ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/1 ojú ìwé 26-31
  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìdarí Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìdarí Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Títún Góńgó Mi Nínú Ìgbésí Ayé Ṣe
  • Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Níye Lórí Gẹ́gẹ́ Bí Aṣáájú Ọ̀nà
  • Yíyọ̀ǹda Ara Wa fún Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílẹ̀-Èdè Mìíràn
  • Láàárín Ìlú Washington àti Gilead
  • Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílé Iṣẹ́ Àgbáyé
  • Mo Di Ọ̀kan Lára Àwọn Olùkọ́ Gilead
  • Bíbá Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣiṣẹ́
  • Wíwo Ọjọ́ Iwájú
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Èèyàn Ń Jàǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Kárí Ayé
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Látorí Akẹ́kọ̀ọ́ Aláṣeyọrí Sórí Mísọ́nnárì Aláṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/1 ojú ìwé 26-31

Fífi Tayọ̀tayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ìdarí Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ ULYSSES V. GLASS ṢE SỌ Ọ́

Àṣeyẹ àrà ọ̀tọ̀ gbáà ló jẹ́. Àwọn mẹ́tàdínláàádóje [127] péré ni akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú gbọ̀ngàn ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, ṣùgbọ́n ẹgbàá mẹ́tàlélọ́gọ́ta àti irínwó dín mẹ́tàlá [126,387] ènìyàn tára wọ́n yá gágá, tí wọ́n wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wà pẹ̀lú wọn níbẹ̀. Ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kọkànlélógún Watchtower Bible School of Gilead ni, èyí táa ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York City ní July 19, 1953. Èé ṣe tí ìyẹn fi jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi? Jẹ́ kí n ṣàlàyé díẹ̀ nípa bó ṣe bẹ̀rẹ̀.

WỌ́N bí mi ní Vincennes, Indiana, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ní February 17, 1912, nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìbí Ìjọba Mèsáyà, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ nínú Ìṣípayá 12:1-5. Ọdún tó ṣáájú rẹ̀ ni àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìdìpọ̀ Studies in the Scriptures ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní àràárọ̀ Sunday, Bàbá á ka ọ̀kan nínú àwọn ìwé wọ̀nyẹn, a ó sì jíròrò nípa rẹ̀.

Màmá ń fi àwọn ohun tó ń kọ́ tọ́ ìrònú àwa ọmọ rẹ̀. Ó ṣèèyàn gan-an—ó jẹ́ onínúure, ó sì máa ń fẹ́ láti ṣèrànwọ́. Mẹ́rin làwa táa jẹ́ ọmọ rẹ̀, àmọ́, Màmá tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ tó wà ládùúgbò pẹ̀lú. Ó máa ń lo àkókò pẹ̀lú wa. Ó máa ń gbádùn sísọ ìtàn Bíbélì fún wa àti kó máa bá wa kọrin.

Ó tún máa ń pe àwọn tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wá sílé wa. Ọjọ́ kan tàbí méjì péré ni wọ́n máa ń lò, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ṣe ìpàdé, tí wọ́n sì ń sọ àwíyé nílé wa. Àwọn táa máa ń fẹ́ràn jù lọ làwọn tó bá ń lo àpèjúwe, tí wọ́n sì ń sọ ìtàn fún wa. Ní àkókò kan ní 1919, nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, arákùnrin tó bẹ̀ wá wò darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwa ọmọdé ní pàtàkì. Ó jíròrò ìyàsọ́tọ̀—ìyẹn ni ohun tí a wá ń pè ní ìyàsímímọ́ báyìí—ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe kan ìgbésí ayé wa. Nígbà tí mo dórí ibùsùn mi lálẹ́ ọjọ́ yẹn, mo gbàdúrà sí Baba mi lọ́run pé mo fẹ́ máa sìn ín títí lọ.

Àmọ́, lẹ́yìn 1922, àwọn àníyàn mìíràn nínú ìgbésí ayé wá bo ìpinnu yẹn mọ́lẹ̀. A ń kó láti ibí kan lọ sí ibòmíràn, a kò sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn ènìyàn Jèhófà kankan. Iṣẹ́ rélùwéè tí Bàbá ń ṣe mú kó filé sílẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa kò lọ déédéé mọ́. Mò ń lọ sílé ẹ̀kọ́ pẹ̀lú èrò àtidi apolówó ọjà, mo sì ń pinnu àtilọ si yunifásítì tó lókìkí.

Títún Góńgó Mi Nínú Ìgbésí Ayé Ṣe

Láàárín àwọn ọdún 1930, ogun kan tó kárí ayé tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Cleveland, Ohio, là ń gbé nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wa. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa ohun táa kọ́ nígbà táa wà lọ́mọdé. Russell, ẹ̀gbọ́n mi, ló múra sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ jù, òun ló sì kọ́kọ́ ṣe ìrìbọmi. Èmi ló kọ́kọ́ fẹ́ dà bí ajá ti yóò sọ nù tí kì í gbọ́ fèrè ọdẹ, ṣùgbọ́n nígba tó di February 3, 1936, mo ṣe ìrìbọmi. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí i mọrírì ohun tí ìyàsímímọ́ sí Jèhófà túmọ̀ sí gan-an, mo sì ń kọ́ bí n óò ṣe máa tẹ́wọ́ gba ìdarí Jèhófà. Ọdún yẹn kan náà ni Kathryn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti Gertrude, àbúrò mi obìnrin, ṣe ìrìbọmi. Ni gbogbo wa bá wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.

Bó ti wù kó rí, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé a kì í ronú nípa nǹkan mìíràn. Ṣe ni mo ṣetí gee nígbà tí ìyàwó ẹ̀gbọ́n mi sọ fún mi nípa arẹwà ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ann, ẹni tí “inú rẹ̀ dùn gan-an” nígbà tó gbọ́ nípa òtítọ́, tó sì jẹ́ pé ilé wa ni yóò ti wá máa ṣe ìpàdé. Ọ́fíìsì amòfin kan ni Ann ti ń ṣe akọ̀wé lákòókò yẹn, ó sì ṣe ìrìbọmi láàárín ọdún kan. N kò tí ì ronú nípa ìgbéyàwó rárá, àmọ́, ó hàn kedere pé Ann tí fara rẹ̀ fún òtítọ́ pátápátá. Ó fẹ́ fara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Kò jẹ́ sọ láé pé, “Ṣé máa lè ṣe é? Dípò bẹ́ẹ̀, á béèrè pé, “Ọ̀nà wo ló dára jù fún mi láti gbà ṣe é?” Ó sì múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Ojú ìwòye àìṣiyèméjì tó ní yẹn fà mí lọ́kan mọ́ra. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọbìnrin náà dára bí egbin, ẹwà rẹ̀ kò sì ṣá di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yí. Ó di ìyàwó mi, kò sì pẹ́ táa fi jọ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀.

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Níye Lórí Gẹ́gẹ́ Bí Aṣáájú Ọ̀nà

Gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, a kọ́ àṣírí bí a ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nígbà tí a bá ní àwọn ìpèsè bín-ín-tín àti nígbà tí a bá ní ọ̀pọ̀ yanturu. (Fílípì 4:11-13) Ó ti ń lọ sí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ kan, kò sì sí nǹkan táa fẹ́ jẹ. Sẹ́ǹtì márùn-ún péré lowó táa ní. A wá lọ síbi tí wọ́n ti ń ta ẹran, a sì bi ẹlẹ́ran pé: “Ǹjẹ́ o lè ta ẹran sísun onísẹ́ǹtì márùn-ún fún wa”? Ó wò wá, ó sì gé ègé mẹ́rin fún wa. Ó dá mi lójú pé ẹran náà ju onísẹ́ǹtì márùn-ún lọ, ìyẹn sì fún wa lókun díẹ̀.

Kì í ṣe ohun àjèjì láti dojú kọ àtakò líle koko lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ojú pópó la wà ní ìlú kan nítòsí Syracuse, New York, tí a ń pín ìwé ìléwọ́ tí a sì gbé bébà tí a kọ nǹkan sí kọ́rùn láti fi pe àfiyèsí sí ìpàdé àkànṣe kan fún gbogbo ènìyàn. Ni ìgìrìpá méjì bá dì mí mú, wọ́n sì ṣe mí ṣúkaṣùka. Ọ̀gá ọlọ́pàá ni ọ̀kan nínú wọn, ṣùgbọ́n kò wọṣọ iṣẹ́, ó sì kọ̀ láti fi ìwé ìdánimọ̀ rẹ̀ hàn mí. Ojú ẹsẹ̀ ni Grant Suiter láti Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn dé tó sọ pé ká lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá. Ìgbà yẹn ló tẹ ọ́fíìsì Society ní Brooklyn, láago, ni wọ́n bá sọ pé kí èmi àti ìyàwó mi jáde sójú pópó lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́jọ́ yẹn gan-an, ká kó ìwé ìléwọ́ dání, ká sì gbé bébà táa kọ nǹkan sí náà kọ́rùn láti lè fi ìyẹn pẹjọ́. Báa ṣe retí pé ó máa rí, wọ́n kó wa. Àmọ́, nígbà táa sọ fún ọlọ́pàá náà pé a ó pè wọ́n lẹ́jọ́ fún mímú wa láìbófinmu, wọ́n fi wá sílẹ̀.

Lọ́jọ́ kejì, àwọn ọ̀dọ́langba kan tí wọ́n ya ewèlè dà bo gbọ̀ngàn táa wà, àlùfáà kan ló dẹ wọ́n sí wa, kò sì sí ọlọ́pàá kankan nítòsí. Ni àwọn ọmọọ̀ta wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí fi igi tí wọ́n fi ń gbá baseball lu ilẹ̀ gbàgbààgbà, pákó sì la fi ṣe ilẹ̀ náà, wọ́n ti àwọn kan lára àwọn èrò ṣubú lórí pákó tí wọ́n jókòó lé, wọ́n gorí pèpéle, níbi tí wọ́n ti gbé àsíá kan tó jẹ́ ti Amẹ́ríkà sókè, tí wọ́n wá ń pariwo pé, “Ẹ kí i! Ẹ kí i!” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin “Beer Barrel Polka.” Wọ́n da ìpàdé yẹn rú pátápátá. A rí ohun tí Jésù ní lọ́kàn lójúkojú, nígbà tó sọ pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòhánù 15:19.

Ní gidi, inú àwíyé kan tí J. F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, sọ lá ti ṣàdàkọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà. Èmi àti Ann dúró sí ìlú yẹn fún ọjọ́ díẹ̀ tí a ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn láti fún wọn láǹfààní àtigbọ́ ọ̀rọ̀ náà nílé wọn. Àwọn díẹ̀ tẹ́wọ́ gbà á.

Yíyọ̀ǹda Ara Wa fún Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílẹ̀-Èdè Mìíràn

Bí àkókò ti ń lọ, àwọn àǹfààní tuntun wá ṣí sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n pé ẹ̀gbọ́n mi Russell àti Dorothy ìyàwó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya sí kíláàsì kìíní ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ní 1943, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n rán wọn lọ sí Cuba láti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Kathryn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin náà wà ní kíláàsì kẹrin. Wọ́n rán òun náà lọ sí Cuba. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n tún rán an lọ sí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Dominican, kí wọ́n tó wá rán an lọ sí Puerto Rico. Èmi àti Ann wá ńkọ́?

Nígbà táa gbọ́ nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead àti pé Society ń wá àwọn míṣọ́nnárì láti rán lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, a gbà pé a óò yọ̀ǹda ara wa láti sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn. Lákọ̀ọ́kọ́, a ronú pé ká dá lọ fúnra wa, bóyá sí Mexico. Àmọ́, a wá pinnu pé yóò dára ká kúkú dúró kí Society lè rán wa lọ lẹ́yìn táa bá lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead. A rí i pé ìyẹn ni ìṣètò tí Jèhófà ń lò.

Wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹrin Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead. Àmọ́, nígbà tó kù díẹ̀ kí kíláàsì náà bẹ̀rẹ̀, N. H. Knorr, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society lákòókò yẹn, wá mọ̀ nípa àìlera tí Ann ní nítorí àìsàn rọpárọsẹ̀ tó ṣe é nígbà tó wà lọ́mọdé. Ó bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó sì pinnu pé kò ní í bọ́gbọ́n mu láti rán wa lọ sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn.

Nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, níbi tí mo tí ń ṣe iṣẹ́ ìmúrasílẹ̀ de àpéjọpọ̀ àgbègbè, Arákùnrin Knorr tún rí mi, ó sì béèrè bóyá ó ṣì wù wá láti lọ sí Gilead. Ó sọ fún mi pé a kò ní lọ ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè mìíràn; pé òun ní ohun mìíràn lọ́kàn fún wa. Nítorí náà, nígbà tí kíláàsì kẹsàn-án forúkọ sílẹ̀ ní February 26, 1947, a wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

A kò lè gbàgbé bí Gilead ṣe rí láyé ọjọ́un láé. Àwọn ẹ̀kọ́ náà dọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí. A bá àwọn kan pàdé níbẹ̀, tí ọ̀rẹ́ wa ò já títí dòní. Ṣùgbọ́n ipa tí mo kó nílé ẹ̀kọ́ náà ju ìyẹn lọ fíìfíì.

Láàárín Ìlú Washington àti Gilead

Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead sì jẹ́ tuntun nígbà náà. Ète ilé ẹ̀kọ́ náà kò tí i fi bẹ́ẹ̀ yé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, nítorí náà ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni wọ́n ń gbé dìde. Society sì fẹ́ ní aṣojú kan ní Washington, D.C. Ibẹ̀ ni wọ́n rán wa lọ lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gilead. Mo ní láti ṣèrànwọ́ àtigba àṣẹ ìwọ̀lú fún àwọn tí wọ́n bá pè sí Gilead láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí n sì gba ìwé ìrìnnà fún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege kí a lè rán wọn lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àwọn kan lára àwọn aláṣẹ náà jẹ́ onínúure, wọ́n sì ṣèrànwọ́. Àwọn mìíràn kì í tiẹ̀ fẹ́ rí Ẹlẹ́rìí sójú. Àwọn díẹ̀ tí ẹ̀mí òṣèlú ń yọ lẹ́nu sọ kedere pé a ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọ̀daràn kan táwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí.

Ọkùnrin kan tí mo lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀ lòdì sí wa gan-an nítorí pé a kì í kí àsíá tàbí ká lọ jagun. Lẹ́yìn tó pariwo nípa ìyẹn fún ìgbà díẹ̀, mo wá sọ pé: “Mo fẹ́ kóo mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bá ẹnikẹ́ni nínú ayé jagun, ó sì dá mi lójú pé o mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àwa kì í lọ́wọ́ nínú àwọn àlámọ̀rí ayé. A kì í lọ́wọ́ nínú ogun wọn, àti ìṣèlú wọn. Aláìdásí-tọ̀tún-tòsì pátápátá ni wá. Àwa ti borí ìṣòro tẹ́ẹ dojú kọ; a ní ìṣọ̀kan nínú ètò wa. . . . Kí lo wá fẹ́ ká ṣe báyìí? Ṣé o fẹ́ ká padà sórí ọ̀nà tí ẹ gbà ń ṣe nǹkan ni, ká sì fi tiwa sílẹ̀?” Kò gbin mọ́.

Odindi ọjọ́ méjì gbáko nínú ọ̀sẹ̀ la yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ tí mo lọ ń ṣe láwọn ọ́fíìsì ìjọba. Láfikún sí ìyẹn, a tún ń sìn bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Láyé ìgbà yẹn, wákàtí márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] la máa ń ní lóṣooṣù (ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló di ogóje wákàtí), nítorí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn títí di alẹ́. A gbádùn rẹ̀ gan-an ni. Ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó gbámúṣé là ń bá àwọn ìdílé lódindi ṣe, wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Èmi àti Ann ti pinnu pé a kò ní bímọ, àmọ́ táa bá sọ ọ́ nípa tẹ̀mí, kì í ṣe àwọn ọmọ nìkan la ní a tún ní àwọn ọmọ-ọmọ àti ọmọ-ọmọ-ọmọ pẹ̀lú. Wọ́n mà ń mú wa láyọ̀ gan-an o!

Ní òpin ọdún 1948, mo tún gba iṣẹ́ mìíràn. Arákùnrin Knorr ṣàlàyé fún mi pé iṣẹ́ pàtàkì kan yóò mú kí ọwọ́ Arákùnrin Schroeder, tó jẹ́ ẹni tó ń forúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead dí, nítorí náà wọ́n ní kí ń lọ máa kọ́ wọn ní kíláàsì Gilead nígbà tó bá yẹ. Pẹ̀lú ojora tí mo ní, èmi àti Ann padà sí Gilead ní Gúúsù Lansing, New York, ní December 18. Lákọ̀ọ́kọ́, a ó wà ní Gilead fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, a ó sì padà lọ sí Washington. Àmọ́, níkẹyìn, àkókò tí mo wá ń lò ní Gilead pọ̀ ju èyí tí mo ń lò ní Washington lọ.

Láàárín àkókò yìí ni mo sọ níṣàájú pé kíláàsì kọkànlélógún ti Gilead kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York. Níwọ̀n bí mo sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wọn, mo láǹfààní láti nípìn-ín nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà.

Iṣẹ́ Ìsìn ní Orílé Iṣẹ́ Àgbáyé

Ní February 12, 1955, iṣẹ́ mìíràn tí a yàn fún wa bẹ̀rẹ̀. A di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí. Àmọ́, kí ló wá ń béèrè lọ́wọ́ wa? Lákọ̀ọ́kọ́ náà, ṣíṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí a bá yàn fún wa, nínípìn-ín nínú àwọn iṣẹ́ tó gba fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣe ìyẹn tẹ́lẹ̀, àmọ́, nísinsìnyí a óò di apá kan àwùjọ títóbi gan-an—ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti orílé iṣẹ́. A fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdarí Jèhófà.

Apá pàtàkì jù nínú iṣẹ́ mi jẹ mọ́ ọ̀ràn tó kan ilé iṣẹ́ ìròyìn. Ìfẹ́ táwọn akọ̀ròyìn ní sí àwọn ìtàn arùmọ̀lára-sókè àti bí wọ́n ṣe ń gba ìsọfúnni látọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́tanú ti mú wọn kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A sapá láti tún ojú ìwòye wọn ṣe.

Arákùnrin Knorr fẹ́ rí i dájú pé gbogbo wa ní iṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe, nítorí náà a tún láwọn iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n yàn fún wa. Lára àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí mú kí n ṣàmúlò ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí apolówó ọjà. Àwọn mìíràn ní í ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ rédíò ti Society, WBBR. Iṣẹ́ wà láti ṣe lórí sinimá tí Society ń ṣe jáde. Ìtàn nípa ìṣàkóso Ọlọ́run jẹ́ apá kan ẹ̀kọ́ ti a ń kọ́ ní Gilead, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ là ń dáwọ́ lé kí àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i, tí wọ́n jẹ́ ti Jèhófà lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn nípa ètò àjọ ìṣàkóso Ọlọ́run tòde òní, kí a sì mú kí èyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ará ìta pẹ̀lú. Sísọ̀rọ̀ níwájú ènìyàn púpọ̀ tún jẹ́ apá mìíràn nínú ẹ̀kọ́ Gilead, a sì gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ láti mú kí àwọn ohun tó yẹ ní lílò fún ọ̀rọ̀ sísọ níwájú ènìyàn púpọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn arákùnrin láwọn ìjọ. Nítorí náà, púpọ̀ wà láti ṣe.

Mo Di Ọ̀kan Lára Àwọn Olùkọ́ Gilead

Ní ọdún 1961, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táa fẹ́ ṣe fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka, mú kí a gbé Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead lọ sí Brooklyn, níbi tí Watch Tower Society ní orílé ọfíìsì rẹ̀ sí. Lẹ́ẹ̀kan sí i mo tún padà sínú kíláàsì—lọ́tẹ̀ yìí, n ò wá bí adelé olùkọ́, bí kò ṣe bí ọ̀kan lára olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà. Àǹfààní ńlá lèyí o! Ó dá mi lójú gbangba pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead jẹ́, ẹ̀bùn kan tó ti ṣàǹfààní fún ètò àjọ rẹ̀ táa lè fojú rí lápapọ̀.

Ní Brooklyn, àwọn kíláàsì Gilead ní ọ̀pọ̀ àǹfààní tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì ti tẹ́lẹ̀ kò mọ̀ nípa rẹ̀. A ní àwọn àlejò púpọ̀ sí i tó wá ń sọ àsọyé, ó ṣeé ṣe láti túbọ̀ ní ìfararora pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àti bíbá ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílé iṣẹ́ kẹ́gbẹ́ pọ̀. Ó tún ṣeé ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ọ́fíìsì, ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ nínú ilé Bẹ́tẹ́lì àti onírúurú ọ̀nà tí a gbà ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé.

Bí ọdún tí ń gorí ọdún ni iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń yí padà, bẹ́ẹ̀ sì ni iye àwọn olùkọ́ pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ń yí ibi ti ilé ẹ̀kọ́ náà wà padà pẹ̀lú. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó wà ní àyíká rírẹwà kan ní Patterson, New York.

Bíbá Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣiṣẹ́

Ayọ̀ ńlá ló mà jẹ́ láti kọ́ àwọn kíláàsì wọ̀nyí o! Níhìn-ín la ti rí àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn nǹkan inú ètò ògbólógbòó yìí kò jọ lójú. Wọ́n fi ìdílé wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn, ilé wọn, àti àwọn tó gbédè wọn sílẹ̀. Ipò ojú ọjọ́ ni o, oúnjẹ ni o—gbogbo nǹkan pátá ló máa yàtọ̀. Wọn ò tilẹ̀ mọ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń lọ, àmọ́ góńgó wọn ṣáá ni kí wọ́n di míṣọ́nnárì. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ lá ń sún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́.

Ìgbàkigbà tí mo bá wọnú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ni mo máa ń fẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ túra ká. Kò sí ẹni tó lè kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nígbà tí ara rẹ̀ kò bá balẹ̀, tó sì ń dààmú. Lóòótọ́, olùkọ́ ni mí, àmọ́, mo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́. Nígbà kan rí, orí ìjókòó lèmi náà máa ń wà, tí wọ́n a máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Dájúdájú, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ gan-an, wọ́n sì ń mọ ohun púpọ̀ ní Gilead, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí wọ́n gbádùn àkókò tí wọ́n lò níbẹ̀ pẹ̀lú.

Mo mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá dé ibi tí a ń rán wọn lọ, àwọn nǹkan kan wà tí wọ́n óò nílò kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí. Wọ́n nílò ìgbàgbọ́ tó lágbára. Wọ́n nílò ìrẹ̀lẹ̀—lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pàápàá. Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ti ń bá àwọn ẹlòmíràn gbé, kí wọ́n fara mọ́ bí ipò nǹkan bá ṣe rí, kí wọ́n sì máa dárí jini fàlàlà. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa mú àwọn èso tẹ̀mí dàgbà. Wọ́n tún ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ táa rán wọn lọ ṣe pẹ̀lú. Nǹkan tí mo máa ń tẹnu mọ́ fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn nígbà tí wọ́n bá wà ní Gilead.

Ń kò lè sọ iye akẹ́kọ̀ọ́ tí mo ti kọ́ jáde ní pàtó. Ṣùgbọ́n mo mọ irú ìmọ̀lára tí mo ní nípa wọn. Lẹ́yìn táa bá ti jọ wà pa pọ̀ nínú iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù márùn-ún, a máa di ọ̀rẹ́ ara wa ṣáá ni. Lẹ́yìn náà tí mo bá wá ń wò wọ́n tí wọ́n ń lọ sórí pèpéle láti lọ gba ìwé ẹ̀rí wọn ní ọjọ́ àṣeyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege, mo mọ̀ pé wọ́n tí kẹ́kọ̀ọ́ wọn yọrí àti pé tó bá ṣe díẹ̀ sí i, ìlọ́ yá nìyẹn. Ó máa ń dà bí pé apá kan ìdílé tèmi gan-an ló ń lọ. Báwo lèèyàn ò ṣe ní nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ṣetán láti yọ̀ǹda ara wọn, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí fẹ́ lọ ṣe?

Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà tí wọ́n bá wá ṣèbẹ̀wò, mo máa ń gbọ́ tí wọ́n máa ń sọ nípa ayọ̀ tí wọ́n ń ní nínú iṣẹ́ ìsìn wọn, ìyẹn sì ń jẹ́ kí ń mọ̀ pé wọ́n ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ tí a yàn wọ́n sí, àti pé wọ́n ń ṣe ohun tí a kọ́ wọn láti ṣe. Báwo nìyẹn ṣe máa ń rí lára mi? Àsọdùn kọ́, inú mi máa ń dùn gan-an ni.

Wíwo Ọjọ́ Iwájú

Ojú mi ti di bàìbàì báyìí, mo sì ń rí ìjákulẹ̀ tí èyí ń fà. N kò lè kọ́ wọn nínú iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ Gilead mọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ìyẹn ṣòro fún mi láti fara mọ́, àmọ́, ní gbogbo ìgbésí ayé mi mo ti kọ́ láti fara mọ́ bí àwọn ipò nǹkan bá ṣe rí, kí ń sì máa fara dà wọ́n. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ rẹ̀. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù gbàdúrà kí òun lè yọ nínú ìpọ́njú yẹn, àmọ́, Olúwa wí fún un pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Pọ́ọ̀lù ń fara dà á nìṣó. Níwọ̀n bí òun tí lè ṣe é, ó yẹ kí ń gbìyànjú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò kọ́ kíláàsì mọ́, mo láyọ̀ pé mò ṣì láǹfáàní láti máa rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bí wọ́n ṣe ń rìn lọ rìn bọ̀ lójoojúmọ́. Nígbà mín-ìn mo máa ń láǹfààní àtibá wọn sọ̀rọ̀, inú mi sì máa ń dùn nígbà tí mo bá ronú nípa ẹ̀mí rere tí wọ́n ń fi hàn.

Ohun tí ọjọ́ iwájú ní nípamọ́ jẹ́ àgbàyanu láti ronú lé lórí. A ti ń fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ báyìí. Gilead sì ti kó ipa pàtàkì nínú rẹ̀. Lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, nígbà táa bá ṣí àkájọ ìwé tí Ìṣípayá 20:12 tọ́ka sí sílẹ̀, odindi ẹgbẹ̀rún ọdún ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà Jèhófà síwájú sí i yóò tún fi wáyé. (Aísáyà 11:9) Kódà ìyẹn kọ́ lòpin rẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ló jẹ́ ní ti gidi. Títí ayé fáàbàdà ni a óò máa rí ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́ nípa Jèhófà àti ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe bí a ti ń rí àwọn ète rẹ̀ tí ń ṣí payá. Ó dá mi lójú gbangba pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí àgbàyanu tí òun ti ṣe ṣẹ, mo sì fẹ́ wà níbẹ̀ kí ń lè nípìn-ín nínú títẹ́wọ́ gba àwọn ìdarí tí Jèhófà ní fún wa nígbà náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege Gilead ní Pápá Ìṣeré Yankee ti New York ní 1953

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Gertrude, èmi, Kathryn, àti Russell

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mo ń bá N.H Knorr (lápá òsì pátápátá) àti M.G. Henschel ṣiṣẹ́ ìṣètò àpéjọpọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mo wà nínú ilé iṣẹ́ rédíò WBBR

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Mo wà nínú iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ Gilead

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Fọ́tò tí èmi àti Ann yà lẹ́nu àìpẹ́ yìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́