ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/15 ojú ìwé 3-4
  • Eeṣe Ti O Fi Nilati Dán Ìpéye Bibeli Wò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eeṣe Ti O Fi Nilati Dán Ìpéye Bibeli Wò?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orisun Àrà-ọ̀tọ̀ Ti Ọgbọn Ti O Ga Ju
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/15 ojú ìwé 3-4

Eeṣe Ti O Fi Nilati Dán Ìpéye Bibeli Wò?

Oju wo ni o fi ń wo Bibeli? Awọn kan gbagbọ lọna ti o fẹsẹmulẹ pe ìfihàn Ọlọrun fun eniyan ni. Awọn miiran gbagbọ pe o wulẹ jẹ́ iwe kan lasan. Sibẹ awọn kan kò dori ipinnu kankan. Bi iwọ bá ní iyemeji eyikeyii nipa ipilẹṣẹ Bibeli, awọn ìdí pipọndandan wà ti o fi nilati ṣayẹwo rẹ̀ ki o sì yanju ọ̀ràn naa.

TÍTÍ fi di ọrundun kejidinlogun, Bibeli ni a bọ̀wọ̀ fun kaakiri nibi gbogbo gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni awọn ilẹ Kristẹndọm. Ṣugbọn lati ọrundun kọkandinlogun siwaju, iye awọn olukọni, onimọ ijinlẹ, ati awọn ẹlẹkọọ-isin ati awọn aṣaaju ṣọọṣi paapaa bẹrẹ sii fi iyemeji hàn nipa ìpéye Bibeli ní gbangba gbàngbà.

Gẹgẹ bi iyọrisi, ìṣelámèyítọ́ Bibeli ti tànkálẹ̀ tobẹẹ gẹẹ debi pe ọpọ ṣedajọ àní lai tilẹ mọ awọn ohun ti o wà ninu Bibeli paapaa. Rọ́pò Bibeli, ọpọlọpọ eniyan ninu Kristẹndọm ń yiju si awọn ọgbọn-imọ-ọran awọn eniyan nisinsinyi. Sibẹ, ọgbọn-imọ-ọran ode-oni kò tíì mú ayé kan ti o tubọ láààbò tabi layọ wá. Iyẹn jẹ́ idi rere kan lati ṣayẹwo Bibeli ki o sì rí i bi itọsọna rẹ̀ bá ń ṣamọna si ayọ ati aṣeyọri.

Idi miiran fun dídán ìpéye Bibeli wò ni ifojusọna àgbàyanu ti o nawọ rẹ̀ jade fun araye. Fun apẹẹrẹ, Orin Dafidi 37:29 sọ pe: “Olódodo ni yoo jogun ayé, yoo sì maa gbé inu rẹ̀ laelae.” (Ìfihàn 21:3-5) Iyọrisi wo ni iru awọn ileri bẹẹ ni lori rẹ? Dajudaju wọn jẹ́ idi ti o pọ̀ tó lati ṣayẹwo Bibeli ki ó sì rí i bi ó bá ṣeegbẹkẹle.

Iwe-irohin yii ti maa ń fi ìgbà gbogbo di ijotiitọ Bibeli mú ó sì sábà maa ń ṣalaye ẹ̀rí ìpéye rẹ̀ ni kedere. Iye awọn agbegbe kan wà ti a lè gbà dán ìpéye Bibeli wò. Oniruuru awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà yoo ràn ọ́ lọwọ lati dahun awọn ibeere wọnyi: Awọn otitọ ti a mọ̀ nipa ìtàn igbaani ha bá Bibeli mu bi? Awọn isọtẹlẹ rẹ̀ ha péye bi? Awọn amọran rẹ̀ ha ṣeefisilo bi, tabi awọn olukọni ati awọn ọlọgbọn-imọ-ọran ode-oni ha ti fẹ̀rí hàn pe Bibeli kò bá ìgbà mu mọ́ bi?

Ẹkọ nipa ìrísí ojú-ilẹ̀ jẹ́ agbegbe miiran ninu eyi ti o lè gbà dán ìpéye Bibeli wò. Àròsọ atọwọdọwọ ti awọn alaigbagbọ sábà maa ń forigbari pẹlu awọn otitọ ẹkọ nipa ìrísí ojú-ilẹ̀. Fun apẹẹrẹ, ọpọ awọn eniyan igbaani sọ ìtàn nipa irin-ajo si ayé ti a ń fẹnu lasan pè ni ti awọn òkú. Nipa awọn Griki igbaani, iwe naa A Guide to the Gods ṣalaye pe: “Ilẹ̀-ayé ni a rí gẹgẹ bi ojú-ilẹ̀ pẹrẹsẹ kan ti ọpọ omi salalu kan ti a ń pè ni Òkun yíká. Ni ikọja eyi ni Ayé-ẹ̀hìn-ọ̀la, ilẹ-ahoro ṣíṣúdùdù kan ti awọn koriko aláìléso wà gátagàta lori rẹ̀.” Nigba ti eyi jasi àròsọ atọwọdọwọ, awọn ọlọgbọn-imọ-ọran alaigbagbọ nilati tun idi ibi ti wọn fẹnu lasan pè ni ayé-ẹ̀hìn-ọ̀la fi mulẹ. “Ibi kan ti o yẹ ni wọn rí, labẹ ilẹ̀-ayé, ti oniruuru hòrò ńlá sopọ mọ́ ayé yii,” ni òǹṣèwé Richard Carlyon ṣalaye. Lonii, a mọ pe eyi pẹlu jẹ́ àròsọ atọwọdọwọ kan. Kò sí iru abẹ́-ilẹ̀-ayé tabi ọ̀nà bẹẹ ti o wà.

Laidabi àròsọ atọwọdọwọ awọn eniyan igbaani, Bibeli kò ní oju-iwoye òdì naa pe ilẹ̀-ayé tẹ́ pẹrẹsẹ ninu. Kaka bẹẹ, ó sọ otitọ ti o bá imọ-ijinlẹ mu pe ilẹ̀-ayé jẹ́ ohun kan ti ó rí rogodo ti kò duro lori ohunkohun. (Jobu 26:7; Isaiah 40:22) Ki ni nipa awọn apejuwe ti ẹkọ nipa ìrísí ojú-ilẹ̀ miiran ti a mẹnukan ninu Bibeli? Wọn ha jẹ́ ti àròsọ atọwọdọwọ, tabi ó hà ṣeeṣe lati foju-inu wo awọn iṣẹlẹ inu Bibeli pẹlu ìpéye nigba ti a bá ń ṣebẹwo si Egipti ode-oni, papọ pẹlu Ilẹ Sinai ti o nà wọnu omi, ati Israeli ode-oni bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

“Oun ni ẹni ti o jokoo lori òbìrí ayé.”—Isaiah 40:22

“Ó . . . fi ayé rọ̀ ni oju òfo.”—Jobu 26:7

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́