Atobilọla Ẹlẹdaa Wa Ati Awọn Iṣẹ́ Rẹ̀
ÓTI TOBILỌLA TÓ! Ìtàkìtì omi adún-bí-àrá ti Iguaçú tabi ti Niagara, afonifoji tooro olomi pipẹtẹri ti Arizona tabi Hawaii, ibi àbáwọlé omi okun gbigborin ti Norway tabi New Zealand—iru igbe fifanilọkanmọra wo ni awọn iyanu iṣẹda wọnyi ń ké jade! Ṣugbọn wọn ha wulẹ jẹ imujade èèṣì ti eyi ti a ń fẹnu lasan pe ni Agbara-idari Yèyé Iṣẹda kan bi? Bẹẹkọ, wọn fi pupọpupọ jù bẹẹ lọ! Wọn jẹ awọn iṣẹ́ àrímáleèlọ ti Atobilọla Ẹlẹdaa kan, Baba ọrun onifẹẹ nipa ẹni ti ọlọgbọn Ọba Solomoni kọwe pe: “O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgbà tirẹ; pẹlupẹlu o fi ayeraye si wọn ni àyà, bẹẹ ni ẹnikan kò lè ridii iṣẹ́ naa ti Ọlọrun ń ṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin.” (Oniwasu 3:11) Lotiitọ, yoo gba akoko ti kò lopin kan fun awọn eniyan lati ṣawari gbogbo iṣẹ́ ológo ti Ẹlẹdaa wa ti fikun inu agbaye.
Ẹlẹdaa ti a ni ti jẹ́ Atobilọla tó! Bawo ni awa si ti layọ tó pe Ọlọrun alagbara julọ yii “ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ ọmọ rẹ̀ bá wa sọrọ, ẹni ti o fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nipasẹ ẹni ti ó dá awọn ayé pẹlu.” (Heberu 1:2) Ọmọkunrin yii, Jesu Kristi, mọriri awọn nǹkan meremere inu iṣẹda Baba rẹ. O tọka si wọn lati ìgbà de ìgbà ni ṣiṣakawe awọn ète Baba rẹ̀ ati ni sisọ ọ̀rọ̀ iṣiri fun awọn ti wọn tẹtisilẹ si i. (Matteu 6:28-30; Johannu 4:35, 36) “Nipa igbagbọ” ọpọlọpọ ti kiyesi pe awọn iyanu iṣẹda ni “a ti dá . . . nipa ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” (Heberu 11:3) Igbesi-aye wa ojoojumọ gbọdọ fi iru igbagbọ bẹẹ hàn.—Jakọbu 2:14, 26.
Eyi ti o tobilọla, niti tootọ, ni awọn iṣẹda Ọlọrun wa. Wọn gbé ọgbọ́n rẹ̀, agbara rẹ̀, òdodo rẹ̀, ati ifẹ rẹ̀ yọ lọna agbayanu. Fun apẹẹrẹ, o dagun ori ilẹ̀-ayé wa ó sì fi si ipo ìrìn kaakiri yipo oorun ki eniyan, iṣẹda rẹ̀ ọjọ iwaju, baa lè gbadun itolọwọọwọ awọn akoko amuni kun fun idunnu. Ọlọrun sọ pe: “Niwọn ìgbà ti ayé yoo wà, ìgbà irugbin, ati ìgbà ikore, ìgbà otutu ati ooru, ìgbà ẹrun oun òjò, ati ọ̀sán ati òru, ki yoo dẹkun.” (Genesisi 8:22) Siwaju sii, Ọlọrun fi awọn alumọọni ilẹ ti o ṣeyebiye lọpọ yanturu kun ori ilẹ̀-ayé wa fọ́fọ́. Paapaa julọ, o pese omi ti o pọ̀, eyi ti o wa di ohun eelo ti o ṣe koko ati itilẹhin fun iwalaaye lori ilẹ lẹhin-ọ-rẹhin.
Ninu ‘awọn ọjọ iṣẹda’ mẹfa ti o tò tẹlera letoleto, ti ọkọọkan ti jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ni gigun, “ẹmi Ọlọrun” ń tẹsiwaju lati mura ori ilẹ̀-ayé silẹ fun gbigbe awọn eniyan. Ìmọ́lẹ̀ nipasẹ eyi ti a ń riran, atẹgun ti a ń mí simu, ori ilẹ gbigbẹ lori eyi ti a ń gbe, awọn eweko, itotẹlera ọ̀sán ati òru, awọn ẹja, ẹyẹ, ẹranko—gbogbo wọn ni a mú jade bi o ti yẹ ki o ri lati ọwọ́ Atobilọla Ẹlẹdaa wa fun ìlò ati igbadun awọn eniyan. (Genesisi 1:2-25) Dajudaju, a le darapọ mọ́ olorin naa ni kikigbe tiyanutiyanu pe: “Oluwa, iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó! Ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kun fun ẹ̀dá rẹ.”—Orin Dafidi 104:24.
Àgbà-iṣẹ́ Iṣẹda ti Ọlọrun
Bi “ọjọ” iṣẹda kẹfa ti ń pari lọ, Ọlọrun ṣe ọkunrin ati lẹhin naa oluranlọwọ rẹ, obinrin. Mimu iṣẹda ori ilẹ̀-ayé wá si ipari ti o fi òye-iṣẹ́ giga hàn, eyi ti o jẹ́ agbayanu lọpọlọpọ ju gbogbo iṣẹda ti o ṣeefojuri ti o tíì ṣẹlẹ ri lọ ni eyi jẹ́! Orin Dafidi 115:16 fi tó wa leti pe: “Ọrun àní ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn ayé ni o fifun awọn ọmọ eniyan.” Ni ibamu pẹlu eyi, Jehofa ṣọnà awa alààyè ọkàn ki a baà lè ni inudidun ninu awọn iṣẹda rẹ̀ atetekọṣe lori ilẹ̀-ayé ki a si ṣamulo wọn. Bawo ni o ti yẹ ki a kun fun ọpẹ́ tó fun oju wa—ti o tubọ diju lati loye ju ẹ̀rọ ìya-fọ́tò didara julọ—eyi ti o lè wo ayé alawọ meremere ti o yí wa ka! A ní awọn etí wa—ti o dara ju eto ohùn eyikeyii ti a ṣe lati ọwọ́ eniyan lọ—ti ń ràn wá lọwọ lati gbadun ijumọsọrọpọ, ohùn-orin, ati orin aladun ti awọn ẹyẹ. A ní eto iṣẹ ẹ̀rọ ọ̀rọ̀ sísọ ti a dá mọ́ wa, eyi ti o ni ninu ahọ́n wa ti o lè lọ sókè-sódò. Awọn iho ìtọ́-nǹkan-wò ahọ́n wa, papọ pẹlu agbara igbooorun, bakan naa ń mú idunnu wá ni gbigbadun itọwo alailopin ti oniruuru awọn ounjẹ. Ẹ sì wo bi a ti mọriri ifọwọkanni onifẹẹ kan tó! Dajudaju a le dupẹ lọwọ Ẹlẹdaa wa, gẹgẹ bi olorin naa ti ṣe ẹni ti o sọ pe: “Emi o yin ọ; nitori tẹrutẹru ati tiyanutiyanu ni a dá mi: iyanu ni iṣẹ́ rẹ; eyiini ni ọkàn mi si mọ̀ dajudaju.”—Orin Dafidi 139:14.
Iṣeun-ifẹ Ẹlẹdaa Wa
Olorin naa kọwe pe: “Ẹ fi ọpẹ́ fun Jehofa, Óò ẹyin eniyan, nitori pe oun dara . . . ; fun Oluṣe awọn nǹkan yiyanilẹnu ti o galọla lati ọwọ oun funraarẹ: nitori iṣeun-ifẹ rẹ̀ jẹ́ titi ayeraye.” (Orin Dafidi 136:1-4, NW) Iṣeun-ifẹ yẹn ń sun un nisinsinyi lati ṣe awọn nǹkan iyanu eyi ti o tobilọla fíìfíì ju gbogbo awọn iṣẹda ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣapejuwe tán. Bẹẹni, àní nigba ti o ń sinmi kuro ninu ṣiṣẹda awọn ohun ti a lè fojuri paapaa, o ń ṣẹda lori ipele ti ẹmi kan. Eyi ni oun ń ṣe ni idahun si ipenija buburu kan ti a dari ni taarata ni ọ̀nà ti ń muni binu si i. Bawo ni o ṣe rí bẹẹ?
Ọkunrin ati obinrin akọkọ ni a fi sinu paradise ológo kan, Edeni. Bi o ti wu ki o ri, angeli ọlọtẹ kan, Satani, gbé ara rẹ̀ dide gẹgẹ bi ọlọrun kan o sì ṣamọna tọkọtaya eniyan akọkọ naa sinu iṣọtẹ lodisi Jehofa. Lọna ti o bá idajọ òdodo mu, Ọlọrun dá wọn lẹbi iku, pẹlu abajade naa pe awọn ọmọ wọn, apapọ gbogbo iran eniyan, ni a ti mu jade lati inu ipo ẹ̀ṣẹ̀, ati iku. (Orin Dafidi 51:5) Akọsilẹ Bibeli ti o niiṣe pẹlu Jobu fihàn pe Satani pe Ọlọrun nija, ni jijẹwọ pe kò si eniyan ti o lè pa iwa-titọ rẹ̀ mọ́ si I labẹ idanwo. Ṣugbọn Jobu fi Satani hàn bi òpùrọ́ paraku, gẹgẹ bi ọpọ awọn iranṣẹ Ọlọrun oluṣotitọ miiran ni awọn akoko ti a kọ Bibeli ati titi di ọjọ tiwa yii ti ṣe. (Jobu 1:7-12; 2:2-5, 9, 10; 27:5) Jesu, gẹgẹ bi ọkunrin pipe kan, ṣapẹẹrẹ ipawatitọmọ alailẹgbẹ kan.—1 Peteru 2:21-23.
Nipa bayii, Jesu lè sọ pe, “Nitori alade ayé yii [Satani] wá, kò si ni nǹkankan lọdọ mi.” (Johannu 14:30) Sibẹ, titi di akoko yii “gbogbo ayé ni o wà ni agbara ẹni buburu nì.” (1 Johannu 5:19) Lẹhin pipe ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọba-alaṣẹ agbaye ti Jehofa níjà, Satani ni a ti fun ni nǹkan bii 6,000 ọdun lati fihàn boya iṣakoso tirẹ lori iran eniyan lè kẹ́sẹjárí. Ẹ wo bi oun ti kùnà lọna ti kò muni layọ tó gẹgẹ bi awọn ipo ayé tí ń bajẹ siwaju ati siwaju sii ti ń jẹrii sii! Ọlọrun wa onifẹẹ, Jehofa, yoo mu awujọ ayé ti o ti dibajẹ yii kuro laipẹ, ni jijẹwọ ipo ọba-alasẹ agbaye títọ́ rẹ̀ lori ayé. Ẹ wo iru idẹra alayọ ti iyẹn yoo mu wa fun iran eniyan ti wọn ń yanhanhan fun iṣakoso alalaaafia, ati olododo!—Orin Dafidi 37:9-11; 83:17, 18.
Bi o ti wu ki o ri, kò tán sibẹ! Iṣeun-ifẹ Ọlọrun ni a o tun fihàn siwaju sii lori ipilẹ ọ̀rọ̀ Jesu ni Johannu 3:16 pe: “Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ má baà ṣègbé , ṣugbọn ki ó lè ni ìyè ainipẹkun.” Imupadabọsipo ifojusọna ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé fun iran eniyan yii wémọ́ dídá awọn ohun titun. Ki ni awọn wọnyi? Bawo ni wọn ṣe ṣanfaani fun iran eniyan tí ń kérora? Ọrọ-ẹkọ wa ti o tẹle e yoo sọ.