Ṣékémù—Ìlú Tí Ń Bẹ Nínú Àfonífojì
NÍSÀLẸ̀ lọ́hùn-ún láàárín gbùngbùn ilẹ̀ tí Ọlọ́run yàn fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ní àárín Òkè Ébálì àti Òkè Gérísímù, ni ìlú Ṣékémù wà. Níhìn-ín yìí—ní nǹkan bí ẹgbàajì ọdún sẹ́yìn—ni Jèhófà ti ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Irú-ọmọ rẹ ni èmi óò fi ilẹ̀ yí fún.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:6, 7.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí yìí, ọmọ-ọmọ Ábúráhámù, Jékọ́bù, pàgọ́ sí Ṣékémù, ó sì kọ́ pẹpẹ tí ó pè ní “Ọlọ́run ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” Ó ṣeé ṣe kí Jékọ́bù ti gbẹ́ kànga kan sí àgbègbè yí láti máa pèsè omi fún ìdílé àti agbo ẹran rẹ̀, kànga tí a óò wá mọ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà sí “ìsun omi Jékọ́bù.”—Jẹ́nẹ́sísì 33:18-20, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW; Jòhánù 4:5, 6, 12.
Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo mẹ́ńbà ìdílé Jékọ́bù ni ó fi ìtara hàn fún ìjọsìn tòótọ́. Dínà, ọmọbìnrin rẹ̀, wá alábàákẹ́gbẹ́ láàárín àwọn ọmọbìnrin Kénáánì ti Ṣékémù. Dínà, tí ó ṣì wà lọ́lọ́mọge nígbà náà, kúrò lábẹ́ ààbò àgọ́ ìdílé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ ìlú tí ó wà nítòsí náà wò ní wíwá ọ̀rẹ́ níbẹ̀.
Ojú wo ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin ìlú náà yóò fi wo wúńdíá ọlọ́mọge tí ó máa ń bẹ ìlú wọn wò déédéé—tí ó hàn gbangba pé òun nìkan ni ó máa ń dá wá yìí? Ọmọ olóyè kan “rí i, ó mú un, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bà á jẹ́.” Èé ṣe tí Dínà fi fa ìjọ̀ngbọ̀n lẹ́sẹ̀ nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ara Kénáánì oníwà àìmọ́? Ó ha jẹ́ nítorí pé ó nímọ̀lára pé òun nílò ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n jẹ́ ojúgbà rẹ̀ bí? Òun ha jẹ́ olóríkunkun àti aṣetinú-ẹni bíi ti díẹ̀ lára àwọn arákùnrin rẹ̀ bí? Ka àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì, kí o sì gbìyànjú láti lóye ìrora ọkàn àti ìtìjú tí Jékọ́bù àti Léà ti ní láti nímọ̀lára rẹ̀ nítorí àbájáde oníbànújẹ́ tí ìbẹ̀wò tí ọmọbìnrin wọn ṣe sí Ṣékémù yọrí sí.—Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31; 49:5-7; tún wo Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1985, ojú ìwé 31.
Ní nǹkan bí 300 ọdún lẹ́yìn náà, ìyọrísí ṣíṣàìnáání ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run tún wá sójú táyé lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní Ṣékémù, Jọ́ṣúà ṣètò ọ̀kan nínú àwọn àpéjọ mánigbàgbé jù lọ nínú ìtàn Ísírẹ́lì. Fojú inú wo ìran náà nínú àfonífojì náà. Àwọn ènìyàn tí ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́—àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé—tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀yà mẹ́fà ti Ísírẹ́lì dúró ní iwájú Òkè Gérísímù. Ní òdì kejì àfonífojì náà, nǹkan bí iye kan náà láti ẹ̀yà mẹ́fà yòó kù ti Ísírẹ́lì dúró ní iwájú Òkè Ébálì.a Nísàlẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí àti láàárín àwùjọ méjì ti Ísírẹ́lì, ni àwọn àlùfáà àti Jọ́ṣúà dúró sí. Ẹ wo irú ìran fífanimọ́ra tí èyí jẹ́!—Jọ́ṣúà 8:30-33.
Ní bíborí àwọn èrò púpọ̀ yamùrá yìí, òkè méjì náà mú ìyàtọ̀ gédégédé ní ti ẹwà àti àìmésojáde wá. Apá òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Gérísímù tutù yọ̀yọ̀, ó sì lọ́ràá, nígbà tí ti Ébálì gbẹ táútáú, tí kò sì ní koríko. O ha lè ronú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń fi ìdùnnú sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ bí wọ́n ti ń dúró de ìgbà tí Jọ́ṣúà yóò sọ̀rọ̀? Ńṣe ni gbogbo ìró ń dún ní àdúntúndún níbi ìran àpéwò tí ó jẹ́ àdánidá yìí.
Láàárín wákàtí mẹ́rin sí mẹ́fà tí Jọ́ṣúà fi ka ‘ìwé òfin Mósè,’ àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú kópa nínú rẹ̀. (Jọ́ṣúà 8:34, 35) Ó hàn gbangba pé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń bẹ ní iwájú Gérísímù ń wí pé Àmín! lẹ́yìn ìbùkún kọ̀ọ̀kan, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ègún kọ̀ọ̀kan ni àwọn tí ń bẹ ní iwájú Ébálì ń fi Àmín! tí wọ́n ń sọ dáhùn sí. Bóyá ìrísí aláìlè-mésojáde tí Òkè Ébálì ní ń ṣèrànwọ́ láti rán àwọn ènìyàn náà létí nípa àbájáde oníjàábá tí àìgbọ́ràn yóò ní.
Jọ́ṣúà kìlọ̀ pé: “Ègún ni fún ẹni tí kò fi bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ pè.” Lẹ́ẹ̀kan náà, ohùn tí ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ fèsì pé: “Àmín!” Jọ́ṣúà dákẹ́ fún ariwo èsì adúnbíàrá yìí láti lọ sílẹ̀ kí ó tún tó máa bá a nìṣó pé: “Ègún ni fún ẹni tí ó ṣí àlà ẹnì kejì rẹ̀ kúrò.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀yà mẹ́fà náà, tí ọ̀pọ̀ àlejò olùgbé dara pọ̀ mọ́, kígbe pé: “Àmín!” (Diutarónómì 27:16, 17) Ká ní ìwọ wà níbẹ̀, ìwọ yóò ha gbàgbé ìpàdé yẹn tí a ṣe láàárín àwọn òkè bí? A kì yóò ha ti tẹ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣègbọràn mọ́ ọ lọ́kàn lọ́nà tí kò ṣeé pa rẹ́ bí?
Kété ṣáájú kí ó tó kú ní nǹkan bí 20 ọdún lẹ́yìn náà, Jọ́ṣúà tún pe orílẹ̀-èdè náà jọ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Ṣékémù kí wọ́n baà lè fìdí ìpinnu wọn múlẹ̀. Ó fi yíyàn tí olúkúlùkù wọn gbọ́dọ̀ ṣe síwájú wọn. Ó wí pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin óò máa sìn ní òní; . . . ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi àti ilé mi ni, OLÚWA ni àwa óò máa sìn.” (Jọ́ṣúà 24:1, 15) Dájúdájú, àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí tí ń ru ìgbàgbọ́ sókè ní Ṣékémù wọni lọ́kàn ṣinṣin. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jọ́ṣúà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fara wé àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin rẹ̀.—Jọ́ṣúà 24:31.
Nǹkan bí ọ̀rúndún 15 lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń sinmi lábẹ́ òjìji Òkè Gérísímù, ìjíròrò amọ́kànyọ̀ kan wáyé níbẹ̀. Bí ó ti rẹ̀ ẹ́ nítorí ìrìn-àjò gígùn, Jésù jókòó níbi ìsun omi Jékọ́bù nígbà tí obìnrin ara Sámáríà kan tí ó gbé ìṣà omi dání wá síbẹ̀. Ẹnu ya obìnrin náà gidigidi nígbà tí Jésù sọ pé kí ó fún òun ní omi mu, níwọ̀n bí àwọn Júù kì í ti í bá àwọn ara Sámáríà sọ̀rọ̀, bèlèǹtàsé kí wọ́n fi ohun èlò wọn mu omi. (Jòhánù 4:5-9) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e túbọ̀ yà á lẹ́nu.
“Gbogbo ẹni tí ó bá ń mu láti inú omi yìí òùngbẹ yóò tún gbẹ ẹ́. Dájúdájú ẹni yòó wù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ rárá láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Jòhánù 4:13, 14) Fojú inú wo bí ọkàn ìfẹ́ tí obìnrin yẹn ní nínú ìlérí yẹn ti tó, nítorí pípọn omi láti inú kànga jíjìn yí jẹ́ iṣẹ́ takuntakun. Jésù ṣàlàyé síwájú sí i pé láìka ìjẹ́pàtàkì tí wọ́n ní nínú ìtàn sí, Jerúsálẹ́mù tàbí Òkè Gérísímù kì í ṣe ọ̀gangan ibi ìsìn tí ó pọn dandan láti tọ Ọlọ́run lọ. Bí ọkàn àyà àti ìwà ṣe rí ni ó ṣe pàtàkì, kì í ṣe ọ̀gangan tí a ti ń jọ́sìn. Ó wí pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Bàbá ní ẹ̀mí àti òtítọ́, . . . ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Bàbá ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ti gbọ́dọ̀ tuni nínú tó! Lẹ́ẹ̀kan sí, àfonífojì yí di ibi tí a ti rọ àwọn ènìyàn láti máa sin Jèhófà.
Lónìí, ìlú Nablus wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwókù Ṣékémù ìgbàanì. Òkè Gérísímù àti Òkè Ébálì ṣì ṣíji bo àfonífojì náà, tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti kọjá. A ṣì lè ṣe ìbẹ̀wò síbi kànga Jékọ́bù, ní ìsàlẹ̀ àwọn òkè wọ̀nyí. Bí a ti ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé níbẹ̀, a rán wa létí ìjẹ́pàtàkì gbígbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jọ́ṣúà àti Jésù ti kọ́ wa láti ṣe.—Fi wé Aísáyà 2:2, 3.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀yà mẹ́fà tí ń bẹ ní iwájú Òkè Gérísímù ni ẹ̀yà Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jósẹ́fù, àti Bẹ́ńjámínì. Ẹ̀yà mẹ́fà tí ń bẹ ní iwájú Òkè Ébálì ni ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gáàdì, Áṣérì, Sébúlónì, Dánì, àti Náfútálì.—Diutarónómì 27:12, 13.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.