ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 3-5
  • Èé Ṣe Táa Fi Ń bẹ̀rù Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Táa Fi Ń bẹ̀rù Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá Ṣe Kó Jìnnìjìnnì Bá Àwọn Kan
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Ìwé Ìṣípayá Kó Jìnnìjìnnì Bá Wa?
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá—Ṣé Ká Máa Bẹ̀rù Rẹ̀ Ni Àbí Ká Máa Retí Ìmúṣẹ Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Ayé Ò Ní Pẹ́ Pa Run? Kí Ni Àpókálíìsì?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • “Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀” Látinú Ìwé Ìṣípayá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Aláyọ̀!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 3-5

Èé Ṣe Táa Fi Ń bẹ̀rù Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá?

DAMIAN Thompson, òǹkọ̀wé nípa ẹ̀sìn, sọ nínú ìwé ìròyìn Time pé: “Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún báyìí làwọn Kristẹni arinkinkin-mọ́lànà ti ń sọ pé, àkókò náà ti kù sí dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo àwùjọ jákèjádò ayé yóò fọ́ yángá. Ṣùgbọ́n ní báyìí o, ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún wọn pé, kì í ṣe pé àwọn èèyàn ti wá ka ọ̀rọ̀ yìí kún nìkan ni, ṣùgbọ́n, àwọn tó máa ń dá yẹ̀yẹ́ ẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ló wá ń tan ọ̀rọ̀ náà kiri: ìyẹn làwọn tó mọ̀ nípa ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà, àwọn olórí oníṣòwò àti àwọn olóṣèlú.” Ó là á mọ́lẹ̀ pé, ìbẹ̀rù pé gbogbo kọ̀ǹpútà tó wà lágbàáyé lè dẹnu kọlẹ̀ lọ́dún 2000 “ti wá sọ gbogbo àwọn tí kò ka ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kún tẹ́lẹ̀ di onígbàgbọ́ àpàpàǹdodo nínú ẹgbẹ̀rúndún,” wọ́n ti wá dẹni tí kò lè sùn, tí kò lè wo, nítorí ìbẹ̀rù àwọn ìjàǹbá bí “jìnnìjìnnì lọ́tùn-ún lósì, ètò ìjọba tó dẹnu kọlẹ̀, rògbòdìyàn nítorí ọ̀wọ́n oúnjẹ, ìfòyà kí àwọn ọkọ̀ òfuurufú máa sẹrí mọ́ àwọn ilé àwòṣífìlà.”

Ohun mìíràn tó tún dákún ìpayà yìí ni ìgbòkègbodò tó ń gbéni lọ́kàn sókè táwọn ẹ̀sìn kéékèèké kan ń bá kiri, ìyẹn làwọn ẹ̀sìn táa sábà ń pè ní “aríran ìyọnu.” Ní January 1999, nínú àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n pè ní “Jerúsálẹ́mù àti Ariwo Ìṣípayá,” ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà, Le Figaro, wí pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò [nílẹ̀ Ísírẹ́lì] fojú bù ú pé yóò lé ní ọgọ́rùn-ún ‘àwọn onígbàgbọ́ nínú ẹgbẹ̀rúndún’ tó ti wà lórí Òkè Ólífì tàbí nítòsí ibẹ̀ báyìí, tí wọ́n ń retí bíbọ̀ Olúwa tàbí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé ìṣípayá.”

Ìwé 1998 Britannica Book of the Year ní ìròyìn pàtàkì kan nípa “Àwọn Ẹgbẹ́ Ìmùlẹ̀ Akéde Àjálù.” Lára àwọn ẹgbẹ́ tó dárúkọ ni, àwọn ẹgbẹ́ tí ń mú kéèyàn gbẹ̀mí ara ẹni, irú ẹgbẹ́ bí Ibodè Ọ̀run, Tẹ́ńpìlì Ènìyàn, àti Ẹgbẹ́ Tẹ́ńpìlì Oòrùn, àti Aum Shinrikyo (Ẹgbẹ́ Olóòótọ́), tó jẹ́ pé àwọn leku ẹdá tó dá wàhálà atẹ́gùn olóró sílẹ̀ lọ́jọ́sí, nígbà tí wọ́n tú atẹ́gùn náà dà sínú afẹ́fẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ nílùú Tokyo lọ́dún 1995, èyí tó gbẹ̀mí èèyàn méjìlá, tó sì ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún léṣe. Nígbà tí Martin E. Marty, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ní Yunifásítì Chicago, ń ṣàkópọ̀ ìròyìn yìí, ó kọ̀wé pé: “Ẹnu á kọ̀ròyìn nígbà táa bá fẹ́ bọ́ sọ́dún 2000—kò sí àní-àní pé oríṣiríṣi àsọtẹ́lẹ̀ àti onírúurú ẹgbẹ́ ni yóò yọjú. Àwọn kan lè jẹ́ eléwu. Yóò jẹ́ àkókò kan tí èèyàn ò gbọ́dọ̀ káwọ́ gbera.”

Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá Ṣe Kó Jìnnìjìnnì Bá Àwọn Kan

Ìṣípayá, tàbí Ìfihàn, ni orúkọ ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ti ń parí lọ nígbà táa kọ ọ́. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ìṣàpẹẹrẹ tó kún inú ìwé yìí, ọ̀rọ̀ ajúwe náà “ìṣípayá” wá di èyí tí a tún fi ń pe àwọn ìwé kan tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ká tó kọ ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì. Láti ìgbà Páṣíà láyé ọjọ́un, àní ṣáájú ìgbà yẹn pàápàá la ti ń lo àwọn ọ̀rọ̀ ìṣàpẹẹrẹ tó jẹ mọ ìtàn ìwáṣẹ̀ tó wà nínú ìwé wọ̀nyí. Látàrí èyí, ìwé The Jewish Encyclopedia sọ nípa “ìwà àwọn ará Bábílónì tó yàtọ̀ gédégbé tó wà nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ táa kọ sínú ìwé yìí [ìyẹn ni ìwé ìṣípayá ti àwọn Júù].”

Ìwé ìṣípayá ti àwọn Júù wà káàkiri láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, títí di òpin ọ̀rúndún kejì ti Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń ṣàlàyé nípa ohun tó fà á táa fi kọ àwọn ìwé wọ̀nyí, ó kọ̀wé pé: “Sànmánì méjì péré làwọn Júù pín gbogbo sànmánì sí. Ọ̀kan ni sànmánì tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, èyí tí kò dáa rárá . . . Nítorí ìdí èyí, àwọn Júù ń dúró de ìgbà tí gbogbo nǹkan yóò wá sópin. Èkejì ni sànmánì tó ń bọ̀, èyí tó máa dùn yùngbà, ìyẹn ni sànmánì aláásìkí tí Ọlọ́run yóò mú wá, níbi tí àlàáfíà, aásìkí àti òdodo máa wà . . . Báwo wá ni sànmánì tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí yóò ṣe wá di sànmánì tó ń bọ̀? Àwọn Júù gbà gbọ́ pé kò sí èèyàn kankan tó lè mú ìyípadà yìí wá, nítorí náà, Ọlọ́run ni wọ́n gbà pé ó lè dá sí ọ̀ràn aráyé ní tààràtà. . . . Ọjọ́ tí Ọlọ́run yóò dé ni wọ́n ń pè ní Ọjọ́ Olúwa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, gọngọ á sọ lọ́jọ́ náà, òkú yóò sùn lọ bẹẹrẹ, ìdájọ́ yóò wáyé, ìwọ̀nyí sì ni yóò jẹ́ ìfilọ́lẹ̀ sànmánì tuntun náà. Gbogbo àwọn ìwé ìṣípayá ló sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.”

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Ìwé Ìṣípayá Kó Jìnnìjìnnì Bá Wa?

Ìwé Ìṣípayá ti inú Bíbélì sọ nípa “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tàbí Amágẹ́dọ́nì, níbi tí a ó ti pa àwọn ẹni búburú run, lẹ́yìn náà ni àkókò ẹgbẹ̀rúndún (tí a sábà ń pè ní Ìjọba Ẹgbẹ̀rúndún) yóò bẹ̀rẹ̀, nígbà tí a ó sọ Sátánì sínú ọ̀gbun, tí Kristi yóò sì ṣèdájọ́ aráyé. (Ìṣípayá 16:14, 16; 20:1-4) Ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àwọn kan ṣi àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí lóye nítorí pé “Ẹni Mímọ́” ìjọ Kátólíìkì nì, Augustine (tó gbé ayé ní 354 sí 430 Sànmánì Tiwa) ti sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìgbà táa bí Kristi ni Ìjọba Ẹgbẹ̀rúndún ti bẹ̀rẹ̀, Ìdájọ́ Ìkẹyìn ni yóò sì tẹ̀ lé e. Ó hàn gbangba pé Augustine kò fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí bí àkókò ti kúrú tó nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n bí ọdún 1000 ti ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni ìbẹ̀rù náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn òpìtàn kò fohùn ṣọ̀kan lórí bí ìpalára tí jìnnìjìnnì àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀làjú fà ṣe pọ̀ tó. Àmọ́ bó ti wù kó pọ̀ tó, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó hàn gbangba pé kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

Bákan náà lónìí, bí onírúurú ẹ̀sìn ti ń kó ìpayà báni, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjọ tí kì í ṣe ti ẹ̀sìn ń da jìnnìjìnnì boni, tí wọ́n ń sọ pé lọ́dún 2000 tàbí ọdún 2001, àsọtẹ́lẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan yóò nímùúṣẹ. Ṣùgbọ́n, ṣé irú ìbẹ̀rù wọ̀nyí tọ́? Ṣé ńṣe ló yẹ ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá tàbí ìwé Ìfihàn tó wà nínú Bíbélì, àbí ńṣe ló yẹ ká máa retí rẹ̀? Jọ̀wọ́ máa kàwé yìí nìṣó.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Gbígbọ̀n táwọn kan ń gbọ̀n jìnnìjìnnì nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀làjú nítorí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá kò tọ́ rárá

[Credit Line]

© Cliché Bibliothèque Nationale de France, Paris

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Maya/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́