‘Ẹ Máa Sa Gbogbo Ipá Yín’
1 Nígbà tí a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣèlérí láti fún un ní ohun tí a ní tí ó dára jù lọ. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní níṣìírí pé kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn láti mú ìdúró wọn dájú níwájú Jèhófà. (2 Pét. 1:10) Dájúdájú, a fẹ́ láti máa sa gbogbo agbára wa láti mú inú Jèhófà dùn ní sísìn ín lónìí. Kí ni èyí ní nínú? Bí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà ti ń jinlẹ̀ sí i tí a sì ń ṣàṣàrò lórí gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún wa, ọkàn àyà wa ń sún wa nígbà gbogbo láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. A fẹ́ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i, níbi tí ó bá sì ti ṣeé ṣe, a fẹ́ láti mú kí ó pọ̀ sí i.—Orin Dá. 34:8; 2 Tím. 2:15.
2 Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tí ó fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé mú kí ìmọrírì òun fún Jèhófà jinlẹ̀ sí i, ó sì gbin ìtara tí ó pọ̀ sí i sínú rẹ̀. Èyí sún un láti kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Arábìnrin kan tí ó ṣòro fún láti bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ fi díẹ̀ nínú àwọn ìgbékalẹ̀ tí ń bẹ nínú ìwé Ìjíròrò Bibeli dánra wò, kò sì pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn àṣeyọrí púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún un láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú tọkọtaya kan tí ó tẹ́wọ́ gba òtítọ́.
3 Ẹ Máa Yọ̀ Nípa Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe: Àwọn kan lára wa ń nírìírí àwọn àyíká ipò líle koko bí ìlera tí kò sunwọ̀n, àtakò ìdílé, òṣì, tàbí ìdágunlá ní ìpínlẹ̀ wa. Ọ̀pọ̀ ìṣòro mìíràn tí ó wọ́pọ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí lè ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn wa. (Lúùk. 21:34, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW; 2 Tím. 3:1) Èyí ha túmọ̀ sí pé a ti kùnà nínú ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ bí a bá ń ṣiṣẹ́ sìn ín dé ibi tí ipá wa mọ.
4 Kò bọ́gbọ́n mu láti fi ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe díwọ̀n ara wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fún wa níṣìírí pé “kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ jẹ́.” Yíyọ̀ǹda ara wa ní kíkún títí dé ìwọ̀n tí agbára àwa fúnra wa mọ ń mú inú Jèhófà dùn ó sì ń fún wa ní “ìdí fún ayọ̀ àṣeyọrí.”—Gál. 6:4; Kól. 3:23, 24.
5 Ǹjẹ́ kí a kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù láti ‘sa gbogbo ipá wa kí Ọlọ́run lè bá wa nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.’ (2 Pét. 3:14) Ẹ̀mí yẹn yóò mú kí a nímọ̀lára ààbò yóò sì fún wa ní àlàáfíà èrò inú tí ó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ni ó lè fi fúnni.—Orin Dá. 4:8.