ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/15 ojú ìwé 5-7
  • Bawo Ni Ihinrere naa Ṣe Lè Ṣanfaani fun Ọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo Ni Ihinrere naa Ṣe Lè Ṣanfaani fun Ọ?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Eniyan ti A Ràn Lọwọ Nipasẹ Ihinrere Naa
  • Ki Ni Ohun Ti Irohin Rere naa Tumọsi Lonii?
  • Agbara Ihinrere naa lonii
  • Awọn Ibukun ti Ó Ṣì Wà Niwaju
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ki Ni Ihinrere Naa Jẹ́ Niti Gidi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Ìhìn Rere”!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/15 ojú ìwé 5-7

Bawo Ni Ihinrere naa Ṣe Lè Ṣanfaani fun Ọ?

BIBELI ni a kàsí lọna ti ó ga fun iniyelori ikọwe rẹ̀—àní awọn alaigbọlọrungbọ kan paapaa kà á si bẹẹ. Niti tootọ, bi o ti wu ki o ri, awọn diẹ ní ń kà á ki wọn baa lè fi ohun ti ó sọ si ìlò. Ju bẹẹ lọ, niwọn ìgbà ti ihinree tí ó wà ninu rẹ̀ ti wà lati nǹkan bii ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, ó jọbi pe ọpọlọpọ eniyan gbagbọ pe a nilati sọ ọ́ di ti ìgbàlódé, ki a mú un bá ìgbà mu. Ihinrere ha ti di ti ìgbà laelae tabi eyi ti kò wúlò mọ́ bi? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá.

Awọn ọkunrin ati obinrin, ọ̀dọ́ ati agbalagba wà, ti iye wọn jẹ́ araadọta-ọkẹ, ti wọn mọ̀ pe Bibeli jẹ́ orisun iranlọwọ ti kò ṣeediyele. Ńṣe ni ó rí bi ọ̀rọ̀-àkọ́sọ inu Todaýs English Version ṣe kà pe: “Bibeli kìí wulẹ̀ ṣe iwe ńlá ti a nilati fẹ́ ki a sì bọ̀wọ̀ fun; Irohin Rere fun gbogbo eniyan nibi gbogbo ni—ihin-iṣẹ kan ti a nilati loye ti a sì nilati fisilo ninu igbesi-aye ojoojumọ ni pẹlu.”

Ki ni Ihinrere naa tumọsi fun ọ? Iwọ ha ń lò ó gẹgẹ bi atọnisọna ninu igbesi-aye rẹ ojoojumọ bi? Gbé bi irohin rere naa ṣe ṣanfaani fun awọn kan ti wọn tẹ́tísílẹ̀ sí i ni ọrundun kìn-ín-ní ati bi awọn kan ṣe janfaani nin akoko wa yẹwo.

Awọn Eniyan ti A Ràn Lọwọ Nipasẹ Ihinrere Naa

Ni ọjọ Jesu awọn ẹnikọọkan bii awọn oṣiṣẹ kára ọkunrin apẹja ati awọn iyawo-ile ni irohin rere fà mọra ti wọn sì kẹkọọ otitọ nipa ète Ọlọrun fun eniyan. Irohin rere yí igbesi-aye wọn pada patapata ó sì sábà maa ń mú itura ńláǹlà wá fun wọn. Fun apẹẹrẹ, Maria Magdaleni ni a dá silẹ lominira kuro lọwọ agbara ìjẹgàba ẹmi-eṣu. Sakeu, ti ó jẹ́ olori agbowo-ode tẹlẹri, pa ọ̀nà igbesi-aye oniwọra rẹ̀ tì. (Luku 8:2; 19:1-10) Awọn afọju ati adẹ́tẹ̀ ni a ràn lọwọ nigba ti wọn wá sọdọ Jesu, ẹni naa tí ń waasu irohin rere naa. (Luku 17:11-19; Johannu 9:1-7) Jesu lè sọ lọna ẹ̀tọ́ pe: “Awọn afọju ń ríran, awọn amọkun sì ń rìn, a ń wẹ awọn adẹ́tẹ̀ mọ́, awọn aditi ń gbọran, a ń jí awọn òkú dide, a sì ń waasu ihinrere fun awọn otoṣi.”—Matteu 11:5.

Bi o ti wu ki o ri, ohun ti o ṣe pataki ju imularada wọn, ni ọ̀nà ti irohin rere gbà yí ọpọlọpọ ninu awọn eniyan aláààbọ̀ ara naa pada gẹgẹ bi ẹnikan. awọn alailabosi-ọkan ni wọn ní ẹkunrẹrẹ ireti ọjọ-ọla. Wọn gbé igbẹkẹle wọn ka Ijọba Ọlọrun—ohun kan ti ó sàn ju ihinrere ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà eyikeyii lọ. (Matteu 4:23) Ireti wọn ni a kò mú ṣákìí nipasẹ ikú Jesu. Ní ṣiṣakawe awọn ọ̀ràn àní lẹhin iṣẹlẹ yẹn, Iṣe 5:42 sọ nipa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ni ojoojumọ ni tẹmpili ati ni ile, wọn kò dẹ́kun ikọni, ati lati waasu Jesu Kristi.” Ni ọrundun kìn-ín-ní, awọn eniyan ni ọpọlọpọ ilẹ gba iranlọwọ tẹmi nitori pe wọn dahunpada si iru iwaasu bẹẹ.

Ijọba naa ni irohin ti o dara julọ ninu awọn irohin nigba naa lọhun-un. Ihin-iṣẹ Ijọba naa ha ṣì jẹ́ irohin rere sibẹ bi?

Ki Ni Ohun Ti Irohin Rere naa Tumọsi Lonii?

Bi o bá ń yánhànhàn fun ayé alalaafia kan, tí ó láàbò, dajudaju nigba naa irohin nipa Ijọba naa jẹ́ rere. Niti tootọ, ninu ayé kan ti ó ní ọgọrọọrun araadọta awọn eniyan ti wọn kò róúnjẹ ti ó tó jẹ ti ebi sì ń pa kú, pẹlu awọn aisan abanilẹru ti ń halẹ̀ mọ gbogbo eniyan, pẹlu ibisi ninu iwa-ọdaran lọna ti ń dáyàfoni, ati pẹlu ìrugùdù ti oṣelu ti ń tànkálẹ̀, oun ni irohin rere tootọ wíwàpẹ́títí kanṣoṣo naa. Ó duro fun ireti kanṣoṣo fun imusunwọn sii tootọ.

Idi niyẹn ti Jesu fi sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ wa pe: “A o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.” (Matteu 24:14) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ni a ń muṣẹ ni ọ̀nà pipẹtẹri kan gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń waasu ihinrere naa ni iye awọn ilẹ ti ó lé ni 200. Itẹjade Katoliki kan, Nova Evangelização 2000, gboriyin fun awọn Ẹlẹ́rìí fun eyi, ni wiwi pe: “Nibo ni a o ti rí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ni ẹnu ilẹkun awọn ojule. Ati lati di Ẹlẹ́rìí fun Jehofa, yatọ si jíjẹ́ ti Jehofa, ẹni kan nilati di ẹlẹ́rìí kan. Niroi naa, a ń rí wọn ti wọn ń ṣiṣẹ, ti wọn ń kéde, ti wọn ń gbé ọ̀rọ̀, ohun ti wọn ti niriiri rẹ̀ kalẹ.”

Bi o ti wu ki o ri, kò sí ẹni ti ó kàn ṣàdéédé janfaani lati inu irohin rere laiṣiṣẹ fun un. Yoo ran kìkì awọn wọnni ti wọn tẹ́tísílẹ̀ ti wọn sì ṣegboran lọwọ. Lati fi kókó yii hàn, Jesu funni ni òwe-àkàwé nipa ọkunrin kan ti o jade lọ lati lọ funrugbin. Oriṣiriṣi iru ilẹ ti awọn irugbin naa bọ́ sí ṣàkàwé oriṣiriṣi iru ipo ọkan-aya ti awọn olùgbọ́ ihinrere naa fihàn. Jesu sọ pe: “Nigba ti ẹnikan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ijọba, ti kò bá si yé e, nigba naa ni ẹni buburu nì wá, a sì mú eyi ti a fún si àyà rẹ̀ kuro. . . . Ṣugbọn ẹni ti o gba irugbin si ilẹ rere ni ẹni ti o gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, ti ó sì yé e; oun ni o sì so eso pẹlu, ó sì so omiran ọgọrọọrun, omiran ọgọtọọta, omiran ọgbọọgbọn.”—Matteu 13:18-23.

Gẹgẹ bi o ti rí ni ọrundun kìn-ín-ní, ọpọ julọ awọn eniyan lonii kò sapá tó lati loye irohin rere naa. Òye rẹ̀ kò yé wọn, wọn sì tipa bayii padanu. Awọn miiran fi imọriri hàn fun irohin rere naa wọn sì kẹkọọ ọ̀nà ti wọn yoo gbà mú igbesi-aye wọn wà ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun. Ni ọ̀nà yii a bukun wọn. Ti ẹgbẹ́ wo ni iwọ íṣe?

Agbara Ihinrere naa lonii

Awọn iriri jẹrii sí i pe liloye irohin rere ń ran awọn wọnni ti wọn ‘kò ní ireti ti wọn kò sì ní Ọlọrun’ lọwọ. (Efesu 2:12; 4:22-24) Roberto lati Rio de Janeiro nilo iranlọwọ. Lati ìgbà èwe rẹ̀, ni ó ti ń gbé igbesi-aye onibajẹ, ni jíjẹ́ ẹni ti o lọwọ ninu oògùn, iwapalapala, ati olè jíjà. Asẹhinwa-asẹhinbọ wọn jù ú sẹ́wọ̀n. Nigba ti ó wà nibẹ Roberto kẹkọọ Bibeli pẹlu Ẹlẹ́rìí kan ti ń ṣebẹwo. Ó tẹsiwaju daradara gan-an debi pe akoko ẹ̀wọ̀n rẹ̀ ni a dínkù gan-an.

Lẹhin ti a ti dá a silẹ, Roberto pade ọdọmọbinrin kan tí ó ti fipá jà lólè ti ó sì ti fi ìbọn halẹ̀ mọ́ rí. Oun pẹlu ń kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ki ni ó ṣẹlẹ? Eyi ti o tẹle e yii ni apakan lẹta ti ń sọ nipa iṣẹlẹ naa pe: “Wọn pade araawọn ni Gbọngan Ijọba fun ìgbà akọkọ lẹhin ifipakọluni naa. Ìbápàdé naa wọnilọkan ṣinṣin. Awọn mejeeji sun ẹkún àròkàn wọn sì dì mọ́ra gẹgẹ bi arakunrin ati arabinrin. Nisinsinyi olè atijọ at ojiya ipalara rẹ̀ ń yin Jehofa.”

Ẹlomiran kan, Isabel, tun nilo iranlọwọ, nitori pe a mọ̀ ọ́n fun inú fùfù rẹ̀. Ó ti kówọnú ibẹmiilo ati iṣẹ́-ajé jinlẹjinlẹ ti awọn ẹmi eṣu sì ń dá a lóró. Bi ó ti ń kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó rí i pe irohin rere ṣeranwọ nitootọ. Lẹhin akoko diẹ, ó gbọn agbara ìdarí awọn ẹmi eṣu danu ó sì yí animọ rẹ̀ pada—ó sì kọ́ lati ṣakoso ibinu rẹ̀ nikẹhin. Nisinsinyi oun jẹ́ Kristian oluṣotitọ kan, ti a mọ̀ gẹgẹ bi ẹnikan ti o jẹ́ oninuure ninu bíbá awọn ẹlomiran lò.

Bẹẹni, irohin rere kìí ṣe àbá-èrò-orí lasan. Ó ni agbara gidi lati yí igbesi-aye pada. (1 Korinti 6:9-11) Ó tilẹ ṣe ju iyèn lọ. Ó tun tọka si awọn ibukun ọjọ-ọla.

Awọn Ibukun ti Ó Ṣì Wà Niwaju

Gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti wi, ọjọ-ọla ní awọn ohun agbayanu ti a ń fojusọna fun. Awa yoo rí imuṣẹ adura Jesu pe ki Ijọba Ọlọrun ki ó dé ati pe ki ifẹ-inu Rẹ̀ di ṣiṣe lori ilẹ̀-ayá gẹgẹ bi ó ti rí ni ọrun. (Matteu 6:10) Laipẹ, eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi pẹlu iwa-ibajẹ ti ń banininujẹ ati iwa-ipa rẹ̀ ni a o mú kuro, ti iṣakoso Ọlọrun ti ọrun, Ijọba rẹ̀, yoo sì ṣakoso lori awọn eniyan ọlọ́kàntítọ́ ti wọn muratan lati tẹ́tísílẹ̀ si irohin rere ki wọn sì gbà á gbọ́.—Danieli 2:44.

Imusunwọn sii patapata yoo tẹle e bi a ti ń dari awọn oluṣotitọ eniyan lati yí ilẹ̀-ayé pada si paradise kan nibi ti awọn ọlọkantutu yoo ti walaaye titilae. (Orin Dafidi 37:11, 29) Dajudaju, irohin rere ni o jẹ́ pe iwa-ọdaran, aisan, ìyàn, bíba-àyíká-jẹ́, ati ogun yoo pòórá titiilae! Iwọ ha lè foju inu woye araarẹ ati idile rẹ ti ń gbé ninu ayé titun yẹn ninu alaafia ati ilera pípé laisi ibẹru aisan ati ikú bí?—Ìfihàn 21:4.

Lootọ, ọpọlọpọ ka iru irohin rere bẹẹ si eyi ti o jẹ fifojú yẹpẹrẹ wo iṣoro ńlá tabi míméfò nǹkan. Ṣugbọn wọn kò tọna. Irohin rere naa ni a gbekari ẹ̀rí ti ó le korán, ó sì ti yí araadọta-ọkẹ igbesi-aye pada ná. Nitori naa, maṣe di ẹni ti a dáyàfò bi awọn ẹlomiran kò bá gbagbọ.

Ronuwoye ọlọgbọn eniyan kan ti ó ra ilẹ ni agbegbe kan ti ó ṣẹṣẹ ń di ilu bọ̀, ní ríretí lati jere lati inu ìdókòwò naa. Ẹnikẹni ha lè dá a lẹbi fun fífi owó rẹ̀ dókòwò ni ọ̀nà yii bi? Bẹẹkọ. Ó ṣeeṣe ju pe, awọn eniyan yoo sọ pe ó ń hùwà pẹlu ọgbọ́n. Eeṣe, nigba naa, ti a kò fi ni ní òye ohun ti yoo ṣẹlẹ nipa Ijọba naa ki a sì dókòwò, gẹgẹ bi a ti ṣe lè sọ, ninu irohin rere naa? Niwọn bi titẹwọgba irohin rere naa ti tumọsi igbala, kò sí ìdókòwò miiran ti yoo mú èrè ti ó sàn jù wá.—Romu 1:16.

Bawo ni o ṣe lè dókòwò ninu irohin rere naa? Lakọọkọ, muratan lati lati di ẹni ti Ọlọrun kọ́. Nigba naa hùwà ni ibamu pẹlu ohun ti o kọ́. Tẹle awọn ohun abeerefun ipilẹ, gẹgẹ bi a ti tò ó lẹsẹẹsẹ nipasẹ wolii Heberu igbaani naa pe: ‘Ki ni ohun ti Oluwa beere lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o sì fẹ́ àánú, ati ki o rìn ni irẹlẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?’ (Mika 6:8) Kikẹkọọ lati bá Ọlọrun rìn a maa gba akoko ati isapa. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti wọn ran Roberto ati Isabel lọwọ, yoo ní inudidun lati ràn ọ́ lọwọ la awọn ọdun wọnyi já.

Nigba ti o ń duro de imuṣẹ awọn ileri Ọlọrun, ṣìkẹ́ ìdókòwò rẹ nipa gbigbe ni ibamu pẹlu irohin rere naa, ní gbigbadun alaafia èrò-inú ati gbígbé ipo-ibatan ti ó tubọ ṣe timọtimọ pẹlu Ọlọrun ró. Ìdókòwò rẹ yoo wà láìléwu—kò sí ilọsilẹ ọrọ̀-ajé tabi ìrugùdù ti oṣelu ti yoo halẹ̀ mọ́ ọn. Ati nikẹhin, yoo mú èrè agbayanu wá fun ọ. Ki ni èrè yẹn? Aposteli Johannu kọwe pe: “Ayé sì ń kọja lọ, ati ifẹkufẹẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti ó bá ń ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.”—1 Johannu 2:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Awọn irugbin irohin rere naa bọ́ sori oniruuru ilẹ ọtọọtọ

[Credit Line]

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́