ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/15 ojú ìwé 4-7
  • Bi A Ṣe Lè Mú Ìdè igbeyawo Lókun Sii

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bi A Ṣe Lè Mú Ìdè igbeyawo Lókun Sii
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipese Ofin Mose
  • Ipilẹ Kanṣoṣo ti Ó Bofinmu fun Ikọsilẹ
  • A Fọnrugbin Rogbodiyan Idile
  • Ẹ Jumọ Sọ Ohun ti O Ń Dùn Yin
  • Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/15 ojú ìwé 4-7

Bi A Ṣe Lè Mú Ìdè igbeyawo Lókun Sii

“OHA tọ́ fun ọkunrin ki o kọ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ràn gbogbo?” ni awọn Farisi ti wọn ń gbiyanju lati dẹkùn mú Jesu Kristi, Olukọ Nla naa beere. Ó da wọn lohun nipa titọka si igbeyawo eniyan akọkọ o sì gbé ọpa-idiwọn kan kalẹ lori ọ̀ràn naa: “Ohun ti Ọlọrun bá so ṣọkan, ki eniyan ki o maṣe yà wọn.”

Awọn Farisi naa jiyàn pe Mose ṣe ipese fun ikọsilẹ nipa didamọran fifi “iwe ikọsilẹ” fun un. Jesu dá wọn lóhùn pe: “Nitori líle àyà yin ni Mose ṣe jẹ́ fun yin lati maa kọ aya yin silẹ, ṣugbọn lati ìgbà atetekọṣe wá kò ri bẹẹ. Mo sì wi fun yin, ẹnikẹni ti o bá kọ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe pe nitori àgbèrè, ti o sì gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga.”—Matteu 19:3-9.

Ní ipilẹṣẹ, igbeyawo ni a ṣe lati jẹ́ ìdè pipẹtiti. Àní iku kì bá ti ya awọn tọkọtaya alajọṣegbeyawo akọkọ paapaa, nitori pe a dá wọn gẹgẹ bi eniyan pípé pẹlu iwalaaye ayeraye ni iwaju. Bi o ti wu ki o ri, wọn dẹ́ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ba igbeyawo eniyan jẹ́. Ọ̀tá naa ikú bẹrẹ sii pín awọn tọkọtaya alajọṣegbeyawo níyà. Ọlọrun wo iku gẹgẹ bi opin igbeyawo kan, gẹgẹ bi a ti kà á ninu Bibeli pe: “A fi ofin de obinrin niwọn ìgbà ti ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ bá kú, o di ominira lati bá ẹnikẹni ti o wù ú gbeyawo; kiki ninu Oluwa.” (1 Korinti 7:39) Eyi yatọ gan-an si iru awọn èrò isin bi abọ́kọkú ti awọn onisin Hindu, ninu eyi ti a ó ti tan aya kan tabi fi agbara mú, nigba ikú ọkọ rẹ̀, lati sun araarẹ̀ titi ti yoo fi kú pẹlu igbagbọ pe ìdè igbeyawo naa ń baa lọ ninu iru iwalaaye kan lẹhin iku.

Ipese Ofin Mose

Ni akoko ti a funni ní Ofin Mose, ibatan ìdè igbeyawo ti joro debii pe, lati inu igbatẹniro fun ọkàn lile awọn ọmọ Israeli, Jehofa ṣe ipese fun ikọsilẹ. (Deuteronomi 24:1) Kìí ṣe ète Ọlọrun fun awọn ọmọ Israeli lati ṣi ofin yii lò lati kọ aya wọn silẹ nitori awọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, gẹgẹ bi o ti hàn gbangba lati inu ofin rẹ̀ pe wọn nilati nifẹẹ ọmọnikeji wọn gẹgẹ bi araawọn. (Lefitiku 19:18) Àní fifunni ni iwe-ẹri ikọsilẹ paapaa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ohun idiwọ nitori pe, bi apakan ilana kíkọ iwe-ẹri naa, ọkọ ti ń fẹ́ ikọsilẹ naa nilati lọ bá awọn ẹni ti a fun ni àṣẹ ti o yẹ, ti wọn lè ti gbiyanju lati ṣe ìlàjà. Rara, Ọlọrun kò fi ofin yii funni lati gbé ẹ̀tọ́ kíkọ aya ẹni “nitori ọ̀ràn gbogbo” kalẹ.—Matteu 19:3.

Bi o ti wu ki o ri, awọn ọmọ Israeli nikẹhin ṣá ẹ̀mí ti ń bẹ lẹhin ofin naa tì tí wọn sì lo apola-ọrọ yii lati gba ikọsilẹ lori ipo eyikeyii ti o bá ti bá èròkerò wọn mu. Nigba ti o di ọrundun karun un B.C.E., wọn ń fi iwa arekereke bá aya ìgbà èwe wọn lò, wọn ń kọ̀ wọn silẹ nitori ọ̀ràn gbogbo. Jehofa sọ fun wọn niti pato pe oun koriira ikọsilẹ. (Malaki 2:14-16) Lori ipilẹ yii ni Jesu fi dẹbi fun ikọsilẹ gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti ń ṣe é ni ọjọ́ rẹ̀.

Ipilẹ Kanṣoṣo ti Ó Bofinmu fun Ikọsilẹ

Bi o ti wu ki o ri, Jesu mẹnukan ipilẹ kanṣoṣo ti o bofinmu fun ikọsilẹ: àgbèrè. (Matteu 5:31, 32; 19:8, 9) Ọ̀rọ̀ naa ti a tumọ si “àgbèrè” nihin-in ni ninu gbogbo ọ̀ràn ibalopọ takọtabo ti kò bofinmu lẹhin ode igbeyawo ti ó bá Iwe Mimọ mu, boya pẹlu ẹnikan ti o jẹ̀ ti ẹya kan-naa tabi ti ẹya odikeji tabi pẹlu ẹranko.

Àní bi o tilẹ ri bẹẹ, kìí ṣe pe Jesu ń dabaa ikọsilẹ kuro lọdọ ẹnikeji alaiṣootọ ni. Ó wà lọwọ alabaaṣegbeyawo ti kò mọwọ́-mẹsẹ naa lati gbé àbájáde tí ó wémọ́ ọn lérí ìwọ̀n kí ó sì pinnu boya oun ń fẹ́ ikọsilẹ lẹhin. Awọn aya ti wọn ń ronu ikọsilẹ lori ipilẹ ti o bá Iwe Mimọ mu yii pẹlu tun lè fẹ́ lati gbé gbolohun-ọrọ Ọlọrun yẹwo nigba ti o ṣe idajọ obinrin akọkọ naa nitori ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ní afikun si idajọ ikú naa, Ọlọrun sọ ni pato fun Efa pe: “Lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yoo maa fà sí, oun ni yoo sì maa ṣe olori rẹ.” (Genesisi 3:16) Iwe Commentary on the Old Testament, lati ọwọ C. F. Keil ati F. Delitzsch, ṣapejuwe “ìfàsí” yii gẹgẹ bi “ìfẹ́-ọkàn ti ó fẹrẹẹ dabi àrùn kan.” A gbà pe, ìfàsí yii kò fi bẹẹ lagbara ninu gbogbo aya, ṣugbọn nigba ti aya alaimọwọmẹsẹ kan bá ń ronu ikọsilẹ, oun yoo jẹ́ ọlọgbọn lati gbé awọn aini ero-imọlara tí awọn obinrin ti jogun lati ọ̀dọ̀ Efa yẹwo. Bi o ti wu ki o ri, bí o ti jẹ́ pe ibalopọ lẹhin òde igbeyawo niha ọ̀dọ̀ ẹnikeji ti o jẹbi naa ti lè yọri si kí ẹnikeji ti kò mọwọ́-mẹsẹ̀ naa kó awọn àrùn ti ibalopọ takọtabo ń tankalẹ, titi kan àrùn AIDS, awọn kan ti pinnu lati fàbọ̀ sori ikọsilẹ gẹgẹ bi Jesu ti ṣalaye rẹ̀.

A Fọnrugbin Rogbodiyan Idile

Líle ọkàn awọn eniyan ní orisun rẹ̀ ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí tọkọtaya akọkọ naa dá lodisi Ọlọrun. (Romu 5:12) Awọn irugbin rogbodiyan idile ni a gbìn nigba ti awọn tọkọtaya eniyan akọkọ dẹṣẹ si Baba wọn ọrun. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? Nigba ti ejò kan tan obinrin akọkọ naa, Efa, jẹ lati jẹ lara igi ti a kaleewọ naa, taarata ni o lọ ti o sì jẹ èso naa. Kiki lẹhin ti ó ti ṣe ipinnu ṣiṣepataki yẹn ni o wá sọ fun ọkọ rẹ̀ nipa ohun ti ejò naa ti sọ fun un. (Genesisi 3:6) Bẹẹni, ó ti gbegbeesẹ laisọ fun ọkọ rẹ̀. Eyi jẹ́ apẹẹrẹ awọn iṣoro ti ọpọ idile ń dojukọ lonii—aisi ifinukonu nipasẹ ijumọsọrọpọ.

Lẹhin naa, nigba ti wọn koju iyọrisi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Adamu ati Efa fàbọ̀ sori ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan-naa tí pupọ awọn tọkọtaya maa ń lò lonii nigba ti wọn bá wà ninu iṣoro, iyẹn ni pe, didẹbi fun ẹnikeji. Ọkunrin akọkọ naa, Adamu, di ẹbi ohun ti ó ti ṣe ru aya rẹ̀ ati Jehofa, ni wiwi pe: “Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, oun ni o fun mi ninu èso igi naa, emi sì jẹ.” Obinrin naa ní tirẹ̀ sì sọ pe: “Ejò ni ó tàn mi, mo sì jẹ.”—Genesisi 3:12, 13.

Ikede idajọ Jehofa sori Adamu ati Efa sọ àsọbádé okunfa miiran sibẹ ninu awọn iṣoro ti yoo dide. Nipa ibatan rẹ̀ pẹlu ọkọ rẹ̀, Jehofa wi fun Efa pe: “Oun ni yoo sì maa ṣe olori rẹ.” Ọpọ awọn ọkọ lonii, bii ti Isao ti a mẹnukan ninu ọrọ-ẹkọ wa akọkọ, ṣe olori aya wọn lọna oníkà laisi ọ̀wọ̀ fun imọlara aya wọn. Sibẹ, pupọ awọn aya ń baa lọ lati ní òòfà-ọkàn fun afiyesi ọkọ wọn. Nigba ti a kò bá tẹ́ òòfà-ọkàn yẹn lọ́rùn, awọn aya lè beere fun afiyesi yẹn ki wọn sì gbegbeesẹ lọna imọtara-ẹni-nikan. Niwọn bi o ti jẹ́ pe pupọ awọn ọkọ ni wọn maa ń ṣe olori ti pupọ awọn aya sì maa ń ní òòfà-ọkàn fun afiyesi ọkọ wọn, imọtara-ẹni-nikan ń gbilẹ, alaafia sì ń gba ojú ferese jade. Ninu iwe-irohin kan ti o ní akọle naa “Bi A Ṣe Lè Ṣalaye Awọn Ikọsilẹ Ode-Oni,” Shunsuke Serizawa wi pe: “Bi a bá gbojufo itẹsi ti o wà nidi ọ̀ràn ti ‘ṣiṣe tinu ẹni’ dá, iyẹn ni pe, fifun awọn ìfẹ́-ọkàn ẹni ni ipo kìn-ín-ní, lojiji ni yoo di ohun ti kò ṣeeṣe lati ṣalaye ikọsilẹ lonii.”

Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jehofa ti pese itọsọna ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ki awọn tọkọtaya alajọṣegbeyawo ti wọn jẹ́ onigbọran baa lè gbadun iwọn ayọ igbeyawo àní nipo aipe wọn paapaa. Isao tẹle itọsọna Ọlọrun, o sì ń gbadun igbesi-aye idile alayọ kan ní bayii. Ẹ jẹ ki a wo bi awọn ilana Bibeli ṣe ran awọn eniyan lọwọ lati fun ìdè igbeyawo lokun.

Ẹ Jumọ Sọ Ohun ti O Ń Dùn Yin

Ninu ọpọ igbeyawo, aisi ijumọsọrọpọ, itẹsi lati di ẹrù ẹ̀bi ru ẹlomiran, ati awọn iṣarasihuwa onimọtara-ẹni-nikan mu ki o ṣoro fun ọkọ ati aya lati lóye awọn ero-imọlara ẹnikinni keji. “Niwọn bi ṣiṣajọpin awọn imọlara ti jẹ́ àtẹ̀gùn si isunmọra pẹkipẹki, isunmọra pẹkipẹki beere fun igbẹkẹle pipeye. Igbẹkẹle sì ṣọ̀wọ́n lonii,” ni oluṣewadii naa Caryl S. Avery sọ. Ìwọ́jọ awọn imọlara inu lọhun-un tí a ṣàjọpín rẹ̀ ń gbé iru igbẹkẹle bẹẹ ró. Eyi beere fun ifinukonu nipasẹ ijumọsọrọpọ laaarin ọkọ ati aya.

Iwe Owe lo àkàwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ lati fun ṣiṣajọpin awọn èrò kọ́lọ́fín inu ẹni ní iṣiri, ni sisọ pe: “Ìmọ̀ ninu ọkàn eniyan dabi omi jíjìn; ṣugbọn amoye eniyan ni i fà á jade.” (Owe 20:5) Awọn tọkọtaya gbọdọ jẹ́ olóye ki wọn sì fa awọn èrò ti o wà nisalẹ ọkan-aya ẹnikeji wọn jade. Finuwoye pe inu ń bí ẹnikeji rẹ. Dipo didahunpada pe: “Emi pẹlu kò gbadun òní,” ki ni ṣe ti o kò fi inurere beere pe: “Iwọ kò ha gbadun òní bi? Kíló ṣẹlẹ?” Ó lè gba akoko ati isapa lati tẹtisilẹ si ẹnikeji rẹ, ṣugbọn o sábà maa ń rọnilọrun, tẹnilọrun, o sì maa ń pa akoko mọ́ lati lo akoko ní ọ̀nà yẹn ju bi o ti jẹ́ lati dagunla si ẹnikeji rẹ ki o sì wá koju awọn ero-imọlara onígbòónára ti o ru jade lẹhin naa.

Lati jere igbẹkẹle, ẹnikọọkan gbọdọ jẹ́ alailaboosi ki ó sì gbiyanju lati sọ awọn imọlara jade ní ọ̀nà kan ti ẹnikeji lè loye. “Bá ọmọnikeji . . . sọ otitọ,” ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbaniniyanju, “nitori ẹ̀yà-ara ọmọnikeji wa ni awa iṣe.” (Efesu 4:25) Sisọ otitọ beere fun òye. Ki a sọ pe aya kan lero pe a kò gbọ́ toun. Ki ó tó sọ̀rọ̀, o nilati ronu lori owe naa: “Ẹni ti o ní ìmọ̀, a ṣẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kù: ọlọkan tutu si ni amoye eniyan.” (Owe 17:27) Dipo ki o fi ẹsun kan ọkọ rẹ̀ pe, “Iwọ kò fetisilẹ si mi rí!” yoo sàn jù lọpọlọpọ ti o bá farabalẹ ṣalaye imọlara rẹ̀ ṣaaju ki ipinnilẹmii ati ijanikulẹ tó gbèrú ninu rẹ̀. Boya ó lè fi bi imọlara rẹ̀ ti ri hàn nipa sisọ ohun kan bii, “Mo mọ̀ pe ọwọ rẹ dí, ṣugbọn níní akoko diẹ sii pẹlu rẹ yoo mu mi layọ gan-an.”

Niti tootọ, “laisi igbimọ, èrò a dasan.” (Owe 15:22) Ẹnikeji rẹ nifẹẹ rẹ, ṣugbọn iyẹn kò tumọsi pe oun lè mọ ohun ti iwọ ń rò. Iwọ gbọdọ jẹ́ ki ẹnikeji rẹ mọ bi imọlara rẹ ti rí lọna ọgbọ́n. Eyi yoo ràn yin lọwọ, gẹgẹ bi tọkọtaya Kristian alajọṣegbeyawo, lati ṣe awọn atunṣebọsipo onifẹẹ lati lè “pa iṣọkan ẹmi mọ́ ni idipọ alaafia.”—Efesu 4:2, 3.

Ẹ wo Kazuo, fun apẹẹrẹ, ẹni ti aya rẹ sábà maa ń pariwo lé lori nitori ìfẹ́-ọkàn oníkànńpá fun tẹ́tẹ́-títa. O wa ríi pe oun ti rì sinu gbèsè ti o pọ̀ tó ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun owo dollar melookan. Ni yíyá owo lati san awọn gbese rẹ̀, ó tubọ ń rì wọnu gbese naa sii. Lẹhin naa, ó bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli ó sì rí igboya naa lati sọ fun aya rẹ̀ nipa awọn iṣoro rẹ̀ nikẹhin. Ó ti muratan lati dojukọ awọn ẹsun ti a bá fi kàn án. Bi o ti wu ki o ri, ẹnu yà á nigba ti aya rẹ̀, ẹni ti ó ti ń kẹkọọ Bibeli ṣaaju ìgbà naa, farabalẹ dahun pe: “Jẹ́ ki a gbiyanju lati wá ojutuu si bi a o ṣe san awọn gbese naa.”

Bẹrẹ ni ọjọ keji, wọn tọ awọn ti wọn jẹ ni gbese lọ wọn sì bẹrẹ sii san awọn gbese wọn, wọn tilẹ ta ile wọn paapaa. Ó gba eyi ti o fẹrẹẹ tó ọdun kan lati san awọn gbese naa. Ki ni ohun ti o yí Kimie, aya rẹ̀ pada? Aya rẹ̀ sọ pe: “Awọn ọ̀rọ̀ ti a rí ninu Filippi ori 4, ẹsẹ 6 ati 7, jẹ́ otitọ niti gidi. ‘Ẹ má ṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹ̀bẹ̀ pẹlu idupẹ, ẹ maa fi ibeere yin hàn fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkàn ati èrò yin ninu Kristi Jesu.’” Ó fikun un pe: “Ọ̀rẹ́ mi kan, ti ẹnu yà nigba ti o ri bi ọyàyà mi ti pọ̀ tó loju awọn iṣoro, bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu mi.” Kazuo ati aya rẹ̀ ti ṣe iribọmi lati ìgbà naa wá wọn sì ń gbadun igbesi-aye idile alayọ nisinsinyi.

Ní afikun si gbigbẹkẹle ẹnikinni keji nipa sisọ otitọ, awọn ọkọ ati aya ti wọn ní awọn iriri ti o wà loke yii ṣe ohun kan ti o ran awọn tọkọtaya lọwọ lati yanju awọn iṣoro igbeyawo wọn. Wọn jumọsọrọpọ pẹlu Olupilẹṣẹ eto igbeyawo, Jehofa Ọlọrun. Laika awọn ikimọlẹ ati iṣoro ti awọn tọkọtaya ń dojukọ sí, oun yoo bukun fun wọn pẹlu alaafia Ọlọrun ti o tayọ èrò gbogbo bi wọn bá sa gbogbo ipa wọn lati fi awọn ilana rẹ̀ silo ki wọn sì fi eyi ti ó kù si ọwọ́ rẹ̀. Gbigbadura papọ ń ṣeranwọ ni pataki. Ọkọ gbọdọ mú ipo iwaju ki o sì ‘tú ọkàn rẹ̀ jade’ niwaju Ọlọrun, ki o maa wá itọsọna ati idari rẹ̀ lori iṣoro eyikeyii ti oun ati aya rẹ̀ ń koju. (Orin Dafidi 62:8) O daju pe, Jehofa Ọlọrun yoo gbọ́ iru awọn adura bẹẹ.

Bẹẹni, o ṣeeṣe lati mu ìdè igbeyawo lokun. Àní nisinsinyi paapaa, ni gbigbe pẹlu gbogbo aipe wa ninu awujọ eniyan ti ń ru gùdù, awọn tọkọtaya alajọṣegbeyawo lè ri iwọn ayọ kan ninu ibaṣepọ wọn. Iwọ lè rí awọn afikun àbá gbigbeṣẹ ati imọran oniwa-bi-Ọlọrun ninu iwe naa Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ, ti a tẹ lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. Siwaju sii, awọn tọkọtaya ti wọn fi tọkantọkan ṣiṣẹ lati fi awọn ilana Bibeli silo ní ireti wiwa papọ ninu ìdè ifẹ ninu ayé titun ti ń bọ̀ laipẹ eyi ti Ọlọrun yoo mú wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́