ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Oògùn Oríire Ha Lè Dáàbòbò Ọ́ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Èéṣe Tí O Fi Níláti Gba Àṣìṣe?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìdáàbòbò Gidi Ha Ṣeéṣe Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • ‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ ha ti mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé bi? Ó dára, wò ó bí o bá le dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lẹ́ e yìí:

▫ Ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ wo ni a lè fifún àwọn aláìsàn àti àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ kan lónìí?

Nínú ìjọ Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, orúkọ àwọn opó tí wọ́n nílò ìtìlẹ́yìn nípa ti ara ní a kọsílẹ̀. (1 Timoteu 5:9, 10) Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà lè ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn aláìsàn àti àwọn àgbàlagbà tí wọ́n nílò àkànṣe àfiyèsí. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò níláti fi í sílẹ̀ fún àwọn alàgbà nìkan láti lo ìdánúṣe nínú ọ̀ràn yìí. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa irú àwọn àìní bẹ́ẹ̀. (1 Timoteu 5:4-8)—8/15, ojú-ìwé 28 sí 29.

▫ Ìtàn Bibeli nípa gbígbé tí ẹran inú òkun kan gbé Jona mì ha jẹ́ aláìṣeégbàgbọ́ bí?

Bẹ́ẹ̀kọ́, yálà ẹja àbùùbùtán ńlá kan, ekurá funfun títóbi kan tàbí ẹja ekurá gbígbórín kan lè gbé ènìyàn mì. Síwájú síi, Jesu fúnraarẹ̀ jẹ́rìí síi pé àkọsílẹ̀ nípa Jona jẹ́ òtítọ́. (Matteu 12:39, 40)—8/15, ojú-ìwé 32.

▫ Ìpalára wo ni ó ń ti ìdí fífi ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lo àwọn ońdè àti oògùn oríire jáde?

Lílò wọn níti gidi ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ènìyàn láti máṣe fi òye kojú àwọn ìṣòro wọn ó sì ń fún wọn ní ìṣírí láti yíjú sí oríire gẹ́gẹ́ bí ojútùú pátápátá. Wọ́n tún ń fún ẹni tí ń lò ó ní ìrònú èké ti wíwà láìléwu. Èyí tí ó léwu jù, ẹnì tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú agbára ońdè onídán àti àwọn oògùn oríire lè yọ̀ǹda ìwàláàyè rẹ̀ fún àwọn ipá ẹ̀mí-èṣù.—9/1, ojú-ìwé 4.

▫ Kí ní àwọn kókó ṣíṣepàtàkì mẹ́rin tí ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìgbéyàwó kan tọ́jọ́?

Ìwọ̀nyí ni ìmúratán láti fetísílẹ̀, agbára-ìṣe náà láti tọrọ àforíjì, agbára láti pèsè ìtìlẹ́yìn ti èrò-ìmọ̀lára tí ó ṣọ̀kan délẹ̀, àti ìfẹ́-ọkàn láti fọwọ́kanni lọ́nà ìfẹ́ni. (1 Korinti 13:4-8; Efesu 5:33; Jakọbu 1:19)—9/1, ojú-ìwé 20.

▫ Kí ní ọ̀nà kan tí Jehofa gbà ń pèsè ìfaradà fún àwọn tí wọ́n bá àdánwò pàdé?

Jehofa ń ṣe èyí nípasẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ ìfaradà tí a kọsílẹ̀ nínú Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Romu 15:4) Bí a ti ń ronú lórí ìwọ̀nyí, a fún wa ní ìṣírí láti faradà, a sì tún kọ́ púpọ̀ síi nípa bí a ṣe lè faradà.—9/15, ojú-ìwé 11 sí 12.

▫ Kí ni ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run?

Ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run tọ́kasí ìfọkànsìn sí Jehofa tí ó ń sún wa láti ṣe ohun tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn, àní lójú àwọn àdánwò tí ó ṣòro, nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun láti inú ọkàn-àyà wá.—9/15, ojú-ìwé 15.

▫ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àánú Ọlọrun?

A kò gbọdọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àánú Ọlọrun láé. O yẹ́ kí a dàbí Paulu kí a sì fi ìmọrírì wa hàn nípa jíjìjàkadì lòdìsí àwọn àìpé tiwa fúnraawa. (1 Korinti 9:27) Ní ọ̀nà yìí àwa yoo fihàn kedere, àní lójú àwọn ìṣòro, pé a ní ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ láti ṣe ohun ti ó tọ́.—10/1, ojú-ìwé 23.

▫ Èéṣe ti ó fi báamu pé Paulu ṣàkọsílẹ̀ ìpamọ́ra gẹ́gẹ́ bí apá àkọ́kọ́ ti ìfẹ́?

A ti sọ ọ́ pé kò lè sí irú nǹkan bí àjọṣe Kristian láìsí ìpamọ́ra, tàbí láìfi sùúrù faradà á fún araawa ní ẹnìkìn-ín-ní kejì. Èyí jẹ́ nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, àwọn àìpé àti àwọn àṣìṣe wa sì ń dán àwọn ẹlòmíràn wò. Nítorí náà, ìpamọ́ra ṣepàtàkì bí ìfẹ́ bá níláti wà láàárín àwọn ará.—10/15, ojú-ìwé 21.

▫ Ǹjẹ́ àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lo orúkọ Ọlọrun bí?

Ẹ̀rí sọ pé bẹ́ẹ̀ni. Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí Ọlọrun pé: “Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.” (Matteu 6:9) Ó sì gbàdúrà lẹ́yìn iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fifún mi láti inú ayé wá.” (Johannu 17:6) Ní àfikún síi, àwọn ẹ̀dà Septuagint àkọ́kọ́ ní orúkọ Ọlọrun ní ọ̀nà-ìṣètò ti Tetragrammaton èdè Heberu náà nínú.—11/1, oju-ìwé 30.

▫ Àwọn àpẹẹrẹ Bibeli wo ni ó fihàn pé ọwọ́ tí a fi ń mú àwọn àṣìṣe wa lè nípa lórí ìgbésí-ayé wa?

Ọba Saulu fi agídí kọ ìmọ̀ràn, àwọn àṣìṣe rẹ̀ sì di púpọ̀, tí ó wá jálẹ̀ sí ikú rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láìrí ojúrere Ọlọrun. (1 Samueli 15:17-29) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, láìka àwọn àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí, Ọba Dafidi fi ìrònúpìwàdà gba àtúnṣe ó sì ń báa lọ bí olùṣòtítọ́ sí Jehofa. Àwọn àpẹẹrẹ Bibeli wọ̀nyí fihàn pe gbígba àwọn àṣìṣe wa ń ràn wá lọ́wọ́ láti di ìdúró rere pẹ̀lú Ọlọrun mú àti nítorí náà kí a ní ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Orin Dafidi 32:1-5)—11/15, ojú-ìwé 29 sí 30.

▫ Bawo ni Jehofa ṣe ń ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú nítorí àwọn ìjábá ti ẹ̀dá tàbí àwọn okùnfà mìíràn?

Jehofa ń ṣèrànwọ́, kìí ṣe nípa dídá àwọn ipá ti ẹ̀dá padà lọ́nà ìyanu tàbí nípa àwọn ìṣe tí ó ju ti ẹ̀dá lọ mìíràn, ṣùgbọ́n nípa ipá mìíràn tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò lóye níti tòótọ́—ìfẹ́. Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ nítòótọ́, ó sì ti mú ìfẹ́ fún ẹnìkín-ín-ní kejì dàgbà láàárín wọn èyí tí ó lágbára débi pé òun lè ṣe ohun tí ó farahàn bí ìyanu fún wọn. (1 Johannu 4:10-12, 21)—12/1, ojú-ìwé 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́