Iwọ Ha Ń Ṣe Gbogbo Ohun Ti O Lè Ṣe Bi?
“EMI yoo gbiyanju bi mo ti lè ṣe tó.” Ẹ wo bi “ṣugbọn” ti ń tẹ̀lé awọn ọ̀rọ̀ wọnyi lọpọ ìgbà tó ati akọsilẹ gigun nipa awọn àwáwí nitori ṣiṣailo ara-ẹni dé gongo! Ki ni nipa iyasimimọ wa si Jehofa? Awa ha ń mu ileri wa ṣẹ lati ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe fun un bi?
Lati ṣe iyasimimọ tumọsi ‘lati ya ara-ẹni sọtọ patapata fun iṣẹ-isin tabi ijọsin olùwà kan ni ọrun tabi fun awọn ìlò mímọ́ ọlọ́wọ̀.’ Jesu ṣe pupọ lati fi ohun ti iyasimimọ si Jehofa ní ninu hàn nipa sisọ pe: “Bi ẹnikan ba ń fẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé [igi idaloro, NW] rẹ̀, ki o si maa tọ̀ mi lẹhin.” (Matteu 16:24) Ẹnikan ti o ti sẹ́ araarẹ ti o sì ti ya araarẹ si mimọ fun Ọlọrun mu ki ṣiṣe ifẹ-inu atọrunwa jẹ́ ilepa pataki julọ ninu igbesi-aye rẹ̀.
Gẹgẹ bi awọn eniyan oluṣeyasimimọ, a nilati wadii araawa wò finnifinni lati ri boya a ń gbe ní ibamu pẹlu iyasimimọ wa. Peteru fi idi rẹ̀ ti a fi nilati ṣayẹwo araawa hàn nigba ti o fun awọn Kristian ẹni-ami-ororo niṣiiri pe: “Ẹ tubọ maa ṣe aisinmi lati sọ ìpè ati yíyàn yin di dajudaju: nitori bi ẹyin ba ń ṣe nǹkan wọnyi, ẹyin ki yoo kọsẹ lae.” (2 Peteru 1:10) Bẹẹni, bi awa ba ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe, awa ki yoo jásí ẹni ìkùnà nipa tẹmi.
Gbogbo Ohun ti A Lè Ṣe Ni A Lè Mú Pọ̀ Sii
Ninu itumọ gbigbooro, gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn ti ṣe iyasimimọ ni a reti pe ki wọn ṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe, tabi isapa wọn didara julọ, lati mu inu Jehofa dùn. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo ohun ti a lè ṣe ninu ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun lè pọ̀ sii. Fun ọmọdekunrin ọlọdun mẹta kan, sisare lọ lati jẹ́ awọn iṣẹ́ kekeke lè jẹ́ gbogbo ohun ti o lè ṣe lati ran iya rẹ̀ lọwọ, ṣugbọn bi o ṣe ń dàgbà sii, yoo ṣeeṣe fun un lati ṣe pupọ sii. Bakan naa ni o ri pẹlu idagbasoke tẹmi wa—ohun ti o ti figba kan ri jẹ gbogbo ohun ti a lè ṣe lè má tun jẹ́ bẹẹ mọ́. A sun wa lati ṣe pupọ sii fun Jehofa.
Imọriri wa ti ń pọ̀ sii fun Jehofa ni o ń bu epo si iná imuratan wa lati ṣe pupọ sii. Imọriri fun ohun ti o ti ṣe fun wa ni a ń fun lagbara sii nipasẹ idakẹkọọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Fun apẹẹrẹ, nigba ti a bá fi tiṣọratiṣọra ṣewadii ti a si ṣàṣàrò lori bi Jehofa ti rán Ọmọkunrin rẹ̀ lati fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ lati sọ aráyé dominira kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀, a sún wa lati ṣiṣẹsin Olupilẹṣẹ iṣeto irapada. (Johannu 3:16, 17; 1 Johannu 4:9-11) Bi a ṣe tubọ ń ‘tọ́ ọ wò, ti a si ń rí i pe, rere ni Oluwa’ tó, bẹẹ ni a ṣe tubọ ń sún ọkan-aya wa lati ṣiṣẹsin in tó.—Orin Dafidi 34:8.
Ojiṣẹ alakooko-kikun kan ti ń jẹ́ Jetter mọ eyi daju. Ki o baa lè walẹ̀ jìn daradara sinu ohun ti o ń kẹkọọ, o ya iyàrá kekere kan sọtọ ninu ilé rẹ̀ fun ète yẹn. O ṣeto rẹ̀ ki o baa lè pọkanpọ nigba ti o ba ń ṣe iwadii. O ní awọn Watch Tower Publications Index, ati awọn ìdìpọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji!, larọọwọto ninu apoti ìkówèésí rẹ̀. “Nigba ti mo ba ṣewadii jinlẹ nipa isọfunni fifanilọkanmọra,” ni oun wi, “mo maa ń haragaga lati ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran.”
Bi o ti wu ki o ri, bi o ti jẹ́ pe jijẹ ounjẹ dídọ́ṣọ̀ kan lẹkọọkan kò mu itura ba ẹnikan kuro ninu aini ojoojumọ lati maa jẹ ounjẹ deedee, iwadii jijinlẹ ti a ṣe sinu Bibeli nigba kan ri kò mu aini ojoojumọ naa lati maa jẹ ounjẹ tẹmi kuro. Ruth mọriri aini yii, nitori pe jinna pada si akoko ti oun lè ranti, idile rẹ̀ ń jumọ ka Bibeli papọ ni gbogbo owurọ ati ní ìrọ̀lẹ́ lẹhin ounjẹ. Nisinsinyi, ni ẹni ọdun 81, ti o ti lo eyi ti o ju 60 ọdun ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun, oun sibẹ ṣì ń ka Bibeli deedee lẹhin jíjí ni agogo 6:00 owurọ. Gbàrà ti o bá ti gba iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji!, Ruth a maa ya akoko sọtọ lati kà wọn. O ń ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan o keretan nígbà mẹta tabi mẹrin ṣaaju ki o tó kẹ́kọ̀ọ́ rẹ ninu ijọ. “Gbigba Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sinu ni ohun ti o nilo lati ma baa lọ ni jijẹ alagbara ninu igbagbọ,” ni o wi. O ti ṣeranwọ fun un pẹlu lati ma baa lọ ninu iṣẹ-isin ijihin-iṣẹ-Ọlọrun fun ọpọ ọdun.
Ṣiṣe Gbogbo Ohun Ti A Lè Ṣe ní Riran Awọn Miiran Lọwọ
Nipa ikẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jinlẹjinlẹ ati deedee, itara wa lati ṣiṣẹsin Ọlọrun ń pọ sii, ti ohun kan ninu wa si ń rọ̀ wa lati ṣe pupọ sii. (Fiwe Jeremiah 20:9.) Iru itara bẹẹ sún Hirohisa lati ṣaṣepari iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ lẹkun-un-rẹrẹ. (2 Timoteu 4:5) O ń gbé ninu idile òbí anikantọmọ pẹlu awọn aburo ọkunrin ati obinrin ti wọn jẹ́ mẹrin. Nigba ti o wà ni awọn ọdun ọdọlangba rẹ̀, Hirohisa ṣetilẹhin fun idile rẹ̀ nipa jíjí ni agogo mẹta owurọ lati pín awọn iwe-irohin ojoojumọ. O fẹ́ lati ṣe pupọ sii ni sisọ fun awọn ẹlomiran nipa Jehofa, nitori naa Hirohisa forukọsilẹ fun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna, bi a ṣe ń pe iṣẹ-ojiṣẹ alakooko-kikun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ṣe jẹ́ ọ̀dọ́ tóo nì, o gbadun riran awọn ẹlomiran lọwọ lati darapọ mọ ọn ninu ṣiṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe lati yin Jehofa.
Ṣiṣe gbogbo ohun ti agbara wa ká lati ran awọn ẹlomiran lọwọ ní ninu didi ọjafafa ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa. Nigba kan Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ niṣiiri pe: “Bi ẹyin bá mọ nǹkan wọnyi, alabukun-fun ni yin, bi ẹyin ba ń ṣe wọn.” (Johannu 13:17) Naomi jẹ apẹẹrẹ rere nipa fifi awọn ìdámọ̀ràn ti eto-ajọ Jehofa fifunni lati mu iṣẹ-ojiṣẹ wa sunwọn sii silo. O ṣoro fun un lati bá awọn ajeji sọrọ lati ilé dé ilé o sì maa ń fẹ́ ọ̀rọ̀ ti yoo sọ kù lọpọ ìgbà bi o ti ń duro lẹnu ọ̀nà. Awọn alagba ninu ijọ rọ̀ ọ́ lati fi awọn ìdámọ̀ràn ti o ri ninu iwe Reasoning From the Scriptures silo, ni ipin naa “Introduction for Use in the Field Ministry” (Awọn Inasẹ Ọ̀rọ̀ fun Lílò Ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Papa).a O kọ́ awọn inaṣẹ ọ̀rọ̀ ti o wà labẹ akori naa “Family/Children” (Idile/Awọn Ọmọ) ni àkọ́sórí o si fi wọn danrawo lọpọ ìgbà. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, o ṣeeṣe fun un lati maa ba ijumọsọrọpọ lọ pẹlu iyawo-ile kan ti o lé ni ẹni 30 ọdun. Koda ṣaaju ki Naomi tó lè ṣe ipadabẹwo, obinrin yii wá si Gbọngan Ijọba. Ikẹkọọ Bibeli kan ni a ṣeto. Iyawo-ile naa ati ọkọ rẹ̀ jẹ Kristian ti o ti ṣe iribọmi nisinsinyi, ti wọn ń gbadun igbesi-aye idile alayọ pẹlu awọn ọmọ wọn.
Ṣiṣe Gbogbo Ohun ti A Lè Ṣe Ninu Fifi Ọkàn-Ìfẹ́ Hàn Ninu Ẹnikọọkan
Awa pẹlu lè ṣafarawe aposteli Paulu, ẹni ti o sọ pe: “Emi sì ń ṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o lè jẹ alabaapin ninu rẹ̀ pẹlu yin.”—1 Korinti 9:22, 23.
Hatsumi fi iṣarasihuwa yii hàn. Nigba ti Hatsumi wà ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba, obinrin kan fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọrọ lori ẹ̀rọ ibanisọrọpọ pe ọwọ́ oun ti dí jù lati sọrọ. Ìró ohùn onílé naa jẹ ti oníwàpẹ̀lẹ́, nitori naa Hatsumi ń baa lọ lati ṣebẹwo sọdọ rẹ̀. Onílé naa wulẹ maa ń dahun lati inu ẹ̀rọ ibanisọrọ ni, kò figba kan ri jade wá lati pade Hatsumi. Eyi ń baa lọ fun ọdun meji ààbọ̀.
Ní ọjọ kan Hatsumi yí akoko ibẹwo rẹ̀ pada, ni ṣiṣe ikesini ní ọwọ́ ọsan. Ẹnikẹni kò dahun. Bi o ti wu ki o ri, bi o ti fẹ maa lọ, ohùn kan ti o mọ̀ dunju bi í latẹhin pe. “Iwọ ta ni?” Obinrin naa ṣẹ̀ṣẹ̀ pada dé sile ni. Bi o ṣe gbọ́ orukọ Hatsumi, o dahunpada kiakia pe, “Óò, iwọ ni o ti maa ń ṣebẹwo sọdọ mi. O ṣeun fun bibikita fun mi nigba gbogbo.” Nitori pe obinrin naa ti ṣíwọ́ ikẹkọọ Bibeli rẹ̀ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ibomiran, oun ni ojú ti gbà tì pupọ jù lati ṣílẹ̀kùn anfaani naa silẹ fun Hatsumi. Ikẹkọọ Bibeli kan ni a tun bẹ̀rẹ̀, ti onílé naa si ń tẹsiwaju daradara gan-an. Awa ha ń bikita lọna pupọ tobẹẹ fun awọn wọnni ti a ń bá pade ninu iṣẹ-ojiṣẹ ilé-dé-ilé bi?
Ṣe Gbogbo Ohun ti O Lè Ṣe
Jehofa mọriri isapa wa lati ṣiṣẹsin in debi ti a bá lè ṣe é dé. O dabi baba kan ti ọmọkunrin rẹ̀ wá sọdọ rẹ̀ pẹlu awọn ẹ̀bùn. Fun ọpọ ọdun ti o ti kọja, ẹ̀bùn naa lè yatọ ni sisinmi lori ọjọ ori ọmọkunrin naa ati ohun ti o ní. Gan-an bi baba naa yoo ti layọ lati gba awọn ẹ̀bùn atọkanwa eyikeyii ti ọmọkunrin rẹ̀ fifun un, bakan naa ni Jehofa ń muratan lati gba iṣẹ-isin atọkanwa wa ní ibamu pẹlu idagba wa nipa tẹmi.
Dajudaju, kò si idi fun fifi gbogbo ohun ti a lè ṣe wera pẹlu ti awọn miiran. Gẹgẹ bi Paulu ti sọ, awa yoo ní idi fun iṣogo nipa ti araawa, ‘kì yoo si ṣe nipa ti ọmọnikeji wa.’ (Galatia 6:4) Ǹjẹ́ ki a maa baa lọ lati kọbiara si ìmọ̀ràn aposteli Peteru pe: “Ẹ mura giri, ki a lè bá yin ni alaafia, ni ailabawọn, ati ni ailabuku ni oju rẹ̀.”—2 Peteru 3:14.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Iwọ ha ń sa gbogbo ipa rẹ lati fi awọn ìdámọ̀ràn fun iṣẹ-ojiṣẹ papa silo bi?