Idaloro Ayeraye—Eeṣe Ti o Fi Jẹ́ Ẹkọ kan Ti Ń Danilaamu?
“Mo gbọ pe ẹ gba iṣẹ́ lọwọ pasitọ yin. Kilo de?”
“Ó dara, ó ń sọ fun wa lemọlemọ pe gbogbo wa ni a ń lọ si ọrun-apaadi.”
“Ki ni pasitọ ti ẹ ṣẹṣẹ gbà sọ?”
“Pasitọ titun naa sọ pe a ń lọ si ọrun-apaadi, pẹlu.”
“Nitori naa kí wá ni iyatọ?”
“Ó dara, iyatọ naa ni pe nigba ti pasitọ ti iṣaaju sọ ọ́, ó dún bi pe inu rẹ̀ dùn nipa rẹ̀; ṣugbọn nigba ti ẹni titun yii ń sọ ọ́, ó ń dún bi pe ó ń ba ọkàn rẹ̀ jẹ́.”
NIBI ti a ti sọ ọ́ ninu alaworan kan, ìtàn yii ń ṣàgbéyọ ni ọ̀nà tirẹ̀ pe ọpọlọpọ awọn olukọ Bibeli, ati awọn olùreṣọ́ọ̀ṣì bakan naa, ni ẹkọ ọrun-apaadi kò tù lára. Ninu ayika-ọrọ ti o tubọ pọ, ó tun jẹrii si ohun ti ẹlẹkọọ-isin ara Canada Clark H. Pinnock ṣakiyesi pe: “Ninu gbogbo ọrọ-ẹkọ nipa isin ti o tíì yọ ẹ̀rí-ọkàn eniyan lẹnu la ọpọ ọrundun ja, mo lero pe iwọnba diẹ ni o ti ṣokunfa aniyan ti o tubọ ju iṣetumọ ti a tẹwọgba nipa ọrun-apaadi gẹgẹ bi ijiya ainipẹkun ti a ń nimọlara rẹ̀ ninu ara ati ọkàn.”
Àkóbá Niti Ọna-Iwahihu
Eeṣe, nigba naa, ti ọpọlọpọ fi ń daamu nipa awọn ìran iná tí ń jó lala ti Kristẹndọm gbekalẹ? (Wo apoti.) Ọjọgbọn Pinnock ṣalaye pe: “Èrò naa pe ẹ̀dá kan ti o nimọlara nilati niriiri idaloro ti ara-ìyára ati ti ọpọlọ jalẹ akoko ti kò lopin jẹ́ ọ̀kan ti ń danilaamu gidigidi, èrò naa pe eyi ni a mú ki o ṣẹlẹ si wọn nipasẹ àṣẹ atọrunwa si pa idaniloju mi nipa ifẹ Ọlọrun lara.”
Bẹẹni, ẹkọ idaloro ayeraye gbe iṣoro kan kalẹ nipa ọ̀ràn iwarere. Fun apẹẹrẹ, awọn Kristian olotiitọ-inu ronu jinlẹ lori awọn ibeere ti ẹlẹkọọ-isin Katoliki Hans Küng gbé dide pe: “Ọlọrun ifẹ ha nilati . . . maa wo idaniloro ti ara-ìyára-òun-èrò-orí rírorò ti o jẹ́ alailopin, alainireti, alailaaanu, alainifẹẹ, ti awọn ẹ̀dá rẹ̀ yii titi gbére bi?” Küng ń baa lọ pe: “Oun ha jẹ́ iru olùwínni ọlọkan lile bẹẹ bi? . . . Ki ni a o rò nipa ẹ̀dá eniyan kan ti o tẹ́ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati gbẹsan lọrun lọna ti kò ṣeeyipada tabi tẹlọrun tobẹẹ?”a Dajudaju, bawo ni Ọlọrun ti ó sọ fun wa ninu Bibeli pe awa nilati nifẹẹ awọn ọ̀tá wa ṣe fẹ́ lati dá awọn ọ̀tá rẹ̀ lóró titi ayeraye? (1 Johannu 4:8-10) Lọna ti kò yanilẹnu, awọn eniyan kan pari-ero pe bi ọrun-apaadi ti rí ni kò bá bi Ọlọrun ti rí mu paapaa, pe ẹkọ yii kò bá ọgbọn ironu iwarere mu.
Ọpọ awọn onigbagbọ miiran gbiyanju lati pa ẹ̀rí-ọkàn wọn lẹnu mọ́ nipa yiyẹra fun awọn ibeere wọnyi. Pipa awọn ibeere wọnyi tì, bi o ti wu ki o ri, kò mú ki awọn idaamu wọnyi pòórá. Nitori naa ẹ jẹ ki a dojukọ ọ̀ràn naa. Ki ni awọn àkóbá niti ọna-iwahihu ti o sopọ mọ́ ẹkọ yii? Ninu Criswell Theological Review, Ọjọgbọn Pinnock kọwe pe: “Idaloro ainipẹkun ni kò ṣeégbà láàyè bi a bá fi oju-iwoye ti ọna-iwahihu wò ó nitori pe ó sọ Ọlọrun di ẹni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ti ongbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ ti o ní Auschwitz ainipẹkun kan bii ti Nazi fun awọn ojiya ti oun kò tilẹ gbà láàyè lati kú.” Ó beere pe: “Bawo ni ẹnikan tí wàrà àánú eniyan wà ninu rẹ̀ ṣe lè gbe jẹẹ ki o si maa ṣaṣaro lori iru èrò [ẹkọ ọrun-apaadi ti igbagbọ atọwọdọwọ] bẹẹ? . . . Bawo ni awọn Kristian ṣe lè fi ọlọrun ti o ní iru ìwà-rírorò ati ẹmi igbẹsan bẹẹ hàn?”
Ni fifi ipa buburu tí ẹkọ yii ti lè ní lori iwa eniyan hàn, Pinnock ṣalaye pe: “Mo tilẹ ṣe kayeefi nipa iwa buburu ti awọn wọnni ti wọn gbagbọ ninu Ọlọrun tí ń dá awọn ọ̀tá rẹ̀ loro ti lè hù?” Ó pari ọ̀rọ̀ pe: “Eyi kìí ha ṣe èrò ti ń danilaamu julọ ti ó gba àtúnrò bi?” Bẹẹni, bi a bá ka iru ìwà-rírorò bẹẹ si Ọlọrun lọ́rùn, kò ni yanilẹnu pe awọn olùreṣọ́ọ̀ṣì ti wọn lẹ́mìí imọlara ń ṣatunyẹwo iná ọrun-apaadi. Ki ni wọn sì rí? Iṣoro miiran ti ń dojukọ èrò nipa idaloro ayeraye.
Ọrun-Apaadi ati Idajọ-Ododo
Ọpọ eniyan ti wọn ronu lori ẹkọ igbagbọ-atọwọdọwọ ti ọrun-apaadi rí i pe ó dabi ẹni pe ó fi Ọlọrun hàn gẹgẹ bi ẹni ti ń huwa lọna ti kò bá ẹ̀tọ́ mu, nitori naa ó ṣẹ̀ sí èrò adanida wọn nipa idajọ-ododo. Ni ọ̀nà wo?
Iwọ yoo ri idahun kan nipa fifi ẹkọ nipa idaloro ayeraye wéra pẹlu ọpa-idiwọn idajọ-ododo ti Ọlọrun fifunni pe: “Oju dipo oju, ehín dipo ehín.” (Eksodu 21:24) Fun ète ariyanjiyan, fi ẹkọ ina ọrun-apaadi silo fun ofin atọrunwa yẹn ti a fifun Israeli igbaani, ofin kan ti o jẹ́ ti isanpada ti o ṣe wẹ́kú. Ipari-ero wo ni o ṣeeṣe ki iwọ dé? Pe kìkì awọn ẹlẹṣẹ wọnni ti wọn ti ṣokunfa idaloro ayeraye ni wọn lẹtọọ si idaloro ayeraye ni ipa tiwọn—idaloro ayeraye fun idaloro ayeraye. Ṣugbọn niwọn bi awọn eniyan (kò sí bi wọn ti lè jẹ́ buburu tó) ti lè ṣokunfa kìkì idaloro ti o lopin, dídá wọn lẹbi si idaloro ayeraye dá aibaramu kan silẹ laaarin iwa-ọdaran wọn ati ijiya ina ọrun-apadi ailopin.
Ki a sọ ọ lọna rírọrùn, idajọ ijiya naa yoo ti wuwo jù. Yoo lọ rekọja “oju dipo oju, ehín dipo ehín.” Ni gbígbé e yẹwo pe awọn ẹkọ Jesu mú èrò nipa igbẹsan dẹ̀rọ̀, iwọ lè gbà pe yoo ga awọn Kristian tootọ lára lati rí ẹ̀tọ́ ti o wà ninu idaloro ayeraye.—Matteu 5:38, 39; Romu 12:17.
Dídá Ẹkọ naa Láre
Bi o tilẹ jẹ pe, ọpọlọpọ awọn onigbagbọ ń baa lọ ni gbigbiyanju lati dáre fun ẹkọ naa. Bawo? Onṣewe ọmọ ilẹ Britain Clive S. Lewis gbẹnusọ fun ọpọ julọ awọn ti ń jà fun ẹkọ naa ninu iwe rẹ̀ The Problem of Pain pe: “Kò sí ẹkọ kankan ti emi yoo fi imuratan mú kuro ninu isin Kristian ju eyi lọ, ti o bá wà ni agbara mi. Ṣugbọn ó ní itilẹhin kikun ti Iwe Mimọ ati, ni akanṣe, ti awọn ọ̀rọ̀ Oluwa Wa.” Nipa bayii, awọn alatilẹhin jẹwọ pe idaloro ayeraye ń koniniriira, ṣugbọn nigba kan-naa, wọn dì í mu pe ẹkọ naa jẹ́ dandan nitori pe wọn nimọlara pe Bibeli ń fi kọni. Pinnock ẹlẹkọọ-isin ṣakiyesi pe: “Nipa jijẹwọgba aigbadunmọni rẹ̀, wọn reti lati fẹ̀rí iwatitọ wọn si Bibeli laiya sọ́tùn-ún-sósì ati iru iwa-akọni kan bayii hàn ninu gbigba ti wọn gba iru otitọ bibanilẹru bẹẹ gbọ kìkì nitori pe iwe mimọ fikọni. Wọn mú ki ó dun bii pe aileṣe-aṣiṣe Bibeli ni ó wà ninu ewu. Ṣugbọn bẹẹ ha ni niti gidi bi?”
Iwọ pẹlu lè ṣe kayeefi boya iwatitọ si Bibeli kò fi ààyè yíyàn kankan silẹ fun ọ ṣugbọn lati tẹwọgba ẹkọ yii. Ki ni ohun ti Bibeli wí niti gidi?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Eternal Life?—Life After Death as a Medical, Philosophical, and Theological Problem, oju-iwe 136.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
AWỌN ÈRE MẸTA TI ERO-INU WỌN DỌGBA
Ijẹwọ Igbagbọ Westminster, tí ọpọ awọn Protẹstanti tẹwọgba sọ pe awọn tí kìí ṣe ayanfẹ “ni a o gbé sọ sinu idaloro ayeraye, ti a o sì fìyà iparun ainipẹkun jẹ.” “Ninu isin Kristian ti Roman Katoliki,” ni iwe naa The Encyclopedia of Religion ṣalaye, “ọrun-apaadi ni a kà sí ipo ijiya ti kò ni opin . . . ti a fihàn . . . nipa ijiya iná ati awọn idaloro miiran.” Iwe gbedegbẹyọ yii fikun un pe “Isin Kristian ti Eastern Orthodox” ṣajọpin “ẹkọ naa pe ọrun-apaadi jẹ ayanmọ iná ati ijiya ayeraye ti ń duro de awọn ẹni ègún.”—Idipọ 6, oju-iwe 238 si 239.