ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 9/15 ojú ìwé 7-8
  • Papias Ka Àwọn Ọ̀rọ̀ oluwa sí Iyebíye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Papias Ka Àwọn Ọ̀rọ̀ oluwa sí Iyebíye
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà-Ìgbàṣe Oníṣọ̀ọ́ra
  • Ìkọ̀wé Rẹ̀
  • Àlàyé Lórí Àwọn Ìhìnrere
  • Àìní Rẹ̀ Nípa Tẹ̀mí Jẹ Ẹ́ Lọ́kàn
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá—Ṣé Ká Máa Bẹ̀rù Rẹ̀ Ni Àbí Ká Máa Retí Ìmúṣẹ Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Ẹ̀kọ́ Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Bá Tàwọn Àpọ́sítélì Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Apa Keji—Awọn Onkọwe Lẹhin Akoko Awọn Apọsiteli Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 9/15 ojú ìwé 7-8

Papias Ka Àwọn Ọ̀rọ̀ oluwa sí Iyebíye

“ÈMI . . . kò gbádùn àwọn wọnnì tí wọ́n ní ohun púpọ̀ láti sọ, bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọ́n ń kọ́ni ní ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Papias, tí ó sọ pé Kristian ni òun ní ọ̀rúndún kejì ti Sànmánì Tiwa, ṣe kọ̀wé.

Papias gbé ní sáà tí ó tẹ̀lé ìgbà ikú àwọn aposteli Jesu Kristi gan-an. Níti tòótọ́, òun jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Polycarp, ẹni tí a ròyìn rẹ̀ pé ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀dọ̀ aposteli Johannu. Àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí, papọ̀ pẹ̀lú ọ̀nà tí Papias fi ń gba ìmọ̀, mú kí ó jọ pé òun ní ìmọ̀ dáradára.

Ọ̀nà-Ìgbàṣe Oníṣọ̀ọ́ra

Òùngbẹ Papias fún òtítọ́ ni ó farahàn kedere nínú àwọn ìwé márùn-ún tí ó papọ̀ jẹ́ ìkọ̀wé rẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa. Ní àwọn ọdún rẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀, kò sí iyèméjì pé Papias to ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí ó ti gbọ́ jọ. Lẹ́yìn náà, láti inú ilé gbígbé rẹ̀ ní ilu Frigia ti Hierapoli, ní Asia Kekere, Papias béèrè ọ̀rọ̀ wò lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà láti mọ̀ dájú bí wọ́n bá ti rí tàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ èyíkèyìí lára àwọn aposteli Jesu rí. Ó fi ìháragàgà béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn ó sì ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ní láti sọ.

Papias ṣàlàyé pé: “Èmi kò ní lọ́tìkọ̀ láti kọ . . . ohunkóhun tí mo fi tìṣọ́ratìṣọ́ra kọ́ sílẹ̀ ní àkókò èyíkéyìí láti ẹnu àwọn àgbà, tí mò sì fi tìṣọ́ratìṣọ́ra rántí, ní mímú òtítọ́ wọn dá yín lójú. Nítorí èmi, bí ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ènìyàn, kò gbádùn àwọn wọnnì tí wọ́n ní ohun púpọ̀ láti sọ, bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọ́n ń kọ́ni ní ohun tí ó jẹ́ òtítọ́; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbádùn àwọn wọnnì tí wọ́n ń sọ àṣẹ àwọn ẹlòmíràn, bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọ́n ń ròyìn èyí tí Oluwa fifúnni fún ìgbàgbọ́ tí ó sì ń ti inú òtítọ́ fúnraarẹ̀ jáde wá. Bí ẹnikẹ́ni tí ó ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn àwọn àgbà bá sì níláti tọ̀ mí wá, èmi yóò béèrè fún àkọsílẹ̀ tí àwọn àgbà fifúnni—ohun ti Anderu tàbí ohun ti Peteru sọ, tàbí ohun tí Filippi tàbí ohun tí Tomasi tàbí Jakọbu, tàbí ohun tí Johannu tàbí Matteu sọ, tàbí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa èyíkéyìí mìíràn.”

Ìkọ̀wé Rẹ̀

Kò sí iyèméjì pé ọ̀pọ̀ jaburata ìmọ̀ tẹ̀mí wà lárọ̀ọ́wọ́tó Papias. A wulẹ̀ lè ronúwòye bí òun ti gbọ́dọ̀ ti fetísílẹ̀ yékéyéké sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó yí ìgbésí-ayé àti iṣẹ́-òjíṣẹ́ ara-ẹni ti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aposteli náà ká ni. Ní nǹkan bíi 135 C.E., Papias kọ ohun tí ó ní láti sọ sínú ìwé kan tí ó jẹ́ tirẹ̀. Lọ́nà tí ó dunni, ìwé yìí ti pòórá. A fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nípasẹ̀ Irenaeus, ẹnìkan tí ó sọ pé Kristian ni òun ní ọ̀rúndún kejì C.E., àti nípasẹ̀ òpìtàn ọ̀rúndún kẹrin náà Eusebius. Ní tòótọ́, a ṣì kà á ní ọ̀rúndún kẹsàn-án C.E. ó sì ti lè wà títí di ọ̀rúndún kẹrìnlá.

Papias gbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi tí ń bọ̀. (Ìfihàn 20:2-7) Gẹ́gẹ́ bí Iranaeus ti wí, ó kọ̀wé nípa àkókò kan “nígbà tí ìṣẹ̀dá, tí a sọ dọ̀tun tí a sì dásílẹ̀, yóò mú ọ̀pọ̀ yanturu gbogbo irú oúnjẹ jáde, láti inú ìrì ojú ọ̀run àti agbára ìmésojáde ilẹ̀-ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbà, tí wọ́n rí Johannu, ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa, ti sọ pé àwọn ti gbọ́ bí Oluwa yóò ti kọ́ni nípa àwọn àkókò wọ̀nyẹn.” Papias kọ̀wé síwájú síi pé: “Fún àwọn onígbàgbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣeégbàgbọ́. Nígbà tí Judasi, afinihàn, sì kọ̀ láti gbàgbọ́ tí ó sì béèrè pé, ‘Báwo ni Oluwa yóò ṣe ṣe àṣepé irú nǹkan bẹ́ẹ̀?’ Oluwa sọ pé, ‘Àwọn wọnnì tí wọn yóò gbé ní àkókò náà yóò ri.’”

Papias kọ̀wé ní àkókò kan nígbà tí Ìmọ̀-awo pọ̀ yamùrá. Àwọn Onímọ̀-awo lọ́ ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn, àbá-èrò, àti ìjìnlẹ̀-awo ìbọ̀rìṣà pọ̀ mọ́ ìsìn Kristian apẹ̀yìndà. Níti gàsíkíyá, títúdìí tí Papias túdìí àṣírí ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa, jẹ́ ìgbìdánwò kan láti dá ìtànkálẹ̀ Ìmọ̀-awo duro. Lẹ́yìn rẹ̀, Irenaeus ń baá lọ láti dènà èké àti àsọdùn ipò-tẹ̀mí àwọn Onímọ̀-awo. Ìwé Ìmọ̀-awo ti níláti tóbi, ní mímú kí Papias fi ìkannú sọ̀rọ̀ bá “àwọn wọnnì tí wọ́n ní púpọ̀ láti sọ.” Ète ìlépa rẹ̀ ṣe kedere—láti fi òtítọ́ kojú èké.—1 Timoteu 6:4; Filippi 4:5.

Àlàyé Lórí Àwọn Ìhìnrere

Nínú àjákù lára àwọn ìwé Papias tí ó ṣì wà, a rí i pé ó mẹ́nukan àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí Matteu àti Marku kọ. Fún àpẹẹrẹ, Papias sọ nípa ìwé Marku pé: “Marku, lẹ́yìn tí ó ti di ògbùfọ̀ Peteru, kọ gbogbo ohun tí ó rántí sílẹ̀ lọ́nà tí ó péye.” Ní jíjẹ́rìí sí ìpéye Ìhìnrere yìí síwájú síi, Papias ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ: “Nítorí náà wàyí Marku kò ṣe àṣìṣe, nígbà tí ó kọ àwọn ohun díẹ̀ sílẹ̀ bí ó ti rántí wọn; nítorí pé ó sọ ọ́ di ìdàníyàn rẹ̀ láti máṣe yọ ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí ó ti gbọ́, tàbí gbé gbólóhùn-ọ̀rọ̀ èké kan kalẹ̀ nínú rẹ̀.”

Papias pèsè ẹ̀rí ẹ̀yìn-òde pé Matteu kọ Ìhìnrere rẹ̀ ní èdè Heberu ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Papias sọ pé: “Ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà ní èdè Heberu, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì ṣètumọ̀ wọn lọ́nà tí ó dára jùlọ bí wọ́n ti lè ṣe tó.” Ó ṣeéṣe pé Papias ṣe ìtọ́ka sí àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìnrere ti Luku àti Johannu, àti àwọn ìkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki mìíràn bákan náà. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, òun yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́rìí ìjímìjí jùlọ tí ń fìdí ìjójúlówó àti ìmísí àtọ̀runwá wọn múlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rì, lọ́nà tí kò ṣe kòńgẹ́ ire, àwọn àjákù tí kò tó nǹkan nínú àwọn ìkọ̀wé Papias ni ó làájá.

Àìní Rẹ̀ Nípa Tẹ̀mí Jẹ Ẹ́ Lọ́kàn

Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó kan nínú ìjọ tí ó wà ní Hierapoli, Papias jẹ́ olùṣèwádìí tí kìí ṣàárẹ̀ kan. Ní àfikún sí jíjẹ́ olùṣèwádìí tí ń ṣiṣẹ́kára, ó fi ìmọrírì mímúná kan fún Ìwé Mímọ́. Papias ṣèdájọ́ lọ́nà tí ó tọ̀nà pé gbólóhùn-ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́-ìsìn èyíkéyìí ti Jesu Kristi tàbí ti àwọn aposteli Rẹ̀ yóò túbọ̀ ṣeyebíye fíìfíì láti ṣàlàyé ju àwọn gbólóhùn-ọ̀rọ̀ tí kò ṣeégbáralé tí a rí nínú àwọn ìwé ọjọ́ rẹ̀.—Juda 17.

Papias ni a ròyìn pé ó jìyà ìjẹ́rìíkú ní Pergamu ní 161 tàbí 165 C.E. Bí àwọn ẹ̀kọ́ Jesu Kristi ti nípa lórí ìgbésí-ayé àti ìwà Papias jinlẹ̀ tó ni a kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú. Síbẹ̀, ó ní ìfẹ́-ọkàn mímúná láti kẹ́kọ̀ọ́ kí ó sì jíròrò Ìwé Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kristian tòótọ́ lónìí ti ń ṣe, nítorí tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ wọ́n lọ́kàn. (Matteu 5:3, NW) Wọ́n sì ka àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa sí iyebíye bíi ti Papias.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́