sééjì ẹlẹ́jẹ̀) gbọdọ jẹ lati inu awọn ẹranko ti a gbọdọ ro ẹ̀jẹ̀ wọn danu nigba ti a bá pa wọn. Nipa bayii, awọn Kristian ni awọn agbegbe wọnni kò nilati ṣaniyan nipa ọ̀nà ti a gbà ń pa ẹran tabi kun wọn. Ni èrò itumọ gbigbooro, wọn wulẹ lè ‘maa jẹ ẹran ti a ń tà ni ọjà, laibeere ohun kan,’ wọn sì lè ni ẹ̀rí-ọkàn jijagaara pe awọn ń fà sẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀.

Bi o ti wu ki o ri, lóòrèkóòrè awọn irohin ti ó tanmọ ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ títà fun lílò eyi ti ó ti daamu awọn Kristian kan ti wà. Awọn kan ni ile-iṣẹ ẹran kíkun ronu pe iwọn ẹ̀jẹ̀ pupọ lati inu awọn ẹranko ti a dúḿbú ni a lè kojọ fun lílò ti ó lọgbọn-ninu ati fun èrè, bii ninu ajilẹ tabi ninu ounjẹ ẹranko. Awọn oluṣewadii ti kẹkọọ boya iru awọn ẹ̀jẹ̀ bẹẹ (tabi awọn èròjà) ni a lè lò ninu awọn ẹran ti a ti kun. Awọn ile-iṣẹ kan tilẹ ti pese plasma ohun olómi, dídì, tabi oniyẹfun (tabi ohun inu sẹẹli ẹ̀jẹ̀ pupa ti a ti pa láwọ̀ dà) ti a lè fi dipo iwọn ẹran ninu awọn ohun amujade bii sọ́sééjì tabi awọn ounjẹ ti a ti gún mọ́ra. Awọn iwadii miiran ti kó afiyesi jọ sori lílo amujade iyẹfun ẹ̀jẹ̀ gẹgẹ bi afikun tabi lati mu omi ati ọ̀rá dì ninu ẹran ti a lọ̀, ninu awọn nǹkan yíyan, tabi ninu awọn ounjẹ ati ohun mímu miiran lati fi protein tabi iron kun un.

Bi o ti wu ki o ri, ó tun yẹ fun afiyesi pe, iru iwadii bẹẹ ti ń baa lọ fun ọpọ ẹwadun. Sibẹ, ó jọ pe ìlò iru awọn ohun amujade bẹẹ ti mọniwọn gidigidi, tabi ki o má tilẹ sí rárá, ni ọpọ awọn ilẹ paapaa. Apẹẹrẹ iru awọn irohin diẹ ṣeranwọ lati fi idi eyi hàn:

“Ẹ̀jẹ̀ jẹ́ orisun ounjẹ afaralokun ati iwọn protein ti ó gbeṣẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹ̀jẹ̀ ẹran maluu ni a ti lo ni iwọn kekere fun ìlò eniyan ni taarata nitori àwọ̀ lilagbara ati irisi itọwo rẹ̀.”—Journal of Food Science, Idipọ 55, Nọmba 2, 1990.

“Awọn protein ninu plasma ẹ̀jẹ̀ ní awọn animọ wiwulo bii yíyọ́ lọna giga, àìleèdìpọ̀ ati ìfàmọ́ alagbara sí omi . . . ti ìlò wọn ninu ounjẹ ṣiṣe sì mú anfaani giga lọwọ. Bi o ti wu ki o ri, kò sí ọ̀nà gbigbeṣẹ kan lati sọ plasma di mímọ́, ni pataki lẹhin sísọ ọ́ di gbígbẹ, ni a ti fidii rẹ̀ mulẹ ni Japan.”—Journal of Food Science, Idipọ 56, Nọmba 1, 1991.

Awọn Kristian kan lẹẹkọọkan maa ń ṣayẹwo lébẹ́ẹ̀lì ti ó wà lara ohun ti a kó ounjẹ si, niwọn bi ọpọlọpọ ijọba ti beere pe ki wọn ṣe akọsilẹ eroja. Wọn sì lè yàn lati ṣe bẹẹ deedee pẹlu ohun amujade eyikeyii ti wọn lè ni idi lati gbagbọ pe ó ní ẹ̀jẹ̀ ninu. Nitootọ, yoo jẹ́ ohun ti ó tọ́, lati yẹra fun ohun amujade ti ó ni akọsilẹ awọn nǹkan bii ẹ̀jẹ̀, plasma ẹ̀jẹ̀, plasma, globin (tabi globulin) protein, tabi hemoglobin (tabi globin) iron. Isọfunni nipa ọjà títà lati ile-iṣẹ kan ni Europe ninu pápá yii gbà pe: “Isọfunni nipa ìlò globin gẹgẹ bi eroja ni a gbọdọ kọ sara ibi ti a di ounjẹ naa sí ni ọ̀nà ti ó fi jẹ́ pe aláràlò naa ni a kò ṣì lọna nipa iniyelori ati ohun ti ounjẹ naa ní ninu.”

Bi o ti wu ki o ri, àní nipa ṣiṣayẹwo lébẹ́ẹ̀lì tabi ṣiṣewadii lọwọ awọn alapata, ilọgbọn-ninu ni a nilo. Kìí wa ṣe bii ẹni pe Kristian kọọkan jakejado ayé gbọdọ kẹkọọ lébẹ́ẹ̀lì ati awọn èròjà ara ohun ti a fi pọ́n ounjẹ tabi gbọdọ fi ọ̀rọ̀ wá awọn oṣiṣẹ ile àrójẹ tabi ile-ounjẹ lẹnu wò. Kristian kan lè kọkọ beere lọwọ araarẹ pe, ‘Ẹ̀rí ti ó fidii mulẹ eyikeyii ha wà pe ẹ̀jẹ̀ ati awọn èròjà rẹ̀ ni a ń lò ninu awọn èròjà ounjẹ ni agbegbe tabi orilẹ-ede yii bi?’ Ni ibi pupọ idahun naa jẹ́ bẹẹkọ. Nitori naa, ọpọ awọn Kristian ti dórí ipinnu naa pe awọn kì yoo dari ọpọ akoko ati afiyesi sori ṣiṣayẹwo awọn ṣiṣeeṣe ti kò múnádóko bẹẹ. Ẹnikan ti kò bá nimọlara lọna yii gbọdọ huwa ni ibamu pẹlu ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀, laiṣedajọ awọn ẹlomiran ti wọn lè yanju ọ̀ràn naa ni ọ̀nà miiran ṣugbọn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn rere niwaju Ọlọrun.—Romu 14:2-4, 12.

Àní bi awọn ounjẹ amujade ti ó ni ẹ̀jẹ̀ ninu bá tilẹ lè di ṣiṣe, ó lè jẹ́ pe eyi ni a kìí ṣe lọna gbigbooro nitori iye owó, ofin, tabi awọn kókó abajọ miiran. Fun apẹẹrẹ, Food Processing (September 1991) ṣakiyesi pe: “Fun awọn wọnni ti ń kun ẹran ti wọn ni iṣoro eyikeyii pẹlu ẹran maluu ti a fi plasma olomi si ti kò tó ipin kan ninu ọgọrun-un, eyi ti o wà ninu adapọ (ègé ẹran pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ti wọn ti ṣetan) naa, apopọ miiran ti a yàn dipo yoo fi àgbájọ omi kíkan protein rọpo rẹ̀ a sì lè tẹwọgba a gẹgẹ bi ounjẹ ti o dara.”

Ó yẹ ki a tẹnumọ ọn pe ofin, aṣa, tabi yíyàn ni ọpọlọpọ ilẹ jẹ́ iru ti pe ẹ̀jẹ̀ ni a nilati ro danu kuro ninu ẹranko ti a dúḿbú ati pe iru ẹ̀jẹ̀ bẹẹ ni a kò lò ninu awọn amujade ounjẹ miiran. Bi kò bá sí idi ti o fẹsẹmulẹ lati ronu pe ipo ọ̀ràn naa yatọ ni adugbo tabi pe iyipada pataki kan ti ṣẹlẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, awọn Kristian gbọdọ ṣọra fun didi ẹni ti a kó idaamu bá nipasẹ iṣeeṣe tabi àhesọ ọ̀rọ̀ lasan. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ó bá daju tabi ti ṣiṣeeṣe naa bá ga pe ẹ̀jẹ̀ ni a ń lò lọna gbigbooro—boya ninu ounjẹ tabi ninu itọju iṣegun—a gbọdọ pinnu lati ṣegbọran si aṣẹ Ọlọrun lati fà sẹhin kuro ninu ẹ̀jẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́