Ìdáàbòbò Gidi Ha Ṣeéṣe Bí?
ALÁRÒKỌ náà Ralph Waldo Emerson sọ nígbà kan rí pé: “Àwọn aláìnírònù jinlẹ̀ ènìyàn gbàgbọ́ nínú oríire . . . Àwọn alókunlágbára ènìyàn gbàgbọ́ nínú okùnfà àti èso iṣẹ́.” Bẹ́ẹ̀ni, ẹnìkan tí ó gbàgbọ́ nínú agbára àwọn ońdè onídán àti àwọn oògùn oríire jọ̀wọ́ ìṣàkóso ìgbésí-ayé rẹ̀ fún àwọn agbára àìrí. Ó kọ ọgbọ́n ìrònú àti ìrònú sílẹ̀ ó sì juwọ́sílẹ̀ fún àwọn ìbẹ̀rù tí kò mọ́gbọ́ndání, tí wọ́n jẹ́ ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán.
Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli lè sọ ẹnìkan dòmìnira kúrò lọ́wọ́ irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀. Ó fihàn pé ońdè àti àwọn oògùn jẹ́ aláìlèṣiṣẹ́, aláìlágbára. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó dára, gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣe sọ, “àwọn ońdè ni a ronú pé wọ́n ń fa agbára láti inú ìsopọ̀ tí wọ́n ní àwọn ipá àdánidá [kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ìpá mìíràn] pẹ̀lú.” Àwọn agbára ìṣẹ̀dá wọ̀nyí lè jẹ́ ‘ẹ̀mí àwọn òkú’ tàbí ‘agbára oríire.’ Ṣùgbọ́n Bibeli fihàn ní kedere pé àwọn òkú “kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5) Nípa báyìí, kò sí ẹ̀mí àwọn òkú tí ó lè ṣèrànlọ́wọ́ tàbí ṣèpalára fún àwọn alààyè; bẹ́ẹ̀ ni kò sí agbára àìrí kankan bíi ti oríire tí ó lè ṣiṣẹ́ fún ọ.
Ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli, Ọlọrun dẹ́bi fún àwọn tí wọ́n ń fi í sílẹ̀, àwọn tí wọ́n ń gbàgbé òkè-ńlá mímọ́ rẹ̀, “tí ó pèsè tábìlì fún Gadi [“ọlọrun Oríire,” NW], tí ó sì fi ọrẹ mímu kún Meni [“ọlọrun Ayanmọ,” NW].” Dípò jíjèrè ààbò, àwọn alágbàwí oríire wọ̀nyẹn ni a fi lé ìparun lọ́wọ́. ‘Èmi ó sì kà yín fún idà,’ ni Jehofa Ọlọrun wí.—Isaiah 65:11, 12.
Nípasẹ̀ àwọn àṣà idán pípa, orílẹ̀-èdè Babiloni àtijọ́ gbàgbọ́ nínú ààbò àwọn agbára awo bákan náà. Ṣùgbọ́n Babiloni jìyà ìyọnu ìjábá bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀. “Máa báa lọ nínú iṣẹ́ àfọ̀ṣẹ rẹ àti iṣẹ́ àjẹ́ aláìbá ìwà ẹ̀dá mu rẹ,” ni ìpèníjà tí wòlíì Isaiah gbé dìde. “Bóyá ìwọ lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ wọn . . . Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀kọ́! lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀ ìwọ jẹ́ aláìlágbára.” (Isaiah 47:12, 13, The New English Bible) Bí àkókò ti ń lọ orílẹ̀-èdè yẹn pòórá pátápátá. Ìgbàgbọ́ nínú ohun ìjìnlẹ̀ awo ti di asán. Bákan náà, kò sí ońdè onídán, oògùn, tàbí oògùn ìṣọ́ra èyíkéyìí tí ó lè ṣe ohunkóhun láti ṣèrànlọ́wọ́ tàbí dáàbòbò ọ́.
Irú Oríṣi Ìbọ̀rìṣà Kan
Síbẹ̀, àwọn kan lè má rí ìpalára kankan nínú rírìn pẹ̀lú kristali, ẹsẹ̀ ehoro, tàbí àmì-ẹ̀yẹ ìsìn. Kìí ha wulẹ̀ ṣe ohun-ọ̀ṣọ́ aláìlèpanilára lásán ni ìwọ̀nyí bí? Kìí ṣe ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli. Ó sọ pé àwọn ohun-èèlò ìjìnlẹ̀ awo jẹ́ apanilára.
Lílo àwọn ońdè jẹ́ irú oríṣi ìbọ̀rìṣà kan—ohun kan tí a dálẹ́bi ní gbangba nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Eksodu 20:4, 5) Lótìítọ́, ẹnìkan lè má nímọ̀lára pé òun ń jọ́sìn ońdè tàbí oògùn ìṣọ́ra kan ní tààràtà. Ṣùgbọ́n kò ha fi ọ̀wọ̀, ìṣesí oníjọsìn hàn fún àwọn agbára ohun ìjìnlẹ̀ awo tí a kò lè rí bí ẹnikẹ́ni bá wulẹ̀ ní ọ̀kan bí? Kò ha sì jẹ́ òtítọ́ pé àfiyèsí oníjọsìn (irú bíi fífi tọ́ ẹnu) ni a sábà máa ń fún àwọn oògùn wọ̀nyẹn fúnraawọn bí? Síbẹ̀ Bibeli, nínú 1 Johannu 5:21, gba àwọn Kristian nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.” Èyí kì yóò ha ní àwọn ohun tí a fojúwò bí oògùn tàbí ońdè nínú bí?
Ìdẹkùn Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Awo
Nípasẹ̀ lílo ońdè, ọ̀pọ̀lọpọ̀ tún kó sínú ìdẹkùn ohun ìjìnlẹ̀ awo. Lótìítọ́, àwọn kan ń mú kristali tàbí oògùn onídán rìn nítorí pé ó jẹ́ àṣà ìbílẹ̀ tí kìí sìí ṣe nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tí ó dájú nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí títage pẹ̀lú aṣẹ́wó kan ṣe lè yọrísí kíkó àrùn AIDS, bẹ́ẹ̀ náà ni títage pẹ̀lú ohun ìjìnlẹ̀ awo pẹ̀lú lè ní àwọn àbájáde aṣèparun. Àwọn ìdí rere wà tí Ọlọrun fi dá àwọn ọmọ Israeli lẹ́kun idán pípa, àfọ̀ṣẹ, àti ìríransọtẹ́lẹ̀. “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLUWA,” ni Bibeli kìlọ̀.—Deuteronomi 18:10-14.
Kí ni ó fa ìkàléèwọ̀ mímúná yìí? Ìdí ni pé àwọn agbára àìrí tí ń bẹ lẹ́yìn irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ẹ̀mí àwọn òkú bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe agbára oríire ṣùgbọ́n Satani Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni.a Ìlò àwọn ońdè sì ní ìsopọ̀ tààràtà pẹ̀lú ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù. Ìwé atúmọ̀-èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé: “Nínú ìṣẹ́-àjẹ́, oògùn lílo, yálà èyí tí ó rọrùn tàbí èyí tí ó lágbára, ni ògèdè àti ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ sí àwọn agbára ohun ìjìnlẹ̀ awo máa ń bá rìn ní gbogbogbòò, pẹ̀lú ìpèsè onírúurú oògùn, ońdè, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Nítorí náà, ẹnìkan tí ó ní oògùn ohun ìjìnlẹ̀ awo kan lọ́wọ́ ń dọ́gbọ́n lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. Ó ń fi ara wewu dídi ẹni tí a mú wá sábẹ́ agbára ìdarí alájàálù-ibi àti ìdarí “ọlọ́run ayé yìí”—Satani Èṣù. (2 Korinti 4:4) Nítorí náà, pẹ̀lú ìdí rere ni Bibeli fi pàṣẹ fún wa láti yẹra fún gbogbo onírúurú ìbẹ́mìílò.—Galatia 5:19-21.
Jíjá Ẹ̀wọ̀n Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbéyọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ó ṣeéṣe kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ní ipa kan nínú ìgbésí-ayé níwọ̀n bí àwọn ènìyàn bá ti ń bẹ̀rù araawọn ẹnìkínní kejì tí wọ́n sì ń ní àwọn àìdánilójú nípa ọjọ́-iwájú.” Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti já ara wọn gbà kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí ó lè panilára. Obìnrin ọmọ South Africa kan padà rántí pé: “Àwọn ẹ̀mí èṣù yọ mí lẹ́nu, ilé mi sì kún fún muti láti dáàbòbò mí kúrò lọ́wọ́ wọn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ràn án lọ́wọ́ láti rí ewu tí ó wà nínú fífi ohun ìjìnlẹ̀ awo ṣeré. Kí ni ìdáhùnpadà rẹ̀? “Mo bẹ̀rẹ̀ síí da gbogbo ohun tí mo ní tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbẹ́mìílò nù,” ni ó wí. “Ìlera mi sunwọ̀n síi. Mo ya ìgbésí-ayé mi sí mímọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa mo sì ṣe ìrìbọmi.” Nísinsìnyí òun ti wà lómìnira kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìbẹ́mìílò.
Tún ṣàgbéyẹ̀wò adáhunṣe ọmọ Nigeria náà tí ó da ìbẹ́mìílò pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìwòsàn rẹ̀. Ó sábà máa ń lo ìhalẹ̀mọ́ni àti èpè, ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dànù kúrò ní ilé rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣe ìkésíni. Nígbà kan ó tilẹ̀ ṣe oògùn àkànṣe kan, ó pe ògèdè sórí rẹ̀, ó sì fẹ́ ẹ lu Ẹlẹ́rìí kan lójú! “Ní ọjọ́ méje òní ìwọ yóò kú!” ni ó pariwo. Ní ọjọ́ méje lẹ́yìn náà Ẹlẹ́rìí náà padà lọ, èyí tí ó mú kí adáhunṣe náà sá jáde, ní gbígbàgbọ́ pé òun ti rí iwin kan! Bí a ti tú àṣírí idán rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jámọ́ nǹkankan nísinsìnyí, ó gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli òun fúnraarẹ̀ sì di Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Ìwọ pẹ̀lú lè di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìbẹ̀rù àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. A gbà pé, èyí lè má rọrùn. Bóyá ìwọ ti dàgbà nínú àṣà ìbílẹ̀ kan níbi tí ìlò àwọn ońdè àti oògùn ti jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀. Àwọn Kristian ní Efesu ìgbàanì kojú irú ìpèníjà bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbé nínú àṣà ìbílẹ̀ kan tí ìbẹ́mìílò ní ipa lórí rẹ̀ lọ́nà rírinlẹ̀. Kí ni wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Bibeli sọ pé: “Kìí sìí ṣe díẹ̀ nínú àwọn tí ń ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn: wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìwọ̀n fàdákà.”—Iṣe 19:19.
Jíjèrè Ààbò Ọlọrun
Bí o bá kó gbogbo àwọn àmì awo kúrò ní sàkáání ọ̀dọ̀ rẹ, a kì yóò ha fi ọ́ sílẹ̀ láìsí ààbò bí? Kí á má rí i, “Ọlọrun ni ààbò wa àti agbára, lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.” (Orin Dafidi 46:1) Ààbò Ọlọrun yóò farahàn ní pàtàkì nígbà tí ó bá pa ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí run. “Oluwa mọ bí a tií yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a tií pa àwọn aláìṣòótọ́ tí a ń jẹ níyà mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́.”—2 Peteru 2:9; fiwé Orin Dafidi 37:40.
Bí àkókò ti ń lọ, ‘ìgbà àti èèṣì ń ṣe sí gbogbo wa.’ (Oniwasu 9:11) Ọlọrun kò ṣèlérí pé àwọn ìránṣẹ́ òun yóò gbé ìgbésí-ayé kan “tí a pamọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro” tàbí pé òun yóò fi asà bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìpalára ti ara-ẹni. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òun ṣèlérí láti dáàbòbo ipò tẹ̀mí wa àti ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú rẹ̀. (Orin Dafidi 91:1-9) Báwo? Fún ohun kan, òun fún wa ní àwọn òfin àti ìlànà tí ó lè ṣe wá láǹfààní kí ó sì dáàbòbò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ìdarí Satani tí ń sọnidìbàjẹ́. (Isaiah 48:17) Nípa jíjèrè ìmọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Jehofa, ‘ìmòye yóò pa wá mọ́, òye yóò sì máa ṣọ́ wa’—fún àpẹẹrẹ, kúrò lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò aláìlérè tàbí apanilára.—Owe 2:11.
Ọ̀nà mìíràn tí Ọlọrun ń gbà dáàbòbò wá jẹ́ nípa pípèsè “ọlá ńlá agbára” fún wa ní àwọn àkókò àdánwò. (2 Korinti 4:7) Nígbà tí ipò àwọn nǹkan bá sì dàbí èyí tí ó fẹ́ ṣíji bo Kristian kan mọ́lẹ̀, Òun ń fúnni ní “àlàáfíà Ọlọrun, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ” láti ṣọ́ ọkàn-àyà àti agbára èrò-orí. (Filippi 4:7) Bẹ́ẹ̀ni, Kristian wà ní ìmúratán láti “kọ ojú ìjà sí àrékérekè Èṣù.”—Efesu 6:11-13.
Báwo ni ìwọ ṣe lè jèrè irú ìdáàbòbò bẹ́ẹ̀? Bẹ̀rẹ̀ nípa gbígba ìmọ̀ Jehofa àti ti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi sínú. (Johannu 17:3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè ṣe púpọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọ̀nà yìí. Bí o ti ń mú ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa dàgbà, ìwọ yóò bẹ̀rẹ̀ síí nírìírí ìdáàbòbò onínúure rẹ̀. Ọlọrun sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní Orin Dafidi 91:14 pé: “Nítorí tí ó fẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ sí mi, nítorí náà ni èmi ó ṣe gbà á: èmi ó gbé e lékè, nítorí tí ó mọ orúkọ mi.”
Níti tòótọ́, bí ìwọ bá jẹ́ olùṣòtítọ́ sí i, Ọlọrun yóò bùkún fún ọ níkẹyìn pẹ̀lú ìyè ayérayé nínú ayé titun tí ń bọ̀. Jehofa fúnni ní ìdánilójú nípa àwọn wọnnì tí wọn yóò gbé ní àkókò yẹn: “Ẹnìkan kì yóò sì dáyà fò wọ́n: nítorí ẹnu Oluwa àwọn ọmọ-ogun ni o ti sọ ọ́.” (Mika 4:4) Àrùn àti ikú kì yóò sí mọ́. (Ìfihàn 21:4) Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí pàápàá ìwọ lè gbádùn ààbò dé ìwọ̀n ààyè kan—bí ìwọ bá mú ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jehofa. Bíi ti olórin náà, ìwọ yóò lè sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ mi ti ọwọ́ Oluwa wá, tí ó dá ọ̀run òun ayé.”—Orin Dafidi 121:2.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Kristian ní Efesu da gbogbo ohun tí ó tanmọ́ iṣẹ́ awo nù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun, ìbẹ̀rù kì yóò sí mọ́