ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/15 ojú ìwé 5-8
  • Jehofa—Ọlọrun Otitọ ati Alààyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa—Ọlọrun Otitọ ati Alààyè
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orukọ ati Òkìkí Rẹ̀
  • Jehofa ati Awọn Animọ Rẹ̀
  • Ọba Ti Ọ̀run Ti Kò Ní Àfiwé
  • Jehofa Ni Ọlọrun Otitọ ati Alààyè
  • Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ta Ni Jehofa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/15 ojú ìwé 5-8

Jehofa—Ọlọrun Otitọ ati Alààyè

FARAO ọba Egipti fi ìṣàyàgbàǹgbà ati ẹ̀gàn sọrọ nigba ti o beere pe: “Ta ni [Jehofa, NW]?” (Eksodu 5:2) Gẹgẹ bi a ṣe fihàn ninu ọrọ-ẹkọ ti o ṣaaju, iṣarasihuwa yẹn mú awọn ìyọnu ati ikú wá sori awọn ará Egipti, ati sàréè oníbú-omi fun Farao ati awọn ipá ológun rẹ̀.

Ni Egipti igbaani, Jehofa Ọlọrun fi ipo-ajulọ rẹ̀ hàn lori awọn ọlọrun èké. Ṣugbọn pupọ pupọ sii ni ó wà ti a nilati mọ̀ nipa rẹ̀. Ki ni diẹ lara awọn apá ti akopọ animọ-iwa rẹ̀ pín si? Ki ni ó sì beere lọwọ wa?

Orukọ ati Òkìkí Rẹ̀

Nigba ti o beere ọ̀rọ̀ lọwọ Farao ọba Egipti, Mose kò sọ pe: ‘Oluwa sọ bayii bayii.’ Farao ati awọn ará Egipti miiran ka ọpọ awọn ọlọrun èké wọn si oluwa. Bẹẹkọ, Mose lo orukọ atọrunwa naa, Jehofa. Oun funraarẹ ti gbọ́ ọ ti a sọ ọ́ lati oke wá nigba ti o wà nibi ìgbẹ́ ti ń jó ni ilẹ Midiani. Akọsilẹ ti a mísí sọ pe:

“Ọlọrun sì sọ fun Mose, ó sì wí fun un pe, Emi ni JEHOFA. . . . Emi sì ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ará Egipti ń mú sìn; emi sì ti ranti majẹmu mi. Nitori naa wí fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi ni [Jehofa, NW], emi o sì mú yin jade kuro labẹ ẹrù awọn ará Egipti, emi ó sì yọ yin kuro ni oko-ẹrú wọn, emi o sì fi apá nínà ati idajọ ńlá dá yin ni ìdè: Emi ó sì gbà yin ṣe eniyan fun ara mi, emi o sì jẹ́ Ọlọrun fun yin: ẹyin ó sì mọ̀ pe emi ni [Jehofa, NW] Ọlọrun yin, ti o mú yin jade kuro labẹ ẹrù awọn ará Egipti. Emi ó sì mú yin lọ sinu ilẹ naa [Kenaani] ti mo ti bura lati fifun [awọn baba-nla yin] Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o sì fi i fun yin ni ìní: Emi ni [Jehofa, NW].”—Eksodu 6:1-8.

Ohun ti Jehofa ṣe gẹ́lẹ́ niyẹn. Ó dá awọn ọmọ Israeli silẹ lominira kuro ni oko-ẹrú awọn ará Egipti ó sì mú ki o ṣeeṣe fun wọn lati gba ilẹ Kenaani. Gẹgẹ bi ó ti ṣeleri, Ọlọrun jẹ́ ki gbogbo eyi ṣẹlẹ. Ó ti ṣe wẹ́kú tó! Orukọ rẹ̀, Jehofa, tumọ si “Ó Mú ki Ó Wà.” Bibeli tọka si Jehofa pẹlu awọn orúkọ-oyè bíi “Ọlọrun,” “Oluwa Ọba-Alaṣẹ,” “Ẹlẹdaa,” “Baba,” “Olodumare,” ati “Ẹni Giga Julọ.” Sibẹ orukọ rẹ̀ Jehofa dá a fihàn yatọ gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ ti ń mú awọn ète titobilọla rẹ̀ ṣẹ ni ṣisẹntẹle.—Isaiah 42:8.

Bi a bá nilati ka Bibeli ni awọn èdè rẹ̀ ipilẹṣẹ, awa yoo rí orukọ Ọlọrun ni ẹgbẹẹgbẹrun ìgbà. Ni èdè Heberu oun ni a mú ki kọnsonanti mẹrin naa Yod He Waw He (יהוה), ti a ń pè ni Tetragrammaton duro fun, a ń kàá lati apá ọ̀tún si òsì. Awọn wọnni ti wọn ń sọ èdè Heberu ń pese awọn ìró fawẹẹli, ṣugbọn awọn eniyan lonii kò mọ ohun ti iwọnyẹn jẹ́ daju. Nigba ti awọn kan faramọ sipẹli naa Yahweh, Jehofa ni ọ̀nà ti ó wọ́pọ̀ ti ó sì fi Ẹlẹdaa wa hàn lọna ti o yẹ.

Lilo orukọ naa Jehofa tun fi Ọlọrun hàn yatọ gédégbé si ẹni naa ti a pè ni “Oluwa mi” ni Orin Dafidi 110:1, nibi ti itumọ kan ti jẹ́: “OLUWA [Heberu, יהוה] wí fun Oluwa mi pe, Iwọ jokoo ni ọwọ́ ọ̀tún mi, titi emi ó fi sọ awọn ọ̀tá rẹ di apoti-itisẹ rẹ.” Ni jijẹwọ ifarahan orukọ Ọlọrun nihin-in ninu ẹsẹ-iwe Heberu, New World Translation kà pe: “Ọrọ-isọjade Jehofa si Oluwa mi ni: ‘Jokoo ni ọwọ́ ọ̀tún mi titi ti emi óò fi fi awọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí fun ẹsẹ rẹ.’” Awọn ọ̀rọ̀ Jehofa Ọlọrun wọnni tọka lọna alasọtẹlẹ si Jesu Kristi, ẹni ti onkọwe naa pè ni “Oluwa mi.”

Jehofa ṣe orukọ kan fun araarẹ̀ ni ọjọ Farao. Nipasẹ Mose, Ọlọrun sọ fun oluṣakoso ọlọkan-lile yẹn pe: “Ìgbà yii ni emi ó rán gbogbo ìyọnu mi si àyà rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn eniyan rẹ; ki iwọ ki o lè mọ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo ayé. Nitori nisinsinyi, emi ì bá na ọwọ́ mi, ki emi ki o lè fi ajakalẹ-arun lù ọ́, ati awọn eniyan rẹ; à bá sì ti ké ọ kuro lori ilẹ. Ṣugbọn nitori eyi paapaa ni emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a lè rohin orukọ mi ka gbogbo ayé.”—Eksodu 9:14-16.

Nipa ijadelọ Israeli kuro ni Egipti ati ibiṣubu awọn ọba Kenaani kan bayii, obinrin naa Rahabu ará Jeriko sọ fun awọn amí Heberu meji pe: “Emi mọ̀ pe [Jehofa, NW] ti fun yin ni ilẹ yii, ati pe ẹ̀rù yin bani, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yii di omi nitori yin. Nitori pe awa ti gbọ́ bi [Jehofa, NW] ti mú omi Òkun Pupa gbẹ niwaju yin, nigba ti ẹyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti ń bẹ ni iha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹyin parun túútúú. Lọ́gán bi awa ti gbọ́ nǹkan wọnyi, àyà wa já, bẹẹ ni kò sì sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori yin; nitori pe [Jehofa, NW] Ọlọrun yin, oun ni Ọlọrun lókè ọ̀run, ati nisalẹ ayé.” (Joṣua 2:9-11) Bẹẹni, òkìkí Jehofa ti tankalẹ.

Jehofa ati Awọn Animọ Rẹ̀

Olorin naa sọ idaniyan atọkanwa yii jade pe: “Ki awọn eniyan ki o lè mọ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo tíí jẹ́ Jehofa, iwọ ni Ọ̀gá-ògo lori ayé gbogbo.” (Orin Dafidi 83:18) Niwọn bi ipo ọba-alaṣẹ Jehofa ti wà fun gbogbo ayé, awọn ọmọlẹhin Jesu ti a ṣe inunibini si lè gbadura pe: “Oluwa, iwọ ti o dá ọ̀run oun ayé, ati òkun, ati ohun gbogbo ti ń bẹ ninu wọn.” (Iṣe 4:24) Ó sì ti ń tunininu tó lati mọ̀ pe Jehofa ni “Olùgbọ́ adura”!—Orin Dafidi 65:2, NW.

Lajori animọ-iwa Jehofa ni ifẹ. Nitootọ, “Ọlọrun jẹ́ ifẹ”—ẹdaya-apẹẹrẹ animọ yii gan-an. (1 Johannu 4:8, NW) Ju bẹẹ lọ, “pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) ni ọgbọ́n ati agbara.” Jehofa ni ọlọ́gbọ́n gbogbo ati alagbara gbogbo, ṣugbọn oun kò tíì ṣi agbara rẹ̀ lò rí. (Jobu 12:13; 37:23) Ó tun lè dá wa loju pe Jehofa yoo maa fi ẹ̀tọ́ bá wa lò nigba gbogbo, nitori pe “òdodo ati idajọ ni ibujokoo ìtẹ́ rẹ̀.” (Orin Dafidi 97:2) Bi a bá ṣẹ̀ ṣugbọn ti a ronupiwada, a lè ri itunu ninu mímọ̀ pe Jehofa jẹ́ “Ọlọrun alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ.” (Eksodu 34:6) Abajọ ti a fi lè layọ ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa!—Orin Dafidi 100:1-5.

Ọba Ti Ọ̀run Ti Kò Ní Àfiwé

Ọmọkunrin Jehofa, Jesu Kristi, sọ pe: “Ẹmi ni Ọlọrun.” (Johannu 4:24) Fun idi eyi, Jehofa jẹ́ ẹni airi fun oju eniyan. Niti tootọ, Jehofa sọ fun Mose pe: “Iwọ kò lè rí oju mi: nitori ti kò sí eniyan kan tíí rí mi, tíí sìí yè.” (Eksodu 33:20) Ọba ti ọ̀run yii ní ògo tobẹẹ gẹẹ debi pe awọn eniyan kò ni lè farada iriri ti fifoju gán-án-ní rẹ̀.

Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa jẹ́ ẹni airi fun oju wa, ọpọlọpọ ẹ̀rí ni ó wà fun wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun Olodumare. Nitootọ, “ohun rẹ̀ ti o farasin lati ìgbà dídá ayé a rí wọn gbangba, a ń fi òye ohun ti a dá mọ̀ ọ́n, àní agbara ati ìwà-Ọlọ́run rẹ̀ ayeraye.” (Romu 1:20) Ilẹ̀-ayé—pẹlu awọn eweko, igi, èso, ewébẹ̀, ati òdòdó rẹ̀—jẹrii si ipo jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa. Laidabii awọn ọlọrun oriṣa ti kò niyelori, Jehofa ń funni ni òjò ati akoko èso. (Iṣe 14:16, 17) Wo awọn irawọ ni ofuurufu alẹ́. Ẹ̀rí ńláǹlà ti ipo jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa ati agbara iṣetojọ wo ni wọn jẹ́!

Jehofa tún ti ṣeto awọn ẹ̀dá ẹmi ọlọgbọnloye, mímọ́ rẹ̀ ni ọ̀run. Gẹgẹ bi eto-ajọ kan tí ó wà ni iṣọkan, wọn ń ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, gẹgẹ bi olorin naa ṣe sọ pe: “Ẹ fi ibukun fun Oluwa, ẹyin angẹli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipá ti ń ṣe ofin rẹ̀, ti ń fi etí si ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ibukun fun Oluwa, ẹyin ọmọogun rẹ̀ gbogbo; ẹyin iranṣẹ rẹ̀, ti ń ṣe ifẹ rẹ̀.” (Orin Dafidi 103:20, 21) Jehofa tún ti ṣeto awọn eniyan rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé jọ. Orilẹ-ede Israeli ni a ṣetojọ daradara, bẹẹ naa sì ni awọn ọmọlẹhin Ọmọkunrin Ọlọrun ni akọkọbẹrẹ. Bakan naa lonii, Jehofa ní eto-ajọ kan kari-aye ti awọn Ẹlẹ́rìí, onitara ti ń polongo ihinrere pe Ijọba rẹ̀ ti sunmọle.—Matteu 24:14.

Jehofa Ni Ọlọrun Otitọ ati Alààyè

Ipo jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa ni a ti fihàn ni ọpọlọpọ ọ̀nà gan-an! Ó rẹ awọn ọlọrun èké Egipti silẹ ó sì mú awọn ọmọ Israeli wọnu Ilẹ Ileri laisewu. Iṣẹda funni ni ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó nipa ipo jíjẹ́ Ọlọrun Jehofa. Kò sì sí ifiwera kankan rara laaarin oun ati awọn ọlọrun oriṣa ti kò wulo ti isin èké.

Wolii naa Jeremiah fi iyatọ gédégédé ti o wà laaarin Jehofa, Ọlọrun alààyè, ati awọn oriṣa alailẹmii ti eniyan ṣe hàn. Iyatọ gédégédé naa ni a sọ daradara ninu Jeremiah ori 10. Laaarin awọn nǹkan miiran, Jeremiah kọwe pe: “Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, oun ni Ọlọrun alààyè, ati Ọba ayeraye!” (Jeremiah 10:10) Ọlọrun alààyè ati otitọ, Jehofa, dá ohun gbogbo. Ó dá awọn ọmọ Israeli ti wọn ń lálàṣí ni oko-ẹrú Egipti nídè. Kò sí ohun ti kò ṣeeṣe fun un.

Jehofa, “Ọba ayeraye,” yoo dahun adura naa pe: “Baba wa ti ń bẹ ni ọ̀run; ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ dé; ifẹ tìrẹ ni ki a ṣe, bii ti ọ̀run, bẹẹ ni ni ayé.” (1 Timoteu 1:17; Matteu 6:9, 10) Ijọba ọ̀run ti Messia, ti o ti wà lọwọ Jesu Kristi ni bayii, yoo tó gbé igbesẹ lodisi awọn olubi laipẹ yoo sì pa gbogbo awọn ọ̀tá Jehofa run. (Danieli 7:13, 14) Ijọba yẹn yoo tun mú ayé titun ti awọn ibukun ailopin wọle wá fun araye onigbọran.—2 Peteru 3:13.

Pupọ pupọ sii ni o wà lati kẹkọọ nipa Jehofa ati awọn ète rẹ̀. Eeṣe ti o kò fi ṣe ipinnu rẹ lati gba iru ìmọ̀ bẹẹ ki o sì huwa ni ibamu pẹlu rẹ̀? Bi o bá ṣe eyi, iwọ yoo lanfaani lati gbadun ìyè ayeraye ninu paradise ori ilẹ̀-ayé kan labẹ iṣakoso Ijọba. Iwọ yoo walaaye nigba ti ibanujẹ, irora, ati iku paapaa yoo ti kọja lọ ti ìmọ̀ nipa Jehofa yoo sì kún ilẹ̀-ayé. (Isaiah 11:9; Ìfihàn 21:1-4) Iyẹn lè jẹ́ ipa tìrẹ bi o bá wá, rí, ti o sì huwa ni ibamu pẹlu awọn idahun ti a gbekari Bibeli si ibeere naa, “Ta ni [Jehofa, NW]?”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́