ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/1 ojú ìwé 3-4
  • Ojú Wo Ni O Fi Ń wo Ẹ̀ṣẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Wo Ni O Fi Ń wo Ẹ̀ṣẹ̀?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Tí Ń Pòórá Nipa Ẹ̀ṣẹ̀ ni Iwọ-oorun
  • Ayé kan Laisi Ẹ̀ṣẹ̀—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìgbà Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Ní Sí Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kí Ló Mú Kí Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀ṣẹ̀ Yí Pa Dà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/1 ojú ìwé 3-4

Ojú Wo Ni O Fi Ń wo Ẹ̀ṣẹ̀?

“ÈÉṢE ti oun fi sábà maa ń beere fun idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ninu adura?” ni iyawo-ile kan tí ń ṣe ikẹkọọ Bibeli pẹlu ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣàròyé. “Ṣe ni ó ń dún bi ẹni pe mo jẹ́ ọ̀daràn.” Gan-an gẹgẹ bii ti obinrin yii, ọpọlọpọ lonii kò nimọlara awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ayafi bi wọn bá ti dá ọ̀ràn kan.

Eyi ni pataki jẹ́ otitọ ni ilẹ Gabasi, nibi ti awọn eniyan kò ti ní èrò nipa ẹṣẹ ti a jogúnbá lọna aṣa atọwọdọwọ gẹgẹ bi a ṣe fi kọni ninu awọn isin Ju-oun-Kristian. (Genesisi 3:1-5, 16-19; Romu 5:12) Fun apẹẹrẹ, awọn onisin Shinto mọ ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹgbin ti a lè rọra nù kuro nipa fífì sọ́tùn-ún-sósì igi alufaa kan, ti a di yẹtuyẹtu bébà tabi òwú mọ ṣonṣo ori rẹ̀. Ninu ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan yii ironupiwada kankan ni a ko beere fun lori ẹṣẹ ti ẹnikan ti dá. Eeṣe? Kodansha Encyclopedia of Japan ṣalaye pe, “Kìí ṣe awọn ìwà ibi nikan, bikoṣe awọn àjálù-ibi àdánidá tí kò ṣeé darí pẹlu, ni a pè ní tsumi [ẹ̀ṣẹ̀].” Awọn àdánù àdánidá, tsumi ti a kò lè kà sí awọn eniyan lọ́rùn, ni a kà sí ẹ̀ṣẹ̀ tí awọn ààtò-ìsìn ìsọdimímọ́ kìí jẹ́ ki ó ṣẹlẹ.

Eyi ṣamọna si ironu naa pe ẹ̀ṣẹ̀ eyikeyii, àní awọn ìwà buburu ti a mọọmọ hù paapaa (ayafi iwa-ọdaran ti ó yẹ́ fun ijiya labẹ ofin) ni a lè nù kuro nipasẹ awọn ààtò-ìsìn ìsọdimímọ́. Labẹ akori naa “Pẹ́pẹ́fúrú-ìsìn ti Ìwẹ̀nùmọ́ Oṣelu ni Japan,” The New York Times tọka si iru oju-iwoye bẹẹ ó sì ṣalaye pe awọn oṣelu ni Japan ti wọn ti lọwọ ninu láìfí atiniloju ka araawọn sí ẹni ti a ti “sọ di mímọ́” nigba ti awọn olùdìbò bá tún wọn yàn. Nipa bayii, kò sí àtúnṣe gidi kankan ti a ṣe, iru awọn láìfí atiniloju kan-naa sì lè pada wáyé.

Awọn onisin Buddha ti wọn gbagbọ ninu samsara, tabi ìtúnbí, ati ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Karma ní oju-iwoye kan ti ó yatọ. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣalaye pe, “ni ibamu pẹlu ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ karman, ìwà rere ń mú iyọrisi onidunnu ati alayọ wá ó sì maa ń muni fẹ́ lati huwa rere bakan-naa, nigba ti iwa buburu ń mú iyọrisi buburu wá ti ó sì maa ń muni fẹ́ lati huwa ibi leralera.” Ni èdè miiran, iwa ẹ̀ṣẹ̀ ń so eso buburu. Ẹ̀kọ́ Karma ní isopọ timọtimọ pẹlu ẹ̀kọ́ ìtúnbí, niwọn bi a ti sọ pe awọn Karma kan ń so eso ninu iwalaaye ọjọ-iwaju kan ti ó jìnnàréré si akoko iwalaaye ninu eyi ti a hu ìwà naa.

Bawo ni ẹ̀kọ́ yii ṣe nipa lori awọn ti wọn gbà á gbọ́? Obinrin onisin Buddha kan ti ó fi otitọ-inu gbagbọ ninu Karma sọ pe: “Mo ronu pe kò bọ́gbọ́n mu lati wá jiya fun ohun kan ti a bí mi mọ́ ṣugbọn ti emi kò mọ ohun kan nipa rẹ̀. Mo nilati gbà á gẹgẹ bii kádàrá mi. Kikọrin ewì Buddha ati gbigbiyanju kára lati gbé ìgbé-ayé rere kò tán awọn iṣoro mi. Mo di òṣónú ati aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ti ó ń ráhùn ni gbogbo ìgbà.” Ẹ̀kọ́ isin Buddha nipa iyọrisi awọn ìwà ibi mú ki o maa gbé pẹlu imọlara ti jíjẹ́ aláìníláárí.

Confucianism, isin ìhà Ila-oorun miiran, kọni ni ọ̀nà ọ̀tọ̀ lati bojuto ìwà ibi eniyan. Gẹgẹ bi Hsün-tzu, ọ̀kan ninu awọn ọlọgbọn-imọ-ọran ńlá mẹta ti Confucius ti sọ, ìwà-ẹ̀dá eniyan jẹ́ ibi ó sì ni itẹsi lati jẹ́ onimọtara-ẹni-nikan. Ki a baa lè pa ìwà-létòlétò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà mọ́ laaarin awọn eniyan ti wọn ni itẹsi ti ó kún fun ẹ̀ṣẹ̀, ó tẹnumọ ijẹpataki li, eyi ti ó tumọsi ìwà-ìmẹ̀tọ́-mẹ̀yẹ, ìwà-inúrere, ati ìwà-létòlétò awọn nǹkan. Meng-tzu, ọlọgbọn-imọ-ọran Confucius miiran, bi o tilẹ jẹ pe ó ń sọ oju-iwoye odikeji nipa ìwà-ẹ̀dá eniyan, mọ̀ nipa wíwà iṣoro ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ati, ní fífọkàntán ìwà-ẹ̀dá eniyan lati jẹ́ rere, ó gbarale ìmúsunwọ̀nsii ara-ẹni fun ojutuu naa. Eyiowu ki o ṣe ninu ọ̀nà mejeeji, awọn ọlọgbọn-imọ-ọran Confucius kọni ni ijẹpataki ẹkọ-iwe ati ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lati lè bá ẹ̀ṣẹ̀ jà ninu ayé. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹ̀kọ́ wọn fohunṣọkan lori ìpọndandan li, èrò wọn nipa ẹ̀ṣẹ̀ ati ibi kò ṣe kedere rárá.—Fiwe Orin Dafidi 14:3; 51:5.

Èrò Tí Ń Pòórá Nipa Ẹ̀ṣẹ̀ ni Iwọ-oorun

Ni Iwọ-oorun, oju-iwoye nipa ẹ̀ṣẹ̀ ni àṣà atọwọdọwọ ti mu ki o jagaara, ọpọ julọ eniyan sì ti gbà pe ẹ̀ṣẹ̀ wà ati pe a gbọdọ yẹra fun un. Bi o ti wu ki o ri, iṣarasihuwa iha Iwọ-oorun si ẹ̀ṣẹ̀ ti ń yipada. Ọpọlọpọ pa gbogbo imọlara nipa ẹ̀ṣẹ̀ tì, ní lilẹ àmì “aṣiṣe ìpẹ̀gàn ara-ẹni,” ohun kan ti a nilati yẹra fun mọ́ ara ẹ̀rí-ọkàn. Ni ohun ti ó ju 40 ọdun lọ sẹhin, Pope Pius XII kédàárò pe: “Ẹ̀ṣẹ̀ ọrundun yii ni ipadanu gbogbo èrò nipa ẹ̀ṣẹ̀.” Gẹgẹ bi iwadii kiri kan ti a tẹjade ninu iwe-irohin ọsọọsẹ ti Katoliki kan Le Pèlerin ti wi, àgbàyanu ipin 90 ninu ọgọrun-un ninu awọn olùgbé France, nibi ti ọpọ julọ eniyan ti sọ pe onisin Roman Katoliki ni awọn, ni kò gbagbọ ninu ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Nitootọ, ní Ila-oorun ati ní Iwọ-oorun, ọpọ julọ eniyan ni ó jọbi ẹni ti ń gbé ninu ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn onígbẹdẹmukẹ nisinsinyi laijẹ ẹni ti a kó idaamu bá nipa imọlara ẹ̀ṣẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn ha tumọsi pe ẹ̀ṣẹ̀ kò sí rárá ni bi? Ó ha lè jẹ́ ohun ti kò lewu ninu fun wa lati ṣàìnáání rẹ̀ bi? Ẹ̀ṣẹ̀ yoo ha jẹ́ pòórá bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́