Awọn Irisi-Iran Lati Ilẹ Ileri
Lílọ Si Ṣiloh—Awọn Ọmọ Rere ati Buburu
NIGBA ti o bá ronu nipa awọn ilu-nla, ilu, tabi agbegbe Ilẹ Ileri, ǹjẹ́ awọn ọkunrin ati obinrin ṣàràkí ṣàràkí kankan ha wá sinu ọkàn rẹ bi? Boya bẹẹ ni, nitori pe ọpọ julọ ninu awọn akọsilẹ Bibeli ní awọn agbalagba ninu. Ṣugbọn ki ni nipa awọn ọmọde nigba naa lọhun-un? Iwọ ha finuwoye wíwà wọn ninu awọn irisi-iran naa bi?
Iran ti o wà loke yii lè ràn wá lọwọ lati kó afiyesi jọ sori awọn akọsilẹ ti ó ní awọn ọ̀dọ́ ninu, diẹ ninu awọn ti wọn jẹ́ apẹẹrẹ rere fun awọn Kristian miiran ati awọn miiran ti wọn jẹ́ apẹẹrẹ ikilọ. Òkè rìbìtì ti ó wà laaarin ni ó jọbi pe ó jẹ́ ọgangan ibi ti Ṣiloh igbaani wà.a
Ó ṣeeṣe ki o ranti pe nigba ti Israeli wọnu Ilẹ Ileri, wọn kọkọ gbé àgọ́-ìsìn Ọlọrun sí Gilgali lẹbaa Jeriko. (Joṣua 4:19) Ṣugbọn nigba ti a ń pín ilẹ naa, àgọ́ mimọ yii—ibi ti ijọsin Israeli korijọ si—ni a ṣí kuro nihin-in lọ si Ṣiloh. (Joṣua 18:1) Eyi jẹ́ nǹkan bii 20 ibusọ ní ariwa Jerusalemu ní ẹkùn olókè ti Efraimu. Awọn ọkunrin ati obinrin jakejako Israeli wá mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ si Ṣiloh; awujọ eniyan lè korajọ ninu afonifoji ti ó wà ni guusu ibi ti àgọ́-ìsìn naa ṣeeṣe ki o fidikalẹ sí. (Joṣua 22:12) Iwọ ha lè finu yaworan awọn ọmọde ti wọn ń wá sihin-in bi?
Awọn kan ṣe bẹẹ. Apẹẹrẹ ti o pàfiyèsí julọ ti a nilati mọ nipa rẹ̀ ni Samueli ọ̀dọ́. Awọn òbí rẹ̀, Elkana ati Hanna, gbé ni ilu kan kọja awọn òkè naa sí iwọ-oorun. Lọdọọdun wọn ń rinrin-ajo wá sihin-in, boya ní mímú awọn ọmọ diẹ ti Elkana bí nipasẹ iyawo rẹ̀ keji dani. Nikẹhin Jehofa fi ọmọkunrin kan ti a pè ni Samueli, ta Hanna lọ́rẹ. Bi akoko ti ń lọ awọn òbí rẹ̀ mú un wa si Ṣiloh ki ó baa lè ṣiṣẹsin ninu àgọ́-ìsìn pẹlu olori alufaa Eli.—1 Samueli 1:1–2:11.
Ọmọdekunrin naa ní awọn iṣẹ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lati ṣe ninu ile Ọlọrun, ó sì ti nilati ni ọpọlọpọ anfaani lati fẹsẹ̀rìn lọ sori awọn oke ti ń bẹ nitosi. (1 Samueli 3:1, 15) Diẹ ninu wọn jẹ́ ilẹ oní pèpéle wọn sì kún fun igi olifi, gẹgẹ bi a ti rí i ninu aworan ti ó wà ní oju-iwe 9. Ṣakiyesi ilé-ìṣọ́nà olókùúta kekere naa. Awọn àgbẹ̀ tabi darandaran ti wọn wà ni àdádó lè ṣọ́nà lati ori iru ilé-ìṣọ́nà kan bẹẹ, ṣugbọn iwọ lè ronu nipa Samueli ọ̀dọ́ tí ń goke lọ lati lọ woran pẹlu. (Fiwe 2 Kronika 20:24.) Ibí yii yoo jẹ́ ọ̀gangan ojúùran didara lati ṣọ́ awọn ẹran ìgbẹ́.
Nigba naa lọhun-un, igi pọ ju ti isinsinyi lọ, àní awọn igbó ẹgàn nibi ti awọn ẹran ìgbẹ́ ti ń rìn fàlàlà. (Joṣua 17:15, 18) A mọ eyi lati inu iṣẹlẹ ìgbà laelae kan nigba ti Eliṣa ti di wolii Ọlọrun pataki. Eliṣa ń rìn bọ̀ lati Jeriko si Beteli, nitori naa ó wà ni agbegbe yii, nǹkan bii ibusọ mẹwaa sí guusu Ṣiloh. Ìkínikáàbọ̀ wo ni oun yoo rígbà lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan Beteli, ti ó ti di ìkóríta fun ijọsin ọmọ akọ maluu oniwura? (1 Ọba 12:27-33; 2 Ọba 10:29) Ó dabi ẹni pe awọn agbalagba jẹ́ adojú-ìjà-kọni sí wolii Jehofa, iṣarasihuwa wọn sì jọbi pé ó ti ran awọn ọmọ wọn.
Awọn Ọba Keji 2:23, 24 sọ fun wa pe àgbájọ awọn ọ̀dọ́ kan fi wolii Ọlọrun ṣe yẹ̀yẹ́ pe: “Goke lọ, apárí! goke lọ, apárí!” Ni idahunpada, Eliṣa “fi wọn bú ni orukọ Oluwa. Abo-beari meji sì jade lati inu igbo wá, wọn sì fà mejilelogoji ya ninu wọn.” Iru awọn beari aláwọ̀-ilẹ̀ ti Siria bẹẹ lè rorò nigba ti a bá gbejako wọn lojiji tabi nigba ti ó bá jọbi ẹni pe a halẹ̀ mọ awọn ọmọ wọn. (2 Samueli 17:8; Owe 17:12; 28:15) Ọlọrun lò wọn lati mú idajọ ododo atọrunwa ṣẹ lodisi awọn wọnni ti wọn ṣaika aṣoju rẹ̀ sí lọna buburu ti wọn sì tipa bẹẹ ṣaika Jehofa fúnraarẹ̀ sí.
Pe ọmọde kan lè pade iru ẹranko ẹhanna kan bẹẹ ni awọn òkè yika Ṣiloh nilati ràn wá lọwọ lati tubọ mọriri igbagbọ ti awọn òbí Samueli fihàn ninu mímú un wa lati ṣiṣẹsin ni àgọ́-ìsìn.
Olujọsin tootọ miiran ti fi iru igbagbọ ati ifọkansin kan-naa hàn ni iṣaaju—Onidajọ Jefta. Ó gbé ni ilu olókè ti Gileadi ni apá ila-oorun Jordani. Ó ní itara fun Jehofa lodisi awọn ará Ammoni ọ̀tá, Jefta jẹ́jẹ̀ẹ́ pe ohun akọkọ lati inu ile rẹ̀ ti ó bá jade wá lati pade oun ni oun yoo fi rubọ si Jehofa. Ọmọbinrin rẹ̀ wundia ni ó di ẹni yẹn. Nitori naa ó mú ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo lọ si ibùjọsìn ni Ṣiloh, nibi ti ó gbé ti ó sì fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa fun ọpọ ọdun.—Onidajọ 11:30-40.
Ifọkansin oloootọ tí Samueli ati ọmọbinrin Jefta fihàn ní agbegbe Ṣiloh jẹ́ iyatọ ifiwera rere dajudaju si apẹẹrẹ ti kò gbéniró ti 42 awọn pòkíì ọmọ ti wọn fi wolii Jehofa ṣẹlẹya ni ẹkùn yii kan-naa.—Fiwe 1 Korinti 10:6, 11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun aworan titobi, wo 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Safari Zoo, Ramat-Gan, Tel Aviv