Àwọn Oògùn Oríire Ha Lè Dáàbòbò Ọ́ Bí?
ÒKÚTA kristali kan nínu àpò ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Brazil kan. Owó-ẹyọ oríire ti asáré-ìje ọmọ America kan. Àgbélébùú Brigid Mímọ́ tí a fi kọ́ sára bẹ́ẹ̀dì nínú ilé ìdílé kan ní Ireland. Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ń lo irú àwọn ohun wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí oògùn oríire tàbí àwọn ońdè.a Wọ́n nígbàgbọ́ pé níní àwọn oògùn wọ̀nyí lọ́wọ́ lè taari ìpalára síwájú kí ó sì mú oríire wá fún wọn.
Fún àpẹẹrẹ, wo bí ọ̀ràn náà ti rí ní Brazil. Gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn náà Veja ti sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ará Brazil a máa rìn pẹ̀lú “èérún òkúta àti àwọn òkúta tí kò níyelórí tó òkúta iyebíye tí a kà sí èyí tí ó ní agbára láti fa oríire àtí àwọn agbára ṣíṣepàtàkì jùlọ wá fún ẹni tí ó ni wọ́n.” Nítorí ìbẹ̀rù láti máṣe fojú tín-ín-rín àwọn ohun ìjìnlẹ̀ awo, àwọn mìíràn ní ilẹ̀ yẹn fi ohun ìṣàpẹẹrẹ ìsìn tàbí àyọkà kan sí ara ògiri ilé wọn. Àwọn kan tilẹ̀ lo Bibeli gẹ́gẹ́ bí oògùn mímọ́ ọlọ́wọ̀; wọ́n ṣí i sílẹ̀ lórí tábìlì kan, sí Orin Dafidi 91 láì kìí pa á dé.
Ní àwọn ìhà gúúsú Africa, muti, tàbí oògùn ìbílẹ̀, ni a máa ń lò bákan náà, kìí wulẹ̀ ṣe nítorí àwọn èròjà amúniláradá inú rẹ̀ lásán ni, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ láburú. Àìsàn, ikú, àwọn àyídà ọ̀ràn-ìnáwó, àti eré-ìfẹ́rasọ́nà tí ó kùnà pàápàá ni a sábà máa ń ronú pé ó jẹ́ àbájáde èèdì láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá tàbí ìkùnà láti tu àwọn babańlá tí wọ́n ti kú lójú. Muti ni a sábà máa ń gbà lọ́wọ́ babaláwo ìgbèríko kan, ẹni tí yóò fi àwọn ewéko, igi, tàbí àwọn ẹ̀yà ara ẹranko ṣe oògùn. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fa àfiyèsí mọ́ra pé, agbára káká ni ìlò muti fi mọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ìgbèríko nìkan; àṣà náà tànkálẹ̀ ní àwọn ìlú-ńlá South Africa. Àwọn ọkùnrin oníṣòwò àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́gboyè yunifásitì wà lára àwọn tí wọn ń gbójúlé muti.
Ìwákiri náà fún oríire tún wọ́pọ̀ ní àwọn ilẹ̀ Europe. Ìwé náà Studies in Folklife Presented to Emyr Estyn Evans fi tó wa létí pé: “Ṣàṣà ni ṣọ́ọ̀ṣì àgbègbè tàbí ìlú kan ní Ireland nínú eyi tí a kò ní rí i kí wọn so pátákò ẹṣin mọ́ ara ilẹ̀kùn tàbí kí wọ́n fi kọ́ òkè àwọn ilé tí a ń gbé tàbí àwọn ilé kéékèèké tí a kọ́ sáàárín àwọn ilé ńlá.” Ohun tí ó tún wá wọ́pọ̀ káàkiri ní ibi gbogbo ní ilẹ̀ yẹn ni àwọn àgbélébùú tí a fi koríko etí odò ṣe èyí ti ń rọ̀ dirodiro lókè àwọn ibùsùn àti ilẹ̀kùn láti mú oríire wá. Àwọn alákìíyèsí sọ pé, lóréfèé, púpọ̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Ireland ń fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú irú àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn díẹ̀ ṣàìnáání wọn pátápátá.
Ìwákiri náà fún Ìdáàbòbò
Kí ni ohun tí irú ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán bẹ́ẹ̀ fi ń fanimọ́ra? Ó dàbí ẹni pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti kúnjú àìní ṣíṣekókó náà tí àwọn ènìyàn ní fún ààbò. Níti tòótọ́, àwọn mélòó ni wọ́n nímọ̀lára ààbò nínú ilé wọn, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìgbà tí wọ́n bá ń rìn ní àwọn òpópónà ní alẹ́? Ní àfikún sí ìyẹn tún ni pákáǹleke ti wíwá jíjẹ mímu àti bíbójútó àwọn ọmọ. Bẹ́ẹ̀ni, a ń gbé nínú ohun tí Bibeli pè ní “àkókò àwọn wàhálà.” (2 Timoteu 3:1, The New English Bible) Nítorí náà ó wulẹ̀ jẹ́ ìwà àdánidá pé kí àwọn ènìyàn ní ìfẹ́-ọkàn lílágbára fún ààbò.
Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan tí onírúurú ìbẹ́mìílò àti idán ti gbajúmọ̀. Ìbẹ̀rù àwọn ẹ̀mí tí a tànmọ́-ọ̀n pé ó jẹ́ ti òkú tàbí ti dídi òjìyà-ìpalára èpè ọ̀tá kan lè mú kí ààbò tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ oògùn tàbí ońdè kan dàbí èyí tí kòṣeémánìí. Gbogbo ẹ, gbògbò ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàkọsílẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn púpọ̀ ní àwọn ìbẹ̀rù tí ń mú kí wọ́n wà ní àìláàbò. Àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ṣèrànlọ́wọ́ láti borí irú àwọn ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ nípa pípèsè ààbò. Wọ́n ń ki àwọn ènìyàn láyà pé wọn yóò rí ohun tí wọ́n ń fẹ́ tí wọn yóò sì kòòré àbìlíì.”
Agbára Ońdè Amúniṣiyèméjì
Nípa báyìí, àwọn ońdè, oògùn ìṣọ́ra, àti oògùn tí wọ́n jẹ́ onírúurú àti oríṣiríṣi ni àwọn ènìyàn jákèjádò gbogbo ayé máa ń fi sára, mú rìn, ti wọ́n sì máa ń gbékọ́. Ṣùgbọ́n ó ha bọ́gbọ́nmu láti gbàgbọ́ pé oògùn tí ènìyàn ṣe lè pèsè ààbò gidi èyíkéyìí bí? Púpọ̀ lára àwọn ohun tí wọn máa ń lò jù gẹ́gẹ́ bí oògùn jẹ́ àwọn ìmújáde ìṣòwò tí a ṣe rẹpẹtẹ. Kò ha tako ọgbọ́n ìrònú àti làákàyè láti gbàgbọ́ pé ohun kan tí a tòpọ̀ nínú ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ kan lè ní agbára idán nínú bí? Àti pé oògùn kan tí babaláwo ìgbèríko kan ṣe lọ́nà àkànṣe kò ju àdàlù àwọn èròjà—gbòǹgbò, ewéko, àti irú bẹ́ẹ̀ lásán lọ. Èéṣe tí irú ohun tí a lú pọ̀ mọ́ra bẹ́ẹ̀ fi lè ní àwọn èròjà onídán nínú? Yàtọ̀ sí ìyẹn, ẹ̀rí gidi kan ha wà pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo ońdè ń wàláàyè fún àkókò pípẹ́ síi—tàbí wọ́n ha láyọ̀ lọ́nà èyíkéyìí—ju àwọn tí wọ́n kò lò ó bí? Àwọn tí wọ́n ń ṣe irú àwọn oògùn oríire onídán bẹ́ẹ̀ fúnraawọn kìí ha di ẹran-ìjẹ fún àìsàn àti ikú bí?
Dípò fífún àwọn ènìyàn ní ojúlówó ààbò àti ìmọ̀lára lílè ṣàkóso ìgbésí-ayé wọn, ìlò ońdè àti àwọn oògùn tí a lè gbékarí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ènìyàn níti gidi láti fi òye kojú àwọn ìṣòro wọn ó sì ń fún wọn ní ìṣírí láti yíjú sí oríire gẹ́gẹ́ bíi gbogboǹṣe. Níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára àwọn ońdè tún lè fún ẹni tí ń lò ó ní ìmọ̀lára tí kò tọ̀nà nípa ààbò. Ọkùnrin kan tí ó wà lábẹ ìdarí ọtí líle lè jiyàn pé agbára ìdáhùnpadà-iṣan àti agbára-ìṣe òun kò fàsẹ́hìn, ṣùgbọ́n bí ó bá gbìyànjú láti wakọ̀, ó ṣeéṣe kí ó mú ìpalára wá fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ẹlòmíràn. Ẹnìkan tí ó gbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ karí agbára ońdè bákan náà lè pa araarẹ̀ lára. Yóò sì máa ní òye ẹ̀tàn pé a ń dáàbòbo òun, a lè sún un láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ eléwu tàbí láti ṣe àwọn ìpinnu tí kò bọ́gbọ́nmu.
Ìgbàgbọ́ nínú agbára ońdè tún ń gbé àwọn ewu wíwúwo mìíràn tí wọ́n farasin fún àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lò wọ́n konilójú. Kí ni àwọn ewu wọ̀nyí, ọ̀nà kan tí ó bá ẹ̀tọ́ mu ha sì wà láti ṣèdíwọ́ fún ìpalára bí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò bójútó àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé atúmọ̀-èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary túmọ̀ “ońdè” sí “oògùn kan (bí ohun-ọ̀ṣọ́ kan) nínú èyí tí ọ̀rọ̀ ògèdè tàbí ohun ìṣàpẹẹrẹ kan sábà máa ń wà láti dáàbòbo ẹni tí ó wọ̀ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ibi (bíi àrùn tàbí àjẹ́) tàbí láti ràn án lọ́wọ́.”