ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/1 ojú ìwé 10-15
  • Ẹkọ-iwe ní Awọn Akoko Ti A Kọ Bibeli

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹkọ-iwe ní Awọn Akoko Ti A Kọ Bibeli
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹkọ-iwe Ti Baba Awọn Heberu
  • Ẹkọ-iwe ni Israeli
  • Awọn Ọ̀nà Ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́
  • Ètò Ẹ̀kọ́ Naa
  • Awọn Alufaa, Ọmọ Lefi, ati Wolii
  • Ẹkọ-iwe Lakooko Igbekun ati Lẹhin Rẹ̀
  • Ile-ẹkọ Awọn Rabbi
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ojú Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń wo Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
    Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
  • Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/1 ojú ìwé 10-15

Ẹkọ-iwe ní Awọn Akoko Ti A Kọ Bibeli

“Ki ẹyin ki ó sì maa fi wọn kọ́ awọn ọmọ yin.”—DEUTERONOMI 11:19.

1. Ki ni ó fihàn pe Jehofa ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹkọ-iwe awọn iranṣẹ rẹ̀?

JEHOFA ni Olùkọ́ni Ńlá naa. Oun kò tíì fi awọn iranṣẹ rẹ̀ silẹ sinu ipo àìmọ̀kan rí. Oun tí maa ń muratan nigba gbogbo lati ṣajọpin ìmọ̀ pẹlu wọn. Ó ń kọ́ wọn ni ifẹ-inu ati ọ̀nà rẹ̀. La àìmọye ẹgbẹrundun já Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀ wà ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí ń kẹkọọ nigba gbogbo gẹgẹ bi “ọ̀gá òṣìṣẹ́” Ọlọrun. (Owe 8:30, NW) Nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé Jesu sọ pe: “Bi Baba ti kọ́ mi, emi ń sọ nǹkan wọnyi.” (Johannu 8:28) Ní titọka si Ọlọrun gẹgẹ bi Olùkọ́ni Alailafiwe, Elihu beere pe: “Ta ni jẹ́ olùkọ́ni bi oun?” (Jobu 36:22) Wolii Isaiah sọ nipa Jehofa pé ó jẹ́ “Atobilọla Olùkọ́ni” fun awọn eniyan Rẹ̀, ó sì sọtẹlẹ pe: “A ó sì kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọ̀dọ̀ Oluwa wá; alaafia awọn ọmọ rẹ yoo sì pọ̀.” (Isaiah 30:20, NW; 54:13) Laiṣiyemeji, Jehofa nifẹẹ-ọkan pe ki awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ di awọn ti a là lóye ti a sì kọ́níwèé daradara.

Ẹkọ-iwe Ti Baba Awọn Heberu

2, 3. (a) Oju wo ni awọn baba awọn Heberu oluṣotitọ fi wo ẹkọ-iwe awọn ọmọ wọn, itọni wo sì ni Jehofa fifun Abrahamu? (b) Ète titobilọla wo ni ó wà lẹhin itọni naa pe ki Abrahamu kọ́ awọn ọmọ rẹ̀ níwèé?

2 Ọ̀kan lara awọn akanṣe ẹ̀tọ́ pataki ti olori idile ni akoko baba awọn Heberu ni kíkọ́ awọn ọmọ rẹ̀ ati agbo-ile rẹ̀. Fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ẹkọ-iwe awọn ọmọ wọn jẹ́ ojuṣe isin. Jehofa sọ nipa iranṣẹ rẹ̀ Abrahamu pe: “Mo mọ̀ ọ́n pe, oun ó fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ará ilé rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki wọn ki o maa pa ọ̀nà OLUWA mọ́ lati ṣe òdodo ati idajọ; ki OLUWA ki o lè mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun un.”—Genesisi 18:19.

3 Gbolohun-ọrọ atọrunwa yii fihàn pe Jehofa ka ẹkọ-iwe sí ohun ti o ṣe pataki gidi. Ọlọrun beere lọwọ Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu lati kọ́ agbo-ilé wọn ni awọn ọ̀nà ododo ati idajọ Rẹ̀ ki awọn iran ọjọ-ọla yẹn baa lè wà ni ipo lati pa ọ̀nà Jehofa mọ́. Nipa bayii, Jehofa yoo mú awọn ileri rẹ̀ nipa iru-ọmọ Abrahamu ati ibukun fun “gbogbo orilẹ-ede ayé” ṣẹ.—Genesisi 18:18; 22:17, 18.

Ẹkọ-iwe ni Israeli

4, 5. (a) Ki ni o ya eto-igbekalẹ ẹkọ-iwe ti Israeli sọtọ kuro lara ti awọn orilẹ-ede miiran? (b) Iyatọ pataki miiran wo ni a lapa-èrò rẹ̀ ninu iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica, ki ni ó sì daju pe ó dakun iyatọ yii?

4 Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pe: “Bibeli ni orisun pataki fun liloye ọ̀nà ìgbàkọ́ni níwèé ni Israeli igbaani.” Jehofa lo Mose gẹgẹ olukọ eniyan akọkọ fun Israeli. (Deuteronomi 1:3, 5; 4:5) Mose ta àtaré awọn ọ̀rọ̀ ti Jehofa fifun un. (Eksodu 24:3) Nitori naa, niti gasikiya, Ọlọrun ni Olùkọ́ni pataki fun Israeli. Eyi funraarẹ ya eto nipa ẹkọ-iwe Israeli sọtọ kuro lara ti awọn orilẹ-ede miiran.

5 Iwe itọkasi kan-naa yii fiyeni pe: “Ẹkọ-iwe giga tabi iwe kíkọ́ ni Mesopotamia ati Egipti jẹ́ bi aṣa a sì fimọ sọdọ ẹgbẹ́ awọn akọwe nikan, eyi ti kò jọbi ẹni pe ó rí bẹẹ ni Israeli. Iyatọ naa laisi iyemeji jẹ́ nitori rírọrùn ti eto lẹta alifabẹẹti tí awọn Heberu ń lò rọrùn. . . . Ijẹpataki ikọwe pẹlu lẹta alifabẹẹti fun ìtàn ẹkọ-iwe ni a kò gbọdọ gbójúfòdá. Ó mú ki wọn jáwọ́ lara aṣa-iṣẹdalẹ iwe kíkọ atọwọdọwọ ti Egipti, Mesopotamia, ati Kenani ẹgbẹrundun keji. Lati jẹ́ ẹni ti ó mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kìí tun ṣe animọ ti ó jẹ́ ti ẹgbẹ awọn ti ń fi iṣẹ akọwe ati alufaa ṣiṣẹṣe, ti wọn jafafa ninu eto lẹta ikọwe ti ọ̀nà ìgbàkọ̀wé awọn ara Mesopotamia igbaani ati ikọwe alaworan ti o ṣoro lati yeni mọ́.”

6. Ẹ̀rí Bibeli wo ni ó wà pe taarata lati ibẹrẹ ìtàn wọn, pe awọn ọmọ Israeli jẹ́ eniyan ti wọn mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà?

6 Bibeli pese ẹ̀rí pe awọn ọmọ Israeli jẹ́ awọn eniyan ti wọn mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Àní ṣaaju ki wọn tó wọ Ilẹ Ileri paapaa, a sọ fun wọn pe ki wọn kọ awọn ofin Jehofa sara ilẹkun ile wọn ati sara ẹnu ibode wọn. (Deuteronomi 6:1, 9; 11:20; 27:1-3) Nigba ti kò si iyemeji pe aṣẹ yii jẹ́ afiṣapẹẹrẹ, dajudaju kì yoo ti ní itumọ kankan fun eyi ti o wọpọ julọ ninu awọn ọmọ Israeli bi wọn kò bá mọ bi a ṣe ń kà ti a sì ń kọ iwe. Iwe Mimọ iru bii Joṣua 18:9 ati Onidajọ 8:14 fihàn pe awọn miiran yatọ si awọn aṣaaju bii Mose ati Joṣua mọ̀ bi a tií kọwe tipẹ́ ṣaaju ki a tó gbé eto ìjọba-ọba-aládé kalẹ ni Israeli.—Eksodu 34:27; Joṣua 24:26.

Awọn Ọ̀nà Ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́

7. (a) Gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi, ta ni ó fun awọn ọmọde ni Israeli ni ipilẹ ẹkọ-iwe wọn? (b) Isọfunni wo ni ọmọwe Bibeli Lede Faranse kan fifunni?

7 Ni Israeli, awọn ọmọde ni a ń kọ́ lati ìgbà kùtùkùtù ọjọ ayé lati ọ̀dọ̀ baba ati ìyá. (Deuteronomi 11:18, 19; Owe 1:8; 31:26) Ninu iwe atumọ-ede Faranse naa Dictionnaire de la Bible, ọmọwe Bibeli E. Mangenot kọwe pe: “Ní gbàrà ti ó bá ti lè sọrọ, ọmọ naa ń kọ́ awọn ọ̀rọ̀-àyọkà diẹ lati inu Ofin. Ìyá rẹ̀ yoo tún ẹsẹ kan sọ; nigba ti ó bá mọ̀ ọ́n, yoo fun un ni omiran. Lẹhin naa, apá ti a kọ ninu awọn ẹsẹ naa ti wọn ti lè kà ní àkọ́sórí ni wọn yoo fi si ọwọ́ awọn ọmọ naa. Nipa bayii, a la oju wọn si iwe kíkà, nigba ti wọn bá sì ti dagba sii, wọn lè maa ba itọni isin wọn lọ nipa kíkà ati rironu jinlẹ lori ofin Oluwa.”

8. (a) Ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ipilẹ wo ni a lò ni Israeli, ṣugbọn pẹlu àmì-ìdámọ̀ pataki wo? (b) Awọn aranṣe agbara iranti wo ni a lò?

8 Eyi tumọsi pe ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ipilẹ ti a lò ni kíkọ́ awọn nǹkan sori. Awọn nǹkan ti a kọ́ nipa awọn ofin Jehofa ati ibalo rẹ̀ pẹlu awọn eniyan ni ó nilati wọnu ọkan-aya ṣinṣin. (Deuteronomi 6:6, 7) Awọn ni a nilati ronu jinlẹ lé lori. (Orin Dafidi 77:11, 12) Lati ran tèwetàgbà lọwọ lati há nǹkan sori, oniruuru aranṣe agbara iranti ni a lò. Iwọnyi ní ninu awọn ọ̀rọ̀-alágbèékà lẹta alifabẹẹti, awọn ẹsẹ títẹ̀léra ninu Orin Dafidi ti ń bẹrẹ pẹlu lẹta ọtọọtọ, ni itotẹlera a b d Heberu (iru bii Owe 31:10-31); ìdúnjọra-ọ̀rọ̀ (awọn ọ̀rọ̀ onilẹta tabi dídún kan-naa); ati nọmba lílò, bi iru awọn ti a lò ninu apá ìlàjì keji Owe ori 30. Lọna ti ó fanilọkanmọra, Kalẹnda Geseri, ọ̀kan lara awọn apẹẹrẹ ikọwe Heberu igbaani, ni awọn ọmọwe kan ronu pe ó jẹ́ idanrawo àkọ́sórí ọmọ ile-ẹkọ kan.

Ètò Ẹ̀kọ́ Naa

9. (a) Ki ni apá pataki kan ninu itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọ fun awọn ọmọde ni Israeli? (b) Ki ni gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli kan sọ nipa ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti a ṣe ni isopọ pẹlu awọn ajọdun ọdọọdun?

9 Ẹkọ-iwe ni Israeli ni a kò fimọ sori kikẹkọọ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Kókó-ẹ̀kọ́ pataki kan ti a fikọni ni ìtàn. Ìkẹ́kọ̀ọ́ nipa awọn ohun agbayanu ti Jehofa ti ṣe ni ojurere si awọn eniyan rẹ̀ ni apa akọkọ ninu ètò-ẹ̀kọ́ naa. Awọn otitọ ninu ìtàn wọnyi ni a nilati fikọni lati ìran dé ìran. (Deuteronomi 4:9, 10; Orin Dafidi 78:1-7) Ayẹyẹ ajọdun ọdọọdun pese anfaani rere fun olori idile lati kọ́ awọn ọmọ rẹ̀. (Eksodu 13:14; Lefitiku 23:37-43) Ni isopọ pẹlu eyi iwe gbédègbẹ́yọ̀ Bibeli naa The International Standard Bible Encyclopedia sọ pe: “Nipasẹ itọni baba ninu ile ati awọn alaye rẹ̀ nipa ijẹpataki awọn ajọdun naa, ọmọ awọn Heberu ni a fi ọ̀nà tí Ọlọrun ti gbà fi Araarẹ̀ hàn fun wọn ni ìgbà ti ó ti kọja hàn, bi wọn ṣe nilati gbé nisinsinyi, ati awọn ileri Ọlọrun nipa ọjọ-ọla awọn eniyan Rẹ̀.”

10. Idanilẹkọọ iṣẹ ṣiṣe wo ni a fifun awọn ọdọmọbinrin? fun awọn ọdọmọkunrin?

10 Ẹkọ-iwe lati ọ̀dọ̀ awọn obi ní idanilẹkọọ iṣẹ ṣiṣe ninu. Awọn ọdọmọbinrin ni a kọ́ ni awọn iṣẹ inu ile. Akori ti ó kẹhin ninu Owe fihàn pe iwọnyi pọ̀ wọn sì jẹ́ oniruuru; wọn ní ninu rírànwùú, híhunṣọ, síseńjẹ, ṣíṣòwò, ati abojuto agbo-ile ni gbogbogboo. Awọn ọdọmọkunrin ni a sábà maa ń kọ́ ni iṣẹ ounjẹ-oojọ baba wọn, yala ninu iṣẹ ọ̀gbìn tabi awọn iṣẹ́-òwò tabi iṣẹ́-ọwọ́. Ni awọn akoko ẹhin ìgbà naa awọn rabbi Ju ni wọn kúndùn lati maa sọ pe: “Ẹni ti kò bá kọ́ ọmọ rẹ̀ ni iṣẹ́-òwò ti ó wúlò ń tọ́ ọ dàgbà lati di olè.”

11. Ki ni ó fi ète pataki ẹkọ-iwe ni Israeli hàn, ẹ̀kọ́ wo ni eyi sì ní ninu fun awọn ọ̀dọ́ lonii?

11 Bi awọn ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti a lò ni Israeli ti jinlẹ tó nipa tẹmi ni o ṣe kedere jalẹ iwe Owe. Ó fihàn pe ète naa ni lati kọ́ “alaimọkan” ni iru awọn nǹkan ti a gbega bii ọgbọ́n, ìbáwí, òye, ijinlẹ-oye, idajọ, ìgbọ́nféfé, ìmọ̀, ati agbara ìrònú—gbogbo eyi ninu “ibẹru Oluwa.” (Owe 1:1-7; 2:1-14) Ó tẹnumọ awọn isunniṣe ti o nilati sún ọkọọkan lara awọn iranṣẹ Ọlọrun lonii lati mú ẹkọ-iwe sunwọn sii lọkunrin tabi lobinrin.

Awọn Alufaa, Ọmọ Lefi, ati Wolii

12. Awọn wo yatọ si awọn òbí ni wọn kopa ninu kíkọ́ awọn eniyan Israeli, kí sì ni itumọ ipilẹ tí ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọ si “ofin” ní?

12 Nigba ti a ń pese ẹkọ-iwe pataki lati ọ̀dọ̀ awọn òbí, Jehofa kọ́ awọn eniyan rẹ̀ siwaju sii nipasẹ awọn alufaa, awọn ọmọ Lefi ti wọn kìí ṣe alufaa, ati awọn wolii. Ninu ibukun rẹ̀ ti ó gbẹhin lori ẹ̀yà Lefi, Mose sọ pe: “Wọn ó maa kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli ni ofin rẹ.” (Deuteronomi 33:8, 10) Lọna ti ó ṣe pataki, ọ̀rọ̀ naa “ofin” ni Heberu (toh·rahʹ) ni a mú jade lati inu gbongbo kan ti ó jẹ́ pe ọ̀rọ̀-ìṣe rẹ̀ tumọsi “lati fihàn,” “lati kọni,” “lati funni nitọọni.” Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pe: “Itumọ ọ̀rọ̀ naa [torah] nigba naa ni ‘ẹ̀kọ́,’ ‘ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́,’ tabi ‘itọni.’”

13. Eeṣe ti Ofin Israeli fi yatọ si awọn eto-igbekalẹ ofin ti awọn orilẹ-ede miiran?

13 Eyi pẹlu ya Israeli sọtọ kuro lara awọn orilẹ-ede miiran ati kuro lara awọn orilẹ-ede ode-oni paapaa. Awọn orilẹ-ede oṣelu lonii ní àgbájọ awọn ofin eyi ti awọn ara-ilu ni gbogbogboo mọ̀ iwọnba ráńpẹ́ ninu rẹ̀. Nigba ti awọn eniyan bá forigbari pẹlu ofin naa, wọn nilati san owo gegere fun awọn lọ́yà lati gbèjà wọn. Awọn ile-ẹkọ ofin wà fun awọn ògbóǹtarìgì. Sibẹ, ni Israeli Ofin jẹ́ ọ̀nà ti Ọlọrun ń gbà sọ fun awọn eniyan rẹ̀ bi ó ṣe fẹ́ ki wọn jọsin oun ki wọn sì gbé ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀. Laidabii awọn àkójọ ofin miiran, ó fi ifẹ fun Ọlọrun ati aladuugbo kun un. (Lefitiku 19:18; Deuteronomi 6:5) Ofin naa yatọ patapata si jíjẹ́ iwe-ofin alaimuniloriya kan. Ó pese ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́, ẹ̀kọ́, ati itọni ni ọ̀nà igbesi-aye ti a nilati kọ́.

14. Ki ni idi kan ti Jehofa fi kọ ipo alufaa awọn ọmọ Lefi silẹ? (Malaki 2:7, 8)

14 Nigba ti wọn jẹ́ oluṣotitọ, awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi mú ẹrù-iṣẹ́ wọn lati kọ́ awọn eniyan ṣẹ. Ṣugbọn ni lemọlemọ, awọn alufaa ṣainaani ojuṣe wọn lati kọ́ awọn orilẹ-ede naa. Aisi ẹ̀kọ́-iwe nipa Ofin Ọlọrun yii ni ó nilati ní awọn abajade buburu fun ati awọn alufaa ati awọn eniyan. Ni ọrundun kẹjọ B.C.E., Jehofa sọtẹlẹ pe: “A ké awọn eniyan mi kuro nitori aini ìmọ̀: nitori iwọ ti kọ ìmọ̀ silẹ, emi ó sì kọ̀ ọ́, ti iwọ ki yoo ṣe alufaa mi mọ́: niwọn bi iwọ ti gbagbe ofin Ọlọrun rẹ, emi pẹlu ó gbagbe awọn ọmọ rẹ.”—Hosea 4:6.

15. (a) Ni afikun si awọn alufaa, awọn wo ni Jehofa gbé dide gẹgẹ bi olukọ ni Israeli, kí sì ni ọmọwe Bibeli kan kọ nipa ìlà-iṣẹ́ wọn gẹgẹ bi olùkọ́ni? (b) Ki ni ó ṣẹlẹ si Israeli ati Judah nigbẹhin nitori pe wọn kọ ìmọ̀ ati awọn ọ̀nà Jehofa silẹ?

15 Ni afikun si awọn alufaa, Jehofa gbé awọn wolii dide gẹgẹ bi olùkọ́ni. A kà pe: “Sibẹ Oluwa jẹrii si Israeli, ati si Juda, nipa ọwọ́ gbogbo awọn wolii, ati gbogbo awọn ariran, wi pe, Ẹ yipada kuro ninu ọ̀nà buburu yin, ki ẹ si pa ofin mi ati ilana mi mọ, gẹgẹ bi gbogbo ofin ti mo pa ni aṣẹ fun awọn baba yin, ti mo rán si yin nipa ọwọ́ awọn wolii iranṣẹ mi.” (2 Ọba 17:13) Niti ìlà-iṣẹ́ awọn wolii gẹgẹ bi olùkọ́ni, ọmọwe Bibeli lede Faranse Roland de Vaux kọwe pe: “Awọn wolii, pẹlu, ni iṣẹ́-àpèrán lati fun awọn eniyan naa ni itọni; eyi ti ó keretan jẹ́ apakan ti ó pọ̀ ninu iṣẹ wọn gẹgẹ bii sisọtẹlẹ nipa ọjọ-ọla. Imisi alasọtẹlẹ sì fi aṣẹ ọ̀rọ̀ Ọlọrun kun iwaasu wọn. Ó daju pe labẹ eto ìjọba-aládé awọn wolii ni olukọ isin ati ìwàrere ti awọn eniyan naa; a sì lè fikun un, pe, wọn jẹ́ awọn ti ó dara jù ninu awọn olukọ wọn, bi wọn kìí bá ṣe awọn ti wọn ń kọbiara sii julọ.” Nipasẹ aini ẹ̀kọ́-iwe ti ó bojumu lati ọdọ awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi papọ pẹlu ikuna lati kọbiara si awọn wolii Jehofa, awọn ọmọ Israeli fi ọ̀nà Jehofa silẹ. Samaria ṣubu sọwọ awọn ará Assiria ni 740 B.C.E., Jerusalemu ati tẹmpili rẹ̀ ni a sì parun lati ọwọ́ awọn ará Babiloni ni 607 B.C.E.

Ẹkọ-iwe Lakooko Igbekun ati Lẹhin Rẹ̀

16, 17. (a) Itolẹsẹẹsẹ ẹkọ-iwe wo ni a fipa múwá sori Danieli ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ mẹta? (b) Ki ni ó mu ki wọn lè gba ẹkọ-iwe Babiloni yii ki wọn sì tun wà gẹgẹ bi oluṣotitọ si Jehofa sibẹ?

16 Ni nǹkan bii ọdun mẹwaa ṣaaju iparun Jerusalemu, Ọba Jehoiakini ati ọ̀wọ́ awọn ọmọ-ọba ati ọ̀tọ̀kùlú ni Ọba Nebukadnessari kó lọ si Babiloni. (2 Ọba 24:15) Lara wọn ni Danieli ati awọn ọ̀tọ̀kùlú ọ̀dọ́ mẹta miiran wà. (Danieli 1:3, 6) Nebukadnessari paṣẹ fun awọn mẹrẹẹrin lati niriiri ipa-ọna idanilẹkọọ akanṣe ọlọdun mẹta kan ninu “iwe ati èdè awọn ará Kaldea.” Ju bẹẹ lọ, a pese “ounjẹ wọn ojoojumọ ninu àdídùn ọba ati ninu ọtí waini ti ó ń mu.” (Danieli 1:4, 5) Eyi lọna ti ó ṣeeṣe léwu ninu fun ọpọlọpọ idi. Ó ṣeeṣe kí, ètò ẹ̀kọ́ naa maṣe jẹ́ ipa-ọna ẹ̀kọ́ èdè ọlọdun mẹta. Èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “awọn ará Kaldea” ninu ọ̀rọ̀-àyọkà yii ni awọn kan ronu pe ó nilati duro fun, “kìí ṣe awọn ará Babiloni gẹgẹ bi eniyan kan, bikoṣe awujọ ẹgbẹ́ awọn ọmọwe.” (The Soncino Books of the Bible) Ninu àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lori Danieli, C. F. Keil sọ pe: “Danieli ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni a o fi ọgbọ́n awọn alufaa ati awọn ọkunrin ọmọwe Kaldea kọ́, eyi ti a fi ń kọni ni awọn ile-ẹkọ Babiloni.” Ipese ounjẹ ọba tún ṣíjú wọn payá sí títàpá sí awọn ikaleewọ ti ounjẹ tí Ofin Mose gbé kà wọn lori. Bawo ni wọn ṣe ṣe?

17 Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun awọn ọ̀tọ̀kùlú ọ̀dọ́ Ju mẹrin naa, Danieli mú un ṣe kedere lati ibẹrẹ pe awọn kò ni jẹ tabi mu ni ìṣẹ̀sí ẹ̀rí-ọkàn wọn. (Danieli 1:8, 11-13) Jehofa bukun iduro gbọnyingbọnyin yii ó sì rọ ijoye-oṣiṣẹ ará Babiloni ti ó wà ni abojuto naa lọkan. (Danieli 1:9, 14-16) Niti ẹ̀kọ́ wọn, awọn iṣẹlẹ ti ó tẹle e ninu igbesi-aye gbogbo awọn ọ̀dọ́ Heberu mẹrin naa jẹrii sii kọja iyemeji pe eto ẹ̀kọ́ kàn-ńpá ọlọdun mẹta wọn ninu iṣẹdalẹ Babiloni kò mú wọn yí kuro ninu isopọ timọtimọ wọn pẹlu Jehofa ati ijọsin mimọgaara rẹ̀. (Danieli, ori 3 ati 6) Jehofa mú ki o ṣeeṣe fun wọn lati móríbọ́ kuro ninu fifi ti a fi ipá mú wọn fun ọdun mẹta lati farafun ẹ̀kọ́ giga ti Babiloni. “Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ̀ ati òye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli funraarẹ sì ní òye ni gbogbo ìran ati àlá. Ati ninu gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n ati òye ti ọba ń beere lọwọ wọn, o rí i pe ni ìwọ̀n ìgbà mẹwaa, wọn sàn ju gbogbo awọn amoye ati ọlọgbọ́n ti ó wà ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀ lọ.”—Danieli 1:17, 20.

18. Itolẹsẹẹsẹ ẹkọ-iwe wo ni a ṣe ni Judah lẹhin igbekun Babiloni?

18 Lẹhin ikolọnigbekun si Babiloni, iṣẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ iwe ńlá ni a ti ọwọ́ Esra ṣe, alufaa kan ti o “mura tan ni ọkàn rẹ̀ lati maa wá ofin Oluwa, ati lati ṣe é, ati lati maa kọni ni ofin ati idajọ ni Israeli.” (Esra 7:10) Ninu eyi oun ni a ràn lọwọ nipasẹ awọn ọmọ Lefi oluṣotitọ, ti wọn “mú ki ofin yé awọn eniyan.” (Nehemiah 8:7) Esra jẹ́ ọmọwe Bibeli kan ati “ayáwọ́-akọ̀wé,” tabi akọwe. (Esra 7:6) Ní ọjọ rẹ̀ ni awọn akọwe di gbajumọ gẹgẹ bi awujọ ẹgbẹ́ kan.

Ile-ẹkọ Awọn Rabbi

19. Ẹgbẹ́ awọn olùkọ́ni wo ni ó farahan ni Israeli ni akoko ti Jesu fi wá sori ilẹ̀-ayé, ati fun awọn idi pataki wo ni oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò fi niriiri ẹkọ-iwe giga ti awọn Ju?

19 Nigba ti Jesu maa fi farahan lori ilẹ̀-ayé, awọn akọwe ti di ẹgbẹ́ ọlọ́lá ti awọn olukọ, ti wọn faramọ awọn aṣa-atọwọdọwọ timọtimọ ju ẹ̀kọ́ tootọ ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lọ. Wọn fẹ́ ki a maa pe awọn ni “Rabbi,” eyi ti ó di orukọ oyè ọlá kan ti ó tumọsi “Ẹni Ńlá (Titayọlọla) Mi.” (Matteu 23:6, 7, akiyesi ẹsẹ-iwe) Ninu Iwe Mimọ Kristian Lede Griki, awọn akọwe ni a sábà maa ń sopọ mọ awọn Farisi, diẹ ninu awọn ti wọn jẹ́ olukọ Ofin funraawọn. (Iṣe 5:34) Jesu fẹsunkan awọn mejeeji fun sisọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun di aláìṣeédaradé nitori aṣa-atọwọdọwọ ati fifi “ofin eniyan kọni fun ẹ̀kọ́.” (Matteu 15:1, 6, 9) Kò yanilẹnu nigba naa pe yala Jesu tabi ọpọ julọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni a kò kọ́ ni ile-ẹkọ awọn rabbi.—Johannu 7:14, 15; Iṣe 4:13; 22:3.

20. Ki ni atunyẹwo yii nipa ẹkọ-iwe ni awọn akoko ti a kọ Bibeli yii ti fihàn wá, ki ni ó sì fihàn pe awọn iranṣẹ Jehofa nilo ẹkọ-iwe?

20 Akọsilẹ ṣókí yii nipa ẹkọ-iwe ni awọn akoko ti a kọ Bibeli ti fihàn pe Jehofa ni Atobilọla Olutọni ti awọn eniyan rẹ̀. Nipasẹ Mose, Ọlọrun ṣe eto ẹkọ-iwe gbigbeṣẹ kan ni Israeli. Ṣugbọn lẹhin akoko gigun kan, ètò ẹ̀kọ́ iwe giga ti awọn Ju kan jẹ jade ti ń fi awọn ohun ti ó lodi si Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kọni. Nigba ti Jesu kò lọ si iru ile-ẹkọ awọn Ju bẹẹ, oun, laika eyiini si, jẹ́ Olukọ ti kò láfiwé. (Matteu 7:28, 29; 23:8; Johannu 13:13) Oun tún fàṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati kọni, àní titi di ìgbà ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan. (Matteu 28:19, 20) Lati ṣe eyi, wọn nilati jẹ́ olukọ rere ati nitori eyi wọn yoo nilati gba ẹkọ-iwe. Nitori naa oju wo ni awọn Kristian tootọ nilati fi wo ẹkọ-iwe lonii? Ibeere yii ni a o gbeyẹwo ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o tẹle e.

Idanwo Agbara Iranti

◻ Eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe Jehofa ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹkọ-iwe awọn iranṣẹ rẹ̀?

◻ Ni ọ̀nà wo ni eto-igbekalẹ ẹkọ-iwe Israeli fi yatọ si ti awọn orilẹ-ede miiran?

◻ Ẹkọ-iwe wo ni awọn ọmọde ni Israeli ń gbà?

◻ Awọn ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ni a lò ni Israeli?

◻ Eeṣe ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kò fi lọ si ile-ẹkọ ìmọ̀ giga ti awọn Ju?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ẹkọ-iwe kàn-ńpá ni Babiloni kò yí Danieli ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ kuro lọdọ Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́