ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 7/15 ojú ìwé 4-7
  • Ìgbà Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Ní Sí Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Ní Sí Mọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ènìyàn—A Dá A Láìlẹ́ṣẹ̀
  • Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀
  • Ẹ̀rí Ọkàn ‘Ń Fẹ̀sùn Kanni’ Tàbí Ó ‘Ń Gbeni Lẹ́yìn’
  • Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀—Lọ́nà Wo?
  • Ohun Tí Ìràpadà Kristi Lè Ṣe fún Wa
  • Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ayé kan Laisi Ẹ̀ṣẹ̀—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 7/15 ojú ìwé 4-7

Ìgbà Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Ní Sí Mọ́

“A HA bí wa sínú ẹ̀ṣẹ̀ bí?” Ìbéèrè yẹn dá akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó ti gboyè jáde ní United States láàmú, kété lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí ẹlẹ́sìn Híńdù ni tẹ́lẹ̀, èrò nípa ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ṣàjèjì sí i. Ó ronú pé, ṣùgbọ́n bí ẹ̀ṣẹ̀ bá jẹ́ àjogúnbá ní tòótọ́, sísọ pé ẹ̀ṣẹ̀ kò sí tàbí ṣíṣàìgbà pé ó wà ní ti gidi kò ní mọ́gbọ́n dání. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yí?

Bí ó bá jẹ́ àjogúnbá, ẹ̀ṣẹ̀ ni láti ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. A ha dá ọkùnrin àkọ́kọ́ ní ènìyàn burúkú bí, tí ó fi tàtaré ìwà ibi sí àwọn ọmọ rẹ̀? Àbí ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni àbùkù náà jẹ yọ? Ìgbà wo gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀? Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí ẹ̀ṣẹ̀ bá jẹ́ ohun búburú kan, tàbí ìlànà burúkú kan tí ó wà lóde ara, a ha lè retí láti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ láé bí?

Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Híńdù, ìyà àti ibi jẹ́ ohun tí ó ń bá ìṣẹ̀dá rìn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú ẹ̀sìn Híńdù sọ pé: “Ìyà [tàbí ibi], gẹ́gẹ́ bí àrùn làkúrègbé tí kì í lọ bọ̀rọ̀, wulẹ̀ máa ń lọ láti ibì kan sì ibòmíràn ni, a kò sì lè mú un kúrò pátápátá.” Kò sí àní-àní pé ibi ti di apá kan ayé aráyé jálẹ̀ ìtàn. Bí ó bá ti wà ṣáájú àkọsílẹ̀ ìtàn ènìyàn, àwọn ìdáhùn tí ó ṣeé gbára lé nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ wá láti orísun kan tí ó ga ju ènìyàn lọ. Àwọn ìdáhùn náà gbọ́dọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 36:9.

Ènìyàn—A Dá A Láìlẹ́ṣẹ̀

Ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Nikhilananda, tí ó tún jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù, gbà pé àkàwé lásán ni àlàyé tí a ṣe nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn nínú àwọn Veda jẹ́. Bákan náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀sìn Ìlà Oòrùn ayé pèsè kìkì àlàyé onítàn àròsọ lásán nípa ìṣẹ̀dá. Síbẹ̀, àwọn ìdí tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ó sì bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu wà fún gbígba ohun tí ó sọ nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá ọkùnrin àkọ́kọ́ gbọ́.a Orí rẹ̀ àkọ́kọ́ pàá sọ pé: “Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; àti akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

Kí ni ó túmọ̀ sí láti dáni “ní àwòrán Ọlọ́run”? Ohun tí ó túmọ̀ sí rèé: A dá ènìyàn ní jíjọ Ọlọ́run, ní ti pé ó ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run—irú bí ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́—tí ó mú kí ó yàtọ̀ pátápátá sí ẹranko. (Fi wé Kólósè 3:9, 10.) Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí fún un ní agbára láti yàn láti ṣe rere tàbí búburú, ní mímú kí ó jẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú ọkùnrin àkọ́kọ́, kò sí ibi tàbí ìyà nínú ìgbésí ayé rẹ̀, nígbà tí a dá a.

Ọkùnrin náà, Ádámù, ni Jèhófà Ọlọ́run fún ní àṣẹ yìí: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ kí ó máa jẹ: ṣùgbọ́n nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú nì, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀: nítorí pé ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀ kíkú ni ìwọ óò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ní yíyàn láti ṣègbọràn, Ádámù àti aya rẹ̀, Éfà, lè mú ìyìn àti ọlá wá fún Ẹlẹ́dàá wọn, kí wọ́n sì wà láìlẹ́ṣẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ṣíṣàìgbọràn yóò fi hàn pé wọ́n kùnà láti kúnjú ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé ti Ọlọ́run, yóò sì sọ wọn di aláìpé—ẹlẹ́ṣẹ̀.

A kò dá Ádámù àti Éfà ní ẹ̀dá ọ̀run. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní ìwọ̀n ànímọ́ díẹ̀ tí ó jẹ́ ti ọ̀run àti agbára láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà híhù. Nítorí tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹni pípé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Diutarónómì 32:4) Dídá tí a dá wọn kò ba ìṣọ̀kan tí ó wà láàárín Ọlọ́run àti àgbáálá ayé fún ọ̀pọ̀ sànmánì ṣáájú àkókò náà jẹ́. Nígbà náà, báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀ṣẹ̀

Ilẹ̀ ọba ẹ̀mí ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ṣáájú kí a tó dá ilẹ̀ ayé àti ènìyàn, Ọlọ́run ti dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóye—àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 1:6; 2:1; 38:4-7; Kólósè 1:15-17) Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí gbé ẹwà tí ó ní àti òye rẹ̀ gẹ̀gẹ̀ gan-an. (Fi wé Ìsíkẹ́ẹ̀lì 28:13-15.) Láti inú ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà láti bímọ, áńgẹ́lì yí lè rí i pé láìpẹ́, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò kún fún àwọn olódodo ènìyàn, tí gbogbo wọn ń jọ́sìn Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ń fẹ́ gba ìjọsìn wọn fún ara rẹ̀. (Mátíù 4:9, 10) Ríronú ṣáá lórí ìfẹ́ ọkàn yí sún un láti gbé ìgbésẹ̀ tí ó lòdì.—Jákọ́bù 1:14, 15.

Ní bíbá Éfà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ejò kan, áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà wí pé nípa kíka èso igi ìmọ̀ rere àti búburú náà léèwọ̀, Ọlọ́run ń fawọ́ ìmọ̀ tí ó yẹ kí obìnrin náà ní sẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Sísọ ìyẹn jẹ́ pípa irọ́ tí ó fi ẹ̀mí ìkórìíra hàn—ìwà ẹ̀ṣẹ̀ kan. Nípa píparọ́ yìí, áńgẹ́lì náà sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí, ó di ẹni tí a ń pè ní Èṣù, abanijẹ́, àti Sátánì, alátakò Ọlọ́run.—Ìṣípayá 12:9.

Ìjiyàn ayíniléròpadà tí Sátánì ṣe ní ipa búburú lórí Éfà. Ní gbígbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ Adánniwò náà, ó yọ̀ǹda kí a tan òun jẹ, ó sì gbà láti jẹ díẹ̀ nínú èso igi tí a kà léèwọ̀ náà. Ọkọ rẹ̀, Ádámù, dara pọ̀ mọ́ ọn nínú jíjẹ èso náà, àwọn méjèèjì sì tipa báyìí di ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6; Tímótì Kíní 2:14) Ó ṣe kedere pé, nípa yíyàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kùnà láti dé ojú ìlà ìjẹ́pípé, wọ́n sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.

Àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ńkọ́? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ inú ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Òfin àjogúnbá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni pẹrẹwu. Ádámù kò lè tàtaré ohun tí kò ní sí àwọn ọmọ rẹ̀. (Jóòbù 14:4) Níwọ̀n bí wọ́n ti pàdánù ìjẹ́pípé, tọkọtaya àkọ́kọ́ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kí wọ́n tó bí àwọn ọmọ wọn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, gbogbo wa pátá—láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀—ti jogún ẹ̀ṣẹ̀. (Orin Dáfídì 51:5 Róòmù 3:23) Ẹ̀wẹ̀, kò sí ohun mìíràn tí ẹ̀ṣẹ̀ mú wá ju ibi àti ìyà lọ. Ní àfikún sí i, nítorí bẹ́ẹ̀, a ń darúgbó, a sì ń kú, “nítorí owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.”—Róòmù 6:23.

Ẹ̀rí Ọkàn ‘Ń Fẹ̀sùn Kanni’ Tàbí Ó ‘Ń Gbeni Lẹ́yìn’

Tún gbé ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ ní lórí ìwà tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹ̀ wò. Wọ́n fi nǹkan bo apá kan nínú ara wọn, wọ́n sì gbìyànjú láti fi ara wọn pa mọ́ fún Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:7, 8) Ẹ̀ṣẹ̀ tipa báyìí mú kí wọ́n mọ̀ pé àwọn jẹ̀bi, kí wọ́n ṣàníyàn, kí ojú sì tì wọ́n. Àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí kò ṣàjèjì rárá sí aráyé lónìí.

Ta ni kò ní ìmọ̀lára tí kò bára dé rí, nítorí àìfi inú rere hàn sí ẹnì kan tí ó ṣaláìní, tàbí ta ni kò banú jẹ́ rí, nítorí sísọ ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde rárá? (Jákọ́bù 4:17) Èé ṣe tí a fi ń ní irú ìmọ̀lára tí ń kó ìdààmú báni bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ‘a kọ òfin sínú ọkàn àyà wa.’ Àyàfi bí ẹ̀rí ọkàn wa bá ti yigbì, rírú òfin yẹn lọ́nàkọnà ń dá rúgúdù síni lọ́kàn. Bí ẹ̀rí ọkàn ṣe ‘ń fẹ̀sùn kàn wá’ tàbí ‘gbè wá lẹ́yìn’ nìyẹn. (Róòmù 2:15; Tímótì Kíní 4:2; Títù 1:15) Yálà a gbà bẹ́ẹ̀ tàbí a kò gbà, a máa ń mọ̀ pé a ti hùwà àìtọ́, a máa ń mọ̀ pé a ti dẹ́ṣẹ̀!

Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun ní ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀. Ó jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí mo bá dàníyàn láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. Ní ti gidi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí nínú àwọn ẹ̀yà ara mi òfin mìíràn tí ń bá òfin èrò inú mi jagun tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ta ni yóò gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?”—Róòmù 7:21-24.

Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀—Lọ́nà Wo?

Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Òmìnira, nínú ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀sìn Híńdù, jẹ́ bíbọ́ lọ́wọ́ àtúnbí àti àtúnkú.” Gẹ́gẹ́ bí ojútùú, ẹ̀sìn Búdà bákan náà tọ́ka sí Nirvana—ipò gbígbàgbé ohunkóhun tí ó lè ti òde ara wá. Nítorí tí kò lóye èròǹgbà ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, ẹ̀sìn Híńdù ṣèlérí kìkì jíjàjàbọ́ lọ́wọ́ wíwà láàyè nínú ẹran ara.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀nà tí Bíbélì gbà ń sọni dòmìnira ń yọrí sí mímú ipò ẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní ti gidi. Lẹ́yìn bíbéèrè bí a ṣe lè gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fèsì pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ní ń gbani sílẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.

Gẹ́gẹ́ bí Ìhìn Rere Mátíù ti sọ, “Ọmọkùnrin ènìyàn,” Jésù Kristi, wá “kí ó . . . fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Tímótì Kíní 2:6, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Jésù “fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà kan tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” Ọ̀rọ̀ náà “ìràpadà” dúró fún sísan owó fún ríra àwọn tí ó wà nígbèkùn pa dà. Òtítọ́ náà pé ó jẹ́ ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí tẹnu mọ́ agbára tí iye owó náà ní láti mú kí òṣùnwọ̀n òfin ìdájọ́ òdodo náà wà déédéé. Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè ka ikú ọkùnrin kan ṣoṣo sí “ìràpadà kan tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn”?

Ádámù ta gbogbo aráyé, títí kan àwa gan-an, sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Iye owó, tàbí ìyà, tí ó san ni ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé. Láti kúnjú èyí, a gbọ́dọ̀ pèsè ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé mìíràn—ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí. (Ẹ́kísódù 21:23; Diutarónómì 19:21; Róòmù 5:18, 19) Níwọ̀n bí kò ti sí ènìyàn aláìpé kankan tí ó lè pèsè ìràpadà yí, Ọlọ́run, nínú ọgbọ́n rẹ̀ tí kò lópin, ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti lè kúrò nínú ipò ìdààmú wọ̀nyí. (Orin Dáfídì 49:6, 7) Láti ọ̀run, ó tàtaré ìwàláàyè pípé ti Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá kan lórí ilẹ̀ ayé, ní mímú kí a bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé.—Lúùkù 1:30-38; Jòhánù 3:16-18.

Láti lè ṣàṣeparí iṣẹ́ ríra aráyé pa dà, Jésù ní láti ní àkọsílẹ̀ tí kò lábààwọ́n jálẹ̀ àkókò tí yóò lò lórí ilẹ̀ ayé. Èyí sì ni ohun tí ó ṣe. Lẹ́yìn náà, ó kú ikú ìrúbọ. Lọ́nà yí, Jésù rí i dájú pé ìtóye ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé kan—tirẹ̀ fúnra rẹ̀—yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti san gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún dídá aráyé nídè.—Kọ́ríńtì Kejì 5:14; Pétérù Kíní 1:18, 19.

Ohun Tí Ìràpadà Kristi Lè Ṣe fún Wa

Ẹbọ ìràpadà Jésù lè ṣe wá láǹfààní nísinsìnyí pàápàá. Nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, a lè gbádùn ìdúró mímọ́ níwájú Ọlọ́run, a sì lè wá sábẹ́ ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Jèhófà. (Ìṣe 10:43; Róòmù 3:21-24) Kàkà tí ẹ̀bi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá yóò fi bò wá mọ́lẹ̀, a lè tọrọ àforíjì ní fàlàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run lórí ìpìlẹ̀ ìràpadà náà.—Aísáyà 1:18; Éfésù 1:7; Jòhánù Kíní 2:1, 2.

Ní ọjọ́ iwájú, ìràpadà náà yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti wo aráyé sàn pátápátá kúrò nínú ipò àìsàn tí ó wà, tí ẹ̀ṣẹ̀ mú wá. Ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe “odò omi ìyè” tí ń ṣàn wá láti orí ìtẹ́ Ọlọ́run. Àwọn igi eléso rẹpẹtẹ tí ó ní ewé “fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn” wà létí bèbè odò náà. (Ìṣípayá 22:1, 2) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, níhìn-ín, Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìpèsè àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe láti dá aráyé sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú títí láé lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù.

Àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ ti inú ìwé Ìṣípayá yóò ní ìmúṣẹ láìpẹ́. (Ìṣípayá 22:6, 7) Nígbà náà, gbogbo àwọn ọlọ́kàn títọ́ yóò di ẹni pípé, tí a ti ‘dá sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ìṣọdẹrú fún ìdibàjẹ́.’ (Róòmù 8:20, 21) Kò ha yẹ kí èyí sún wa láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀ adúróṣinṣin, Jésù Kristi, tí ó di ìràpadà náà bí?—Jòhánù 17:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ádámù mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí aráyé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ẹbọ ìràpadà Jésù mú bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́