ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/15 ojú ìwé 3-4
  • Ki Ni Ihinrere Naa Jẹ́ Niti Gidi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ki Ni Ihinrere Naa Jẹ́ Niti Gidi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ki Ni Ihinrere naa Jẹ́?
  • Dídá Ihinrere naa Mọ̀ Yatọ
  • Ihin-iṣẹ kan Ti Ó Ṣe Ketekete
  • Irú Ìwé Wo Ni “Ìhìn Rere Júdásì”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Bawo Ni Ihinrere naa Ṣe Lè Ṣanfaani fun Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Ìtàn Jésù?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣóòótọ́ Làwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/15 ojú ìwé 3-4

Ki Ni Ihinrere Naa Jẹ́ Niti Gidi?

NÍ ÌGBÀ ọdun Keresimesi, awọn eniyan ni ọpọlọpọ ilẹ ń gbọ́ nipa Ihinrere naa, wọn tilẹ ń sọrọ nipa rẹ̀, lẹnikọọkan. Èdè-ìsọ̀rọ̀ naa wọ́pọ̀ gan-an ni, ṣugbọn ó ha ni itumọ ju bi ọpọ julọ ti ronuwoye bi? Ihinrere ha lè tumọsi ohun didara lọna títayọ kan fun iwọ ati awọn olólùfẹ́ rẹ bi?

“Ihinrere” tumọsi “irohin rere,” o si daju pe, irohin rere ni a sì ń tẹwọgba kìí wulẹ ṣe ni akoko Keresimesi nikan ni ṣugbọn nigbakigba. Bi o ti wu ki o ri, Ihinrere naa kìí wulẹ ṣe irohin rere eyikeyii. Ó jẹ́ irohin rere pàtó kan lati orisun pàtó kan nipa kókó-ẹ̀kọ́ pàtó kan. Nitootọ, ó jẹ́, ihin-iṣẹ kan ti Ọlọrun ti yàn pe a nilati kéde fun gbogbo araye.

Eugênio Salles, biṣọọbu-agba ti Rio de Janeiro, Brazil, sọrọ nipa irohin rere yẹn nigba ti ó rọni pe: “A gbọdọ huwa ni ibamu pẹlu Ihinrere naa ti a kò sì gbọdọ gbé iṣarasihuwa wa kari awọn èròǹgbà.” Biṣọọbu-agba naa tọna. Lati huwa ni ibamu pẹlu Ihinrere naa, bi o ti wu ki o ri, beere pe ki a mọ ohun ti Ihinrere naa jẹ́. Bawo ni a ṣe lè mọ iyẹn? Bawo sì ni hihuwa ni ibamu pẹlu Ihinrere ṣe lè ràn wá lọwọ?

Ki Ni Ihinrere naa Jẹ́?

Bi Ihinrere ti jẹ́ gan-an ni a sábà maa ń ṣì lóye. Ni 1918 Igbimọ Apapọ ti Awọn Ṣọọṣi Kristi ni America kókìkí Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ti ó ti kógbásílé nisinsinyi gẹgẹ bii ìfihànsóde Ijọba Ọlọrun lọna oṣelu lori ilẹ̀-ayé ó sì polongo pe oun ni a “fidii rẹ̀ mulẹ sinu Ihinrere.” Ẹgbẹ́ yẹn kuna lọna ti ó banininujẹ ninu gongo rẹ̀ lati pa alaafia mọ́. Ni kedere, igbimọ naa kò tọna. Imulẹ Awọn Orilẹ-ede kò ni ohunkohun ṣe pẹlu Ihinrere naa.

Ni awọn ọdun aipẹ yii awọn olùṣagbátẹrù ẹkọ-isin isọnidominira ti bẹrẹsii jiroro nipa Ihinrere ní fàlàlà nigba ti wọn bá ń sọrọ nipa èròǹgbà wọn fun àtúnṣe nipasẹ oṣelu tabi ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Ni ṣiṣe bẹẹ wọn ti ṣaika Ihinrere tootọ sí. Iwe-irohin Brazil naa Veja ṣalaye pe: “Ṣọọṣi Katoliki bẹrẹ sii fọwọsi ijọba ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ní gbigboju fo awọn aini tẹmi awọn oluṣotitọ rẹ̀ dá. Awọn wọnni ti ń wá ọ̀rọ̀ naa Ọlọrun ninu iwaasu kan sábà maa ń rí kìkì awọn àròyé ẹjọ́ lodisi awọn aiṣedajọ-ododo laaarin ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà.”

Imusunwọn sii ninu awọn ipo gbígbé igbesi-aye tabi iyipada kan ninu awọn eto-igbekalẹ oṣelu lè jẹ́ irohin rere fun awọn kan. Sibẹ, iru iyẹn kọ́ ni irohin rere naa, Ihinrere naa. Ní titẹwọgba ikuna ṣọọṣi rẹ̀ lati waasu Ihinrere tootọ naa, biṣọọbu kan sọ pe: “A kò bikita nipa ikọnilẹkọọ nipa tẹmi ti awọn oluṣotitọ wa lati awọn ọdun 1960 nitori ifẹ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì ti ó kówọnú ẹkọ-igbagbọ wa.”

Irohin kan ninu iwe-irohin U.S. naa Time mú un ṣe kedere pe awọn Protẹstanti pẹlu kò pọkàn pọ̀ mọ́ nipa Ihinrere naa. Iwe-irohin naa ṣakiyesi pe: “Kìí ṣe pe ẹgbẹ́ awujọ isin atọwọdọwọ ń kuna lati sọ ihin-iṣẹ wọn funni lasọye nikan ni; ohun ti ihin-iṣẹ yẹn jẹ́ gan-an ni kò dá wọn loju siwaju ati siwaju sii.” Ki ni ihin-iṣẹ wọn nilati jẹ́? Ki ni Ihinrere naa jẹ́?

Dídá Ihinrere naa Mọ̀ Yatọ

Iwe atumọ èdè naa Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary tumọ “Ihinrere” gẹgẹ bi “ihin-iṣẹ naa nipa Kristi, ijọba Ọlọrun, ati igbala.” Ọ̀rọ̀ naa “ihinrere” ni a tun tumọ gẹgẹ bii “iṣetumọ ihin-iṣẹ Kristian (ihinrere ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà)”; “ihin-iṣẹ tabi awọn ẹ̀kọ́ olukọ isin kan.” Gbogbo itumọ wọnyi ha tan mọ́ ọn bi? Bẹẹkọ, kìí ṣe bi a bá ń sọrọ nipa Ihinrere naa. Ihinrere tootọ naa ni a gbekari Bibeli; fun idi yii, eyi akọkọ nikan ninu awọn itumọ mẹta wọnyẹn ni ó péye. Meji ti ó kẹhin wulẹ fi ọ̀nà ti a ń gbà lo ọ̀rọ̀ naa “ihinrere” lonii hàn ni.

Ni ibamu pẹlu èrò yii, Vine’s Expository Dictionary of New Testament Words sọ pe ninu Iwe Mimọ Kristian Lede Griki (“Majẹmu Titun” naa), Ihinrere naa “duro fun làbárè rere nipa Ijọba Ọlọrun ati igbala nipasẹ Kristi, ti a o rigba nipa igbagbọ, lori ipilẹ ikú elétùtù Rẹ̀.” Ó ṣe pataki lati loye eyi nitori pe òye titọna nipa irohin rere tootọ naa ní ohun pupọ ṣe pẹlu wíwà lalaafia wa isinsinyi ati ayọ wa ọjọ-ọla.

Ihin-iṣẹ kan Ti Ó Ṣe Ketekete

Gẹgẹ bi iwe itọkasi ti a ṣẹṣẹ mẹnuba yii ti fihàn, Ihinrere wà ni ìsopọ̀ pẹkipẹki pẹlu Jesu Kristi—lọpọlọpọ gan-an debi pe awọn akọsilẹ Bibeli mẹrin nipa igbesi-aye rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé ni a pè ni awọn Ihinrere mẹrin. Taarata lati ibẹrẹ igbesi-aye rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá eniyan, ni irohin nipa Jesu ti jẹ́ irohin rere. Nigba ti ó ń kéde ìbí rẹ̀, angẹli kan sọ pe: “Ẹ wò ó! mo ń kéde irohin rere [tabi, ihinrere] ayọ ńlá fun yin ti gbogbo eniyan yoo ní, nitori a bí Olugbala kan fun yin lonii, tíí ṣe Kristi Oluwa.”—Luku 2:10, 11, NW.

Jesu ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí naa yoo dagba di Kristi, Messia naa ti a ṣeleri. Oun yoo ṣí ète Ọlọrun fun igbala payá, fi iwalaaye ẹ̀dá eniyan pípé rẹ̀ lélẹ̀ nitori ti araye, a o jí i dide, ati lẹhin naa yoo di Ọba Ijọba Ọlọrun naa ti a yàn. Irohin rere nitootọ! Idi niyẹn ti a fi pe ihin-iṣẹ nipa rẹ̀ ni Ihinrere.

Lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ onigba kukuru lori ilẹ̀-ayé, Jesu jẹ́ onitara gan-an ninu wiwaasu irohin rere. A kà ninu Ihinrere ti Matteu pe: “Jesu sì rin si gbogbo ilu-nla ati ileto, ó ń kọni ninu sinagogu wọn, ó sì ń waasu ihinrere ijọba.” (Matteu 9:35) Iwaasu rẹ̀ kìí wulẹ ṣe lati jẹ́ ki ara awọn eniyan yá. Marku ṣakọsilẹ pe Jesu sọ pe: “Akoko naa dé, ijọba Ọlọrun sì kù sí dẹ̀dẹ̀: ẹ ronupiwada, ki ẹ sì gba ihinrere gbọ́.” (Marku 1:15) Bẹẹni, awọn wọnni ti wọn dahunpada ti wọn sì gba ihinrere gbọ́ rí i pe ó yí igbesi-aye wọn pada.

Lẹhin ikú Jesu, awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ń baa lọ lati waasu Ihinrere naa. Kìí ṣe kìkì pe wọn sọrọ nipa Ijọba naa nikan ni ṣugbọn wọn fi irohin alayọ naa pe a ti jí Jesu dide si ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun ninu awọn ọrun ti o sì ti fi iniyelori iwalaaye eniyan pípé rẹ̀ lélẹ̀ nitori ti araye kún un. Gẹgẹ bi ẹni naa ti Ọlọrun yàn lati ṣakoso lori gbogbo ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun, oun yoo di Aṣoju Ọlọrun ninu pipa awọn ọ̀tá Ọlọrun run ati ninu mimu ilẹ̀-ayé padabọ si ipo paradise kan.—Iṣe 2:32-36; 2 Tessalonika 1:6-10; Heberu 9:24-28; Ìfihàn 22:1-5.

Lonii, irohin rere naa ní kókó pataki siwaju sii ninu. Ni ibamu pẹlu gbogbo ẹ̀rí imuṣẹ asọtẹlẹ, Jesu ni a ti gbé kari ìtẹ́ nisinsinyi, a sì ń gbé ni awọn ọjọ ikẹhin ti eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii. (2 Timoteu 3:1-5; Ìfihàn 12:7-12) Akoko naa nigba ti Ijọba naa yoo gbé igbesẹ lodisi awọn ọ̀tá Ọlọrun ń súré tete bọ̀ nitosi. Irohin wo ni ó tun lè sàn ju eyi lọ?

Awa yoo ri bi Ihinrere naa ti lagbara tó ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti ó tẹle e. Ó ran obinrin kan ti a ti fi oògùn onídán dẹkùn mú lọwọ lati rí ominira. Ó ran ọkunrin kan ti ó wà ninu ẹ̀wọ̀n fun dídigun-jalè lọwọ lati rí ayọ. Yoo sì ṣanfaani gidigidi fun iwọ naa pẹlu—bi iwọ bá tẹ́tísílẹ̀ sí irohin rere ti o sì gbà á gbọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́