ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 9/1 ojú ìwé 8-9
  • Gileadi—Ẹkùn-Ilẹ̀ fún Àwọn Ènìyàn Onígboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gileadi—Ẹkùn-Ilẹ̀ fún Àwọn Ènìyàn Onígboyà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́fútà Mú Ẹ̀jẹ́ Tó Jẹ́ Fún Jèhófà Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Ará Ammoni Àwọn Afibi-San-Oore
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìdarí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Sọ́ọ̀lù—ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 9/1 ojú ìwé 8-9

Àwọn Ìrísí-i̇̀ran Láti Ilẹ̀ Ìlérí

Gileadi—Ẹkùn-Ilẹ̀ fún Àwọn Ènìyàn Onígboyà

NÍ ÀKÓKÒ díẹ̀ ṣáájú kí Israeli tó ṣọdá Odò Jordani bọ́ sínú Ilẹ̀ Ìlérí, Mose rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ ṣe gírí ki ẹ sì mú àyà le. . . . OLUWA Ọlọrun rẹ, òun ni ó ń bá ọ lọ.”—Deuteronomi 31:6.

Ẹ̀yà Reubeni àti Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase wà nínú àwọn tí Mose gbàníyànjú. Wọ́n ti ríi ‘pé ilẹ̀ Gileadi jẹ́ ilẹ̀ fún ohun ọ̀sìn,’ nítorí náà wọ́n ti níláti béèrè pé kí a yàn fún wọn láti gbé ní ẹkùn-ilẹ̀ Gileadi.—Numeri 32:1-40.

Gileadi wà ní òdìkejì, ìhà ìlà-oòrùn, Jordani. Ó jẹ́ bí ó ti yẹ kí ó rí gan-an ní gbogbo ìhà ìlà-oòrùn pátápátá, láti ìpẹ̀kun ìhà àríwá Òkun Òkú títí dé Òkun Galili. Ẹkùn-ilẹ̀ yii ga sókè láti Àfonífojì Jordani wá títí lọ dé ibi àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírin gbingbin àti àwọn òkè-kéékèèké rìbìtì rìbìtì. Nítorí náà Gileadi jẹ́ ẹkùn-ilẹ̀ dáradára mímú àwọn ẹran-ọsìn jẹko. Àwòrán tí ó wà lókè yìí fún ọ ní èrò nípa bí apákan Gileadi ti rí. Ṣùgbọ́n èéṣe tí a fi so ìgboyà pọ̀ mọ́ irú àgbègbè gbígbádùnmọ́ni dé ìwọ̀n ààyè kan yìí?

Ó hàn gbangba pé àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yàn láti gbé ní Gileadi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù. Rántí pé wọ́n gbà láti sọdá Jordani láti bá àwọn ọ̀tá ní Ilẹ̀ Ìlérí náà jà. Nígbà tí wọn sì padà sí Gileadi, wọ́n nílò ìgboyà púpọ̀ síi. Èéṣe? Ó dára, wọ́n wà ní ààlà ilẹ̀, wọ́n dojúkọ àtakò láti ọwọ́ àwọn ará Amoni ní ìhà gúúsù ìlà-oòrùn àti àwọn ará Siria ní ìhà àríwá. Wọ́n sì gbéjà kò wọ́n níti gidi.—Joṣua 22:9; Onidajọ 10:7, 8; 1 Samueli 11:1; 2 Ọba 8:28; 9:14; 10:32, 33.

Àwọn ìgbéjàkò wọ̀nyẹn jẹ́ àwọn àkókò pàtó nígbà tí wọ́n nílò ìgboyà. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jehofa ti jẹ́ kí àwọn ará Amoni pọ́n Gileadi lójú, àwọn ènìyàn Ọlọrun ronúpìwàdà wọ́n sì yíjú sí “akọni ọkùnrin” kan fún ipò aṣíwájú, ẹni tí orúkọ baba rẹ̀ pẹ̀lú ń jẹ́ Gileadi. Akọni, tàbí onìgboyà ọkùnrin yii ni Jefta. A mọ̀ ọ́n dáradára fún ìbúra kan ti o fihàn pé, bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ onígboyà, ó wá ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn Ọlọrun. Jefta jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí Ọlọrun ba jẹ́ ki òun borí àwọn apọ́nnilójú ará Amoni náà, ẹni àkọ́kọ́ tí ó bá ti ilé òun jáde wá láti pàdé òun ni ‘a o fi rú ẹbọ sísun,’ tàbí fi rúbọ, sí Ọlọrun.a Ìyẹn wá jẹ́ ọmọ Jefta kanṣoṣo náà, ọmọbìnrin rẹ̀, ẹni tí ó lọ níkẹyìn láti ṣiṣẹ́sìn ní ibi ìjọsìn Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ni, Jefta àti, ní ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀, ọmọbìnrin rẹ̀, fi ìgboyà hàn.—Onidajọ 11:1, 4-40.

Ìfìgboyà hàn tí ó lè dàbí èyí tí a kò mọ̀ dáradára ṣẹlẹ̀ ní àkókò Saulu. Láti lóye ipò tí ó yí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ká, rántí pé nígbà tí Saulu di ọba, àwọn ará Amoni ṣe kùkùfẹ̀fẹ̀ pé àwọn yóò yọ ojú ọ̀tún àwọn ọkùnrin Jabeṣi-Gileadi, ìlú tí ó lè ṣeéṣe pé ó wà ni ojú-àyè jíjinnú tí ó la àárín àwọn òkè kéékèèké kọjá lọ sí Jordani. Saulu yára kó àwọn ọmọ-ogun jọ láti sọ Jabeṣi di alágbára. (1 Samueli 11:1-11) Pẹ̀lú ipò àtilẹ̀wá yẹn lọ́kàn, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òpin ìṣàkósò Saulu kí á sì wo bí ó ṣe fi ìgboyà hàn.

Ìwọ lè rántí pé Saulu àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kú lákòókò ogun kan pẹ̀lú àwọn ará Filistini. Àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn gé orí Saulu wọ́n sì fi pẹ̀lú ìjagunmólú gbé òkú Saulu àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí ògiri Betṣani. (1 Samueli 31:1-10; ní apá ọ̀tún, ìwọ yóò rí òkìtì Betṣani ti a hú jáde.) Ọ̀rọ̀ yii dé Jabeṣi, lórí àwọn òkè kéékèèké Gileadi ní òdìkejì Jordani. Kí ni àwọn ará Gileadi lè ṣe lójú ọ̀tá kan tí ó lágbára débi pé ó lè borí ọba Israeli?

Wo àwòrán ilẹ̀ náà láti ṣàkíyèsí ọ̀nà tí àwọn ará Gileadi gbà. “Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Saulu, àti òkú àwọn ọmọbíbí rẹ̀ kúrò lára odi Betṣani, wọ́n sì wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.” (1 Samueli 31:12) Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n ṣe sùnmọ̀mí òru lọ sínú odi agbára àwọn ọ̀tá náà. Ìwọ lè lóye ìdí tí Bibeli fi pè wọ́n ní akọni, tàbí onìgboyà.

Bí àkókò ti ń lọ, ẹ̀yà mẹ́wàá yapa láti parapọ̀ di ìjọba ìhà àríwá Israeli, èyí sì ní àwọn ará Gileadi nínú. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, lákọ̀ọ́kọ́ Siria àti lẹ́yìn náà Assiria, bẹ̀rẹ̀ síí gba àwọn apákan ìpínlẹ̀ náà ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Nítorí náà, lójú àwọn àpẹẹrẹ ìgboyà tí ó ti kọjá, àwọn ènìyàn Gileadi san iye owo kan fún wíwà ní ibi ààlà-ilẹ̀.—1 Ọba 22:1-3; 2 Ọba 15:29.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà pẹlú ìṣọ́ra mú ẹ̀sùn náà pé Jefta fi ọmọ rẹ̀ rúbọ ní elékèé. Wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ 2, ojú-ìwé 27 sí 28, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÒKUN GALILI

ÒKUN ÒKÚ

Odò Jordani

Betṣani

Ramoti-Gileadi

Jabeṣi

GILEADI

[Credit Line]

A gbé e karí àwòrán-ilẹ̀ kan tí Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. àti Survey of Israel ní ẹ̀tọ́ ìpamọ́-fisúra rẹ̀.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́