ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/1 ojú ìwé 15-21
  • Awọn Igbokegbodo Ti A Mú Gbooro Sii Nigba Wíwàníhìn-ín Kristi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Igbokegbodo Ti A Mú Gbooro Sii Nigba Wíwàníhìn-ín Kristi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Afikun Anfaani
  • Kíkó Awọn Agutan Jọ
  • Awọn Ọmọ-Abẹ Ijọba Naa
  • Ríran Ọba Naa Lọwọ
  • Awọn Igbokegbodo Ti A Mu Gbooro Sii
  • “Ẹrú” Tí ó Jẹ́ Olóòótọ́ Àti Olóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Ní Ti Tòótọ́, Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ Àti Olóye?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí Kristi Àti Sí Ẹrú Rẹ̀ Olóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Wọ́n “Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn Ṣáá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/1 ojú ìwé 15-21

Awọn Igbokegbodo Ti A Mú Gbooro Sii Nigba Wíwàníhìn-ín Kristi

“Nigba naa ni Ọba yoo wi fun awọn ti o wa ni ọwọ ọtun rẹ̀ pe, Ẹ wa, ẹyin alabukunfun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.”—MATTEU 25:34.

1. Ni ọ̀nà wo ni pa·rou·siʹa Kristi fi ri gẹlẹ bi “ọjọ Noa”?

WÍWÀNÍHÌN-ÍN Kristi—iṣẹlẹ ti a ti ń duro dè tipẹtipẹ naa! Akoko naa ti o dabii ti “ọjọ Noa,” eyi ti Jesu sọrọ nipa rẹ̀ ní isopọ pẹlu “opin ayé” dé ni ọdun 1914. (Matteu 24:3, 37) Ṣugbọn ki ni wíwàníhìn-ín tabi pa·rou·siʹa Kristi, tumọsi fun aṣẹku ẹni-ami-ororo ti “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa? (Matteu 24:45) Họwu, pe wọn nilati tubọ jẹ́ ẹni ti o jafafa lọna ti ń ga sii gẹgẹ bi olùtan ìmọ́lẹ̀! Awọn ohun agbayanu yoo ṣẹlẹ! Iṣẹ ikojọpọ kan ti a kò tii ri iru rẹ̀ ri ti fẹ́ bẹrẹ.

2. Iru ìfọ̀mọ́ wo ni o ti ṣẹlẹ ni imuṣẹ Malaki 3:1-5?

2 Bi o ti wu ki o ri, lakọọkọ, awọn Kristian ẹni-ami-ororo wọnyi nilo ìfọ̀mọ́. Gẹgẹ bi Malaki 3:1-5 ti sọtẹlẹ, Jehofa Ọlọrun ati “iranṣẹ majẹmu” rẹ̀, Jesu Kristi, wá lati bẹ tẹmpili ti ẹmi wò ni ìgbà iruwe 1918. Idajọ ni o nilati bẹrẹ pẹlu “ile Ọlọrun.” (1 Peteru 4:17) Malaki 3:3 sọ asọtẹlẹ pe: “Oun [Jehofa] óò si jokoo bi ẹni ti ń yọ́, ti o si ń da fadaka: yoo si [wẹ] awọn ọmọ Lefi mọ́, yoo si yọ́ wọn bii wura oun fadaka.” O jẹ́ akoko ìyọ́mọ́ ati ìfọ̀mọ́.

3. Eeṣe ti o fi ṣekoko pe ki ìfọ̀mọ́ nipa tẹmi ṣẹlẹ?

3 Ni lila idajọ yii kọja, eyi ti o dé otente rẹ̀ ni 1918, aṣẹku ẹgbẹ́ ẹrú naa ni a fọ̀mọ́ kuro ninu isọdẹgbin ti ayé ati ti isin. Eeṣe ti Jehofa fi fọ̀ wọn mọ́? Nitori pe o ni tẹmpili tẹmi rẹ̀ ninu. Eyi ni iṣeto ti o dabii tẹmpili fun jijọsin Jehofa lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu Kristi. Jehofa fẹ́ ki tẹmpili rẹ̀ wà ni ipo mimọ ki o baa lè jẹ́ pe nigba ti a bá mú iye awọn olujọsin nla ti wọn ni ireti ti ori ilẹ̀-ayé wá si ibẹ, wọn yoo ri ibikan ti a ti ń bọwọ fun ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀, ibi ti a ti ń ya orukọ atọrunwa rẹ̀ si mimọ, ati ibi ti a ti ń ṣegbọran si awọn ofin òdodo rẹ̀. Nipa bayii, wọn yoo mọriri Jehofa wọn yoo sì darapọ ninu sisọ awọn ète rẹ̀ titobilọla di mímọ̀.

Awọn Afikun Anfaani

4, 5. (a) Bawo ni ibeere kan nipasẹ Jesu Kristi ṣe pe ọkọọkan ninu ẹgbẹ́ ẹrú naa nija lonii? (b) Ni awọn ọ̀nà wo ni a gbọdọ gbà loye awọn ọ̀rọ̀ naa “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” ati “awọn ara-ile rẹ̀”? (c) Àṣẹ wo ni Jesu fifun ẹrú naa?

4 Ni 1919 ẹgbẹ́ ẹrú ti a fọ̀mọ́ naa lè fojusọna fun awọn igbokegbodo ti ń gbooro siwaju ati siwaju sii. Nigba naa ni 1914, Jesu Kristi, Ọ̀gá wọn, ti gba Ijọba ti ọrun. Nigba ti o pada sọdọ awọn oṣiṣẹ agbo ile rẹ̀ lati ṣayẹwo “ile” rẹ̀, oun ni a fi iyi-ọla bii ti ọba ṣeélọ́ṣọ̀ọ́, eyi ti oun kò tii ní nigba ti o wà níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé. Ki ni o rí? Ǹjẹ́ ọwọ́ ẹgbẹ́ ẹrú naa ha dí ni bibojuto ire Ọ̀gá naa bi? Gẹgẹ bi a ṣe ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matteu 24:45-47 (NW), Jesu beere ibeere kan ti o pe ọkọọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ẹni-ami-ororo nija lati ṣayẹwo ifọkansin rẹ̀ si Messia Jehofa: “Ta ni niti gidi ni ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa ẹni ti ọ̀gá rẹ̀ yansipo ṣe olori awọn ara-ile rẹ̀, lati fun wọn ni ounjẹ wọn ni akoko yiyẹ? Alayọ ni ẹrú yẹn bi ọ̀gá rẹ̀ ba ri i ti o ń ṣe bẹẹ nigba ti o bá dé. Loootọ ni mo wi fun yin, Oun yoo yan an sipo ṣe olori gbogbo ohun-ìní rẹ̀.”

5 Lọna ti o ṣe kedere, apejuwe Jesu nipa ẹrú oluṣotitọ yii kò bá eniyan kanṣoṣo eyikeyi mu. Bẹẹkọ, ṣugbọn o ṣapejuwe ijọ awọn ẹni-ami-ororo oluṣotitọ ti Kristi lapapọ, gẹgẹ bi agbo kan. Awọn ara-ile naa ni awọn ọmọlẹhin ẹni-ami-ororo Kristi gẹgẹ bi ẹnikọọkan. Jesu mọ nigba naa pe oun maa tó ra awọn ẹni-ami-ororo wọnyi pẹlu ẹjẹ ounfunra-oun, nitori naa o fi ẹtọ tọka si wọn lapapọ gẹgẹ bi ẹrú rẹ̀. Korinti Kìn-ín-ní 7:23 sọ nipa wọn pe: “A ti rà yin [ni sisọrọ wọn lapapọ] ni iye kan; ẹ maṣe di ẹrú eniyan.” Jesu fi aṣẹ fun ẹgbẹ́ ẹrú rẹ̀ lati jẹ́ ki ìmọ́lẹ̀ wọn tan lati fa awọn eniyan mọra ki wọn sì kó awọn ọmọ-ẹhin miiran jọ ati lati bọ́ awọn ara-ile rẹ̀ lọna ti ń tẹsiwaju nipa fifun wọn ni ounjẹ tẹmi wọn ni akoko yiyẹ.

6. Bawo ni a ṣe san èrè fun ẹrú naa gẹgẹ bi abajade ibẹwo Jesu?

6 Lati ìgbà ti wíwàníhìn-ín Kristi ti bẹrẹ ati titi de 1918, ẹgbẹ́ ẹrú naa, laika ailokiki, inunibini, ati paapaa idarudapọ melookan si, ti ń wá ọ̀nà lati fun awọn ara-ile naa ni ounjẹ ti o bọ́sákòókò. Eyi ni ohun ti Ọ̀gá naa ri ni nigba ti ibẹwo rẹ̀ bẹrẹ. Inu Oluwa Jesu dùn, nigba ti o si di 1919 o kede ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ ti a tẹwọgba naa ni alayọ. Ki ni èrè amunilayọ ti o jẹ́ ti ẹrú naa fun ṣiṣe ohun ti Ọ̀gá rẹ̀ ti yàn án lati ṣe? Igbega! Bẹẹni, awọn ẹrù-iṣẹ́ ti o tubọ pọ̀ sii ni a gbé lé e lọwọ ni mimu ire Ọ̀gá rẹ̀ tẹsiwaju. Niwọn bi Ọ̀gá naa ti jẹ́ Ọba ti ọrun nisinsinyi, họwu, nigba naa, awọn ohun-ìní rẹ̀ ti ilẹ̀-ayé di eyi ti o tubọ ṣeyebiye sii.

7, 8. (a) Ki ni “gbogbo ohun-ìní” Ọ̀gá naa? (b) Ki ni ohun ti a beere lọwọ ẹrú naa ni ṣiṣabojuto awọn ohun-ìní wọnyi?

7 Nitori naa, ki ni “gbogbo ohun-ìní rẹ̀”? Iwọnyi ni awọn ọrọ-ìní tẹmi lori ilẹ̀-ayé ti wọn ti di ohun-ìní Kristi ni ibatan pẹlu ọla-aṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba ti ọrun. Dajudaju eyi ní ọla-aṣẹ ti sisọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin Kristi ninu, pẹlu anfaani titobilọla ti ṣiṣiṣẹ gẹgẹ bi aṣoju Ijọba Ọlọrun ti a gbekalẹ fun gbogbo orilẹ-ede ayé.

8 Iru igbega kan bẹẹ sipo abojuto gbogbo ohun-ìní Ọ̀gá naa beere pe ki ẹgbẹ́ ẹrú naa fi akoko ati afiyesi ti o tubọ pọ̀ sii fun ṣiṣe iṣẹ Ijọba naa ati, bẹẹni, ki wọn mú ohun-eelo ti o tubọ pọ̀ sii dagba fun iṣẹ naa. O eś ní papa iṣẹ ti o tubọ tobi sii lọpọlọpọ nisinsinyi—gbogbo orilẹ-ede ayé ti awọn eniyan ń gbé.

Kíkó Awọn Agutan Jọ

9. Ki ni o ti jẹ́ abajade igbooro siwaju sii awọn igbokegbodo ẹrú naa?

9 Tìgbọràn-tìgbọràn, nigba naa, ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ti Kristi mú awọn igbokegbodo rẹ̀ gbooro sii. Ki ni abajade rẹ̀? Awọn ti o gbẹhin ninu awọn 144,000 ẹni-ami-ororo ni a kojọ. Nigba naa ni iran Johannu gẹgẹ bi a ṣe ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Ìfihàn 7:9-17 wá di otitọ gidi ti ń runisoke, ti ń mu ọkàn layọ. Ni pataki julọ lati 1935 ni ẹgbẹ́ ẹrú naa ti gbadun ṣíṣẹlẹ́rìí iṣipaya imuṣẹ iran yii ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Kaakiri gbogbo ilẹ̀-ayé, “ogunlọgọ nla” ti awọn araadọta-ọkẹ ń korajọ si ayika tẹmpili tẹmi Jehofa nisinsinyi gẹgẹ bi olujọsin rẹ̀. Angẹli Jehofa sọ fun Johannu pe kò si eniyan ti o lè ka iye ogunlọgọ nla yii. Iyẹn tumọsi pe kò si ààlà ti a fi si iye eniyan ti ẹgbẹ́ ẹrú naa yoo mu wa sinu tẹmpili tẹmi Jehofa. Niwọn ìgbà ti ọ̀nà bá ṣì ṣí silẹ, iṣẹ kiko wọn jọ yoo maa baa lọ.

10. Igbokegbodo onifẹẹ wo ni ẹrú naa ń lọwọ ninu rẹ̀ lonii?

10 Ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ naa ní ẹrù-iṣẹ́ wiwuwo ni bibojuto iye awọn “agutan miiran” ti iye wọn ń roke sii lemọlemọ, ni mímọ̀ pe awọn ẹni-bi-agutan wọnyi lati inu gbogbo orilẹ-ede jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n gidigidi fun Ọ̀gá naa, Jesu. Wọn jẹ́ agbo rẹ̀ niti gidi. (Johannu 10:16; Iṣe 20:28; 1 Peteru 5:2-4) Nitori naa pẹlu ifẹ fun Ọ̀gá naa ati fun awọn agutan, ẹgbẹ́ ẹrú naa ń fi tayọtayọ bojuto awọn aini tẹmi ti awọn ogunlọgọ nla naa.

11-13. Alaye ṣiṣewẹku wo ni ààrẹ Watch Tower Society ìgbà naa ṣe nipa igbokegbodo ẹrú naa?

11 Bẹẹni, apa ti o ga ju ninu ọla-aṣẹ ìmọ́lẹ̀ títàn awọn ẹrú naa ní ninu ṣiṣakojọ awọn ọmọ-abẹ Ijọba Ọlọrun ti wọn wà lori ilẹ̀-ayé wọnyi. Ni jijiroro lori igbokegbodo ẹrú oluṣotitọ naa ti ń tẹsiwaju sii, F. W. Franz, ti o jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nigba naa, sọ ni kété ṣaaju iku rẹ̀ ni December 1992 pe:

12 “Jesu Kristi ti lo eto-ajọ naa lọna agbayanu siwaju ati siwaju sii ni gbogbo ìgbà, ni ibamu pẹlu iriri igbesi-aye mi fun ọdun 99. Kìí ṣe eniyan lasan kan ni ń dari eto-ajọ naa, ṣugbọn o gbọdọ jẹ́ Oluwa Jesu Kristi. Nitori pe o ti yọrisi rere lọna titobilọla gan-an ati lọna agbayanu ju bi a ti rò pe o yẹ ki o jẹ́. Lonii a ni eto-ajọ kan ti o ti gbooro kaakiri agbaye. O ń ṣiṣẹ ni Ariwa apa Ilaji Ilẹ̀-ayé ati ni Guusu apa Ilaji Ilẹ̀-ayé, ni Ila-oorun ati ni Iwọ-oorun. Kiki ẹnikanṣoṣo ni o ti lè mú ẹrù-iṣẹ́ fun igbooro siwaju sii ti o pẹtẹri yii wàyé—Ọmọkùnrin Ọlọrun, ẹni ti ń ṣe abojuto ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa. O ti ń dójú-ìlà awọn ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀, eyi si ni okunfa fun igbooro siwaju sii titobilọla ti a ti ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ naa.

13 “Ọ̀ràn naa kò mọ sọwọ eniyan kan. A ni eto-ajọ kan ti o jẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun, o si ń ṣiṣẹ ni ọ̀nà ti iṣakoso Ọlọrun, ni ọ̀nà kan ti Ọlọrun ń dari. Kò si eniyan kan, kìí tilẹ ṣe oludasilẹ Watch Tower Bible and Tract Society paapaa, ti o lè jẹwọ tabi jẹ́ ẹni ti a kasi okunfa aṣeyọrisirere eru-iṣẹ fun ohun ti a ti ṣaṣepari rẹ̀ ni ọ̀nà kan ti o ni gbogbo ilẹ̀-ayé ninu. O wulẹ jẹ ohun iyanu ṣaa ni.” Ǹjẹ́ gbogbo awọn ti wọn jẹ́ ara ogunlọgọ nla kò ha wà ni ifohunṣọkan tinutinu pẹlu ero oloogbe Arakunrin Franz yẹn bi? Bẹẹni, nitootọ, awọn ni wọn kun fun imọriri julọ fun awọn igbokegbodo ẹrú oluṣotitọ ti a ti mu gbooro siwaju sii.

Awọn Ọmọ-Abẹ Ijọba Naa

14, 15. (a) Ki ni Jesu ṣakawe ninu owe talẹnti (Matteu 25:14-30)? (b) Lọna ti o baamu, ki ni ohun ti o tẹlee ninu Matteu ori 25?

14 Ninu Matteu ori 25, akawe Jesu nipa awọn agutan ati ewurẹ ṣapejuwe iṣẹ nla ti kíko awọn ọmọ-abẹ Ijọba Ọlọrun ni ori ilẹ̀-ayé jọ yii. Ninu owe ti o ṣaaju rẹ̀, ti talẹnti, Jesu ṣakawe pe awọn ọmọ-ẹhin ẹni-ami-ororo ti wọn nireti lati ṣakoso pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba rẹ̀ ti ọrun gbọdọ ṣiṣẹ lati mú ki awọn ohun-ìní rẹ̀ ti ori ilẹ̀-ayé pọ̀ sii. Lọna ti o baa mu gẹẹ, nigba naa, ninu owe ti o tẹlee, Jesu gbe akawe alaworan kalẹ nipa ohun ti a beere lọwọ awọn wọnni ti wọn fẹ́ lati di ọmọ-abẹ Ijọba rẹ̀ ti ọrun.

15 Ṣakiyesi awọn ọrọ-akiyesi rẹ̀ ninu Matteu 25:31-33 pe: “Nigba ti Ọmọ eniyan yoo wá ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ pẹlu rẹ̀, nigba naa ni yoo jokoo lori ìtẹ́ ògo rẹ̀: niwaju rẹ̀ ni a o sì kó gbogbo orilẹ-ede jọ: yoo sì yà wọn si ọ̀tọ̀ kuro ninu araawọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti i ya agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: oun o sì fi agutan si ọwọ ọtun rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsì.”

16. Bawo ni a ṣe ń kó awọn orilẹ-ede jọ ti a si ń ya awọn eniyan sọtọọtọ?

16 Jesu dé ninu ògo rẹ̀ ni 1914. Ni bibẹrẹ igbesẹ naa, oun, pẹlu gbogbo awọn angẹli rẹ̀, doju ija kọ awọn ẹmi-eṣu ti wọn jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ wọn si lé wọn kuro ni ọrun. Ohun ti o tẹlee kete ninu owe rẹ̀ ràn wá lọwọ lati mọriri pe jijokoo ti Jesu jokoo lori ìtẹ́ ológo ń ṣoju fun ipo idajọ nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀. Ikojọpọ gbogbo orilẹ-ede niwaju rẹ̀ tumọsi pe Jesu ń ṣiṣẹ fun awọn orilẹ-ede gẹgẹ bi agbo rẹ̀ ọjọ-ọla, ni ede-isọrọ iṣapẹẹrẹ. O jẹ́ agbo kan ti o ni awọn agutan ati awọn ewurẹ ninu. Nigba ti o lè gba apakan akoko ninu ọjọ kan lati ya awọn agutan lara awọn ewurẹ ninu agbo gidi kan, iyasọtọ awọn eniyan ti wọn lominira lati yàn laaarin rere ati buburu kaakiri agbaye gba akoko ti o ju bẹẹ lọ. Eyi jẹ́ nitori pe iyasọtọ naa ni a gbekari ipa-ọna iwa eniyan lẹnikọọkan.

17. Eeṣe ti ipo-ọran lonii fi ni jẹpataki ti o jinlẹ fun gbogbo eniyan?

17 Ninu owe naa, Ọba-Oluṣọ-Agutan naa fi awọn ẹni-bi-aguntan si apa ọ̀tún rẹ̀ ati awọn ẹni-bi-ewurẹ si apa òsì rẹ̀. Apa ọ̀tún naa wá jásí idajọ ti o ní abajade titẹnilọrun—ìyè ayeraye. Apa òsì duro fun idajọ ti kò tẹnilọrun—iyẹn ni ti iparun ayeraye. Ipinnu Ọba naa nipa ọ̀ràn naa ní awọn abajade ti o rinlẹ niti ijẹpataki.

18. Eeṣe ti aiṣeefojuri Ọba naa kò fi dá ẹnikẹni si?

18 Aiṣeefojuri Ọmọkunrin eniyan ti ń ṣakoso naa nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀, tabi pa·rou·siʹa, kò da ẹnikẹni si. Pupọpupọ sii awọn ẹni-bi-agutan lonii ń darapọ mọ ẹgbẹ́ ẹrú naa ninu wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun kari ayé, ni jíjẹ́ ki ìmọ́lẹ̀ wọn tan. Loootọ, ijẹ́rìí wọn ti de igun agbaala ayé jijinna réré.—Matteu 24:14.

19. Awọn animọ ẹgbẹ́ agutan wo ni a ṣakawe ninu owe awọn agutan ati ewurẹ?

19 Eeṣe ti Ọba-Oluṣọ-Agutan naa ṣe fi ọjọ-ọla onibukun san èrè fun awọn ẹgbẹ́ agutan? Nitori itilẹhin iṣẹ iwaasu Ijọba afitọkantọkanṣe wọn ati inuure tí wọn fihàn si awọn arakunrin rẹ̀ ẹni-ami-ororo, eyi ti Jesu kasi pe a ṣe si oun fúnraarẹ̀. Nipa bayi, Ọmọkùnrin eniyan ti o jẹ́ ọba sọ fun wọn pe: “Ẹ wá, ẹyin alabukun fun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.”—Matteu 25:34; 28:19, 20.

Ríran Ọba Naa Lọwọ

20, 21. Ẹri wo ni awọn agutan fifunni pe wọn duro ni iha Ijọba naa?

20 Ṣakiyesi pe nigba ti Ọba kesi awọn agutan wọnyi lati jogun ilẹ-ọba Ijọba Ọlọrun ti ori ilẹ̀-ayé, wọn fi iyalẹnu hàn. Wọn beere lọwọ rẹ̀ pe: ‘Oluwa, nigba wo ni a ṣe nǹkan wọnyi fun ọ?’ O fesi pada pe: “Loootọ ni mo wi fun yin, niwọn bi ẹyin ti ṣe é fun ọ̀kan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹyin ti ṣe é fun mi.” (Matteu 25:40) Nigba ti Jesu farahan fun Maria Magdalene ni ọjọ ajinde rẹ̀, o sọrọ nipa awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi nigba ti o sọ fun un pe: “Ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi.” (Johannu 20:17) Nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀ laiṣeefojuri, Jesu ní kiki aṣẹku kekere ti 144,000 awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi ti wọn ṣì walaaye lori ilẹ̀-ayé

21 Niwọn bi Jesu ti jẹ́ alaiṣeefojuri ninu awọn ọrun, kiki lọna kan ti kò ṣe taarata ni awọn eniyan ẹni-bi-agutan ṣe awọn ohun onifẹẹ wọnni si i. Wọn ri i lori ìtẹ́ rẹ̀ kiki pẹlu oju igbagbọ wọn. Jesu mọriri gbogbo isapa ti wọn ṣe lati ran awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi lọwọ, awọn ti yoo di ajumọjogun rẹ̀ ti ọrun. Ohun ti a ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀ ni o kàsí pe a ṣe fun oun fúnraarẹ̀. Awọn ẹni-bi-aguntan naa mọọmọ ṣe rere fun awọn arakunrin Kristi nitori pe wọn dá wọn mọ̀ yatọ pe bẹẹ ni wọn rí. Wọn mọriri pe awọn arakunrin tẹmi Jesu ni aṣoju Ijọba Jehofa, wọn si fẹ́ lati funni ni ẹ̀rí ti o daju pe awọn ń mu ipo awọn pẹlu wọn niha Ijọba yẹn.

22. Bawo ni a ṣe san èrè fun ẹgbẹ́ awọn agutan? (Fiwe Ìfihàn 7:14-17.)

22 Jehofa rii tẹlẹ pe ẹgbẹ́ awọn ẹni-bi-agutan yii yoo farahan nigba wíwàníhìn-ín Ọmọkunrin rẹ̀, o sì ní èrè agbayanu ni ipamọ fun wọn! Awọn ogunlọgọ nla yoo jogun awọn ibukun alaafia níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé nigba Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun alayọ lati ọwọ Ọba Jehofa, Jesu Kristi.

23. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn agutan gbà mọ̀ọ́mọ̀ ran awọn arakunrin Ọba naa lọwọ?

23 Nigba ti a bá ṣayẹwo awọn asọtẹlẹ Bibeli ti o ni ifisilo ni akoko wíwàníhìn-ín Kristi, pẹlu akawe Jesu nipa awọn agutan ati awọn ewurẹ, ki ni ohun ti a ri? Eyi: Kìí ṣe ọ̀ràn àìmọ̀ tabi ṣiṣeeṣi ṣe rere fun ọ̀kan ninu awọn arakunrin tẹmi Ọba naa ni ń sọ ẹnikan di agutan pẹlu iduro òdodo niwaju Ọlọrun ati Ọba rẹ̀. Awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti ẹgbẹ́ agutan mọ ohun ti wọn ń ṣe, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò ri Ọba ti ń ṣakoso naa pẹlu ojúyòójú wọn. Wọn ń sakun lati ran awọn arakunrin Ọba naa lọwọ kìí ṣe kiki ni ọ̀nà ti ara nikan ṣugbọn pẹlu ni ọ̀nà ti ẹmi. Bawo? Nipa ṣiṣeranwọ fun wọn ninu iwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun ati nipa ṣiṣe awọn ikẹkọọ Bibeli ki wọn baa lè sọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin fun Kristi. Nipa bayii, lonii iye ti o lé ní million mẹrin awọn olupokiki Ijọba Ọlọrun ti ń tan ìmọ́lẹ̀ ni ń bẹ.

Awọn Igbokegbodo Ti A Mu Gbooro Sii

24. Awọn iṣẹ aṣekara onifẹẹ wo ni o mu ki ẹgbẹ́ ẹrú naa di eniyan alayọ julọ lori ilẹ̀-ayé lonii?

24 Ẹ jẹ́ ki a ṣayẹwo diẹ ninu awọn iṣẹ rere tí ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ naa. Ekinni, ẹgbẹ́ ẹrú naa ni a ti yàn lori awọn ohun-ìní Ọ̀gá naa—anfaani-ire Ijọba rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé—ati awọn ohun-ìní wọnyi si ń baa lọ lati maa pọ̀ sii. Ẹẹkeji, ẹgbẹ́ yẹn ń fi ounjẹ tẹmi bọ́ kìí ṣe kiki awọn ara-ile ẹni-ami-ororo nikan ṣugbọn ogunlọgọ nla awọn agutan miiran ti ń gbooro sii laisọsẹ. Ẹẹkẹta, ẹgbẹ́ ẹrú naa ń mú ipo iwaju ninu títan ìmọ́lẹ̀ Ijọba kalẹ. Ẹẹkẹrin, igbooro siwaju sii igbokegbodo giga julọ rẹ̀ wa ninu ikojọpọ ogunlọgọ nla awọn agutan miiran, ni mimu wọn wa si tẹmpili tẹmi ti Jehofa. Ẹẹkarun-un, ẹgbẹ́ ẹrú naa, pẹlu itilẹhin afitọkantọkanṣe awọn ti ẹni-bi-agutan, ń pese awọn ile-lilo ti a mu tobi sii fun iṣetojọ awọn ẹka kaakiri agbaye, ati bakan naa ni awọn orile-iṣẹ ni United States. Iru iṣẹ aṣekara onifẹẹ bẹẹ ti sọ ẹgbẹ́ ẹrú naa di awọn eniyan ti wọn layọ julọ lori ilẹ̀-ayé lonii, wọn sì ti sọ ọpọ million eniyan miiran di alayọ pẹlu. Gbogbo awọn wọnyi fi ọpẹ́ fun Jehofa Ọlọrun ati fun Jesu Kristi, ẹni ti o ti dari awọn igbokegbodo ẹrú ọlọgbọn-inu ti ń gbooro siwaju sii naa!

25. Bawo ni awọn agutan ṣe le maa baa lọ lati ti ẹgbẹ́ ẹrú naa lẹhin, pẹlu ifojusọna wo ni ọjọ iwaju?

25 Ẹgbẹ́ ẹrú naa tubọ ń ṣiṣẹ karakara ju ti igbakigba ri lọ nisinsinyi nibi awọn ojuṣe ti Ọlọrun yàn fun un. Akoko ti o ṣẹku ṣaaju ibẹsilẹ “ipọnju nla” ti fẹrẹẹ tán! (Matteu 24:21) Ẹ wo bi o ti ṣe koko tó pe ki awọn wọnyi ti wọn jẹ́ agutan Ọlọrun duro ni apa ọtun ojurere Ọba-Oluṣọ-Agutan rẹ̀! Nitori naa, nigba naa, ẹ jẹ ki gbogbo wa maa baa lọ pẹlu ìtara lati ti ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa lẹhin. O jẹ kiki nipa ṣiṣe eyi ni o fi lè jẹ́ pe lọjọ kan laipẹ gbogbo awọn ẹni-bi-aguntan yoo lè gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ alayọ wọnyẹn pe: “Ẹ wa, ẹyin alabukunfun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.”

Iwo Ha Lè Dahun Bi?

◻ Idajọ akọkọṣe wo ni o tẹle ìgbégoríìtẹ́ Ọba naa?

◻ Bawo ni Matteu 24:45-47 ṣe ni imuṣẹ ode-oni kan?

◻ Niti awọn igbokegbodo ti a mu gbooro sii, fun ki ni ẹgbẹ́ ẹrú naa ati ogunlọgọ nla kun fun imọriri julọ?

◻ Bawo ni Matteu 25:34-40 ṣe ni imuṣẹ nigba pa·rou·siʹa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀gá naa fi gbogbo ohun-ìní rẹ̀ lé ẹrú oluṣotitọ naa lọwọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jesu ti gun ori ìtẹ́ ògo rẹ̀ lati ṣedajọ araye

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́