Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
NI Heberu 11:26, ṣé Mose ni a ń sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bii “Kristi” naa, tabi oun ha wulẹ jẹ iru Jesu Kristi kan bi?
Nigba ti o ń sọrọ nipa igbagbọ Mose, aposteli Paulu kọwe pe Mose “ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitori ti o ń wo èrè naa.” (Heberu 11:26) O dabi ẹni pe Paulu ń tọka si Mose gẹgẹ bii “Kristi,” tabi ẹni-ami-ororo, ni ero itumọ kan.
A gbà pe, ni ọpọlọpọ ọ̀nà Mose fi apẹẹrẹ lelẹ fun Messia ti ń bọwa naa. Bi o tilẹ jẹ pe wolii kan ni Mose fúnraarẹ̀ jẹ, oun sọtẹlẹ nipa dide wolii titobi jù kan ‘bii ti oun.’ Ọpọ awọn Ju fòyemọ̀ pe Jesu ni “Wolii naa,” eyi ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fẹ̀rí rẹ̀ mulẹ. (Deuteronomi 18:15-19; Johannu 1:21; 5:46; 6:14; 7:40; Iṣe 3:22, 23; 7:37) Mose tun jẹ alarina majẹmu Ofin pẹlu, ṣugbọn Jesu gba “iṣẹ iranṣẹ ti o lọ́la jù” gẹgẹ bi “alarina majẹmu ti o dara jù,” majẹmu titun ologo naa. (Heberu 8:6; 9:15; 12:24; Galatia 3:19; 1 Timoteu 2:5) Nitori naa ní awọn ọ̀nà kan Mose ni a le sọ pe o ti jẹ apẹẹrẹ iru Messia ti ń bọwa naa.
Iyẹn, bi o ti wu ki o ri, ko dabi ẹni pe o jẹ itumọ ipilẹ tí Heberu 11:26 ní. Kò si ẹ̀rí pe Mose mọ kulẹkulẹ nipa Messia naa, ti o si mọ̀ọ́mọ̀ ka ohun ti o jiya rẹ̀ ni Egipti si ohun yiyẹ nitori ti Messia tabi gẹgẹ bi aṣoju Rẹ̀.
Awọn kan ti dabaa pe awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Heberu 11:26 ni ijẹpataki kan ti o dabi ti ọ̀rọ̀ akiyesi rẹ̀ pe awọn Kristian ‘jiya fun Kristi.’ (2 Korinti 1:5,) Awọn Kristian ẹni-ami-ororo mọ pe Jesu Kristi ti jiya ati pe bi awọn ba jiya ‘papọ pẹlu rẹ̀ a o ṣe wọn logo pọ̀ pẹlu rẹ̀’ ni ọrun. Ṣugbọn Mose ko mọ ohun ti Messia ti ń bọwa naa yoo jiya rẹ̀, bẹẹ sì ni Mose kò ni ireti ti ọrun.—Romu 8:17; Kolosse 1:24.
Òye kan ti o tubọ rọrun wà nipa bi Mose ti ṣe “ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀.”
Nigba ti Paulu kọ “Kristi” ni Heberu 11:26, o lo ọ̀rọ̀ Griki naa Khri·stouʹ, eyi ti ó dọgba pẹlu ti Heberu naa Ma·shiʹach, tabi Messia. Ati “Messia” ati “Kristi” tumọ si “ẹni-ami-ororo.” Nitori naa Paulu ń kọwe nipa pe Mose ‘ka ẹgan ẹni-ami-ororo si ọrọ̀.’ A ha le pe Mose fúnraarẹ̀ ni “ẹni-ami-ororo bi”?
Bẹẹni. Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli a lè fidi fifi ẹnikan jẹ oyè kan mulẹ nipa dida ororo sii lori. “Samueli sì mú igò ororo, o si tu u si i [Saulu] ni ori.” “Samueli mu ìwo ororo, o si fi yà á si ọ̀tọ̀ laaarin awọn arakunrin rẹ̀. Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi.” (1 Samueli 10:1; 16:13; fiwe Eksodu 30:25, 30; Lefitiku 8:12; 2 Samueli 22:51; Orin Dafidi 133:2.) Sibẹ, awọn kan, bii wolii Eliṣa ati ọba Siria naa Hasaeli, ni a sọrọ wọn gẹgẹ bi “ẹni-ami-ororo” bi o tilẹ jẹ pe kò si ẹ̀rí pe a da ororo gidi si wọn lori. (1 Awọn Ọba 19:15, 16; Orin Dafidi 105:14, 15; Isaiah 45:1) Nipa bayii, ẹnikan lè jẹ “ẹni-ami-ororo” nipa didi ẹni ti a yàn tabi pinṣẹ fun lọna akanṣe.
Ni oye-itumọ yii Mose fúnraarẹ̀ jẹ ẹni-ami-ororo Ọlọrun, awọn Bibeli kan si lo itumọ bii “Ẹni-ami-ororo Ọlọrun” tabi “Ẹni-ami-ororo naa” ni Heberu 11:26. A pinṣẹ fun Mose gẹgẹ bi aṣoju Jehofa ati ẹni naa ti yoo ṣaaju Israeli jade kuro ni Egipti. (Eksodu 3:2-12, 15-17) Bi o tilẹ jẹ pe a tọ́ Mose dagba laaarin ọlá ati ọlà Egipti, oun ka iṣẹ-ayanfunni rẹ̀ si iyebiye gidigidi, eyi ti oun tẹwọgba ti o si muṣẹ. Ni ibamu pẹlu eyi, Paulu lè kọwe pe Mose “ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ.”