Eeṣe Ti O Fi Nilati Ṣiṣẹsin Jehofa?
“ỌJỌ Jehofa ti sunmọle! ‘ipọnju nla’ ti sunmọle, iwọ kì yoo sì laaja bi o kò bá ṣiṣẹsin Ọlọrun.” Bi ẹnikan bá sọ iyẹn fun ọ, bawo ni iwọ yoo ṣe huwapada?—Sefaniah 2:2, 3; Matteu 24:21.
Lotiitọ, a gbọdọ fi ọjọ Jehofa sọkan, lila ipọnju nla naa ti o rọdẹdẹ já sì sinmi lori iṣẹ-isin olóòótọ́ si Ọlọrun. Ṣugbọn ǹjẹ́ awọn otitọ wọnyi ha gbọdọ jẹ olori ète ti a fi ń ṣiṣẹ isin mimọ ọlọ́wọ̀ si Jehofa Ọlọrun bi? Eeṣe ti iwọ fi ń ṣiṣẹsin Jehofa?
Aini fun Isunniṣe Titọna
Bi ẹnikan kò bá fi isunniṣe ti o tọna ṣiṣẹsin Ọlọrun, oun lè ṣíwọ́ bi awọn ifojusọna rẹ̀ kò bá ni imuṣẹ laaarin akoko pato kan. Fun apẹẹrẹ, awọn eniyan kan ṣereti pe ki Jesu Kristi padawa ni 1843 tabi 1844, awọn ọjọ ti o kọja lọ laisi imuṣẹ awọn ireti wọn. Eyi ti o fanilọkanmọra ní ọ̀nà yii ni ohun ti George Storrs, onṣewe Bible Examiner ti o wá di ojulumọ Charles Taze Russell, aarẹ akọkọ Watch Tower Society lẹhin naa sọ. Ninu Bible Examiner ti September 1846, Storrs kọwe pe:
“Ẹrù-iṣẹ́ naa lati ṣiṣẹsin Ọlọrun ga gan an ju kìkì otitọ naa pe ọjọ naa ti fẹrẹẹ lọ tan. . . . Ihuwapada ti yoo wáyé bi ọdun 1846 ati 1847 bá kọjalọ bi wọn ti lè ṣe, laifojuri ipadabọ ẹlẹẹkeji naa, yoo jẹ elewu rekọja ohunkohun ti o ṣeé fi òye gbé. Iriri fi eyi hàn—iriri 1843 ati 1844 ni mo nílọ́kàn. Nibo ni awọn ẹni pupọ wọnyẹn, awọn ti wọn jẹwọ pe, ‘a ru awọn soke lati ṣiṣẹsin Ọlọrun’ gẹgẹ bi o ti yẹ fun wọn nipa ipolongo naa pe o ti tó akoko fun dídé Oluwa wà nisinsinyi? Mo sì tun wi pe—NIBO!!! Ekukaka ni a fi lè rí ọ̀kan ninu mẹwaa wọn ti ń rin ninu igbagbọ sibẹ lati lè bọla fun ijẹwọ jíjẹ́ Kristian wọn. Eeṣe ti ko fi ri bẹẹ? A ru wọn soke nipa awọn isunniṣe ti kò tọna. Imọtara-ẹni-nikan wọn ni olori ohun ti a fọranlọ ti a sì ru soke. Wọn wulẹ dabii ẹlẹṣẹ naa ti o ronu pe oun ti sunmọ bèbè iku lori ibusun aisan tabi ninu ìjì lori òkun. Bi oun ba gbọdọ kú, oun yoo di Kristian. Bi o ba mọ̀ pe oun ti bọ lọwọ jamba, yoo dagunla bi o ti ṣe jẹ́ tẹlẹ.”
Fifi Isunniṣe Titọna Ṣiṣiṣẹsin
Imọtara-ẹni nikan ati ibẹru iparun lè sún awọn kan lati ṣaibikita niti ṣiṣe ifẹ-inu Jehofa. Awọn miiran ni ireti iwalaaye ninu Paradise ti lè gba afiyesi wọn debi pe wọn yoo ṣiṣẹsin Ọlọrun kìkì fun ète yẹn. Sibẹ, bi awọn eniyan ti a sún ni pataki nipa iru isunniṣe bẹẹ bá ronu pe ọjọ Jehofa ati ipọnju nla kò fi bẹẹ sunmọle, wọn lè má ni itẹsi lati fi itara ṣiṣẹsin Ọlọrun.
Niti tootọ, kìí ṣe imọtara-ẹni nikan lati yọ̀ ninu awọn ileri ati ibukun Ọlọrun ti a sọtẹlẹ. Oun ń fẹ́ ki a layọ nipa awọn ireti ti a gbeka iwaju wa bi awọn ọmọ-ẹhin Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi. “Ẹ yọ̀ ninu ireti,” ni aposteli Paulu wi, ni fifi kun un pe: “Ẹ farada labẹ ipọnju. Ẹ foriti ninu adura.” (Romu 12:12, NW) Papọ pẹlu adura, “ayọ Oluwa” ń ràn wa lọwọ lati foriti awọn idanwo ki a sì fi suuru duro de imuṣẹ awọn ileri Ọlọrun. (Nehemiah 8:10) Nipa bayii, a ni ọpọlọpọ ìdí lati ṣiṣẹsin Jehofa. Ki ni diẹ ninu iwọnyi?
Ojúṣe ati Anfaani
Gẹgẹ bi Ọba Alaṣẹ-agbaye, Jehofa yẹ fun o sì ń fi dandan beere fun ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé. (Eksodu 20:4, 5) Nitori naa Kristian kọọkan ni iye iwọn aigbọdọmaṣe kan-naa si Ọlọrun boya ipọnju nla naa bẹrẹ ni ọ̀la, ọdun ti ń bọ̀, tabi ni akoko ti o wà niwaju. Oun wà labẹ aigbọdọmaṣe lati ṣiṣẹsin Jehofa laisi imọtara-ẹni-nikan nitori ninifẹẹ Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkanaya, ọkàn, ero-inu, ati okun rẹ̀. (Marku 12:30) Awọn Kristian akọkọbẹrẹ kan lero pe ọjọ Jehofa ti sunmọle, ṣugbọn awọn ireti wọn kò tii ṣẹ, wọn sì kú lairi iṣẹlẹ yẹn. (1 Tessalonika 5:1-5; 2 Tessalonika 2:1-5) Bi o ti wu ki o ri, bi wọn bá ṣe olóòótọ́ de oju iku, awọn ẹni-àmì-òróró ọmọlẹhin Kristi wọnni yoo gba èrè ajinde si iwalaaye ti ọrun ni asẹhinwa-asẹhinbọ.—Ìfihàn 2:10.
Awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa ti a ti baptisi gbọdọ fi iṣotitọ ṣiṣẹsin in nitori pe wọn ti fínnúfíndọ̀ gba iṣẹ-aigbọdọmaṣe naa lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀. Ṣa rò ó wò na! Bi awọn angẹli mimọ, awa lè ṣe ifẹ-inu Ọba-Alaṣẹ Agbaye naa. (Orin Dafidi 103:20, 21) Jesu gbé iru ẹrù-iṣẹ́ bẹẹ larugẹ debi ti oun fi wi pe: “Ounjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹni ti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.” (Johannu 4:34) Bi awa bá ni iru ẹmi kan-naa, awa yoo fi itara polongo iyin Jehofa a o si sọ fun awọn miiran nipa awọn ète rẹ̀, bi a ti ṣipaya wọn ninu Iwe Mimọ. Ní ọ̀nà yii, a tun ni anfaani lati ran awọn ẹlomiran lọwọ nipa tẹmi. Dajudaju, ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun lati inu ifẹ fun un jẹ́ anfaani agbayanu, laika ìgbà ti ọjọ Jehofa bẹrẹ sí.
Imoore Ń Pese Isunniṣe
Imoore fun ifẹ Ọlọrun niti pipese ẹbọ irapada Ọmọkunrin rẹ̀ tún gbọdọ sun wa lati ṣiṣẹsin Jehofa. Ní akoko kan a jẹ́ ajeji si Jehofa Ọlọrun nitori ẹ̀ṣẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, Jesu wi pe: “Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o lè ni ìyè ainipẹkun.” (Johannu 3:16) Jehofa lo idanuṣe ni ọ̀nà yii, gẹgẹ bi Paulu ti kọwe pe: “Ọlọrun fi ifẹ Oun paapaa si wa hàn ni eyi pe, nigba ti awa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fun wa.” (Romu 5:8) Imoore fun ìfihànjáde ifẹ Ọlọrun yii gbọdọ sún wa lati ṣiṣẹsin in tọkantọkan.
Imọriri fun awọn ipese Jehofa nipa ti ara ati tẹmi fun wa ni ìdí siwaju sii lati fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin in. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ amọ̀nà ti o daju—ìmọ́lẹ̀ si ipa-ọna wa. Awọn itẹjade ti a ń pese nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ń ràn wa lọwọ lati mú iwalaaye wa ṣọkan pẹlu ifẹ-inu atọrunwa. (Matteu 24:45-47; Orin Dafidi 119:105) Nitori pe awa si kọkọ ń wa Ijọba naa, Jehofa ń pese fun wa nipa ti ara. (Matteu 6:25-34) Iwọ ha ń fi imọriri rẹ hàn fun awọn nǹkan wọnyi bi?
Imoore fun ominira ti Ọlọrun fifunni kuro ninu isin èké funni ni ìdí miiran lati fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa. Aṣẹwo onisin naa Babiloni Nla “jokoo lori omi pupọ,” eyi ti o tumọsi “awọn eniyan ati ẹ̀yà ati orilẹ ati oniruuru èdè.” (Ìfihàn 17:1, 15) Sibẹ, oun kò jokoo lori awọn iranṣẹ Jehofa, ni nini ipa lori ati ṣiṣakoso wọn niti ijọsin. Fun apẹẹrẹ, wọn kọ ẹkọ isin èké naa pe ọkàn eniyan jẹ́ alaileeku. Wọn mọ̀ pe a dá eniyan ni “alaaye ọkàn,” pe awọn oku “kò mọ ohun kan,” ati pe ajinde kan yoo wà. (Genesisi 2:7; Oniwasu 9:5, 10; Iṣe 24:15) Nitori naa wọn kò bẹru bẹẹ ni wọn kò jọsin awọn òkú. Imoore fun iru ominira isin bẹẹ ha mú ki o dènà ipẹhinda ki o si rọ̀ mọ́ ijọsin Jehofa mimọgaara bi?—Johannu 8:32.
Imọriri fun itilẹhin Jehofa lojoojumọ nilati fikun ipinnu wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin in. Olorin naa Dafidi polongo pe: “Ibukun ni fun Jehofa, ẹni ti ń ru ẹrù wa lojoojumọ.” (Orin Dafidi 68:19, NW) Ní ibomiran olórin naa wi pe: “Nigba ti baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigba naa ni Oluwa yoo tẹwọgba mi.” (Orin Dafidi 27:10) Bẹẹni, ẹnikan ti ń fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa lè kó ajaga ifiṣapẹẹrẹ rẹ̀, iru bii àròdùn ati adanwo, lọ sara Ọlọrun. Iwọ ha ń fi imọriri hàn fun itilẹhin alaiyẹsẹ Jehofa nipa fifi òdodo ṣiṣẹsin in bi?—Orin Dafidi 145:14.
Kókìkí Jehofa ati Ipò-Ọba Rẹ̀
Ìfẹ́-ọkàn kan lati fi ògo fun Jehofa tun nilati sun wa lati ṣiṣẹsin in. Awọn ẹ̀dá ọrun ni a fihàn gẹgẹ bi ẹni ti ń fi ògo fun Ọlọrun pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Oluwa, iwọ ni o yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbara: nitori pe iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni wọn fi wà ti a si dá wọn.” (Ìfihàn 4:11) Ọba Dafidi kókìkí Ọlọrun nipa sisọ pe: “Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ògo, ati iṣẹgun, ati ọla-nla . . . ijọba ni tirẹ, Oluwa . . . Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọ̀dọ̀ rẹ ní tii wá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo . . . Ǹjẹ́ nisinsinyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yin orukọ ògo rẹ.” (1 Kronika 29:10-13) Gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa, awa ha gbọdọ ṣe ohun tí ó dinku si fifi ògo fun un ninu ọ̀rọ̀ ati ni iṣe bi a ti ń duro de awọn ileri rẹ̀ bi?—1 Korinti 10:31.
Ìsúnniṣe lilagbara kan lati sọrọ nipa Ijọba Ọlọrun funni ni iṣiri miiran sibẹ lati ṣiṣẹsin Jehofa. Isunniṣe pipeye yẹn ni a sọ jade daradara ninu ọ̀rọ̀ olorin naa pe: “Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yoo maa yìn ọ; awọn eniyan mimọ rẹ yoo sì maa fi ibukun fun ọ. Wọn o maa sọrọ ògo ijọba rẹ, wọn ó sì maa sọrọ agbara rẹ: Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mímọ̀ fun awọn ọmọ eniyan, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo, ijọba rẹ ijọba ayeraye ni, ati ijọba rẹ lati irandiran gbogbo.” (Orin Dafidi 145:10-13) Pipolongo ihin-iṣẹ Ijọba naa jẹ́ iṣẹ-ayanfunni Kristian ati iṣẹ ti o ṣe pataki julọ ti a ń ṣe ni ọjọ wa. (Matteu 24:14; 28:19, 20) Iwọ ha ni ọkàn-ìfẹ́ ti a mu gbona lati yin Jehofa ati lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Ijọba rẹ̀ bi?
Ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa ati idalare ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ gbọdọ jẹ́ eyi ti o ṣe pataki si wa tobẹẹ ti a fi nilati fẹ́ lati fi iṣotitọ ṣiṣẹsin in. A lè gbadura fun ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa ati fun idalare ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀. (Matteu 6:9) A lè huwa ni ibamu pẹlu awọn adura wa nipa lilọwọ deedee ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian ati nipa títan otitọ kalẹ nipa iru awọn ọ̀ràn oníjẹ̀ẹ́pataki gidi bẹẹ.—Esekieli 36:23; 39:7.
Ayọ ati Itẹlọrun
Nipa fifi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin Jehofa, a ni itẹlọrun ti mimu ọkan-aya rẹ̀ yọ̀ ati fifi Eṣu hàn bi opurọ. Bi o tilẹ jẹ pe Satani tẹpẹlẹ mọ́ ọn pe awọn eniyan ń ṣiṣẹsin Ọlọrun fun ète onimọtara-ẹni-nikan, iṣẹ-isin oniduroṣiṣin wa ti a ń fi ifẹ ṣe fun Jehofa, fi itẹnumọ apẹgan yẹn hàn pe ó jẹ́ èké. (Jobu 1:8-12) Eyi fun wa ni ìdí rere lati maa baa lọ ni ṣiṣe ohun ti a sọ ninu Owe 27:11 pe: “Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn. ki emi ki o lè dá ẹni ti ń gàn mi lohun.” Siwaju sii, nigba ti a bá fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin Jehofa laika gbogbo ohun ti Satani ń ṣe lati dí wa lọwọ si, ipa-ọna ipawatitọ mọ́ wa ṣeeṣe ki o fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa lokun.—Filippi 1:12-14.
Ayọ ati itẹlọrun ti ninipin in ninu ikore tẹmi tun gbọdọ sún wa lati fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin Jehofa. Jesu ri ayọ̀ ninu riran awọn eniyan lọwọ, ni pataki ni awọn ọ̀nà ti ẹmi. Matteu 9:35-38 wi pe: “Jesu sì rìn si gbogbo ilu-nla ati ileto, o ń kọni ninu sinagogu wọn, o sì ń waasu ihinrere ijọba, o sì ń ṣe iwosan arun ati gbogbo aisan ni ara awọn eniyan. Ṣugbọn nigba ti o ri ọpọ eniyan, aanu wọn ṣe e, nitori ti aarẹ mu wọn, wọn sì tukaakiri bi awọn agutan ti ko ni oluṣọ. Nigba naa ni o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Loootọ ni ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe kò tó nǹkan; Nitori naa ẹ gbadura si Oluwa ikore ki o lè rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.” Bi iṣẹ ikore naa bá pẹ́ ju bi a ti lero lọ, eyi yoo fun wa ni anfaani pupọ sii lati ri ayọ ati itẹlọrun ninu riran awọn ẹlomiran lọwọ nipa ti ẹmi. Ọ̀nà kan sì tun ni eyi jẹ́ lati fi ifẹ aladuugbo ti a reti lati ọ̀dọ̀ wa hàn.—Matteu 22:39.
Eeṣe Ti Iwọ Fi Ń Ṣiṣẹsin Ọlọrun?
A ti ṣayẹwo kìkì diẹ ninu ọpọ awọn idi amúnilápàpàǹdodo fun fifi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin Jehofa. O jẹ ohun ti o dara lati ronu taduratadura nipa idi tiwa alára fun ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun, nitori pe ẹnikọọkan wa yoo nilati jihin fun un. (Romu 14:12; Heberu 4:13) Awọn ti wọn sì ń baa lọ ni wiwulẹ ni isunniṣe onimọtara-ẹni-nikan kì yoo gbadun ojurere atọrunwa.
Ki ni a lè reti bi ohun akọkọ ninu aniyan wa bá jẹ ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa ti a sì ń ṣe iṣẹ-isin mimọ ọlọ́wọ̀ fun Ọlọrun pẹlu awọn isunniṣe alaimọtara-ẹni-nikan? Họ́wù, Jehofa yoo bukun wa ati iṣẹ-ojiṣẹ wa! (Owe 10:22) Awa yoo tun gba iwalaaye ayeraye nitori pe a ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹsin Jehofa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹgbẹẹgbẹrun ń ṣiṣẹsin Jehofa ni Japan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣiṣiṣẹsin Jehofa ni Côte d’Ivoire
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
SIX SERMONS, lati ọwọ́ George Storrs (1855)