Irisi Ìran Lati Ilẹ Ileri
Ẹ Yọ̀! Awọn Ẹkù naa Kún fun Òróró ni Àkúnwọ́sílẹ̀
WOLII Joeli rọ ‘awọn ọmọ Sioni lati jẹ alayọ ki wọn sì ni idunnu ninu Jehofa.’ Oun lo òróró olifi ni ṣiṣapejuwe ayọ ati aasiki wọn: “Awọn ilẹ ìpakà yoo kun fun ọkà, ati [ẹkù, NW] wọnni yoo ṣàn jade pẹlu ọti-waini ati òróró.”—Joeli 2:23, 24.
Bi o bá jẹ́ pe iwọ ti gbé ni Israeli ni awọn akoko Bibeli ni, iwọ yoo ti ni inu didun lati ni igi olifi kan iru eyi ti a fihan loke, ni itosi ile rẹ, tabi ninu papa rẹ.a Yoo ti mu ki igbesi-aye rẹ jẹ eyi ti o gbadunmọni, ọ̀kan ti o tubọ rọrun. Eeṣe ti igi olifi kan yoo fi ṣe pataki tobẹẹ?—Fiwe Onidajọ 9:8, 9.
Lakọọkọ, wo igi rẹ daradara. Igi olifi lè gbé fun ọpọ ọrundun, awọn miiran ni eyi ti o ju ẹgbẹrun ọdun lọ, nitori naa o ṣeeṣe ki ayẹwo kan fi iti igi oníkókó, aláwọ̀ eérú kan hàn. Igi rẹ̀ lè tó mita mẹfa ni giga, niti gidi kìí ṣe ni giga fiofio bii igi kedari tabi ki o lẹwa bi ọ̀pẹ. Awọn ewé rẹ̀ ti o saba maa ń tutùyọ̀yọ̀, pẹlu ara rẹ̀ ti ń dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́ bii fadaka, a maa pese ibòji yika ọdun. Sibẹ, iwọ ki yoo ka igi rẹ si eyi ti o niyelori kìkì nitori ìrísí rẹ̀ tabi ibòji rẹ̀. Bẹẹkọ rara.
Eso rẹ̀ ni ohun idiyele naa, ẹgbẹẹgbẹrun awọn olifi alawọ ewé tabi dúdú wọnyẹn! Iyẹn ni yoo mu ki igi olifi naa jẹ́ ohun pataki kan ninu igbesi-aye ojoojumọ ati igbokegbodo awọn eniyan ni Israeli. Igi naa a maa kun fun awọn òdòdó alawọ mimọlẹ ni May, ni imurasilẹ fun awọn èso olifi naa. (Jobu 15:33) Bi awọn wọnyi ba ti gbó, wọn lè yipada kuro ni àwọ̀ ewé olomi goolu si àwọ ilẹ ṣíṣú tabi dúdú.
Kikore olifi laaarin oṣu October si November jẹ iṣẹ alaapọn. Iwọ yoo fi ọ̀pá lu igi naa ki eso ti o ti pọ́n baa lè jabọ sori aṣọ ti a tẹ́ silẹ. (Deuteronomi 24:20) Olifi naa ni a o fọ̀ ki a tó ṣe é fun lilo, iru bii rírẹ ẹ́ sinu omi oniyọ lati lè mú itọwo kikoro ti wọn ti ni tẹlẹ kuro. Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹhin naa?
Iyẹn yoo sinmile bi iwọ ṣe fẹ lati gbadun tabi jere lati inu ikore rẹ jingbinni. Iwọ lè jẹ eso olifi naa ni tútù, tabi iwọ le pa wọn mọ pẹlu omi iyọ ki o baa lè ṣeeṣe fun idile rẹ lati lè maa ni ipese rẹ̀ ti o ladun lọwọ fun ọpọ oṣu. Eso olifi lè jẹ apa pataki kan ninu ounjẹ ti a ń jẹ deedee, ounjẹ kan boya ti o ni awọn itasansan olifi pẹlu awọn akara baali.
Boya ṣáá o, iwọ yoo ṣiṣẹ lé ọpọ eso olifi lori ní ọ̀nà ti a ń gbà ṣe é lati lè rí ohun eelo iyebiye ti o wulo dọ́ba naa fayọ—òróró olifi. Iwọ le ri oniruuru ìsọ̀rí òróró, ni lilo iwọnyi ni ọ̀nà pupọ. Lakọọkọ, iwọ lè rọra lù tabi gún olifi pípọ́n naa ninu ọlọ tabi ki o tilẹ fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọn. (Mika 6:15) Iyẹn a mu òróró didara julọ jade, ti a ń pè ni àlékún-ògidì nisinsinyi, eyi ti o ṣe wẹ́kú fun awọn àtùpà ti ń pese imọlẹ fun agọ-ajọ. (Eksodu 25:37; 27:20, 21) Finuwoye bi iwọ yoo ti nifẹẹ si ipese òróró iyebiye yii lati lò ni sise ounjẹ fun ayẹyẹ pataki kan!
Olifi, àní awọn ti ijojulowo wọn kò tó nǹkan, ni a lè kó sinu ohun ti a fi ń fun nǹkan lati fún òróró pupọ sii jade lati inu iṣu inu eso naa, bi o tilẹ jẹ pe òróró naa yoo jẹ eyi ti ìsọ̀rí rẹ̀ rẹlẹ̀. Iṣu inu eso naa ní òróró ti o jẹ nǹkan bi ipin 50 ninu ọgọrun-un. Oriṣiriṣi ọ̀nà ti a ń gbà fún nǹkan ni a lè lò, ṣugbọn ọ̀kan ni a ṣapejuwe rẹ̀ nihin-in. Olifi ti a fọ́ lodiidi tabi laabọ ni a ń kó sori okuta kan ti o fẹjú bi agbada. Ọlọ kan, ti kẹtẹkẹtẹ tabi eniyan kan ń yí, yoo yí gbirigbiri kọja lori wọn, ti yoo si fún òróró naa jade, eyi ti yoo ṣàn kuro ti a o sì tere rẹ̀ jọ sinu awọn ìsà.—Matteu 18:6.
Òróró olifi ni a lè fiwe omi goolu—a fi oju ṣiṣeyebiye wò ó a si ń lo o ni ọ̀nà pupọ. Igi kan lè mu ipese òróró ọdun kan wa fun idile kan ti o ni mẹmba marun un tabi mẹfa. Yoo jẹ apa pataki kan ninu ounjẹ wọn, bi o ti jẹ eyi ti o maa ń tete dà ti ó sì ni eroja afunni lagbara ti o pọ. (Fiwe Jeremiah 41:8; Esekiel 16:13.) Iwọ lè fi lọ́fíńdà sinu òròró diẹ ki o sì lò ó bi ohun iṣaraloge kan tabi ki o da diẹ si ori alejo kan gẹgẹ bi àmì ìwà ọ̀làwọ́. (2 Samueli 12:20; Orin Dafidi 45:7; Luku 7:46) Iwọ lè lò ó gẹgẹ bi egboogi atura loju egbò.—Isaiah 1:6; Marku 6:13; Luku 10:34.
Iyẹn kò ni jẹ kiki ọ̀nà ti o lè gbà lo ipese òróró olifi kan ti o jẹ ojulowo. Iwọ tun lè lò ó lati fi tan iná si ile rẹ, lati jẹ apakan irubọ si Ọlọrun, tabi gẹgẹ bi eelo kan fun iṣowo ti o lere lori. Bẹẹni, ni awọn akoko Bibeli igi olifi jẹ́ igi kan ti o niyelori julọ, nitori naa Joeli lè lò ó lọna ti o yẹ lati duro fun aasiki ati idunnu.—Deuteronomi 6:11; Orin Dafidi 52:8; Jeremiah 11:16; Matteu 25:3-8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun aworan iran yii ti o tubọ tobi sii, wo 1993 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.