Bibojuto Awọn Arugbo Awọn Ipenija ati Èrè
SHINETSU, Kristian ojiṣẹ kan, ń gbadun iṣẹ-ayanfunni rẹ̀ gidigidi. Idile rẹ̀ ti gbogbo wọn jẹ́ mẹta ní iya iyawo rẹ̀ ninu. Wọn ń fi tayọtayọ ṣiṣẹ pẹlu ijọ kekere ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, ni kíkọ́ awọn eniyan ni Bibeli, titi di ọjọ kan ti a sọ fun un lati ronu nipa ririnrin-ajo pẹlu aya rẹ̀ lati bẹ awọn ijọ miiran wò. Yoo beere fun ṣiṣipopada lọsọọsẹ. Inu rẹ̀ dùn fun ifojulọna yii, ṣugbọn ta ni yoo bojuto Iya iyawo rẹ̀?
Ọpọlọpọ idile yoo dojukọ ipenija ti o rí bakan naa lẹhin-ọ-rẹhin—ọ̀nà ti ó dara julọ lati gbà bojuto awọn òbí ti ń darugbo. Niye ìgbà a kìí ronu pupọ nipa ọ̀ràn naa nigba ti awọn òbí bá ṣì ni ilera ti ó dara ti wọn sì ń ṣiṣẹ. Bi o ti wu ki o ri, awọn ohun diẹ lè ṣipaya pe wọn tubọ ń dagba, iru bii ọwọ́ gbígbọ̀n bi wọn ti ń gbiyanju lati fi òwú bọ abẹrẹ tabi agbara-iranti ti kò já gaara bi wọn ti ń gbiyanju lati ranti ìgbà ti wọn foju gán-án-ni ohun kan ti wọn kò mọ ibi ti wọn fi sí mọ gbẹhin. Niye ìgbà, bi o ti wu ki o ri, jamba ojiji tabi aisan ní o ń mú ki ẹnikan mọ awọn aini wọn. A gbọdọ ṣe ohun kan.
Ni awọn orilẹ-ede kan awọn òbí tí ń gbadun ilera ti ó dara ni ifiwera yàn lati lo awọn ọdun ẹhinwa-ọla wọn pẹlu alabaaṣegbeyawo wọn nikan dipo ki o jẹ́ pẹlu awọn ọmọ wọn. Ni awọn orilẹ-ede miiran, iru bii ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ilẹ Gabasi ati Africa, ó jẹ́ ohun aṣa fun awọn agbalagba lati gbé pẹlu awọn ọmọ wọn, ni pataki dáódù wọn. Eyi jẹ́ otitọ ni pataki bi ọ̀kan lara awọn òbí naa bá jẹ́ ẹni ti kò lè dide kuro lori ibusun. Ni Japan, fun apẹẹrẹ, ninu awọn wọnni ti wọn jẹ́ ẹni ọdun 65 ati ju bẹẹ lọ ti wọn sì jẹ́ ẹni ti kò lè dide kuro lori ibusun dé iwọn kan, nǹkan bii 240,000 ni awọn idile wọn ń bojuto ni ile.
Awọn Iṣẹ-aigbọdọmaṣe Ti Iwarere ati Ti Iwe Mimọ
Bi o tilẹ jẹ pe a ń gbé ninu iran naa ninu eyi ti ọpọlọpọ ti di “olufẹ araawọn,” ti wọn ṣalaini “ifẹni adanida,” awa ni kedere ní awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe ti iwarere ati ti Iwe Mimọ siha ọ̀dọ̀ awọn agbalagba. (2 Timoteu 3:1-5, NW) Tomiko, tí ń bojuto ìyá rẹ̀ agba, ti àrùn Parkinson kọlu, sọ iṣẹ-aigbọdọmaṣe ti iwarere ti ó mọlara jade nigba ti ó sọ nipa ìyá rẹ̀ pe: “Ó bojuto mi fun 20 ọdun. Nisinsinyi emi fẹ ṣe ohun kan-naa fun un.” Ọlọgbọn Ọba Solomoni ṣinileti pe: “Fetisi ti baba rẹ ti ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nigba ti ó bá gbó.”—Owe 23:22.
Kìí ṣe yala ẹtanu isin tabi kèéta ní apa ọ̀dọ̀ òbí alaigbagbọ kan ni ó fagile itọsọna ti o bá Iwe Mimọ mu yẹn. Kristian aposteli Paulu ni a mísí lati kọwe pe: “Bi ẹnikẹni kò bá pese fun awọn tirẹ̀, paapaa fun awọn ará ile rẹ̀, ó ti sẹ́ igbagbọ, ó buru ju alaigbagbọ lọ.” (1 Timoteu 5:8) Jesu fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun wa nigba ti, gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn igbesẹ rẹ̀ ti o kẹhin ṣaaju ki ó tó kú, ó ṣeto fun bibojuto ìyá rẹ̀.—Johannu 19:26, 27.
Yíyanjú Awọn Iṣoro Ti A Bá Pade
Ọpọ atunṣebọsipo ni olukuluku nilati ṣe nigba ti a bá tún idile sopọṣọkan lẹhin gbigbe lọtọọtọ fun ọpọlọpọ ọdun. Awọn iyipada wọnyi beere fun ifẹ, suuru, ati òye tọtun-tosi ńláǹlà. Bi dáódù, tabi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin miiran kan, bá kó idile rẹ̀ wá sinu ile awọn òbí, odindi eto awọn ipo ayika titun ni ó ń gbé araarẹ kalẹ. Iṣẹ titun, ile-ẹkọ titun fun awọn ọmọ, ati awọn aladuugbo titun ti a nilati dojulumọ wọn lè wà. Niye ìgbà yoo tumọsi iṣẹ pupọ sii fun aya.
Bakan naa ni yoo jẹ ohun ti ó ṣoro fun awọn òbí lati ṣatunṣebọsipo. Iwọn idakọnkọ, idakẹjẹẹ, ati ominira kan ti lè mọ́ wọn lara; nisinsinyi wọn yoo ní wótòwótò ariwo yànmù ti awọn ọmọ-ọmọ ti wọn jẹ́ onípàáǹle ati awọn ọ̀rẹ́ wọn. Ó ti mọ́ wọn lara lati ṣe ipinnu tiwọn funraawọn wọn sì lè kọ awọn igbiyanju eyikeyii lati dari wọn. Ọpọ awọn òbí, ní rírí akoko naa nigba ti idile ọmọ wọn yoo wá bá wọn gbé ṣaaju, ti kọ́ awọn ile ọ̀tọ̀ sẹbaa ile tabi ni afikun si ile tiwọn pẹlu ọdẹdẹ ti ó so wọn pọ̀, ni pipese iwọn ominira kan fun gbogbo wọn.
Nibi ti ile naa bá ti kéré, awọn atunṣebọsipo pupọ ni ó lè pọndandan lati pese ààyè fun awọn ẹni titun ti wọn ṣẹṣẹ dé naa. Ìyá kan bú sẹ́rìn-ín bi ó ti ranti bi awọn ọmọbinrin rẹ̀ mẹrin ti bọkanjẹ tó nigba ti awọn ohun ìtolé onigi ati awọn ohun eelo miiran bẹrẹ sii wá sinu yàrá ibusun wọn ki wọn baa lè pese ààyè fun iya agba wọn ẹni ti o jẹ́ ẹni 80 ọdun. Sibẹ, ọpọ julọ ninu awọn iṣoro wọnyi sábà maa ń yanju araawọn bi gbogbo eniyan ti wá ń lóye idi fun awọn atunṣebọsipo naa ti wọn sì ranti iṣileti Bibeli naa pe ifẹ “kìí wá ohun ti ara rẹ̀.”—1 Korinti 13:5.
Ipadanu Ominira
Iṣoro pataki kan fun obinrin Kristian lè gbèrú bi ọkọ rẹ̀ kò bá ṣajọpin igbagbọ rẹ̀ ti ó sì pinnu lati kó idile naa lọ bá awọn òbí rẹ̀. Ibeere fun bibojuto idile lè mu ki ó jọbi ohun ti ó fẹrẹẹ ma ṣeeṣe fun un lati mú iṣẹ-aigbọdọmaṣe Kristian rẹ̀ ṣe deedee pẹlu awọn ojuṣe rẹ̀ miiran. Setsuko sọ pe: “Ọkọ mi lero pe ó léwu lati dá fi ìyá rẹ̀ ti ó ti di kùjọ́kùjọ́ lọna kan ṣáá sílé ni oun nikan, ó sì fẹ́ ki n maa wà nile ni gbogbo ìgbà. Bi mo bá gbiyanju lati lọ si ipade, oun yoo binu yánnayànna yoo sì wíjọ́. Lakọọkọ, nitori ipo àtilẹ̀wá mi gẹgẹ bi ará Japan, emi pẹlu lero pe kò tọna lati fi oun nikan silẹ. Ṣugbọn bi akoko ti ń lọ, mo wá mọ̀ pe a lè yanju awọn ọ̀ràn.”
Hisako ní iṣoro ti ó rí bakan naa. “Nigba ti a kó tọ idile ọkọ mi lọ,” ni ó rohin, “oun, nitori ibẹru ohun ti awọn ẹbí yoo rò, fẹ́ kí n yi isin mi pada ki n sì dáwọ́ igbokegbodo isin mi duro. Lati mú ọ̀ràn tubọ buru sii, ni awọn ọjọ Sunday awọn ẹbí ti wọn ń gbé nitosi yoo wá ṣebẹwo, ni mímú ki ó ṣoro fun mi lati lọ si awọn ipade. Siwaju sii, awọn ọmọ fẹ́ lati bá awọn ọmọ ibatan baba wọn ṣere dipo lilọ si awọn ipade. Mo lè rí i pe ipo tẹmi wa ni a ń nipa lé lori. Mo nilati di iduro gbọnyingbọnyin mú ki n sì ṣalaye fun ọkọ mi pe isin mi kìí ṣe ohun ti a nilati pada bi aṣọ agbádá ṣugbọn ó ṣe pataki fun mi. Bi akoko ti ń lọ, idile naa ṣe atunṣebọsipo.”
Awọn kan ti yanju iṣoro titubọ rí akoko ti o ṣí silẹ sii nipa jijẹ ki olutọju-ile alakòókò kúkúrú wá lati ràn wọ́n lọwọ ni ọjọ kan tabi meji lọ́sẹ̀. Awọn miiran ti ri iwọn ominira niti ìránniníṣẹ́ ati igbokegbodo Kristian nipa wiwa aranṣe awọn ọmọ wọn, awọn ẹbí ti ń bẹ nitosi, àní awọn ọ̀rẹ́ ninu ijọ paapaa. Awọn ọkọ pẹlu ti lè pese iranlọwọ ni awọn alaalẹ́ ati opin ọsẹ nigba ti wọn bá wà ni ile.—Oniwasu 4:9.
Mímú Wọn Jafafa
Mímú ki awọn agbalagba jafafa jẹ́ ipenija miiran ti a nilati dojukọ. Awọn agbalagba kan ni inu wọn dùn lati ṣajọpin ninu sise ounjẹ ati awọn iṣẹ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ miiran layiika ile. Wọn nimọlara pe awọn wulo bi a bá sọ fun wọn lati bojuto awọn ọmọ wọ́n sì ń ritẹẹlọrun ninu bibojuto ọgbà ẹ̀fọ́ kekere kan, titọju awọn òdòdó, tabi ṣiṣajọpin ninu awọn igbokegbodo àfipawọ́.
Awọn miiran, bi o ti wu ki o ri, fẹ́ lati sùn ni gbogbo ọjọ wọn sì reti pe ki awọn awọn ẹlomiran duro tì wọn. Ṣugbọn mímú wọn jafafa bi ó bá ti lè ṣeeṣe tó jọ bi pe ó ṣe pataki fun wíwà lalaafia, gígùn ọjọ-ori, ati iwalojufo wọn niti èrò orí. Hideko rí i pe bi o tilẹ jẹ pe ìyá oun wà lori àga-alágbàá-kẹ̀kẹ́, mímú un lọ si awọn ipade gan-an ni itaniji kánmọ́kánmọ́ ti ìyá oun nilo. Gbogbo eniyan fi tọyayatọyaya kí i kaabọ a sì mú un dásí awọn ijumọsọrọpọ. Afiyesi ti a fifun un lẹhin-ọ-rẹhin ṣamọna rẹ̀ sí gbígbà lati ṣekẹkọọ Bibeli pẹlu obinrin agbalagba miiran kan. Tọkọtaya kan ti wọn ni òbí kan ti aisan Arán Ṣíṣe ń yọlẹnu, mú un dání pẹlu wọn lọ si awọn ipade Kristian. “Kò fẹ́ ṣe ohunkohun rárá,” ni wọn ṣakiyesi, “ṣugbọn ó layọ ni awọn ipade. A fi tọyayatọyaya kí i kaabọ, nitori naa ó ń wa pẹlu imuratan. A nimọlara pe ó ṣanfaani gidigidi fun un.”
Shinetsu, ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ naa, yanju iṣoro rẹ̀ nipa wíwá ile-ibuwọ kan ti ó wà ni ọ̀gangan àárín agbegbe ibi ti o ti ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojiṣẹ arinrin-ajo fun ìyá iyawo rẹ̀. Oun ati aya rẹ̀ yoo tipa bayii wà pẹlu rẹ̀ laaarin awọn ibẹwo rẹ̀ si awọn ijọ lọsọọsẹ. Aya rẹ̀, Kyoko, sọ pe: “Ìyá mi nimọlara pe oun jẹ́ apa pataki kan ninu iṣẹ wa ó sì nimọlara pe a nilo oun. Inu rẹ̀ a maa dùn nigba ti ọkọ mi ba sọ fun un pe ki o se iru ounjẹ akanṣe kan.”
Kíkojú Arán
Bi awọn òbí ti ń darugbo, oniruuru iwọn arán lè jẹyọ, nitori naa wọn nilo afiyesi pupọ pupọ sii. Wọn a maa gbagbe awọn ọjọ, akoko, ìgbà, ati ileri. Wọn lè gbagbe lati gé irun wọn ki wọn sì fọ aṣọ wọn. Wọn tilẹ lè gbagbe bi wọn yoo ti wọ aṣọ ki wọn sì wẹ araawọn paapaa. Ọpọlọpọ di ẹni ti ó ní ìdàrúdàpọ̀-ọkàn, nigba ti ó jẹ́ pe ó maa ń ṣoro fun awọn miiran lati sùn ni òru. Itẹsi lati ṣe aṣetunṣe iwọnyi lè wà wọn yoo sì kanra bi a bá mú un wá si afiyesi wọn. Ero-inu wọn lè tàn wọn jẹ. Wọn lè tẹnumọ́ ọn pe a ti jí ohun kan mọ wọn lọwọ tabi pe awọn adigunjale ń gbiyaju lati fọ́lé. Idile kan ti ó ni awọn ọmọbinrin mẹrin nilati farada ifẹsunkanni lemọlemọ nipa ti iwa-aitọ ibalopọ takọtabo ti kò ni ipilẹ. “Ó tó ohun ti a ń jà sí,” ni wọn sọ, “ṣugbọn a wulẹ kẹkọọ lati farada awọn iyipada naa ti a sì gbiyanju lati yi kókó-ọ̀rọ̀ naa pada. Biba Iya-agba jà jẹ́ imulẹmofo.”—Owe 17:27.
Awọn Aini Ero-imọlara ti A Nilati Kájú
Ọjọ́-ogbó ń mú awọn idanwo wá fun awọn agbalagba. Awọn aisan lilekoko, ailegbera kuro lojukan, ati idaamu ti ọpọlọ wà lati farada. Ọpọ nimọlara pe igbesi-aye awọn kò lójú tabi ní ète. Wọn lè nimọlara pe awọn jẹ́ ẹrù-ìnira ki wọn sì fi ìfẹ́-ọkàn lati kú hàn. Wọn nilati nimọlara pe a nifẹẹ wọn, pe a bọ̀wọ̀ fun wọn, ati pe a kò kóyán wọn kéré. (Lefitiku 19:32) Hisako sọ pe: “A sábà maa ń gbiyanju lati mú Ìyakọ mi wọnu ijumọsọrọpọ wa nigba ti ó bá wà nibẹ, ni jijẹ ki ọ̀rọ̀ dá lé e lori nibi ti ó ba ti ṣeeṣe.” Idile miiran sakun lati fun ọ̀wọ̀ ara-ẹni baba-baba wọn lokun nipa sisọ fun un lati dari ijiroro ẹsẹ iwe mimọ ojoojumọ kan.
Ẹnikan nilati lakaka lemọlemọ lati pa oju-iwoye bibojumu mọ nipa awọn agbalagba. Awọn alaisan ti wọn kò lè dide kuro lori ibusun maa ń binu nigba ti wọn bá nimọlara pe a ń sọrọ si awọn lara tabi bá awọn lò lọna àìlọ́wọ̀. “Ìyá wà lojufo ṣamṣam,” ni Kimiko, ẹni ti ó ń gbé pẹlu ìyakọ rẹ̀ ti ó jẹ́ abirùn ṣalaye, “ó sì mọ ìgbà ti emi kò fi gbogbo ọkan-aya mi sinu bibojuto o tabi ti mo di ẹni ti ń sọrọ sí i lara.” Hideko tun nilati ṣiṣẹ lori iṣarasihuwa rẹ̀. “Lakọọkọ gbogbo rẹ̀ sú mi nigba ti mo nilati bojuto ìyakọ mi. Mo ti jẹ́ aṣaaju-ọna [ojiṣẹ alakooko kikun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa], emi kò sì le ṣe iṣẹ-ojiṣẹ naa mọ́. Nigba naa ni mo rí i pe mo nilati ṣe atunṣebọsipo ninu ironu mi. Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile ṣe pataki, eyi jẹ́ apa pataki kan ninu kikọbiara si awọn ofin Ọlọrun. (1 Timoteu 5:8) Mo mọ̀ pe mo nilati mú ifẹ ati igbatẹniro pupọ sii dagba bi emi yoo bá ni ayọ. Ẹ̀rí-ọkàn mi yoo yọ mi lẹnu nigba ti mo bá wulẹ ṣe awọn nǹkan lọna afaraṣemáfọkànṣe laisi imọlara pe ojuṣe mi ni mo ń ṣe. Nigba ti mo ni ijamba kan ti mo sì wà ninu irora, mo ronu nipa ìyakọ mi ati irora ti ó ní. Lẹhin iyẹn ó rọrùn fun mi lati fi ọyaya ati igbatẹniro pupọ sii hàn.”
Awọn Olutọju Pẹlu Nilo Itọju
Eyi ti a kò nilati gbojufoda ni aini naa fun fifi imọriri hàn fun ẹni naa ti ẹrù-ìnira bibojuto arugbo já lé lori ni pataki. (Fiwe Owe 31:28.) Ọpọ julọ awọn obinrin ń baa lọ lati bojuto awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe wọn pẹlu gbígbọ́ tabi ṣiṣaigbọ awọn ọ̀rọ̀ imọriri. Nigba ti a bá ronu nipa ohun ti iṣẹ wọn ni ninu, bi o ti wu ki o ri, iru awọn ọ̀rọ̀ bẹẹ yẹ wẹ́kú dajudaju. Ó ṣeeṣe ki wọn ni afikun sisọ ile di mimọ tonitoni, fifọṣọ, ati sise ounjẹ. Pẹlupẹlu, gbe awọn irin-ajo lọ si ile-iwosan tabi sọdọ dokita yẹwo, ati fifun agbalagba alaisan kan lounjẹ tabi wíwẹ̀ ẹ́. Obinrin kan, ti ó bojuto ìyakọ rẹ̀ fun ìgbà pipẹ, sọ pe: “Mo mọ pe kò rọrùn fun ọkọ mi lati sọ ọ ni ọ̀rọ̀, ṣugbọn ó maa ń fi hàn mi ni awọn ọ̀nà miiran pe oun mọriri ohun ti mo ń ṣe.” Awọn ọ̀rọ̀ idupẹ rírọrùn lè jẹ ki gbogbo rẹ̀ dabi ohun ti ó níláárí.—Owe 25:11.
Awọn Èrè Wà Pẹlu
Ọpọlọpọ idile ti wọn ti bojuto awọn òbí ti wọn ń darugbo fun ọpọ ọdun sọ pe eyi ti ran awọn lọwọ lati mú awọn animọ Kristian pataki dagba: ifarada, ifara-ẹni-rubọ, ifẹ ainimọtara-ẹni-nikan, aápọn, irẹlẹ, ati iwa-onijẹlẹnkẹ. Ọpọlọpọ idile ti fà sunmọra pẹkipẹki niti ero-imọlara. Ẹbun afikun kan ni anfaani lati tubọ jumọsọrọpọ pẹlu awọn òbí ki a sì tubọ mọ̀ wọn daradara sii. Hisako sọ nipa ìyakọ rẹ̀ pe: “Ó ní igbesi-aye ti o dara. Ó la ọpọlọpọ inira kọja. Mo ti wá mọ̀ ọ́n daradara sii mo sì ti kẹkọọ lati mọriri awọn animọ ti o wà ninu rẹ̀ ti emi kò mọ daju tẹlẹ.”
“Akoko kan wà ṣaaju ki n tó kẹkọọ Bibeli nigba ti mo fẹ́ lati gba iwe ikọsilẹ ki n sì yọ́ ipo naa silẹ,” ni Kimiko, ẹni ti o bojuto awọn òbí ọkọ rẹ̀ ti o wà ni ìdùbúlẹ̀, ṣalaye. “Lẹhin naa mo kà pe a nilati ‘bojuto . . . awọn opó ninu ipọnju wọn.’ (Jakọbu 1:27) Inu mi dùn pe mo ṣe gbogbo ohun ti mo lè ṣe, gẹgẹ bi o ti jẹ pe kò si ẹnikẹni ninu idile naa ti ó lè fi ẹ̀tọ́ wíjọ́ nipa awọn igbagbọ mi. Ẹ̀rí-ọkàn mi mọ́ kedere.” Ẹlomiran sọ pe: “Mo ti foju araami rí awọn iyọrisi buburu jai ti ẹṣẹ Adamu mo sì tubọ mọriri aini naa fun irapada siwaju sii.”
Iwọ yoo ha gba mẹmba miiran ninu idile rẹ sinu agbo-ile rẹ laipẹ bi? Tabi boya iwọ yoo ṣí lọ bá awọn òbí rẹ arugbo? Iwọ ha nimọlara ibẹru diẹ bi? Iyẹn yéni. Awọn atunṣebọsipo yoo wà lati ṣe. Ṣugbọn iwọ yoo ri pe a san èrè jingbinni fun ọ fun iriri kikoju ipenija naa lọna ti o kẹsẹjari.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Awọn arugbo fẹ́ lati mọ pe a ni ifẹ ati ọ̀wọ̀ fun wọn