Èéṣe Tí O Fi Níláti Gba Àṣìṣe?
Ọ̀KAN lára àwọn ohun tí kò wọ́pọ̀ jùlọ tí ènìyàn lè bá pàdé nínú ìtàn ológun ni. Ikọ̀ kan tí kò dira ogun dá irínwó ọmọ-ogun tí ìjà ti mú lọ́kàn yigbì tí wọ́n sì ti gbékútà láti gbẹ̀san ìwọ̀sí kan ti a fi lọ̀ wọ́n padà. Lẹ́yìn gbígbọ́ ìpàrọwà kìkì obìnrin onígboyà kanṣoṣo, aṣáájú àwọn ọmọ-ogun wọnnì pa iṣẹ́ ìdáwọ́lé rẹ̀ tì.
Aṣáájú náà ni Dafidi, ẹni tí ó wá di ọba Israeli lẹ́yìn náà. Ó fetísí obìnrin náà Abigaili nítorí pé ó fẹ́ láti tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn. Nígbà tí ó fi hàn án pẹ̀lú ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ pé gbígbẹ̀san lára ọkọ òun, Nabali, yóò yọrísí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Dafidi polongo pé: “Alábùkún fún Oluwa Ọlọrun Israeli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi. Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún fún sì ní ìwọ, tí o dá mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi.” Dafidi kún fún ìmoore pé Ọlọrun lo Abigaili láti dá òun dúró láti máṣe ṣe àṣìṣe wíwúwo.—1 Samueli 25:9-35.
Nínú orin kan, Dafidi béèrè pé: “Àṣìṣe—ta ni ó lè fòye mọ̀?” (Orin Dafidi 19:12, NW) Bíi tirẹ̀, àwa lè má mọ àwọn àṣìṣe wa àyàfi bí ẹnìkan bá fi wọ́n hàn wá. Ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn àwọn àbájáde tí kò dùnmọ́ni a máa sún wa láti mọ̀ pé a ti ṣàṣìṣe, hùwà àìlọ́gbọ́n, tàbí jẹ́ aláìnínúure.
Kò Sí Ìdí fún Àìnírètí
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni a ń ṣe àṣìṣe, ìwọ̀nyí kò níláti jẹ́ ìdí fún àìnírètí. Àṣojú Orílẹ̀-Èdè Edward John Phelps ṣàkíyèsí pé: “Ẹnìkan tí kò ṣe àṣìṣe kìí sábà ṣe ohunkóhun.” Kristian ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu sì sọ pé: “Nínú ohun pípọ̀ ni gbogbo wa ń ṣì í ṣe.” (Jakọbu 3:2) Ọmọdé kan yóò ha kọ́ láti rìn láìta gẹ̀ẹ́ gẹ̀ẹ́ láé bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, nítorí pé ọmọdé kan ń kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àṣìṣe tí yóò sì máa gbìyànjú nìṣó títí tí yóò fi lè dúró déédéé.
Láti gbé ìgbésí-ayé tí ó wà déédéé, àwa pẹ̀lú ni àìní wà fún láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe wa àti ìwọ̀nnì tí ó jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn. Níwọ̀n bí Bibeli ti ròyìn ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí àwọn àyíká-ipò wọn lè bá tiwa mu, a lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe irú àwọn àṣìṣe kan-náà tí wọ́n ṣe. Nígbà náà, ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú àwọn àṣìṣe wọn?
Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Ànímọ́ Ṣíṣekókó Kan
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan ni pé Ọlọrun kìí dẹ́bi fún gbogbo àwọn tí ń ṣe àṣìṣe ṣùgbọ́n ó ń ṣèdájọ́ fún kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n ń kọ̀ láti ṣàtúnṣe wọn bí ó bá ṣeéṣe. Ọba Saulu ti Israeli ṣàìgbọ́ràn sí àwọn ìtọ́ni Jehofa nípa ìparun àwọn ará Amaleki. Nígbà tí wòlíì Samueli kò ó lójú, Saulu kọ́kọ́ fojú kékeré mú àwọn ọ̀ràn tí ó sì gbìyànjú láti dẹ́bi fún àwọn ẹlòmíràn lẹ́yìn náà. Ó ṣàníyàn púpọ̀ jù nípa dídi ẹni tí a tẹ́lógo níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ ju kí ó mú àṣìṣe náà tọ́ lọ. Fún ìdí yìí, ‘Oluwa sì kọ̀ ọ́ ní ọba.’—1 Samueli 15:20-23, 30.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrọ́pò Saulu, Dafidi, ṣe àwọn àṣìṣe wíwúwo, a dáríjì í nítorí pé ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí. Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Dafidi sún un láti kọbiara sí àwọn ọ̀rọ̀ Abigaili. Ara àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ti wà lọ́nà fún ìjà. Síbẹ̀, níwájú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, Dafidi gbà pé òun ti fi ìwàǹwára ṣèpinnu. Jálẹ̀ ìgbésí-ayé rẹ̀, irú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bẹ́ẹ̀ ran Dafidi lọ́wọ́ láti wá ìdáríjì kí ó sì ṣàtúnṣe àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tún ń sún àwọn ìrańṣẹ́ Jehofa láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú. Lákòókò ìgbẹ́jọ́ kan níwájú àwọn Sanhedrin, àlùfáà àgbà pàṣẹ pé kí a gbá Paulu létí. Aposteli náà fèsìpadà pé: “Ọlọrun yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn ní ẹfun.” (Iṣe 23:3) Bóyá nítorí ìríran ojú tí kò dára tó, Paulu kò mọ ẹni tí òun ń sọ̀rọ̀ sí títí tí àwọn òǹwòran tí ń bẹ ní ìdúró fi béèrè pé: “Olórí àlùfáà Ọlọrun ni ìwọ ń gàn?” Kí ni ó gbọ́ bẹ́ẹ̀ sí, Paulu gba àṣìṣe rẹ̀ lójú-ẹsẹ̀, ní wíwí pé: “Ará, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ ní búburú.” (Iṣe 23:4, 5; Eksodu 22:28) Bẹ́ẹ̀ni, Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gba àṣìṣe rẹ̀.
Wọ́n Gba Àṣìṣe
Bibeli tún fihàn pé àwọn kan yí ọ̀nà ìgbàronú wọn tí ó ní àṣìṣe nínú padà. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ti Asafu olórin yẹ̀wò. Nítorí pé ó dàbí ẹni pé nǹkan ń ṣẹnuure fún àwọn ènìyàn burúkú, ó sọ pé: “Nítòótọ́ ní asán ni mo wẹ àyà mi mọ́.” Ṣùgbọ́n orí Asafu wálé lẹ́yìn lílọ sí ilé Jehofa àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn àǹfààní ìjọsìn mímọ́gaara. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gba àṣìṣe rẹ̀ ní Orin Dafidi 73.
Jona pẹ̀lú yọ̀ọ̀da ìrònú òdì láti ṣíji bo ojú-ìwòye rẹ̀. Lẹ́yìn wíwàásù ní Ninefe, ìdáláre ara rẹ̀ dípò dídá àwọn olùgbé ìlú-ńlá náà sí jẹ ẹ́ lọ́kàn. Kò dùn mọ́ Jona nínú nígbà tí Jehofa kò fìyà jẹ àwọn ará Ninefe láìbìkítà nípa ìrònúpìwàdà wọn, ṣùgbọ́n Ọlọrun tọ́ ọ sọ́nà. Jona wá mọ̀ pé ojú-ìwòye òun ní àṣìṣe nínú, nítorí pé ìwé Bibeli náà tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ fi àìlábòsí jẹ́wọ́ àṣìṣe rẹ̀.—Jona 3:10–4:11.
Bí ó ti fi àṣìṣe rò pé Jehofa Ọlọrun, kìí ṣe Satani Eṣu, ni ó ń fa ìdààmú òun, ọkùnrin náà Jobu gbìyànjú láti fẹ̀rí hàn pé àwọn ìjìyà òun kò tọ́ sí òun. Òun kò mọ̀ nípa ọ̀ràn àríyànjiyàn gíga jù náà: Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun yóò hà máa báa lọ ní jíjẹ́ adúróṣinṣin sí i lábẹ́ ìdánwò bí? (Jobu 1:9-12) Lẹ́yìn tí Elihu àti Jehofa ti ran Jobu lọ́wọ́ láti rí àṣìṣe rẹ̀, ó gbà pé: “Èmi . . . ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀ . . . Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà ṣe tótó nínú ekuru àti eérú.”—Jobu 42:3, 6.
Gbígba àṣìṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa ipò-ìbátan rere mọ́ pẹ̀lú Ọlọrun. Bí àwọn àpẹẹrẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nukàn tán yìí ti fihàn, òun kì yóò dá wa lẹ́bi fún àwọn àṣìṣe wa bí a bá gbà wọ́n tí a sì ṣe ohun tí a lè ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn ìrònú òdì, ọ̀rọ̀ aláìnírònú, tàbí àwọn ìgbésẹ̀ olóríkunkun. Báwo ni a ṣe lè fi ìmọ̀ yìí sílò?
Ṣíṣe Ohun kan Nípa Àwọn Àṣìṣe Wa
Fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gba àṣìṣe kan àti ṣíṣe ohun kan nípa rẹ̀ lè fún ìdè ìdílé lókun. Fún àpẹẹrẹ, bóyá nítorí ìdánilágara tàbí ìmúnibínú, òbí kan ti lè fi ìwàǹwára hàn nínú fífún ọmọ rẹ̀ ní ìbáwí. Kíkọ̀ láti tún àṣìṣe yìí ṣe lè ní àwọn ìyọrísí búburú. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe mú àwọn ọmọ yín bínú: ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.”—Efesu 6:4.
Kristian ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Paulu fi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà pè é padà sọ́kàn pé: “Dádì a máa tọrọ àforíjì nígbà gbogbo tí ó bá nímọ̀lára pé ohun tí ṣe àṣerégèé. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ láti bọ̀wọ̀ fún un.” Yálà ìtọrọ àforíjì jẹ́ ohun yíyẹ nínú ipò-ọ̀ràn pàtó kan jẹ́ ohun kan tí ẹnìkan gbọ́dọ̀ pinnu fúnraarẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìtọrọ àforíjì ni ìsapá onífọkànsí gbọ́dọ̀ tẹ̀lé láti yẹra fún irú àwọn àṣìṣe kan-náà ní ọjọ́-iwájú.
Kí ni bí ọkọ tàbí aya kan bá ṣe àṣìṣe tí ó fa ìdààmú? Fífí tòótọ́-tòótọ́ gba àṣìṣe náà, ìtọrọ àforíjì látọkànwá, àti ẹ̀mí ìdáríjini yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí wọ́n pa ipò-ìbátan onífẹ̀ẹ́ wọn mọ́. (Efesu 5:33; Kolosse 3:13) Jesús, ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Spain kan tí ó jẹ́ onínú-líle tí ó sì ti lé ní ẹni àádọ́ta ọdún, ni kò gbéraga jù láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ aya rẹ̀, Albina. “Ó jẹ́ àṣà wa láti máa tọrọ àforíjì nígbà tí a bá ṣẹ araawa,” ni òun sọ. “Èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìfẹ́ faradà á fún araawa.”
Nígbà tí Alàgbà kan Bá Ṣe Àṣìṣe
Gbígba àṣìṣe àti fífi òtítọ́-inú tọrọ àforíjì yóò tún ran àwọn Kristian alàgbà lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìṣọ̀kan kí wọ́n sì ‘máa fi ọlá fún araawọn.’ (Romu 12:10) Alàgbà kan lè lọ́ra láti gba àṣìṣe nítorí pé ẹ̀rù ń bà á pé èyí yóò jin ọlá-àṣẹ òun lẹ́sẹ̀ nínú ìjọ. Bí ó ti wù kí ó rí, gbígbìyànjú láti dáre fún, fojútín-ín-rín, tàbí fọwọ́ kékeré mú àṣìṣe kan ni ó ṣeéṣe jùlọ pé yóò mú kí àwọn ẹlòmíràn sọ ìgbẹ́kẹ̀lé nù nínú àbójútó rẹ̀. Arákùnrin kan tí ó dàgbàdénú tí ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tọrọ àforíjì, bóyà fún àwọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú kan, ń jèrè ọ̀wọ̀ àwọn ẹ̀lòmíràn.
Fernando, alàgbà kan ní Spain, pe àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan padà sọ́kàn nígbà tí alábòójútó àyíká kan tí ń ṣàbójútó ìpéjọpọ̀ ńlá ti àwọn alàgbà kan sọ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ kan tí kò tọ̀nà nípa bí ó ṣe yẹ kí a darí ìpàdé kan. Nígbà tí alàgbà kan fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàtúnṣe ohun tí ó ti sọ, alábòójútó àyíká náà gbà lójú-ẹsẹ̀ pé ohun ti ṣe àṣìṣe. Fernando pè é padà sọ́kàn pé: “Nígbà tí mo rí i pé ó gba àṣìṣe rẹ̀ níwájú gbogbo àwọn alàgbà wọnnì, ó wú mi lórí gidigidi. Mo túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún un lọ́pọ̀lọpọ̀ síi lẹ́yìn ìtọrọ àforíjì náà. Àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ mi bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti mọ àwọn àìdójú-ìwọ̀n mi.”
Yára Láti Gba Àṣìṣe
Ìtọrọ-àforíjì ni a sábà máa ń mọrírì, pàápàá jùlọ bí a bá tètè tọrọ rẹ̀. Nítòótọ́, bí a bá ti tètè gba àṣìṣe kan tó ní ọ̀ràn yóò ti túbọ̀ dára tó. Láti ṣàkàwé: Ní October 31, 1992, Poopu John Paul Kejì gbà pé Àjọ Aṣèwádìígbógunti Àdámọ̀ ti “fi àṣìṣe” gbégbèésẹ̀ ní ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn fún fífìyàjẹ Galileo fún fífi ìtẹnumọ́ kéde pé ilẹ̀-ayé kìí ṣe àárín-gbùngbùn àgbáálá-ayé. Síbẹ̀, sísún ìtọrọ àforíjì kán síwájú fún àkókò gígùn kan bẹ́ẹ̀ dàbí èyí tí ó dín ìníyelórí rẹ̀ kù.
Ohun kan-náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nínú ipò-ìbátan ara-ẹni. Títètè tọrọ àforíjì lè wo ọgbẹ́ tí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe aláìnínúure ti jẹ́ okùnfà fún sàn. Jesu gbà wá níyànjú láti máṣe fi wíwá alááfíà falẹ̀, ní wíwí pé: “Bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá sí ibi pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé, arákùnrin rẹ ní ohun kan nínú sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, sì lọ, kọ́ bá arákùnrin rẹ̀ làjà ná, nígbà náà ni kí o tó wá íbun ẹ̀bùn rẹ̀.” (Matteu 5:23, 24) Lọ́pọ̀ ìgbà, mímú ipò-ìbátan alálàáfíà padàbọ̀sípò wulẹ̀ béèrè fún gbígbà pé a ti fọwọ́ mú àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí kò tọ́ kí á sì tọrọ àforíjì. Bí a bá ṣe dúró pẹ́ tó láti ṣe èyí, bẹ́ẹ̀ ní yóò ṣe nira tó.
Wọ́n Láyọ̀ Láti Gba Àṣìṣe
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Saulu àti Dafidi ti ṣàkàwé, ọ̀nà tí a gbà ń bójútó àwọn àṣìṣe wa lè nípa lórí ìgbésí-ayé wa. Saulu fi agídí-ọkàn kọ ìbáwí, àwọn àṣìṣe rẹ̀ sì di púpọ̀, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ó parí sí ikú rẹ̀ láìrójúrere Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka àwọn àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ Dafidi sí, ó fi ìrònúpìwàdà gba ìtọ́sọ́nà ó sì ń bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jehofa nìṣó. (Fiwé Orin Dafidi 32:3-5.) Ìyẹn kò ha jẹ́ ìfẹ́-ọkàn wa bí?
Èrè títóbi jùlọ fún gbígbà àti ṣíṣàtúnṣe àṣìṣe kan tàbí ríronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ni mímọ̀ pé Ọlọrun ti dárí rẹ̀ jì. “Ìbùkún ni fún àwọn . . . tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀,” ni Dafidi sọ. “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Oluwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.” (Orin Dafidi 32:1, 2) Ó ti bọ́gbọ́nmu tó, nígbà náà, láti gba àṣìṣe!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọmọdé kan yóò ha kọ́ láti rìn láìta gẹ̀ẹ́ gẹ̀ẹ́ láé bí?