ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 April ojú ìwé 2-7
  • “Ẹ Fúnra Yín Yan Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ Máa Sìn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Fúnra Yín Yan Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ Máa Sìn”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ JÉSÙ FI PINNU PÉ JÈHÓFÀ LÒUN MÁA SÌN
  • ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌKAN
  • ÌDÍ TÁ A FI PINNU PÉ JÈHÓFÀ LA MÁA SÌN
  • MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 April ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

“Ẹ Fúnra Yín Yan Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ Máa Sìn”

“Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—JÓṢ. 24:15.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa rán wa létí ìdí tá a fi pinnu pé Jèhófà la máa sìn.

1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, kí sì nìdí? (Àìsáyà 48:17, 18)

BÀBÁ wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. (Oníw. 3:12, 13) Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi lè ṣe àwọn nǹkan àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò dá wa láti ṣàkóso ara wa tàbí ká pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Oníw. 8:9; Jer. 10:23) Ó mọ̀ pé tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ sin òun, ká sì máa tẹ̀ lé ìlànà òun.—Ka Àìsáyà 48:17, 18.

2. Èrò tí ò tọ́ wo ni Sátánì fẹ́ ká ní, kí sì ni Jèhófà ṣe láti fi hàn pé ohun tí Sátánì sọ kì í ṣòótọ́?

2 Sátánì fẹ́ ká máa rò pé tí Jèhófà ò bá ṣàkóso wa mọ́, a máa láyọ̀ àti pé àwa èèyàn lè ṣàkóso ara wa lọ́nà tó dáa. (Jẹ́n. 3:4, 5) Kí Jèhófà lè fi hàn pé ohun tí Sátánì sọ kì í ṣòótọ́, ó fàyè gba àwa èèyàn ká ṣàkóso ara wa fúngbà díẹ̀. Àwa náà ti fojú ara wa rí wàhálà tí ìṣàkóso èèyàn fà. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí wọ́n láyọ̀ torí pé wọ́n sin Jèhófà. Ẹni tó gbawájú nínú wọn ni Jésù. Torí náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jésù fi pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà Bàbá wa ọ̀run nìkan ló yẹ ká jọ́sìn. Níkẹyìn, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tá a fi pinnu pé Jèhófà la máa sìn.

ÌDÍ TÍ JÉSÙ FI PINNU PÉ JÈHÓFÀ LÒUN MÁA SÌN

3. Kí ni Sátánì sọ pé òun máa fún Jésù, kí ni Jésù sì ṣe?

3 Nígbà tí Jésù wà láyé, àtikékeré ló ti mọ ẹni tóun máa sìn. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, Sátánì sọ fún un pé òun máa fún un ní gbogbo ìjọba ayé yìí tó bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ni Jésù bá dá a lóhùn pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’” (Mát. 4:8-10) Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ìpinnu yẹn? Ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ lára ìdí náà.

4-5. Sọ díẹ̀ lára ìdí tí Jésù fi pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn.

4 Ìdí pàtàkì tí Jésù fi pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀ gan-an. (Jòh. 14:31) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù sin Jèhófà torí ohun tó yẹ kó ṣe nìyẹn. (Jòh. 8:28, 29; Ìfi. 4:11) Ó mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìyè, yàtọ̀ síyẹn, òun ló fún wa ní gbogbo nǹkan rere tá à ń gbádùn, a sì lè gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 33:4; 36:9; Jém. 1:17) Àtìbẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti jẹ́ kí Jésù mọ òtítọ́, òun ló sì fún un ní gbogbo ohun tó ní. (Jòh. 1:14) Àmọ́ Sátánì yàtọ̀ sí Jèhófà torí pé òun ló jẹ́ káwa èèyàn máa dẹ́ṣẹ̀, ká sì máa kú. Òpùrọ́ ni, ó lójú kòkòrò, tara ẹ̀ nìkan ló sì mọ̀. (Jòh. 8:44) Àwọn nǹkan tí Jésù mọ̀ yìí ò jẹ́ kó fìwà jọ Sátánì tàbí kó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.—Fílí. 2:5-8.

5 Nǹkan míì tó mú kí Jésù máa sin Jèhófà ni pé ó ń fojú sọ́nà fáwọn nǹkan rere tó máa ṣẹlẹ̀ tóun bá jẹ́ olóòótọ́. (Héb. 12:2) Ó mọ̀ pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́, òun máa sọ orúkọ Bàbá òun di mímọ́, ìyẹn ló sì máa mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò pátápátá.

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌKAN

6-7. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi sin Jèhófà lónìí, àmọ́ kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun nìkan ló yẹ ká máa sìn?

6 Lónìí, ọ̀pọ̀ ni ò sin Jèhófà torí pé wọn ò mọ àwọn ànímọ́ tó ní, wọn ò sì mọ gbogbo ohun rere tó ti ṣe fún wọn. Bí ọ̀rọ̀ àwọn tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún ní Áténì náà ṣe rí nìyẹn.—Ìṣe 17:19, 20, 30, 34.

7 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé Ọlọ́run òtítọ́ ló “fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” Ó tún sọ pé: “Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, “láti ara ọkùnrin kan ló ti dá àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè,” torí náà òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn.—Ìṣe 17:25, 26, 28.

8. Kí ni Jèhófà ò ní ṣe láé? Ṣàlàyé.

8 Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, òun sì ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó lè fipá mú gbogbo èèyàn pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun. Àmọ́, Jèhófà ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé òun wà àti pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an. Ó fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn di ọ̀rẹ́ òun títí láé. (1 Tím. 2:3, 4) Torí náà, Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ohun rere tó fẹ́ ṣe fáráyé lọ́jọ́ iwájú, ó sì fẹ́ ká kọ́ àwọn èèyàn nípa ẹ̀. (Mát. 10:11-13; 28:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣètò ìjọ tí àá ti máa jọ́sìn ẹ̀ àtàwọn alàgbà táá máa bójú tó wa.—Ìṣe 20:28.

9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ò gbà pé Ọlọ́run wà, àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe fún wọn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí àìmọye èèyàn ti ń gbé ìgbé ayé wọn bí wọ́n ṣe fẹ́ dípò kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Síbẹ̀, Jèhófà ń fìfẹ́ pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè wà láàyè, kí wọ́n sì gbádùn ayé wọn. (Mát. 5:44, 45; Ìṣe 14:16, 17) Ó mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kí wọ́n ní ìdílé, kí wọ́n sì gbádùn iṣẹ́ wọn. (Sm. 127:3; Oníw. 2:24) A ti rí i kedere pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. (Ẹ́kís. 34:6) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ lára ìdí tá a fi pinnu pé Jèhófà la máa sìn àti bó ṣe ń bù kún àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀.

ÌDÍ TÁ A FI PINNU PÉ JÈHÓFÀ LA MÁA SÌN

10. (a) Kí nìdí pàtàkì tá a fi ń sin Jèhófà? (Mátíù 22:37) (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń mú sùúrù fún ẹ? (Sáàmù 103:13, 14)

10 Bíi Jésù, ìdí pàtàkì tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an. (Ka Mátíù 22:37.) Àwọn ànímọ́ Jèhófà tá a mọ̀ ló jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń mú sùúrù fún wa. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú yín.” (Jer. 18:11) Kódà tá a bá ṣàṣìṣe, Jèhófà máa ń rántí pé aláìpé ni wá, ó sì máa ń dárí jì wá. (Ka Sáàmù 103:13, 14.) Tó o bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń mú sùúrù fún wa àtàwọn ànímọ́ ẹ̀, ṣé ìyẹn ò ní mú kó wù ẹ́ láti máa sìn ín títí láé?

11. Àwọn ìdí míì wo la fi pinnu pé Bàbá wa ọ̀run la máa sìn?

11 Ìdí míì tá a fi pinnu pé Jèhófà la máa sìn ni pé ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn. (Mát. 4:10) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan rere ló máa ṣẹlẹ̀. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, a máa ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́, a máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, a sì máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀. Tá a bá sì pinnu pé Jèhófà la máa sìn báyìí, àá láǹfààní láti máa sìn ín títí láé!—Jòh. 17:3.

12-13. Kí la kọ́ lára Jane àti Pam?

12 Àtikékeré ló yẹ ká ti kọ́ bá a ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ sí i bá a ṣe ń dàgbà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tí wọ́n ń jẹ́ Jane àti Pam.a Ọmọ ọdún mọ́kànlá (11) ni Jane, ọmọ ọdún mẹ́wàá sì ni Pam nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí wọn ò gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n gba àwọn ọmọ náà láyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa lọ sípàdé, ìyẹn tí wọ́n bá ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù nínú ìdílé wọn. Jane sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń fẹ́ kí n lo oògùn olóró, kí n sì ṣèṣekúṣe. Àmọ́ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi ni ò jẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀.”

13 Nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n pé ogún ọdún (20), àwọn méjèèjì ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, síbẹ̀, wọ́n ṣì ń tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Nígbà tí wọ́n rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, Jane sọ pé: “Mo ti rí i pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àti pé bí 2 Tímótì 2:19 ṣe sọ, ‘Jèhófà mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.’” Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó pinnu láti sìn ín, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀!

14. Báwo ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa ṣe ń mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ó wù wá láti mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé o ní ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ onínúure, ó lawọ́, ó sì máa ń dárí jini. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, o gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ yẹn burú, alágàbàgebè sì ni. Kí lo máa ṣe? Ó yẹ kó o gbèjà ẹ̀ ni. Lọ́nà kan náà, tí Sátánì àtàwọn èèyàn ayé yìí bá ń ba orúkọ Jèhófà jẹ́, tí wọ́n sì ń parọ́ mọ́ ọn, ó yẹ ká sọ òtítọ́ nípa Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, à ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ nìyẹn. (Sm. 34:1; Àìsá. 43:10) Torí náà, ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa ló máa fi hàn pé a fẹ́ sin Jèhófà tọkàntọkàn.

Ọmọ Léfì kan dúró sáàárín pẹpẹ bàbà àti ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì.

Ṣé wàá jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 14)b


15. Àǹfààní wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nígbà tó ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé ẹ̀? (Fílípì 3:7, 8)

15 Ó máa ń wù wá láti ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa ká lè sin Jèhófà bó ṣe fẹ́ tàbí ká lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ipò pàtàkì tó wà sílẹ̀ kó lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, kó sì lè sin Jèhófà. (Gál. 1:14) Ohun tó ṣe yẹn mú káyé ẹ̀ dáa, ó sì jẹ́ kó wà lára àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. Kò kábàámọ̀ pé òun sin Jèhófà, àwa náà ò sì ní kábàámọ̀ ẹ̀ láé.—Ka Fílípì 3:7, 8.

16. Kí la kọ́ lára Arábìnrin Julia? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Tá a bá pinnu pé Jèhófà la máa fayé wa sìn, a máa gbádùn ayé wa báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Julia. Kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àtikékeré ló ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ. Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olórin kan rí i pé ó morin kọ, ó sì dá a lẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ tí Julia fi di gbajúgbajà tó ń kọrin láwọn gbọ̀ngàn ńlá. Nígbà tó wà nílé ìwé ńlá kan tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn lórin, ọmọ kíláàsì ẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, ó sì sọ fún un pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Julia ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Nígbà tó yá, ó pinnu pé Jèhófà lòun máa fayé òun sìn, dípò kóun máa lé bóun ṣe máa di olókìkí. Ìpinnu yẹn ò rọrùn fún un rárá, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ fún mi pé mò ń fayé mi ṣòfò, àmọ́ Jèhófà ni mo fẹ́ fayé mi sìn.” Báwo ni ìpinnu tó ṣe ní ohun tó ju ọgbọ̀n (30) ọdún sẹ́yìn yẹn ṣe rí lára ẹ̀? Ó sọ pé: “Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, mo sì gbà pé Jèhófà máa fún mi ní gbogbo ohun tí mo fẹ́ lọ́jọ́ iwájú.”—Sm. 145:16.

Fọ́tò: Àwòrán tó jẹ́ ká rí àwọn àyípadà tí Julia ṣe. 1. Ó ń kọrin fáwọn èèyàn ní gbọ̀ngàn ńlá kan. 2. Òun àti ọkọ ẹ̀ ń kọrin nípàdé.

Tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà, ìgbésí ayé wa máa dáa, àá sì láyọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 16)c


MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ

17. Kí ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ káwọn tí ò tíì máa sin Jèhófà báyìí ṣe, kí ló sì fẹ́ káwọn tó ti ń sìn ín mọ̀?

17 Bá a ṣe mọ̀, òpin ò ní pẹ́ dé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Torí ní ‘ìgbà díẹ̀ sí i’ àti pé ‘ẹni tó ń bọ̀ máa dé, kò sì ní pẹ́.’” (Héb. 10:37) Kí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ? Ó fẹ́ káwọn tí ò tíì máa sin Jèhófà báyìí pinnu pé òun làwọn máa sìn kó tó pẹ́ jù. (1 Kọ́r. 7:29) Tá a bá sì ti ń sin Jèhófà báyìí, ó fẹ́ ká mọ̀ pé a máa fara da àwọn ìṣòro kan, àmọ́ fún “ìgbà díẹ̀” ni.

18. Kí ni Jésù àti Jèhófà fẹ́ ká ṣe?

18 Jésù gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn òun, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, ó tún ní kí wọ́n máa tẹ̀ lé òun. (Mát. 16:24) Torí náà tá a bá ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kó sú wa. Jèhófà fẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa sin òun nìṣó. Ó lè má rọrùn lóòótọ́, àmọ́ ọkàn wa máa balẹ̀, ó máa bù kún wa báyìí, ó sì tún máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ iwájú!—Sm. 35:27.

19. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gene?

19 Ó máa ń ṣe àwọn kan bíi pé òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà ti le jù. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò gbádùn ayé ẹ torí pé ò ń sin Jèhófà? Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Gene sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè ṣe ohun tó wù mí torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ó jọ pé àwọn ẹgbẹ́ mi máa ń gbádùn ara wọn torí wọ́n máa ń lọ patí, wọ́n lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́, wọ́n máa ń gbá géèmù ìwà ipá, àmọ́ ní tèmi ìpàdé àti òde ìwàásù ni mo máa ń lọ ṣáá.” Àkóbá wo nìyẹn wá ṣe fún Gene? Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí ò dáa, mo sì jayé orí mi fúngbà díẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yẹn ò jẹ́ kí n láyọ̀ tòótọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn ìlànà Bíbélì tí mo ti pa tì, mo sì pinnu pé màá máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ó jọ pé àtìgbà yẹn ni Jèhófà ti ń gbọ́ gbogbo àdúrà mi.”

20. Kí la pinnu pé àá máa ṣe?

20 Onísáàmù kan kọrin sí Jèhófà pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.” (Sm. 65:4) Torí náà, ẹ jẹ́ káwa náà pinnu bíi Jóṣúà tó sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣ. 24:15.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tí Jésù fi pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sin Jèhófà nìkan?

  • Kí nìdí tó o fi pinnu pé Jèhófà ni wàá sìn?

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí obìnrin kan gbọ́ táwọn èèyàn ń ta kò wá níwájú ìta ibi tá a ti ń ṣe àpéjọ wa, ó lọ síbi táwọn ará wa kan pàtẹ ìwé sí, ó sì gbọ́ ìwàásù.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí iṣẹ́ tí Julia ń ṣe tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe ń fayé ẹ̀ sin Jèhófà tọkàntọkàn báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́