ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/15 ojú ìwé 27-30
  • Ògo-ẹwà Orí-ewú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ògo-ẹwà Orí-ewú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Agbara Èwe
  • Jijere Ẹwà-Ògo
  • Bibọla fun Orí-Ewú
  • Maa Wo Iwaju, Kìí Ṣe Ẹhin
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ohun Tó Ń Mú Kí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ “Adé Ẹwà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/15 ojú ìwé 27-30

Ògo-ẹwà Orí-ewú

YOO ti dunmọni tó lati bá awọn ọkunrin ati obinrin ìgbà laelae sọrọ! Iwọ wulẹ ronu nipa bíbá awọn ọkunrin bi Noa, Abrahamu, Mose, ati Johannu Arinibọmi sọrọ, ati pẹlu awọn obinrin bi Sara, Rahabu, Rutu, ati Debora! A kò ha ní gbà ọ́ lọkan lati gbọ́ ki wọn rohin akọsilẹ awọn iṣẹlẹ titayọ ti wọn foju araawọn ri ni ìgbà pipẹ sẹhin bi?

Àní lonii paapaa, iwọ kò ha ni gbadun gbígbọ́ ki awọn agbalagba oluṣotitọ ṣajọpin awọn iriri nipa bi awọn ati awọn miiran ṣe pa iwatitọ wọn mọ́ si Ọlọrun labẹ awọn adanwo, ti ó ní awọn ifofinde, nínà, ati ifisẹwọn nitori òdodo ninu bi? Ó daju pe bẹẹ ni yoo rí! Ifẹ wa fun Ọlọrun ati kíkà ti a kà wọn sí gidigidi yoo ga sii bi wọn ti ń sọ fun wa nipa awọn imọlara wọn ati ni pataki nipa imọriri atọkanwa wọn fun itọju onifẹẹ ti Jehofa.

Laaarin awọn eniyan Ọlọrun, awọn ọkunrin ati obinrin agbalagba oluṣotitọ ni a ti sábà maa ń bọwọ fun fun iriri, ìmọ̀, ati ọgbọ́n wọn. Nitootọ, àṣẹ ti o tẹle e yii wà ninu Ofin ti Ọlọrun fifun awọn ọmọ Israeli: “Ki iwọ ki o sì dide duro niwaju orí-ewú, ki o sì bọwọ fun oju arugbo, ki o sì bẹru Ọlọrun rẹ: Emi ni OLUWA.” (Lefitiku 19:32) Ọ̀rọ̀ Heberu fun ọjọ-ori tabi ọjọ́ ogbó wá lati inu gbongbo kan ti o tumọsi “dàgbà di ewú” a sì tun tumọ rẹ̀ si “orí-ewú.” Nitori naa awọn ọmọ Israeli ni a reti pe ki wọn dide gẹgẹ bi àmì ọ̀wọ̀ fun agbalagba kan, ni ṣiṣe bẹẹ ninu ibẹru ọlọ́wọ̀-ńlá fun Ọlọrun.

Iru iṣarasihuwa ọlọ́wọ̀ bẹẹ ha wà lonii bi? Fun apẹẹrẹ, ǹjẹ́ awọn ọ̀dọ́ ha ń fi àánú ṣí ilẹkun fun awọn agbalagba bi? Ǹjẹ́ awọn èwe tabi awọn ọ̀dọ́ agbalagba ha sábà maa ń fi ààyè wọn fun agbalagba kan ninu ẹ̀rọ agbéniròkè kan ti ó ti kún bi? Tabi awọn ti wọn tubọ jẹ́ ọ̀dọ́ ni gbogbogboo ha ń fi ijokoo wọn silẹ fun agbalagba ninu bọọsi tabi ọkọ̀ oju-irin ti o kun fun èrò bi? Ikuna lati ṣe iru awọn nǹkan bẹẹ ni a tilẹ ti kiyesi laaarin awọn Kristian.

Lati wu Jehofa Ọlọrun, bi o ti wu ki o ri, awọn Kristian gbọdọ huwa ni iṣọkan pẹlu oju-iwoye rẹ̀ ki wọn sì yẹra fun ironu, ọrọ-sisọ, ati iṣesi awọn wọnni ti wọn jẹ́ ‘olufẹ ti araawọn, aṣaigbọran si òbí, alailọpẹ, ati alainifẹẹ ohun rere.’ (2 Timoteu 3:1-5) Nigba naa, ki ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nipa wíwà ni èwe ni isopọ pẹlu orí-ewú?

Agbara Èwe

Bibeli mọ okun ìgbà èwe ati awọn anfaani rẹ̀, ni sisọ pe: “Ògo awọn ọdọmọkunrin ni agbara wọn.” (Owe 20:29) Ni Israeli igbaani agbara awọn ọmọ Lefi ọ̀dọ́ ni a fisilo ninu tẹmpili, niye ìgbà fun ọpọlọpọ awọn iṣẹ alagbara. Lonii, ọpọ julọ ninu awọn iṣẹ ile-ẹrọ, ni awọn ile Beteli, ati ni awọn ibi ikọle Watch Tower Society ni awọn ọ̀dọ́kùnrin ati ọ̀dọ́bìnrin ti wọn ti yọnda okun ati agbara wọn lati mú ki awọn ire Ijọba tẹsiwaju ń ṣe. (Matteu 6:33) Wọn ń tipa bayii gbadun awọn anfaani rere ninu iṣẹ-isin Ọlọrun.

Owe ti a ṣẹṣẹ ṣayọlo tán yii pari pẹlu awọn ọ̀rọ̀ naa, “ẹwà awọn arugbo ni [orí-ewú, NW].” Nigba ti okun ìgbà èwe bá papọ pẹlu iriri ati ọgbọ́n ọpọ ọdun, iparapọ ti o lagbara gan-an ni a mu ki o wà.

Lati ṣàkàwé: Ọ̀dọ́ ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ gbẹnagbẹna kan ti a ti sọ fun pe ki o kan awọn pákó kan wá ọ̀nà lati ṣe iṣẹ-ayanfunni naa pẹlu agbara ìgbà èwe. Gbẹnagbẹna agbalagba, ti o niriiri ju kan ṣakiyesi pe laika okun rẹ̀ sí, ọ̀dọ́ olùrànlọ́wọ́ naa ń gbá ìṣó fun ìgbà melookan ki ó tó wọlé. Oṣiṣẹ agbalagba naa damọran pe ki ọ̀dọ́kùnrin naa di hámà naa mú ni ìdí, dipo ibi ti ó sunmọ ibi òòlù rẹ̀. Eyi jẹ́ ki ó ṣeeṣe fun ọ̀dọ́ naa lati fi ipá ti ó pọ̀ sii gbá awọn èṣó naa, ni pipa akoko ati okunra diẹ mọ́.

Bakan naa, ọ̀dọ́bìnrin, ti ó ní okunra kan lè kẹkọọ nipa igbiyanju ati aṣiṣe pe awọn aṣọ kan ni a o bajẹ bi a kò bá fọ̀ wọn ni ibamu pẹlu awọn itọni. Obinrin kan ti o niriiri, bi o ti wu ki o ri, mọ iniyelori lilo akoko lati ṣa awọn aṣọ naa sọtọọtọ ki ó sì fọ awọn ẹ̀wù kan lọtọọtọ. Oun tún ti kẹkọọ pe oun lè yẹra fun aṣọ lílọ̀ diẹ nipa kíká awọn aṣọ bi oun ti ń kó wọn kuro lori awọn okùn ìsáṣọ tabi kuro ninu ẹ̀rọ ti a fi ń gbẹ aṣọ.

Kikẹkọọ lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan oniriiri lè mú ki igbesi-aye tubọ dẹrun. Bi o tilẹ ri bẹẹ, akoko kan ń bọ̀ nigba ti oniriiri eniyan kan paapaa kò ni lè bojuto awọn iṣẹ kan ti oun lọkunrin tabi lobinrin ti ṣaṣepari rẹ̀ ni iwọnba awọn ọdun diẹ ṣaaju. Onkọwe kan ṣakiyesi lọna ti ó ṣe wẹ́kú pe: “Yoo ti dara tó ki a sọ pe awọn èwe ní ìmọ̀, ki awọn agbalagba sì ní okun.” Ṣugbọn yoo ti dara tó nigba ti awọn agbalagba bá mọriri okun awọn ọ̀dọ́ ki wọn sì fi suuru ṣajọpin iriri ti wọn ti jèrè lati ọpọ ọdun wá pẹlu wọn—ki awọn èwe sì fi tirẹlẹtirẹlẹ tẹwọgba awọn idamọran! Ni ọ̀nà yii, awujọ ọjọ-ori mejeeji yoo janfaani.

Jijere Ẹwà-Ògo

Ọjọ-ori lasan kò tó. “Eniyan ńláǹlà kìí ṣe ọlọgbọn, bẹẹ ni awọn àgbà ni òye idajọ kò yé” ni ọdọmọkunrin naa Elihu sọ. (Jobu 32:9; Oniwasu 4:13) Lati mọriri ẹni nitori orí-ewú, agbalagba kan ti nilati ṣe ohun pupọ ninu igbesi-aye rẹ̀ ju lilo awọn ọjọ rẹ̀ lọna ìmẹ́lẹ́ ní wiwo tẹlifiṣọn, lilọ si awọn ibi iṣẹlẹ eré aṣedaraya, tabi wiwulẹ gbadun araarẹ̀ lọna miiran kan ṣá. Ati ni awọn ọdun ẹhinwa ìgbà naa paapaa, agbalagba naa nilati maa baa lọ lati kẹkọọ.

Awọn eniyan kan ń fọ́nnu nipa ṣiṣe awọn nǹkan ni ọ̀nà ti araawọn, tabi ki wọn sọ pe: “Iriri ni olukọ didara julọ.” Sibẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbanni nimọran pe: “Ọlọgbọn yoo gbọ́, yoo sì maa pọ̀ sii ni ẹkọ; ati ẹni òye yoo gba igbimọ ọgbọn.” (Owe 1:5; fiwe 1 Korinti 10:11.) Iriri kìí figba gbogbo jẹ́ olukọ didara julọ, nitori pe a lè kẹkọọ lara aṣiṣe awọn ẹlomiran laisi pe a nilati ṣe aṣiṣe kan-naa funraawa. Ju bẹẹ lọ, Kristian kan yoo fẹ́ lati fi i sọkan pe “ade ògo ni orí-ewú, bi a bá rí i ni ọ̀nà òdodo.” (Owe 16:31) Igbesi-aye kan ti a lò ninu iṣẹ-isin olotiitọ si Jehofa lẹwa loju iwoye Jehofa ó sì yẹ fun ọ̀wọ̀ awọn ẹlomiran gẹgẹ bi apẹẹrẹ rere kan. Dajudaju, kikẹkọọ nipa Ọlọrun ati jijere iriri “ní ọ̀nà òdodo” lè bẹrẹ ni kutukutu igbesi-aye ó sì nilati jẹ́ ọ̀nà-ìgbàṣe ti kò lopin.—Romu 11:33, 34.

Eyi ni a lè ṣàkàwé rẹ̀ nipasẹ iriri ti ó wémọ́ ọdọmọkunrin ẹni ọdun meje kan ni Sweden. Ó beere lọwọ alaboojuto Ilé-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun ninu ijọ bi oun bá lè darapọ mọ ilé-ẹ̀kọ́ naa. Alaboojuto naa beere pe, “Eeṣe?” Fun eyi, ọdọlangba naa fesipada pe: “Eeyan kò lè wá fi gbogbo igbesi-aye rẹ̀ tàfàlà jàre!” (Oniwasu 12:1) Ẹ wo iru apẹẹrẹ gbigbeniro ti eyi jẹ́ fun tèwe-tàgbà bakan naa!

Bibọla fun Orí-Ewú

Ìtẹ̀sí kan ti ń danilaamu ninu awujọ ode-iwoyi ni lati gbé iniyelori ńláǹlà kari níní kìmí ti ara-ìyára ati wíwà ni ka-npe ati lati foju tín-ín-rín awọn agbalagba. Ki ni o nilati jẹ́ iṣarasihuwa Kristian si awọn olórí-ewú ninu ijọ?

Dipo gbigboju fo awọn Kristian agbalagba dá, a nilati kà wọn sí ki a sì lo akoko pẹlu wọn. Fun apẹẹrẹ, ni awọn ipade ọsọọsẹ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ninu Gbọngan Ijọba, iwọ ha ń sapa lati kí awọn agbalagba bi? Wọn mọriri ikini awọn ọ̀dọ́ ati ti awọn miiran nitootọ. Ẹ sì wo bi awọn agbalagba ti gbadun wiwa nibi ikorajọ ẹgbẹ-oun-ọgba ti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn jẹ́ ọlọ́jọ́-orí yiyatọsira tó! Bi o tilẹ jẹ pe tọkọtaya ti wọn jẹ́ ọ̀dọ́ lè ní ọkàn-ìfẹ́ tọtuntosi ti o tubọ pọ si ninu awọn tọkọtaya miiran ti wọn jẹ́ irọ̀ wọn, yoo mu itẹnilọrun wá lati fi awọn agbalagba kún iru ikorajọ alayọ bẹẹ.—1 Tessalonika 3:12; 5:15.

Ó ti ṣe pataki tó lati jẹ́ agbatẹniro nigba ti a bá ń bá awọn agbalagba sọrọ! Nigba ti arakunrin agbalagba kan ti o ti lo 40 ọdun ninu iṣẹ-isin si Jehofa bá alagba miiran sọrọ nipa bi a ṣe lè lo oun ninu ijọ, ọ̀dọ́kùnrin naa sọ pe: “Ẹyin kò ní ohun ti o pọ̀ tó lati fifunni.” Ẹ wo iru ọ̀rọ̀ alaininuure ti eyi jẹ́! Arakunrin agbalagba naa ní okunra ti ó dinku si eyi ti ó ní ní igbakan ri, ipin rẹ̀ ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá ti jó rẹhin lọna kan ṣáá, iru awọn anfaani iṣabojuto kan ni kedere sì ti kọja agbara rẹ̀ nisinsinyi; sibẹ, oun ní pupọ lati fifunni. Ó ní ọgbọn ati iriri ni ọ̀nà òdodo ti o ti kójọ fun ọpọ ọdun. Nitori pe iru awọn agbalagba bẹẹ ṣiṣẹ kára gẹgẹ bi oniwaasu Ijọba, ti wọn farada inunibini, gbé awọn ẹrù wiwuwo ti ẹrù-iṣẹ́ Kristian, ti wọn sì dá awọn ẹlomiran lẹkọọ, awọn eniyan Ọlọrun ń gbadun eto-ajọ lilagbara kan tí ẹmi Ọlọrun ń tì lẹhin nisinsinyi. Nitori naa, ǹjẹ́ ki awa fi ọ̀wọ̀ hàn fun awọn agbalagba wọnyi gẹgẹ bi awọn olugbaninimọran ọlọgbọn, oluṣọ-agutan onifẹẹ, ati olukọ gbigbeṣẹ.

Idi rere tún wà lati fi igbeyẹwo onironujinlẹ fun awọn imọran ti awọn agbalagba bá dá. Fun apẹẹrẹ, arakunrin oniriiri kan damọran pe ki a má jẹ́ ki ilẹkun Gbọngan Ijọba kan bayii wà ni ìhà iwọ-oorun ile naa. Awọn ará ti wọn tubọ jẹ́ ọ̀dọ́ ti ẹwà ti wọn ronu pe ile naa lè ní jẹ lógún jù kò tẹle amọran rẹ̀. Lẹhin awọn ọdun melookan, bi o ti wu ki o ri, ilẹkun naa ni a tún yọ si ibomiran nitori pe ìjì ati òjò ìgbà gbogbo lati iwọ-oorun ti ṣokunfa ibajẹ rẹ̀. Ọgbọn ti o gbéṣẹ lati inu iriri wá ju awọn kókó ti èrò-ẹwà lọ. Bi awọn ti wọn tubọ jẹ́ ọ̀dọ́ bá bọla fun awọn agbalagba nipa fifetisilẹ si awọn èrò ati ọgbọn gbígbéṣẹ́ wọn, eyi bakan naa lè dín akoko ati owó kù. Àní bi a kò tilẹ tẹle amọran agbalagba naa, oun ni a lè bọla fun nipa jijẹ ki ó mọ̀ pe a gbé e yẹwo, ṣugbọn awọn kókó miiran ṣamọna si ipinnu miiran.—Fiwe Owe 1:8.

Maa Wo Iwaju, Kìí Ṣe Ẹhin

Awọn agbalagba kan gba oju-iwoye yii pe: “Kò sí ìgbà ti o dabi ìgbà yẹn lọ́hùn-ún nigba ti iwọ ati emi wà ni ọ̀dọ́.” Dipo rironu lori awọn akoko ti ó ti kọja lọ, bi o ti wu ki o ri, iru awọn agbalagba bẹẹ ni a lè fun niṣiiri lati maa wo iwaju fun ọjọ naa nigba ti wọn yoo gba èrè wọn ti ọrun tabi tun ri okunra ìgbà èwe wọn gbà labẹ iṣakoso Ijọba Ọlọrun. Laaarin akoko yii ná, ààlà wọn nitori ọjọ-ori nilati di mímọ̀ fun wọn. Mímọ̀ yii ati èrò-imọlara ìdẹ́rìn-ín-pani mímú hánhán kò ṣeediyele nigba ti a bá gboju fo agbalagba kan dá fun anfaani iṣẹ-isin lọna ti o ṣe kedere.

Fun apẹẹrẹ, arakunrin agbalagba kan ni a ti lè maa lò deedee ninu awọn itolẹsẹẹsẹ apejọpọ agbegbe ni ọpọ ọdun sẹhin. Nisinsinyi ọpọlọpọ alagba titootun ati yíyan awọn ọkunrin ti wọn ni agbara ikọnilẹkọọ gbigbooro wà. Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ́ ọ̀dọ́ ni ifiwera, diẹ lara awọn alagba wọnyi ti fi ìtara ati agbára-òye hàn kedere, wọn lè kọni daadaa ki wọn sì funni ni iṣileti, wọn sì lè gba awọn ẹlomiran niyanju. (1 Tessalonika 5:12, 13; 1 Timoteu 5:17) Gẹgẹ bi iyọrisi, arakunrin agbalagba kan ti kìí farahàn lori itolẹsẹẹsẹ apejọpọ lè nimọlara pe a gboju fo oun dá ó sì lè má layọ pe awọn anfaani naa ni a ti fifun awọn alagba ti wọn tubọ jẹ́ ọ̀dọ́. Sibẹ, imọlara òdì yẹn ti ń jẹ jade lati inu aipe eniyan ni a lè bori. Nitootọ, gbogbo awọn ti wọn wà ninu ijọ lè ṣeranwọ nipa jijẹki awọn agbalagba mọ̀ pe a nilo wọn, pe a nifẹẹ wọn fun iṣotitọ wọn, ati pe awọn èrò wọn ni a kà sí iyebiye.

Dajudaju, agbalagba kan nilati ranti pe awọn olujọsin ẹlẹgbẹ oun ni oun gbọdọ bọla fun gan-an gẹgẹ bi oun yoo ti fẹ́ ki a bọla fun oun. (Matteu 7:12; Romu 12:10) Dipo ninimọlara pe a ti fẹhin wọn tì nitori ọjọ ori wọn ki wọn sì maa jiya lọwọ oju-iwoye òdì, awọn agbalagba nilati yọ̀ nitori ọpọ ọdun iduroṣinṣin ninu iṣẹ-isin wọn. Ó sì daju pe, gbogbo wa nilati kún fun imoore pe gẹgẹ bi iyọrisi ibukun Jehofa, iye awọn alaboojuto titotun ti ń pọ sii wà lati ṣajọpin ẹrù-iṣẹ́ ati lati gba awọn ẹrù-iṣẹ́ ijọ bi ogunlọgọ ti “awọn agutan miiran” ti ń rọ́ wọnu eto-ajọ Kristian.—Johannu 10:16; Isaiah 60:8, 22; 2 Timoteu 2:2.

Nitori irora, ara ti kò dá, tabi awọn kókó-abájọ miiran, awọn olórí-ewú nigba miiran a maa kanragógó. Eyi beere fun iloye ati igbatẹniro ni apa ọ̀dọ̀ awọn mẹmba idile tabi ijọ miiran. Ó tun beere pe ki awọn agbalagba ṣiṣẹ kára lati pa iṣarasihuwa onifojusọna fun rere mọ, lati wà ni ọ̀dọ́ ni ọkan-aya ati ero-inu. Nigba ti alájọgbélé ti o tubọ jẹ́ ọ̀dọ́ fun mẹmba Ẹgbẹ́ Oluṣakoso Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ń fi Beteli silẹ ni awọn ọdun diẹ sẹhin, ọkunrin agbalagba naa sọ fun alájọgbélé rẹ̀ pe ki o damọran arọ́pò rere kan ó sì sọ pe oun yoo fẹ́ arakunrin ti o jẹ́ ọ̀dọ́, ti o gboṣaṣa lati ran oun lọwọ lati wà ni ọ̀dọ́ ki oun sì jafafa. Arakunrin agbalagba ẹni-ami-ororo naa kò fẹ́ lati fawọsẹhin tabi fẹhinti, nitori pe iṣẹ wà lati ṣe. Iru apẹẹrẹ rere ti wiwo iwaju ati pipa oju-iwoye onifojusọna fun rere mọ́ wo ni eyi jẹ́!

Laiṣe àní-àní, “ògo awọn ọdọmọkunrin ni agbara wọn: ẹwà awọn arugbo ni [orí-ewú, NW]” wọn. Ó ti jẹ́ agbayanu tó nigba ti awọn ọ̀dọ́ eniyan bá lo okun wọn ti awọn agbalagba sì fi ọgbọn wọn silo ninu lilepa ọ̀nà òdodo! Awọn Kristian tàgbà tèwe bakan naa ń niriiri ayọ ńláǹlà bi wọn ti ń fi iṣọkan gbé ijọsin tootọ ti Jehofa Ọlọrun, “Ẹni-àgbà ọjọ naa” ga siwaju.—Danieli 7:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Awọn Kristian olórí-ewú ní pupọpupọ lati fifunni fun anfaani awọn ẹlomiran

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́