ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/1 ojú ìwé 20-23
  • Ọlọrun Ń Mú Ki Ó Dagba—Iwọ Ha Ń Kó Ipa Tirẹ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ń Mú Ki Ó Dagba—Iwọ Ha Ń Kó Ipa Tirẹ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Ń Mu Ki O Dagba
  • “Kìí Ṣe Ẹni ti O Ń Gbin Nǹkankan”
  • Awọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹlu Ọlọrun
  • Ṣe Ipa Tirẹ
  • “Maṣe Dá Ọwọ́ Rẹ Duro”
  • Ápólò—Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Olùpòkìkí Òtítọ́ Kristẹni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Sún Mọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/1 ojú ìwé 20-23

Ọlọrun Ń Mú Ki Ó Dagba—Iwọ Ha Ń Kó Ipa Tirẹ Bi?

RONU nipa iran naa. Iwọ wà ninu ọgba ẹlẹwa kan, ní ayika eyi ti awọn igi giga fíofío, awọn igbó ṣíṣùbolẹ̀ rẹ̀gẹ̀jì, ati oniruuru awọn òdòdó alawọ meremere wà. Awọn pẹtẹlẹ ti a fi koriko oniyebiye bò da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ seti bèbè odò kan ti a ṣe daradara ninu eyi ti omi mimọgaara bii kristali ń rugùdù. Kò si ohunkohun ti o ba iran naa jẹ́. Bi o ti wú ọ lori, iwọ beere ẹni ti o ṣe ibi gbígbámúṣé yii. Ni idahunpada oluṣọgba naa fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà sọ pe Ọlọrun ni o ń mu ki ohun gbogbo dagba.

Lọna ti o bá iwa ẹ̀dá mu, iwọ mọ iyẹn. Iwọ si ranti awọn ọ̀rọ̀ oluṣọgba naa nigba ti o dé ile ti o si ri ẹhinkule tirẹ ti o rí wúruwùru, nibi ti ohunkohun ti ń danilọrun kò ti hù, pantiri ń korajọ pelemọ, ti omi òjò si dárogún sinu awọn ihò kaakiri ilẹ̀. Iwọ lọna jijinlẹ lọkan-ifẹ lati ni ọgba kan bi eyi ti o ṣẹṣẹ ṣebẹwo si tán. Nitori naa, ni fifi idaniloju gba ọ̀rọ̀ oluṣọgba naa gbọ́, iwọ kunlẹ o si gbadura atọkanwa si Ọlọrun lati jẹ ki awọn òdòdó ẹlẹwa hù ninu agbala rẹ. Ki ni ṣẹlẹ? Kò si ohunkohun, niti gidi.

Ki ni nipa ti idagbasoke tẹmi? Iwọ le ni ọkàn-ìfẹ́ mímú hánnhán lati ri ki awọn nǹkan maa dagba nipa tẹmi, bii pe ki awọn ọmọlẹhin titun maa dahunpada si otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tabi pe ki iwọ ni idagbasoke nipa tẹmi. Iwọ sì lè gbadura latọkanwa si Jehofa lati mu iru awọn idagbasoke bẹẹ wa, pẹlu idaniloju jijinlẹ pe oun ni agbara lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn ǹjẹ́ ọkàn-ìfẹ́ jijinlẹ, adura atọkanwa, ati igbẹkẹle rẹ ninu awọn agbara Ọlọrun tikaraawọn yoo ha mu idagbasoke wa bi?

Ọlọrun Ń Mu Ki O Dagba

Boya iwọ nimọlara pe ipa tirẹ ni mimu ki idagbasoke nipa tẹmi wáyé kò jamọ nǹkankan ti o sì jẹ́ alainitumọ paapaa. Aposteli Paulu kò ha dabaa eyi ni 1 Korinti 3:5-7? Ó kọwe pe: “Ki ni Apollo ha jẹ? ki ni Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹni ti ẹyin ti gbagbọ, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun un. Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni ń mu ibisi wá. Ǹjẹ́ kìí ṣe ẹni ti o ń gbin nǹkankan, bẹẹ ni kìí ṣe ẹni ti ń bomirin; bikoṣe Ọlọrun [ti ń mú ki ó dagba, NW].”

Paulu jẹwọ lọna ti o yẹ pe nigba ti awọn nǹkan ba dagba, gbogbo ọpẹ́ lọ sọdọ Ọlọrun. Oluṣọgba kan lè ṣeto ilẹ rẹ̀, gbin eso rẹ̀, ki o si fi tiṣọratiṣọra tọju awọn ọgbin naa, ṣugbọn ni ikẹhin o jẹ́ nitori agbara iṣẹda yiyanilẹnu ti Ọlọrun ni ohun gbogbo fi dagba. (Genesisi 1:11, 12, 29) Bi o ti wu ki o ri, ki ni, Paulu ni lọkan nigba ti o wipe “kìí ṣe ẹni ti o ń gbin nǹkankan, bẹẹ ni kìí ṣe ẹni ti ń bomirin”? (“Kìí ṣe awọn aṣọgba pẹlu gbigbin ati bibomirin wọn ni o jà,” The New English Bible.) Oun ha ń bu ijẹpataki ipa ti ojiṣẹ kọọkan ni ninu sisọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin titun kù ni bi, ni didabaa pe nikẹhin, ọ̀nà ti a gbà bojuto iṣẹ-ojiṣẹ wa kò fi bẹẹ jamọ nǹkan?

“Kìí Ṣe Ẹni ti O Ń Gbin Nǹkankan”

Fi sọkan pe ni apa ibi yii ninu lẹta rẹ̀, Paulu kò jiroro iṣẹ-ojiṣẹ Kristian bikoṣe iwa omugọ ti o wà ninu titẹle eniyan dipo Jesu Kristi. Awọn kan ni Korinti ń fi ijẹpataki ti kò tọ́ fun awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn lokiki, bii Paulu ati Apollo. Awọn miiran ń gbe iyapa larugẹ ti wọn si ń ṣagbega awọn eniyan ti wọn lero pe awọn ṣe pataki ju awọn Kristian arakunrin wọn lọ.—1 Korinti 4:6-8; 2 Korinti 11:4, 5, 13.

Fifogo fun awọn eniyan ni ọ̀nà yii kù diẹ ki a to. O jẹ ironu ti ara, o si ń mú owú ati ija wa. (1 Korinti 3:3, 4) Paulu fi abajade iru awọn ironu bẹẹ hàn. Ó wi pe: “Ìjà ń bẹ laaarin yin. Ǹjẹ́ eyi ni mo wi pe, olukuluku yin ń wi pe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi.”—1 Korinti 1:11, 12.

Nipa bayii, nigba ti o kọwe pe, “ẹni ti ń gbìn ati ẹni ti ń bomirin kò jamọ nǹkankan” (Phillips), aposteli naa ń jagun pẹlu iru ironu nipa ti ara bẹẹ, ni titẹnumọ aini naa lati bojuwo Jesu Kristi gẹgẹ bi Aṣiwaju ati lati jẹwọ pe gbogbo ògo fun ibisi ninu ijọ lọ si ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Awọn aposteli ati awọn alagba miiran wulẹ jẹ iranṣẹ ijọ ni. A kò gbọdọ gbe eyikeyii ga bẹẹ ni awọn funraawọn kò gbọdọ wá ipo ọla tabi okiki. (1 Korinti 3:18-23) Nitori naa ẹni ti ń gbìn ati ẹni ti ń bomirin kò jamọ nǹkankan, ni Paulu sọ, “ni ifiwera pẹlu ẹni ti o ń fi iwalaaye fun eso naa.”—1 Korinti 3:7, Phillips.

Awọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹlu Ọlọrun

Nitori naa, ni sisọ eyi, kìí ṣe pe aposteli Paulu ń bu ijẹpataki ipa tiwa ninu gbigbin ati bibomirin naa kù. Oun kò nilọkan pe ki a bẹrẹ sii ronu pe, “Ọlọrun yoo mu awọn nǹkan bisii ni akoko tirẹ,” ki a wá wulẹ fẹhinti ki a si maa duro dè é lati ṣe é. Oun mọ̀ pe ohun ti awa ti ṣe ati bi a ṣe ṣe é ni ipa lori bi awọn nǹkan ṣe ń dagba.

Idi niyẹn ti Paulu fi maa ń fun awọn Kristian ni iṣiri leralera lati ṣiṣẹ kára ninu iṣẹ-ojiṣẹ wọn ati lati sunwọn sii ninu ijafafa wọn gẹgẹ bi olukọ. Ronu nipa imọran ti o fifun ọdọmọkunrin naa Timoteu. “Maa ṣe itọju araarẹ ati ẹkọ rẹ; maa duro laiyẹsẹ ninu nǹkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gba araarẹ ati awọn ti ń gbọ ọ̀rọ̀ rẹ là.” (1 Timoteu 4:16) “Nitori naa mo paṣẹ fun ọ . . . , waasu ọ̀rọ̀ naa; ṣe aisinmi . . . , pẹlu ipamọra ati ẹkọ gbogbo. . . . Ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe.” (2 Timoteu 4:1, 2, 5) Yoo jẹ ohun ti o kò bọgbọnmu fun Timoteu lati ṣiṣẹ kára lati mú ijafafa rẹ̀ sunwọn sii bi gbígbìn ati bibomirin rẹ̀ kò ba nilati ni ipa lori mimu ki awọn nǹkan dagba.

Gẹgẹ bii Paulu ati Apollo, iwọ pẹlu lè ni anfaani alaiṣeediyele ti ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun. (1 Korinti 3:9; 2 Korinti 4:1; 1 Timoteu 1:12) Nipa bẹẹ, iṣẹ rẹ ṣe pataki. Oluṣọgba naa kò reti pe ki Ọlọrun lọna iyanu pese ọgba ẹlẹwa kan laisi isapa niha ọ̀dọ̀ oluṣọgba naa. O ha gbọdọ jẹ odikeji pẹlu idagba nipa tẹmi bi? Dajudaju bẹẹkọ. Gẹgẹ bi àgbẹ̀ naa ti o ń fi ifarabalẹ “reti eso iyebiye ti ilẹ,” awa gbọdọ kọkọ lo araawa tokuntokun ninu gbigbin ati bibomirin, ni diduro nigba ti Ọlọrun ń mu ki o dagba.—Jakọbu 1:22; 2:26; 5:7.

Ṣe Ipa Tirẹ

Niwọn bi, gẹgẹ bi aposteli Paulu ti sọ, “olukuluku yoo si gba èrè tirẹ gẹgẹ bi iṣẹ tirẹ,” o dara ki a bi araawa leere bi awa ti ń ṣiṣẹ si.—1 Korinti 3:8.

Oluṣọgba ti o jẹ́ ògbógi Geoffrey Smith wi pe: “A kò nilo awọn akanṣe ẹ̀rí itootun kan lati di oluṣọgba, kiki ìfẹ́-ọkàn ninu awọn ohun ọgbin ni.” (Shrubs & Small Trees) Bakan naa, a kò nilo awọn ẹ̀rí itootun alaiṣeeyasọtọ pataki kan fun wa lati jẹ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, kiki ojulowo ìfẹ́-ọkàn ninu awọn eniyan ati imuratan lati jẹ ki Ọlọrun lò wá.—2 Korinti 2:16, 17; 3:4-6; Filippi 2:13.

Gbe diẹ yẹwọ ninu awọn imọran daradara ti awọn ọjafafa oluṣọgba. Gẹgẹ bi alaṣẹ kan ṣe sọ, bi oluṣọgba kan ti kò niriiri ba ṣetan lati fetisilẹ si awọn ti wọn tubọ ni iriri jù ú lọ, “akẹkọọ naa lè di ògbógi ni kiakia.” Alaṣẹ kan-naa yii sì tun sọ pe, “ògbógi naa sábà maa ń wa ohun titun kan lati kọ́.” (The Encyclopedia of Gardening) Iwọ ha ń fi tinutinu tẹwọgba iranlọwọ ati idalẹkọọ ti Jehofa ń pese ki o baa lè gbìn ki o si bomirin lọna gbigbeṣẹ bi? Bi iwọ ba ṣe bẹẹ, boya iwọ jẹ ẹni titun lẹnu iṣẹ naa tabi o jẹ oniriiri ninu rẹ̀, iwọ le mu awọn òye siwaju sii dagba gẹgẹ bi alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ki o si tipa bẹẹ di ẹni “ti yoo le maa kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu.”—2 Timoteu 2:2.

Bi oun bá muratan lati fetisilẹ ki o sì kẹkọọ, ni Geoffrey Smith wi, “ṣẹṣẹbẹrẹ naa yoo yẹra fun awọn ọ̀fìn biburu jai.” Bi awa bá fetisilẹ si itọsọna ti Jehofa ń fifunni nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati eto-ajọ rẹ̀, awa yoo maa ṣe awọn nǹkan ni ọ̀nà tirẹ̀. Awa nigba naa, fun apẹẹrẹ, yoo yẹra fun iru awọn ọ̀fìn bii jijiyan lọna omugọ pẹlu awọn ti o jẹ pe wọn wulẹ fẹ́ fajọgbọn tabi jíjà ọ̀rọ̀.—Owe 17:14; Kolosse 4:6; 2 Timoteu 2:23-26.

Imọran didara miiran kan lori iṣẹ ọ̀gbìn ni lati ronu tiṣọratiṣọra lori awọn nǹkan ki a tó haragaga lati gbẹ́ ilẹ. “Ṣaaju ki o tó ki ṣọ́bìrì bọlẹ̀,” ni The Encyclopedia of Gardening sọ, “fi pẹlẹpẹlẹ lo akoko fun ṣiṣayẹwo [awọn ifojusọna rẹ].” Iwọ ha ń ṣubu sinu idẹkun hiharagaga wọnu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian lai kọkọ fi ironu ti o kun fun iṣọra ati adura fun ohun ti iwọ fẹ lati ṣaṣepari ati ọ̀nà didara julọ ti o lè gba ṣe e bi? Ni gbogbo awọn ète rẹ kedere lọkan ki o tó bẹrẹ. Ronu, fun apẹẹrẹ, nipa iru awọn eniyan ti o lè bá pade ati awọn iṣoro ti o lè koju, ki o si murasilẹ lati bojuto iwọnyi. Eyi yoo fun ọ laaye lati “le jèrè pupọ sii [bi iwọ ti] di ohun gbogbo fun gbogbo eniyan.”—1 Korinti 9:19-23.

“Maṣe Dá Ọwọ́ Rẹ Duro”

Bi awa bá mọriri anfaani ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, awa kìí yoo ṣe ìmẹ́lẹ́ nipa ipin wa ninu ajọṣepọ naa. “Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati ni aṣalẹ maṣe dá ọwọ́ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ eyi ti yoo ṣe rere, yala eyi tabi eyiini, tabi bi awọn mejeeji yoo dara bakan naa.” (Oniwasu 11:6) Awọn abajade ikẹhin wà ni ọwọ́ Jehofa, ṣugbọn awa yoo karugbin kiki bi a ba kọkọ funrugbin loju mejeeji.—Oniwasu 11:4.

Kò si ọgba kan ti a tii sọ di ẹlẹwa ri nipasẹ gbigbẹlẹ ati fífọ́n awọn irugbin lọna aibikita ṣakala kan. Bakan naa, pupọ sii ni a beere ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian ju ajọpin ṣakala kan ninu ipinkiri awọn iwe ikẹkọọ Bibeli. Gẹgẹ bi alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, awa nilati kede irohin rere naa nipa Ijọba Ọlọrun kínníkínní ati lọna pipeye, ni ṣiṣawari awọn wọnni ti wọn ni itẹsi ọkàn-aya lọna títọ́. (Iṣe 13:48) Ranti ilana naa ti o wà ninu awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ni 2 Korinti 9:6 pe: “Ẹni ti o ba fọ́nrúgbìn kinun, kinun ni yoo ká; ẹni ti o ba si fọ́nrúgbìn pupọ, pupọ ni yoo ká.”

Bii gbogbo awọn oluṣọgba daradara, awa gbiyanju lati gbìn sori ilẹ rere. Gbara ti a bá ti gbin ohun kan àní sori ilẹ ti o dara julọ paapaa, sibẹsibẹ, kìí ṣe opin ọ̀ràn naa niyẹn. Geoffrey Smith sọ pe: “Eyi kò tumọsi pe niwọn ti a ba ti gbìn ín kò si ohunkohun ti a tun ń beere mọ́ lọwọ ẹni ti o ni ẹru-iṣẹ naa ju ki o fẹhinti lati maa gbáládùn.” Rara, fun awọn nǹkan lati dagba, isapa ni a beere fun ni bibomirin ati didaabobo awọn ohun ọgbin naa.—Fiwe Owe 6:10, 11.

Iṣẹ-ojiṣẹ Kristian lè, niti tootọ, tumọsi awọn akoko gigun oniṣẹ aṣekara nigba ti o jọ pe ohun pupọ kò ṣẹlẹ. Ṣugbọn lojiji, ati ni awọn ìgbà miiran lairotẹlẹ, awọn abajade yiyanilẹnu lè jade wá. Geoffrey Smith sọ pe: “Iṣẹ́ ọ̀gbìn ni ninu awọn akoko gigun ti làálàá atigbadegba eyi ti awọn asiko ẹwà giga tobẹẹ là laaarin debi pe gbogbo ilẹ gbígbẹ́, oko ríro, ati awọn aniyan ti o hàn gbangba ni a gbàgbé.” Iwọ pẹlu lè ni awọn asiko onitẹẹlọrun giga nigba ti ọkan-aya ṣiṣisilẹ kan bá dahunpada si ihin-iṣẹ otitọ naa—kiki bi o bá ti muratan lati ṣe iṣẹ ilẹ gbígbẹ́, gbígbìn, oko riro, ati bibomirin lakọọkọ.—Fiwe Owe 20:4.

Paulu ati Apollo mọ pe iṣẹ wọn ti iwaasu Ijọba ati sisọni di ọmọ-ẹhin kò mu awọn akanṣe okiki kan wa fun wọn ninu ijọ Kristian. Wọn loye pe Ọlọrun ni o ń mú ki awọn nǹkan dagba. Sibẹ, wọn ń gbìn wọn si ń bomirin—lojumejeeji. Njẹ ki awa tẹle apẹẹrẹ wọn ki a si mu araawa wà larọọwọto fun Ọlọrun gẹgẹ bi “awọn iranṣẹ nipasẹ ẹni ti [awọn ẹlomiran ti] gbagbọ.”—1 Korinti 3:5, 6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọlọrun ń mu ki gbogbo nǹkan dagba—ṣugbọn oluṣọgba naa ń ṣe ipa tirẹ̀ pẹlu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́