Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá—Ṣé Ká Máa Bẹ̀rù Rẹ̀ Ni Àbí Ká Máa Retí Ìmúṣẹ Rẹ̀?
“Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ ìwé ìṣípayá ti kúrò lórúkọ táa fi ń júwe Bíbélì, ó ti wá di ohun tó lè ṣẹlẹ̀ gan-an.”—Javier Pérez de Cuéllar, akọ̀wé àgbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀ rí ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀NÀ tí ẹni ńlá nínú ayé yìí gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìṣípayá” fi hàn bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ṣe lóye ọ̀rọ̀ náà sí, ó jẹ́ ká mọ bí wọn ṣe ń lò ó nínú sinimá àti àkọlé àwọn ìwé, àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn, àti ìròyìn táwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ń gbé jáde. Èrò àjálù tí yóò kárí ayé ló máa ń mú wá síni lọ́kàn. Àmọ́, kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìṣípayá” túmọ̀ sí gan-an? Èyí tó tún ṣe pàtàkì ni pé, àwọn ọ̀rọ̀ wo ló wà nínú ìwé Bíbélì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìṣípayá, tàbí Ìfihàn yìí?
Ọ̀rọ̀ náà “ìṣípayá” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ṣíṣíbòjú,” tàbí “títú síta.” Kí la tú síta, tàbí táa tú fó nínú ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì? Ṣé ọ̀rọ̀ ìdájọ́, àsọtẹ́lẹ̀ ìparun, tí kò sẹ́ni tó lè là á já nìkan ló wà nínú ẹ̀ ni? Nígbà táa béèrè èrò tí òpìtàn náà, Jean Delumeau, tó jẹ́ mẹ́ńbà Institut de France, ní nípa ìwé Ìṣípayá, ó sọ pé: “Ìwé ìtùnú àti ìrètí nìwé náà. Àwọn èèyàn sì ti jẹ́ ká mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ nípa dídarí àfiyèsí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ runlérùnnà tó wà nínú rẹ̀.”
Àwọn Ṣọ́ọ̀sì Ìjímìjí àti Ìwé Ìṣípayá
Kí lèrò “àwọn Kristẹni” ìjímìjí nípa Ìwé Ìṣípayá àti ìrètí tó gbé kalẹ̀ nípa Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi (Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún) lórí ilẹ̀ ayé? Òpìtàn kan náà sọ pé: “Lápapọ̀, lójú tèmi, ó jọ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nígbàgbọ́ nínú ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún. . . . Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn Kristẹni ìjímìjí tó nígbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ni Papias, bíṣọ́ọ̀bù Hirapólísì ní Éṣíà Kékeré, . . . Justin Mímọ́, táa bí ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì, ẹni tí wọ́n pa ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 165 nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, ẹlòmíràn ni Irenæus Mímọ́, bíṣọ́ọ̀bù Lyons, tó kú lọ́dún 202, bẹ́ẹ̀ náà ni Tertullian, tó dolóògbé lọ́dún 222, àti . . . akọ̀wé-kọ-wúrà nì, Lactantius.”
Nípa Papias, ẹni táa gbọ́ pé wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ní Pẹ́gámọ́mù lọ́dún 161 tàbí 165 Sànmánì Tiwa, ìwé The Catholic Encyclopedia wí pé: “Bíṣọ́ọ̀bù Papias ti Hirapólísì, tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jòhánù Mímọ́, la mọ̀ gẹ́gẹ́ bí alágbàwí fún ìgbàgbọ́ ẹgbẹ̀rúndún. Ó sọ pé àwọn alájọgbáyé àwọn Àpọ́sítélì ló fi ẹ̀kọ́ tí òun ń kọ́ni lé òun lọ́wọ́, Irenæus sì ṣàlàyé pé ‘àwọn àlùfáà’ yòókù, tí wọ́n ti rí ọmọ ẹ̀yìn náà Jòhánù, tí wọ́n sì ti gbọ́ nípa rẹ̀, kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbàgbọ́ ẹgbẹ̀rúndún lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀kọ́ tí Olúwa fi kọ́ni. Gẹ́gẹ́ bí Eusebius ti sọ . . . Papias sọ nínú ìwé rẹ̀ pé ẹgbẹ̀rún ọdún ìjọba ológo Kristi, tí yóò ṣeé fojú rí lórí ilẹ̀ ayé ni yóò tẹ̀ lé àjíǹde àwọn òkú.”
Kí lèyí ń sọ fún wa nípa ipa tí ìwé Ìṣípayá tàbí Ìwé Ìfihàn ní lórí àwọn onígbàgbọ́ láyé ọjọ́un? Ṣé ó kó jìnnìjìnnì bá wọn ni àbí ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀? Ìgbà tọ́rọ̀ máa sọra ẹ̀, làwọn òpìtàn bá pe àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni chiliasts, ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì yìí wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, khiʹli·a eʹte (tó túmọ̀ sí ẹgbẹ̀rún ọdún). Wọn ò purọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni ayé ọjọ́un la mọ̀ dáadáa pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, èyí tí wọ́n gbà pé yóò mú párádísè wá sáyé. Ibì kan ṣoṣo tí Bíbélì ti mẹ́nu kan ìrètí ẹgbẹ̀rún ọdún náà sì ni ìwé Ìṣípayá, tàbí Ìfihàn. (20:1-7) Látàrí èyí, kàkà táwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ láyé ọjọ́un yóò fi máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí ìwé Ìṣípayá, ṣe ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Nínú ìwé rẹ̀, The Early Church and the World, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì nílé ẹ̀kọ́ gíga ti Oxford, Cecil Cadoux, kọ̀wé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn àwọn èèyàn kò tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye àwọn onígbàgbọ́ ẹgbẹ̀rúndún mọ́, fún àkókò gígùn Ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́ gbà á, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òǹṣèwé táa bọ̀wọ̀ fún láwùjọ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi kọ́ni.”
Ìdí Táwọn Kan Ò Fi Gba Ìwé Ìṣípayá Gbọ́
Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé ìtàn tòótọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé, tí kò bá tiẹ̀ jẹ́ àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni ìjímìjí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló nígbàgbọ́ nínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi lórí párádísè ilẹ̀ ayé, báwo ló ṣe wá jẹ́ pé “lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn àwọn èèyàn kò tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye àwọn onígbàgbọ́ ẹgbẹ̀rúndún mọ́”? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Robert Mounce ti sọ, àwọn ìdí táwọn kan fi ṣe lámèyítọ́ wọn ni pé, “ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹgbẹ̀rúndún ba nǹkan jẹ́, wọ́n gbé ojú ìwòye wọn gbòdì, wọ́n mú oríṣiríṣi ẹ̀mí kíkó ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jọ àti ṣíṣe fàájì àṣerégèé wọnú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú àkókò ẹgbẹ̀rún ọdún.” Àmọ́ à bá ti ṣàtúnṣe sáwọn ojú ìwòye aláṣerégèé yìí láìjẹ́ pé a kọ ìrètí tòótọ́ tó wà nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀.
Èyí tó tiẹ̀ yani lẹ́nu gidigidi ni ọ̀nà tí àwọn ọ̀tá ìgbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún gbà láti tẹ̀ ẹ́ rì. Ìwé Dictionnaire de Théologie Catholique sọ nípa àlùfáà ará Róòmù náà, Caius (tó gbé ayé ní òpin ọ̀rúndún kejì, títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹta) pé “láti lè rí i pé ìgbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ò gbérí mọ́, ó ní irọ́ pátápátá ló wà nínú ìwé Ìṣípayá [Ìfihàn] àti Ìhìn Rere ti Jòhánù.” Ìwé Dictionnaire yìí tún fi kún un pé, Dionysius, bíṣọ́ọ̀bù Alẹkisáńdíríà ní ọ̀rúndún kẹta, kọ̀wé kan tó tako ìgbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún, ó sọ pé “kí àwọn tó di ojú ìwòye yìí mú má bàá gbé ìgbàgbọ́ wọn ka ìwé Ìṣípayá ti Jòhánù Mímọ́, gbangba-gbàǹgbà ni wọ́n ti ń sọ pé ìwé náà ò ṣeé gbà gbọ́ rárá.” Irú àtakò tó kún fún ẹ̀tanú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi hàn sí ìrètí ìbùkún tí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún fẹ́ mú wá sórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ká mọ bí ọgbọ́n burúkú tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ń lò nígbà yẹn ti pọ̀ tó.
Nínú ìwé rẹ̀, The Pursuit of the Millennium, Ọ̀jọ̀gbọ́n Norman Cohn kọ̀wé pé: “Ọ̀rúndún kẹta làwọn èèyàn ti kọ́kọ́ gbìyànjú láti fẹnu tẹ́ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún, ìyẹn ni ìgbà tí Origen, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló jẹ́ abẹnugan jù lọ láàárín àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní Ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí, bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò ní wáyé lọ́nà táa gbà ń retí rẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé inú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ nìkan ló ti máa wáyé.” Nítorí tí Origen gbára lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì dípò Bíbélì, ó ṣàbùlà ìrètí àgbàyanu ti ìbùkún orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà náà, ó sọ ọ́ di ohun tó díjú pátápátá, ó pè é ní “ìṣẹ̀lẹ̀ . . . tó máa wáyé nínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́.” Òǹṣèwé kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, Léon Gry, kọ̀wé pé: “Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì tó ń gbilẹ̀ . . . bi èrò àwọn Onígbàgbọ́ Nínú Ẹgbẹ̀rúndún ṣubú pátápátá.”
“Ṣọ́ọ̀ṣì Ti Gbàgbé Iṣẹ́ Afinilọ́kànbalẹ̀ Táa Fi Rán An”
Kò sí àní-àní pé Augustine ni Baba Ṣọ́ọ̀ṣì tó jà fitafita jù lọ láti pa ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì pọ̀ mọ́ ohun tó fara jọ ẹ̀sìn Kristẹni tó wà nígbà ayé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, alágbàwí fún ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún lọkùnrin yìí tẹ́lẹ̀ rí o, àmọ́, nígbà tó yá ló bá jáwọ́ nínú èrò pé Ẹgbẹ̀rúndún Ìjọba Kristi ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ ayé. Ló bá gbé ìtumọ̀ ìwé Ìṣípayá orí ogún gbòdì pátápátá.
Ìwé The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Níkẹyìn, ìgbàgbọ́ Augustine ni pé ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún kò ní wáyé mọ́. . . . Ó ṣàlàyé pé, àjíǹde ìṣáájú tí ìwé yẹn sọ ń tọ́ka sí títún èèyàn bí nípa tẹ̀mí nígbà ìbatisí; ìyè àìnípẹ̀kun tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni yóò jẹ́ sábáàtì ẹgbẹ̀rún ọdún tí yóò tẹ̀ lé ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà tí èèyàn ti wà níhìn-ín.” Ìwé The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Báyìí ni ìtàn àròsọ ẹlẹ́gbẹ̀rúndún tí Augustine gbé kalẹ̀ ṣe wá di ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì fàṣẹ sí . . . Bó ṣe di pé gbogbo Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì Alátùn-únṣe Ẹ̀sìn ti Luther, Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin, àti àwọn ọmọ ìjọ Áńgílíkà . . . ṣe fi wá tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye Augustine nìyẹn.” Bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ nìyẹn tó di pé a gba ìrètí ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún lọ́wọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù.
Láfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sweden, Frédéric de Rougemont, ti sọ, “kíkọ̀ tí [Augustine] kọ ohun tó gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀ fa ìpalára tó kúrò ní kèrémí fún Ṣọ́ọ̀ṣì. Nítorí orúkọ tó ní láwùjọ, ó fọwọ́ sí àṣìṣe tó gba àǹfààní orí ilẹ̀ ayé tí [Ṣọ́ọ̀ṣì] ì bá ní mọ́ wọn lọ́wọ́.” Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ọmọ ilẹ̀ Jámánì nì, Adolf Harnack, gbà pé kíkọ ìgbàgbọ́ nínú Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀ ṣàkóbá fáwọn gbáàtúù ní ti pé “ó gba ẹ̀sìn tí wọ́n lóye mọ́ wọn lọ́wọ́,” ó wá fi “ẹ̀sìn tí wọn ò mọ ojútùú rẹ̀ rárá” rọ́pò “ẹ̀sìn àti ìrètí tó ti wà láti ìgbà ìwáṣẹ̀.” Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti di ahoro ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí jẹ́ ẹ̀rí kedere pé àwọn ènìyàn nílò ìgbàgbọ́ àti ìrètí tí wọ́n lè lóye.
Nínú ìwé rẹ̀, Highlights of the Book of Revelation, ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, George Beasley-Murray, kọ̀wé pé: “Nítorí ipa tó gadabú tí Augustine kó nínú títako ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún, tí àwọn ẹ̀sìn tó yapa sì wá di ìgbàgbọ́ yìí mú gírígírí, ni àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì bá pohùn pọ̀ láti pa ẹ̀kọ́ náà tì. Nígbà táa bi wọ́n pé ìrètí mìíràn wo ni wọ́n ní fún aráyé nínú ayé yìí, èsì wọn ni pé: Kò sí ìrètí kankan. Ayé máa pa run ni nígbà tí Kristi bá dé, kí ọ̀run rere àti ọ̀run àpáàdì bàa lè wà, nígbà tí a ò ní rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wá rí mọ́. . . . Ṣọ́ọ̀ṣì ti gbàgbé iṣẹ́ afinilọ́kànbalẹ̀ táa fi rán an.”
Ìrètí Àgbàyanu Tó Wà Nínú Ìṣípayá Kò Tíì Parẹ́!
Tó bá jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní o, ó dá wọn lójú ṣáká pé àwọn ìlérí àgbàyanu tó so mọ́ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún yìí yóò ṣẹ. Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Jean Delumeau, lẹ́nu wò, lórí ètò tẹlifisọ́n kan nílẹ̀ Faransé, tó dá lórí kókó náà “Ọdún 2000: Ìbẹ̀rù Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá,” ó wí pé: “Ipasẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ nínú ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún gan-an làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tọ̀ ní tiwọn, nítorí ohun táwọn ń sọ ni pé, láìpẹ́ jọjọ . . . a óò wọ sáà ẹgbẹ̀rúndún aláyọ̀, àmọ́ ṣá o, gudugbẹ̀ yóò kọ́kọ́ já.”
Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran náà nìyẹn, ohun tó sì ṣàlàyé rẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá, tàbí ìwé Ìfihàn nìyẹn. Ó kọ̀wé pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan . . . Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:1, 3, 4.
Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jákèjádò ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lọ́wọ́ báyìí, kí wọ́n bàa lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìrètí yìí. Inú wọn yóò dùn púpọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́, kíwọ náà lè kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Papias sọ pé àwọn tó jẹ́ alájọgbáyé àwọn àpọ́sítélì ló fi ẹ̀kọ́ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún lé òun lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tertullian nígbàgbọ́ nínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi
[Credit Line]
© Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Kíkọ̀ tí [Augustine] kọ ohun tó gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣàkóso ẹgbẹ̀rúndún sílẹ̀ fa ìpalára tó kúrò ní kèrémí fún Ṣọ́ọ̀ṣì.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Párádísè ilẹ̀ ayé táa ṣèlérí nínú ìwé Ìṣípayá jẹ́ ohun táa gbọ́dọ̀ máa yán hànhàn fún