ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 1/1 ojú ìwé 24-25
  • Gerisinu—‘Lori Oke Yii Ni A Ti Jọsin’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gerisinu—‘Lori Oke Yii Ni A Ti Jọsin’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣékémù—Ìlú Tí Ń Bẹ Nínú Àfonífojì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Jésù Kọ́ Obìnrin Ará Samáríà Kan Lẹ́kọ̀ọ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Kíkọ́ Obinrin Ara Samaria Kan Lẹkọọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 1/1 ojú ìwé 24-25

Awọn Irisi-iran Lati Ilẹ Ileri

Gerisinu—‘Lori Oke Yii Ni A Ti Jọsin’

OBINRIN ará Samaria naa tí ó wà lẹbaa kanga. Apola ọ̀rọ̀ yẹn kò ha mú akọsilẹ wiwọnilọkan ṣinṣin ti ijẹrii alaijẹ-bi-aṣa Jesu fun obinrin kan lẹbaa “isun omi Jakọbu” (NW), ni Sikari, ilu-nla Samaria kan, wá sí ọkàn rẹ bi? Iwọ yoo ha fẹ lati mú ki oju-iwoye rẹ nipa iṣẹlẹ ti o kun fun itumọ yẹn jipepe sii bi?—Johannu 4:5-14.

Ṣakiyesi awọn oke meji ti o wa loke yii, ti wọn jẹ nǹkan bii 30 ibusọ si ariwa Jerusalemu.a Ni iha apa osi (guusu) ni Gerisimu ti o kun fun igi wà; awọn isun omi ti o pọ fikun jíjẹ́ ọlọraa ati ẹwa rẹ̀. Si apa ọtun (ariwa) ni Ebali, eyi ti o ga soke diẹ ṣugbọn ti o jẹ́ olokuuta ati alailọraa.

Laaarin wọn ni afonifoji ọlọraa ti Ṣekemu gba kọja. Ranti pe nigba ti ọ̀rẹ́ Ọlọrun, Abramu (ti a pè ni Abrahamu nigba ti ó yá) rinrin-ajo la Ilẹ Ileri kọja, o duro diẹ ni Ṣekemu. Nihin-in ni o ti kọ́ pẹpẹ kan fun Jehofa, ẹni ti o ṣẹṣẹ farahan an ti o si ṣeleri ilẹ yii fun iru ọmọ rẹ̀. (Genesisi 12:5-7) Ẹ wo bi eyi ti jẹ ibi ti o bojumu tó lati ṣe iru ileri kan bẹẹ, ni aarin gbungbun ilẹ naa! Yala lati ibi ṣóńṣó Gerisimu tabi ti Ebali, baba awọn Heberu naa lè woye awọn apa ti o tobi ju ninu Ilẹ Ileri naa. Ilu-nla Ṣekemu (Nablus ode-oni) jẹ́ ibùdó igbokegbodo kan ti o ṣepataki, bi o ti wà ni aarin meji oju ọ̀nà oke ti ariwa ati guusu eyi ti o sunmọ aarin meji ọ̀nà ila-oorun oun iwọ-oorun ti ń bẹ laaarin bèbè etikun ati Afonifoji Jordani.

Pẹpẹ Abrahamu ni kìkì idagbasoke apafiyesi kanṣoṣo ti o jẹ́ ti isin nihin-in. Lẹhin naa, Jakọbu ra ilẹ ni agbegbe yii o si ń ba ijọsin tootọ lọ. O tun gbẹ́ kanga tabi sanwo fun gbigbẹ kanga jijin kan, lẹbaa isalẹ Gerisimu. Ni ọpọ ọrundun lẹhin naa obinrin ará Samaria naa sọ fun Jesu pe: “Jakọbu baba wa . . . , ẹni ti o fun wa ni kanga naa, . . . mu ninu rẹ̀.” O ti lè jẹ́ pe isun omi ni orisun omi naa, eyi ti o lè ṣalaye idi ti aposteli Johannu fi pe e ni “isun omi Jakọbu” (NW).

Mimẹnukan ti a mẹnukan ijọsin tootọ ni isopọ pẹlu Gerisimu ati Ebali tun lè mu ki o sọ si ọ lọkan pe Joṣua mu Israeli wa sihin-in, gẹgẹ bi Mose ti dari rẹ̀. Joṣua kọ́ pẹpẹ kan sori Ebali. Ronuwoye idaji awọn eniyan naa niwaju Gerisimu ati iyoku wọn niwaju Ebali gẹgẹ bi Joṣua ṣe ń ka “ọ̀rọ̀ ofin, ibukun ati ègún.” (Joṣua 8:30-35; Deuteronomi 11:29) Ni ọpọ ọdun lẹhin naa, Joṣua pada wa o sì sọ ninu igbaninimọran ti o kẹhin pe: “Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA ni awa ó maa sìn.” Awọn eniyan naa dá majẹmu lati ṣe bakan naa. (Joṣua 24:1, 15-18, 25) Ṣugbọn wọn yoo ha ṣe bẹẹ, niti gidi bi?

Idahun naa lè ràn ọ́ lọwọ lati loye ijumọsọrọpọ Jesu pẹlu obinrin ará Samaria naa. Ṣe o rii, ijọsin tootọ naa ti Abrahamu, Jakọbu, ati Joṣua tẹle ṣíwọ́ lati maa baa lọ nihin-in ni Samaria.

Lẹhin ìgbà ti awọn ẹya mẹwaa iha ariwa yà kuro, wọn yiju si ijọsin ọmọ maluu. Nitori naa Jehofa fayegba awọn ara Assiria lati ṣẹgun agbegbe yii ni 740 B.C.E. Wọn kó eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan naa lọ, ni mimu awọn ajeji wọle gẹgẹ bi afidipo lati ibomiran ni Ilẹ-ọba Assiria, awọn olujọsin awọn ọlọrun ajeji. Diẹ ninu awọn abọriṣa wọnyi ni o ṣeeṣe ki wọn ṣegbeyawo pẹlu awọn ọmọ Israeli ki wọn si kẹkọọ diẹ ninu awọn ẹkọ ijọsin tootọ, iru bi ìkọlà. Ṣugbọn ẹ̀yà ijọsin awọn ará Samaria ti o jẹ abajade rẹ̀ ni o daju pe kò tẹ́ Ọlọrun lọrun ni kikun.—2 Ọba 17:7-33.

Ninu ijọsin wọn aládàlú, awọn ará Samaria tẹwọgba kiki iwe marun-un akọkọ Mose, Pentateuch, gẹgẹ bi Iwe Mimọ. Ni nǹkan bi ọrundun kẹrin B.C.E., wọn gbe tẹmpili kan kalẹ lori Oke Gerisimu, ni idije pẹlu tẹmpili Ọlọrun ni Jerusalemu. Bi akoko ti ń lọ tẹmpili Gerisimu ni a yasimimọ fun Zeus (tabi, Jupiter) ti a sì pa á run nigbẹhin-gbẹhin. Sibẹ, Gerisimu ń baa lọ lati jẹ́ ibùdó fun ijọsin awọn ará Samaria.

Titi di oni olonii, awọn ará Samaria ń ṣe ayẹyẹ Ajọ-irekọja ọlọdọọdun lori oke Gerisimu. Awọn ọdọ-agutan ti o pọ ni a ń pa. Oku wọn ni a ń rì bọnu awọn àgbá omi gbigbona ki a baa lè fá irun ara wọn danu, nigba naa ti wọn yoo si se ẹran naa ninu ihò fun ọpọ wakati. Ni ọganjọ oru ọgọrọọrun awọn ará Samaria, ti ọpọ ti Jerusalemu wá, yoo jẹ ounjẹ ajọ irekọja wọn. Ni apa osi, iwọ le ri olori alufaa ará Samaria, ti o bo ori rẹ̀, ti o ń bojuto ijọsin nibi ayẹyẹ Ajọ Irekọja kan lori Oke Gerisimu.

Ranti ohun ti abinrin ará Samaria naa sọ fun Jesu: “Awọn baba wa sin lori oke yii.” Jesu tọ́ oun, ati awa naa pẹlu sọna pe: “Wakati ń bọ, nigba ti kì yoo ṣe lori oke yii, tabi Jerusalemu, ni ẹyin o maa sin Baba. . . . Ṣugbọn wakati ń bọ, o sì dé tán nisinsinyi, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ: nitori iru wọn ni Baba ń wa ki o maa sin oun.”—Johannu 4:20-24.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iwọ le ṣayẹwo fọto yii ni iwọn ti o tubọ tobi sii ninu 1993 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Garo Nalbandian

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́