Ṣíṣe Oluṣọ-agutan Pẹlu Atobilọla Ẹlẹdaa Wa
“Oluwa ni Oluṣọ-agutan mi; emi kì yoo ṣe alaini. Ó tu ọkàn mi lára; ó mú mi lọ nipa ọ̀nà ododo nitori orukọ rẹ̀.”—ORIN DAFIDI 23:1, 3.
1. Iru itura onifẹẹ wo ni Jehofa pese?
ORIN Dafidi kẹtalelogun, “orin-adùnyùngbà ti Dafidi,” ti mú itura wá fun ọpọlọpọ ọkàn ti ń ṣàárẹ̀. Ó ti fun wọn niṣiiri lati ní igbọkanle ti a sọrọ rẹ̀ ni ẹsẹ 6 pe: “Nitootọ, ire ati aanu ni yoo maa tọ̀ mi lẹhin ni ọjọ ayé mi gbogbo; emi ó sì maa gbé inu ile Oluwa laelae.” Iyẹn ha jẹ́ ìfẹ́-ọkàn rẹ lati maa gbé ninu ile ijọsin Jehofa ni gbogbo ìgbà, ni isopọṣọkan pẹlu awọn eniyan rẹ̀ ti a ń kójọ nisinsinyi lati inu gbogbo orilẹ-ede ilẹ̀-ayé? “Oluṣọ-agutan ati alaboojuto ọkàn yin,” Atobilọla Ẹlẹdaa wa, Jehofa Ọlọrun, yoo ràn ọ́ lọwọ lati jẹ́ ki ọwọ́ rẹ tẹ gongo yẹn.—1 Peteru 2:25, NW.
2, 3. (a) Bawo ni Jehofa ṣe ń fi tifẹtifẹ ṣe oluṣọ-agutan awọn eniyan rẹ̀? (b) Bawo ni “ọ̀wọ́-ẹran” Jehofa ṣe ń lọ soke lọna ti ń muni jígìrì?
2 Ẹlẹdaa “awọn ọrun titun ati ayé titun” naa jẹ́ Oluṣeto ati Alaboojuto Titobi Julọ ti ijọ Kristian, “ile Ọlọrun.” (2 Peteru 3:13; 1 Timoteu 3:15) Oun lọkan-ifẹ jijinlẹ ninu ṣiṣoluṣọ awọn eniyan rẹ̀, gẹgẹ bi Isaiah 40:10, 11 ṣe sọ ọ ni kedere pe: “Kiyesii, Oluwa Jehofa yoo wá ninu agbara, apá rẹ̀ yoo ṣe akoso fun un: kiyesii, èrè rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ niwaju rẹ̀. Oun ó bọ́ ọ̀wọ́-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agutan: yoo sì fi apá rẹ̀ kó awọn ọdọ-agutan, yoo sì kó wọn sí àyà rẹ̀, yoo sì rọra da awọn ti ó loyun.”
3 Ni èrò-ìtumọ̀ kan ti ó gbooro, “ọ̀wọ́-ẹran” yii ní awọn wọnni ti wọn ti rìn ninu otitọ Kristian fun ìgbà pípẹ́ ninu ati “awọn ọdọ-agutan” ti a ti kojọ ni awọn akoko lọ́ọ́lọ́ọ́ yii—bi iru iye ńláǹlà ti a ń baptisi ni Africa ati iha Ila-oorun Europe nisinsinyi. Apa alagbara, ati adaaboboni ti Jehofa ń kó wọn jọ si oókan-àyà rẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti dabi awọn agutan ti ó sako lọ nigba kan ri, wọn ti wá sinu ibatan timọtimọ kan pẹlu Ọlọrun onifẹẹ ati Oluṣọ-agutan wọn.
Oluṣọ-agutan Alabaakẹgbẹ Ti Jehofa
4, 5. (a) Ta ni “oluṣọ-agutan rere” naa, bawo sì ni asọtẹlẹ ṣe tọka sí i? (b) Iru iṣẹ́ iyasọtọ wo ni Jesu ń ṣabojuto rẹ̀, pẹlu iyọrisi titayọ wo?
4 Ni ṣiṣiṣẹsin ni apa ọ̀tún Baba rẹ̀ ni ọrun, “oluṣọ-agutan rere” naa, Jesu Kristi, tun fi akiyesi oníyọ̀ọ́nú fun “awọn agutan” pẹlu. Ó fi iwalaaye rẹ̀ lélẹ̀ lati ṣanfaani lakọọkọ fun “agbo kekere” ti awọn ẹni-ami-ororo ati lẹhin naa, lonii, awọn ogunlọgọ ńlá ti “agutan miiran” rẹ̀. (Luku 12:32; Johannu 10:14, 16) Oluṣọ-agutan Titobi Julọ, Jehofa Ọlọrun, bá gbogbo awọn agutan wọnyi sọrọ, ni sisọ pe: “Kiyesi, emi, àní emi, ó ṣe idajọ laaarin ọ̀wọ́ ẹran ti ó sanra, ati eyi ti ó rù. Emi ó sì gbé oluṣọ-agutan kan soke lori wọn, oun ó sì bọ́ wọn, àní Dafidi iranṣẹ mi; oun ó bọ́ wọn, oun ó sì jẹ́ oluṣọ-agutan wọn. Emi Oluwa yoo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi ó jẹ́ ọmọ-alade laaarin wọn, emi Oluwa ni ó ti sọ ọ́.”—Esekieli 34:20-24.
5 Iyansipo-iṣẹ “iranṣẹ mi Dafidi” tọka lọna alasọtẹlẹ si Kristi Jesu, “iru-ọmọ” naa ti ó jogun ìtẹ́ Dafidi. (Orin Dafidi 89:35, 36) Ni ọjọ idajọ awọn orilẹ-ede yii, Oluṣọ-agutan alabaakẹgbẹ ti Jehofa ati Ọba, Kristi Jesu, Ọmọkunrin Dafidi, ń baa lọ lati ṣe iyasọtọ laaarin “agutan” iran eniyan kuro lara awọn wọnni ti wọn jẹwọ jíjẹ́ “agutan” ṣugbọn ti wọn jẹ́ “ewurẹ” niti gidi. (Matteu 25:31-33) “Oluṣọ-agutan kan” yii ni a gbé dide pẹlu lati bọ́ awọn agutan. Ẹ wo iru imuṣẹ ológo ti asọtẹlẹ yii ti a ń ri lonii! Nigba ti awọn oṣelu ń sọrọ nipa siso araye pọ ṣọkan nipasẹ eto ayé titun kan, Oluṣọ-agutan kan naa ń so awọn agutan gbogbo orilẹ-ede pọ ṣọkan niti gidi nipasẹ igbetaasi ijẹrii ọlọpọ èdè naa iru eyi ti o jẹ́ pe kìkì eto-ajọ Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé nikan ni ó jẹ́ dabaa lati dáwọ́lé irú rẹ̀.
6, 7. Bawo ni “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ṣe rí sii pe ‘ounjẹ ni akoko yiyẹ’ ni a mú wa larọọwọto fun awọn agutan?
6 Bi ihin-iṣẹ Ijọba naa ti ń tàn ká awọn ipinlẹ titun lemọlemọ, “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ti awọn Kristian ẹni-ami-ororo, gẹgẹ bi a ṣe paṣẹ fun wọn lati ọwọ́ Oluṣọ-agutan kanṣoṣo naa, rí sí i pe gbogbo ipese ni a ṣe lati ran ‘ounjẹ ni akoko yiyẹ’ jade. (Matteu 24:45, NW) Ọpọ ninu awọn ẹ̀ka itẹwe 33 ti Watch Tower Society kaakiri ilẹ̀-ayé ń jẹ ki imujade lọ soke lati kunju awọn ibeere ti ń ga soke sii fun iwe-ikẹkọọ ati iwe-irohin Bibeli ti ó pọ̀ ti ó sì tubọ dara sii.
7 Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe lati mú ki ijojulowo itumọ ni awọn èdè bii 200 tubọ dara sii ati lati bẹrẹ itumọ ni awọn afikun èdè sii gẹgẹ bi a ti nilo rẹ̀ lati lè kari gbogbo pápá ayé. Eyi jẹ́ ni itilẹhin fun àṣẹ ti Jesu fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni Iṣe 1:8 pe: “Ṣugbọn ẹyin ó gba agbara, nigba ti Ẹmi Mimọ bá bà le yin: ẹ ó sì maa ṣe ẹlẹ́rìí mi . . . titi dé opin ilẹ̀-ayé.” Siwaju sii, Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures, eyi ti a ti tẹ̀ ni odindi tabi ni apakan ni èdè 14, ni a ń tumọ nisinsinyi si èdè 16 miiran ni Europe, Africa, ati ni ilẹ Gabasi.
Gbigbadun “Alaafia Ọlọrun”
8. Bawo ni a ṣe bukun awọn agutan ni jingbinni nipa majẹmu alaafia ti Jehofa ti bá wọn dá?
8 Nipasẹ Oluṣọ-agutan kan rẹ̀, Kristi Jesu, Jehofa bá awọn agutan Rẹ̀ ti a bọ́ yó dá “majẹmu alaafia” kan. (Isaiah 54:10) Ni lílo igbagbọ ninu ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ, awọn agutan ni a mu ki o ṣeeṣe fun lati rìn ninu ìmọ́lẹ̀. (1 Johannu 1:7) Wọn ń gbadun ‘alaafia Ọlọrun ti ó ju imọran gbogbo lọ ti ó sì ń ṣọ́ ọkàn ati èrò wọn ninu Kristi Jesu.’ (Filippi 4:7) Gẹgẹ bi Esekieli 34:25-28 ṣe ń baa lọ lati ṣapejuwe, Jehofa ń dari awọn agutan rẹ̀ sinu paradise tẹmi, ipo aabo amunilayọ kan, aasiki ti ń tunilara, ati imesojade. Oluṣọ-agutan onifẹẹ yii sọ nipa awọn agutan rẹ̀ pe: “Wọn ó sì mọ pe emi ni Oluwa, nigba ti emi ó ti ṣẹ edidi ajaga wọn, ti emi ó sì ti gbà wọn lọwọ awọn ti wọn ń sìn bi ẹrú. Wọn kì yoo sì ṣe ìjẹ fun awọn Keferi mọ, . . . ṣugbọn wọn ó wà ni alaafia ẹnikẹni kì yoo sì dẹ́rù bà wọn.”
9. Awọn anfaani wo ni ó ti ṣí silẹ fun awọn eniyan Ọlọrun nipa ‘ṣiṣẹ edidi’?
9 Ṣaaju, ninu awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́ yii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ọpọlọpọ orilẹ-ede ti ni iriri ṣiṣẹ “edidi ajaga.” Wọn lominira lati waasu ju ti igbakan ri lọ. Ǹjẹ́ ki gbogbo wa, ni gbogbo ilẹ, lo aabo ti Jehofa pese lọna rere bi a ti ń tẹsiwaju lati ṣe iṣẹ́ naa laṣepari. Iru imudaniloju lẹẹkansii wo ni Jehofa ń pese bi a ti ń sunmọ akoko ipọnju nla julọ ti araye yoo kọ́kọ́ rí rí!—Danieli 12:1; Matteu 24:21, 22.
10. Ta ni Jehofa ti pese lati ṣeranlọwọ fun Oluṣọ-agutan Rere naa, Kristi Jesu, bawo sì ni aposteli Paulu ṣe bá diẹ ninu awọn wọnyi sọrọ?
10 Ni imurasilẹ fun ọjọ ibinu rẹ̀ yẹn lodisi awọn ẹni buburu, Jehofa ti pese awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ lati ṣeranlọwọ fun Oluṣọ-agutan Rere naa, Kristi Jesu, ni bibojuto agbo. Awọn wọnyi ni a ṣapejuwe ninu Ìfihàn 1:16 gẹgẹ bi iye pípé perepere ti “irawọ meje” ni ọwọ́ ọ̀tún Jesu. Ni ọrundun kìn-ín-ní, aposteli Paulu bá ẹgbẹ ti ń ṣoju fun awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ wọnyi sọrọ, ni sisọ pe: “Ẹ kiyesi araayin, ati si gbogbo agbo ti ẹmi mimọ fi yin ṣe alaboojuto rẹ̀, lati maa tọju ijọ Ọlọrun, ti ó ti fi ẹ̀jẹ̀ [Ọmọkunrin rẹ̀, NW] rà.” (Iṣe 20:28) Lonii, ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa-mẹwaa awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ ni ó wà tí wọn ń ṣiṣẹsin ninu 69,558 awọn ijọ kaakiri ilẹ̀-ayé.
Awọn Oluṣọ-agutan Ọmọ-abẹ Lọwọ Iwaju!
11. Bawo ni awọn oluṣọ-agutan melookan ti ṣe fi aṣeyọrisirere mu ipo iwaju ni awọn ipinlẹ ti a ń kari lemọlemọ?
11 Ni ọpọlọpọ ibi awọn oluṣọ-agutan wọnyi gbọdọ mú ipo iwaju ninu awọn ipinlẹ ti a ti kárí leralera ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi. Bawo ni wọn ṣe lè mú kí itara-ọkàn awọn agbo wà ni ipele ti ó ga? Awọn oluṣọ-agutan naa ti ń ṣiṣẹ lọna ti a fi lè gboriyin fun wọn gidigidi, ọ̀kan ninu awọn ọ̀nà ti wọn sì ti gbà ṣaṣeyọri jẹ́ nipa ríru iṣẹ́ aṣaaju-ọna deedee ati oluranlọwọ soke. Ọpọ awọn oluṣọ-agutan ti funraawọn nipin-in ninu iṣẹ-isin yii, ti awọn akede wọnni ti wọn kò si lè ṣe bẹẹ paapaa sì ti fi ẹmi aṣaaju-ọna hàn, ni fifi ayọ ti ń ṣeranlọwọ ni bibori ẹ̀tanú ni ipinlẹ naa ṣiṣiṣẹsin. (Orin Dafidi 100:2; 104:33, 34; Filippi 4:4, 5) Nipa bayii, bi iwa-buburu ati eyi ti o sunmọ rukerudo ẹlẹ́hànnà ṣe ń bo ayé mọlẹ, ọpọ awọn ẹni-bi-agutan ni a ń tají si ireti Ijọba naa.—Matteu 12:18, 21; Romu 15:12.
12. Iṣoro lilekoko wo ni ó dide ni awọn pápá ti ń dagbasoke kánkán, bawo ni a sì ṣe ń bojuto eyi nigba miiran?
12 Iṣoro miiran ni pe lọpọ ìgbà kìí sí awọn oluṣọ-agutan ti o tootun tó lati bojuto agbo. Nibi ti idagbasoke ti ó yara kánkán bá wà, gẹgẹ bi o ti ri ni iha Ila-oorun Europe, ọpọ awọn ijọ titun ni wọn wà laini awọn alagba ti a yànsípò rárá. Awọn agutan onifẹẹ-imuratan tẹwọgba ẹrù naa, ṣugbọn wọn jẹ alainiriiri rárá, iranlọwọ ni a sì nilo lati lè dá awọn agutan ti ń rọ́wọnú awọn ijọ lẹkọọ. Ni awọn ilẹ bii Brazil, Mexico, ati Zaire, nibi ti idagbasoke ti yára kánkán, awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni ifiwera ni a nilati lò ninu ṣiṣeto iṣẹ-isin ati dídá awọn ẹni titun yooku lẹkọọ. Awọn aṣaaju-ọna ń funni ni iranlọwọ ti ó pegede, ibi yii sì ni pápá kan nibi ti awọn arabinrin ti lè dá awọn arabinrin titun lẹkọọ. Jehofa nipasẹ ẹmi rẹ̀ ń bukun awọn abajade naa. Ibisi naa ń baa lọ lati maa wá.—Isaiah 54:2, 3.
13. (a) Niwọn bi ikore ti pọ̀ gidigidi, ki ni gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí gbọdọ gbadura fun? (b) Bawo ni a ṣe dahun adura awọn eniyan Ọlọrun ṣaaju ati nigba ogun agbaye keji?
13 Ni awọn ilẹ nibi ti iṣẹ́ iwaasu naa ti di eyi ti o fidimulẹ daradara, ni awọn ilẹ nibi ti a ti mú ikalọwọko kuro ni lọ́ọ́lọ́ọ́, ati ni awọn ipinlẹ ti a ṣẹṣẹ ṣí ni titun, awọn ọ̀rọ̀ Jesu ni Matteu 9:37, 38 ṣì ṣee fisilo sibẹ pe: “Loootọ ni ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan; nitori naa ẹ gbadura si Oluwa ikore ki ó rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.” A nilati gbadura, bakan naa pẹlu, pe Jehofa yoo gbé awọn oluṣọ-agutan pupọ sii dide. Oun ti fihàn pe oun lè ṣe eyi. Ṣaaju ati nigba Ogun Agbaye II, awọn alaṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ buburu bi awọn ará Assiria gbiyanju lati pa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa run. Ṣugbọn ni idahun si adura wọn, Jehofa tun eto-ajọ wọn ṣe bọsipo, ni mímú ki o jẹ ti iṣakoso Ọlọrun nitootọ, ti ó sì pese “awọn oluṣọ-agutan” ti a nilo.a Eyi wà ni ibamu pẹlu asọtẹlẹ naa pe: “Nigba ti ará Assiria yoo wá si ilẹ wa; nigba ti yoo sì tẹ awọn aafin wa mọlẹ, nigba naa ni awa o gbé oluṣọ-agutan meje dide sii, ati olori eniyan mẹjọ”—àní ju awọn alagba oluṣeyasimimọ ti ó tó lati mú ipo iwaju lọ paapaa.—Mika 5:5.
14. Aini titayọ wo ni ó dide ninu eto-ajọ, iṣiri wo ni a sì fifun awọn arakunrin?
14 Aini titayọ wà fun gbogbo awọn ọkunrin Ẹlẹ́rìí ti wọn ti ṣe iribọmi lati nàgà fun awọn anfaani siwaju sii. (1 Timoteu 3:1) Ipo naa jẹ́ kanjukanju. Opin eto-igbekalẹ yii ń sunmọle kíkankíkan. Habakkuku 2:3 sọ pe: “Nitori ìran naa jẹ́ ti ìgbà kan ti a yàn, yoo maa yára si igbẹhin, kì yoo sì ṣeke, . . . nitori ní dídé, yoo dé kì yoo pẹ́.” Ẹyin arakunrin, ẹ ha lè nàgà lati lè tootun fun awọn anfaani siwaju sii ninu iṣẹ́ ṣíṣe oluṣọ-agutan yii—ṣaaju ki opin tó dé bi?—Titu 1:6-9.
Ṣiṣe Oluṣọ-agutan Lọna ti Iṣakoso Ọlọrun
15. Ni ọ̀nà wo ni awọn eniyan Jehofa gbà jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun?
15 Lati lè nipin-in ni kikun ninu igbooro siwaju sii eto-ajọ Jehofa, awọn eniyan rẹ̀ nilati jẹ́ ki oju-iwoye wọn jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun. Bawo ni wọn ṣe lè ṣaṣepari eyi? Ó dara, ki ni èdè isọrọ naa “ti iṣakoso Ọlọrun” tumọsi? Webster’s New Twentieth Century Dictionary tumọ “iṣakoso Ọlọrun” gẹgẹ bi “iṣakoso orilẹ-ede kan lati ọwọ Ọlọrun.” Ni èrò itumọ yii ni “orilẹ-ede mimọ” ti awọn eniyan Jehofa gbà jẹ́ iṣakoso Ọlọrun. (1 Peteru 2:9; Isaiah 33:22) Gẹgẹ bi awọn mẹmba tabi alabaakẹgbẹ orilẹ-ede ti iṣakoso Ọlọrun yẹn, awọn Kristian tootọ gbọdọ gbé igbesi-aye ki wọn sì ṣiṣẹsin ni igbọran si Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati awọn ilana rẹ̀.
16. Bawo, niti gidi, ni a ṣe lè fi araawa hàn pe a jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun?
16 Aposteli Paulu ṣalaye ni kedere bi awọn Kristian ṣe nilati jẹ ti iṣakoso Ọlọrun. Lakọọkọ, ó sọ pe wọn gbọdọ “gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyi ti a dá nipa ti Ọlọrun ni ododo ati ni iwa mimọ otitọ.” Akopọ animọ Kristian ni a gbọdọ mọ ni ibamu pẹlu awọn ilana ododo ti Ọlọrun ti a gbekalẹ ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O gbọdọ jẹ́ aduroṣinṣin si Jehofa ati si awọn ofin Rẹ̀. Lẹhin ṣiṣapejuwe bi a ṣe lè se eyi, Paulu rọ̀ wá pe: “Ẹ maa ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n.” (Efesu 4:24–5:1) Gẹgẹ bi awọn ọmọ onigbọran, a gbọdọ ṣafarawe Ọlọrun. Iyẹn jẹ́ iṣakoso Ọlọrun tootọ lẹnu iṣẹ́, ni fífihàn pe a ń ṣakoso wa niti gidi lati ọwọ Ọlọrun!—Wo Kolosse 3:10, 12-14 pẹlu.
17, 18. (a) Animọ titayọ ti Ọlọrun wo ni awọn Kristian ti iṣakoso Ọlọrun ń ṣafarawe? (b) Ninu awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ si Mose, bawo ni Jehofa ṣe tẹnumọ animọ Rẹ̀ ṣiṣekoko julọ, ṣugbọn ikilọ wo ni Ó fikun un?
17 Ki ni animọ pataki ti Ọlọrun ti a gbọdọ ṣafarawe? Aposteli Johannu dahun ninu 1 Johannu 4:8 (NW) nigba ti o sọ pe: “Ọlọrun jẹ́ ifẹ.” Ẹsẹ mẹjọ lẹhin naa, ni ẹsẹ 16, ó tun ilana ṣiṣekoko yii sọ pe: “Ọlọrun jẹ́ ifẹ, ẹni ti ó bá sì duro ninu ifẹ wà ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun tí Ọlọrun sì wà ni irẹpọ pẹlu rẹ̀.” Oluṣọ-agutan Nla naa, Jehofa, jẹ́ ogidi-apẹẹrẹ ifẹ. Awọn oluṣọ-agutan ti iṣakoso Ọlọrun ṣafarawe rẹ̀ nipa fifi ifẹ jijinlẹ hàn fun awọn agutan Jehofa.—Fiwe 1 Johannu 3:16, 18; 4:7-11.
18 Ọlọrun Alakoso Nla naa ṣí araarẹ̀ payá fun Mose gẹgẹ bi “OLUWA, OLUWA, Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti ó pọ̀ ni oore ati otitọ; ẹni ti ó ń pa aanu mọ́ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti ó ń dari aiṣedeedee, ati irekọja, ati ẹṣẹ jì, ati nitootọ ti kìí jẹ ki ẹlẹbi lọ laijiya; a maa bẹ ẹṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara ọmọ-ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin.” (Eksodu 34:6, 7) Jehofa tipa bayii tẹnumọ oniruuru ẹ̀ka animọ iṣakoso Ọlọrun titayọ rẹ̀, ifẹ, nigba ti ó ń ṣekilọ taratara pe oun yoo fiya jẹ awọn eniyan fun aṣiṣe nigba ti ó bá yẹ bẹẹ.
19. Ni ifiwera pẹlu awọn Farisi, bawo ni awọn oluṣọ-agutan Kristian ṣe gbọdọ huwa ni ọ̀nà ti iṣakoso Ọlọrun?
19 Fun awọn wọnni ti wọn ni ipo ẹrù-iṣẹ́ ninu eto-ajọ naa, ki ni ohun ti o tumọ si lati jẹ́ ẹni ti iṣakoso Ọlọrun? Jesu sọ nipa awọn akọwe ati Farisi ti ọjọ rẹ̀ pe: “Nitori wọn a di ẹrù wuwo ti ó sì ṣoro lati rù, wọn a sì gbe e ka awọn eniyan ni ejika; ṣugbọn awọn tikaraawọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan ẹrù naa.” (Matteu 23:4) Eyiini ti jẹ́ agbonìmọ́lẹ̀ ati alainifẹẹ tó! Iṣakoso Ọlọrun tootọ, tabi akoso-Ọlọrun, ń beere fun ṣiṣe oluṣọ-agutan agbo nipa fifi awọn ilana onifẹẹ Bibeli silo, kìí ṣe nipa didi ẹrù ru awọn agutan pẹlu awọn ofin alailopin ti a ti ọwọ́ eniyan ṣe. (Fiwe Matteu 15:1-9.) Ni akoko kan-naa, awọn oluṣọ-agutan ti iṣakoso Ọlọrun gbọdọ ṣafarawe Ọlọrun nipa fifi iduro gbọnyingbọnyin fun pípa ijẹmimọ ijọ mọ́ kun ifẹ wọn.—Fiwe Romu 2:11; 1 Peteru 1:17.
20. Awọn iṣeto ti eto-ajọ wo ni awọn oluṣọ-agutan ti iṣakoso Ọlọrun mọ̀?
20 Awọn oluṣọ-agutan tootọ mọ pe ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi, Jesu ti yan ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu rẹ̀ sori gbogbo ohun-ìní rẹ̀ ati pe ẹmi mimọ ti dari ẹrú yii ninu yíyan awọn alagba sipo fun ṣiṣe oluṣọ-agutan awọn agutan. (Matteu 24:3, 47; Iṣe 20:28) Nitori naa, jíjẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun ní ninu níní ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun ẹrú yii, fun awọn iṣeto ti eto-ajọ ti ẹrú naa ti dá silẹ, ati fun iṣeto alagba ninu ijọ.—Heberu 13:7, 17.
21. Apẹẹrẹ rere wo ni Jesu fi lélẹ̀ fun awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ́?
21 Jesu funraarẹ fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀, ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jehofa ati Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lemọlemọ fun itọsọna. Ó sọ pe: “Emi kò lè ṣe ohun kan fun ara mi: bi mo ti ń gbọ́, mo ń dajọ: ododo sì ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikaraami, bikoṣe ifẹ ti ẹni ti ó rán mi.” (Johannu 5:30) Awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ Jesu Kristi Oluwa gbọdọ mú iṣarasihuwa onirẹlẹ bẹẹ dagba. Bi alagba kan bá ń fi gbogbo ìgbà fi ọ̀ràn lọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun idari, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, nigba naa oun jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun nitootọ.—Matteu 4:1-11; Johannu 6:38.
22. (a) Ni ọ̀nà wo ni gbogbo wa fi gbọdọ lakaka lati jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun? (b) Ikesini oninurere wo ni Jesu fifun awọn agutan?
22 Ẹyin ọkunrin ti ẹ ti ṣe iribọmi, ẹ nàgà lati tootun fun awọn anfaani ninu ijọ! Gbogbo ẹyin agutan ọ̀wọ́n, ẹ fi ṣe gongo lati jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun, ni ṣiṣafarawe Ọlọrun ati Kristi ni fifi ifẹ hàn! Ǹjẹ́ ki awọn oluṣọ-agutan ati agbo bakan naa yọ̀ nitori pe wọn ti dahun ikesini Jesu pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ń ṣíṣẹ̀ẹ́, ti a sì di ẹrù wuwo lé lori, emi ó sì fi isinmi fun yin. Ẹ gba ajaga mi si ọrùn yin, ki ẹ sì maa kọ́ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninututu ati onirẹlẹ ọkàn ni emi; ẹyin ó sì rí isinmi fun ọkàn yin.”—Matteu 11:28-30.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) ti ó ni akọle naa “Organization,” ninu itẹjade ti June 1 ati 15, 1938.
Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?
◻ Ki ni “ọ̀wọ́-ẹran” Jehofa, ta ni ó sì ní ninu?
◻ Bawo ni Jesu ṣe gbegbeesẹ gẹgẹ bi “oluṣọ-agutan rere” ni ọrundun kìn-ín-ní, ati lonii?
◻ Ipa ṣiṣekoko wo ni awọn oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ ń kó ninu bibojuto agbo?
◻ Ki ni itumọ abẹ́nú fun ọ̀rọ̀ naa “iṣakoso Ọlọrun”?
◻ Bawo ni Kristian kan—ni pataki julọ oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ kan—ṣe gbọdọ gbegbeesẹ ki ó baa lè jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Gẹgẹ bi oluṣọ-agutan olufọkansin kan, Jehofa ń bikita fun agbo rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣiṣafarawe animọ ifẹ ti Jehofa Ọlọrun jẹ́ iṣakoso Ọlọrun lẹnu iṣẹ́