ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 4/15 ojú ìwé 32
  • Ṣé Igi Tí Wọ́n Gé Lulẹ̀ Tún Lè Hù Pa Dà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Igi Tí Wọ́n Gé Lulẹ̀ Tún Lè Hù Pa Dà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jóòbù Gbà Pé Àjíǹde Máa Wà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Igi Ólífì Gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nínú Ilé Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • ‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ẹ Yọ̀! Awọn Ẹkù naa Kún fun Òróró ni Àkúnwọ́sílẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 4/15 ojú ìwé 32
Igi kan tí wọ́n gé lulẹ̀ hù pa dà

Ṣé Igi Tí Wọ́n Gé Lulẹ̀ Tún Lè Hù Pa Dà?

IGI ólífì tára rẹ̀ rí ṣágiṣàgi, tó sì lọ́ mọ́ra bìrìpà lè má dùn ún wò tá a bá fi wé igi kédárì ti Lẹ́bánónì. Àmọ́ igi ólífì rọ́kú, kò sí ojú ọjọ́ tí kò bá a lára mu, àtìgbà òjò àtìgbà ẹ̀rùn. A gbọ́ pé àwọn míì ti lo ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Gbòǹgbò igi ólífì máa ń ta gan-an, ó sì máa ń rinlẹ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ kó tún lè sọjí bí wọ́n tiẹ̀ gé ìtì rẹ̀ lulẹ̀. Tí gbòǹgbò ẹ̀ ò bá ṣáà ti kú, ó máa hù pa dà.

Jóòbù baba ńlá ìgbàanì gbà gbọ́ dájú pé bí òun bá tiẹ̀ kú, òun ṣì máa pa dà wà láàyè. (Jóòbù 14:13-15) Ó fi ọ̀rọ̀ igi ṣàpèjúwe bó ṣe dá òun lójú tó pé Ọlọ́run máa jí òun dìde, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi ólífì ló ní lọ́kàn. Jóòbù sọ pé: “Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù.” Nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lẹ́yìn tí ọ̀dá ti mú kí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, kùkùté igi ólífì tó ti gbẹ lè sọjí pa dà, á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ẹ̀tun bí ọ̀gbìn tuntun.”—Jóòbù 14:7-9.

Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń retí ìgbà tí gbòǹgbò igi ólífì tí wọ́n gé lulẹ̀ máa sọjí pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń retí ìgbà tó máa jí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì tó ti kú dìde kí wọ́n lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. (Mát. 22:31, 32; Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ náà máa jẹ́ nígbà tá a bá tún rí àwọn tó ti kú, tí wọ́n sì ń gbádùn ayé wọn lẹ́ẹ̀kan sí i!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́