Ìlànà Tàbí Ìgbajúmọ̀—Èwo Ni Atọ́nà Rẹ?
NORIHITO ti ó wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kẹfà ń kópa nínú eré-ìdárayá kan. Lójijì, ó dojúkọ ìpinnu kan. Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni a béèrè pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè-ẹni. Òun ha níláti darapọ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ohun tí ó dàbí ìgbésẹ̀ ìgbà gbogbo yìí bí?
Norihito ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bibeli pé kò tọ̀nà láti darapọ̀ nínú ìṣe ìjọsìn sí ọlọrun èyíkéyìí yàtọ̀ sí Jehofa. (Eksodu 20:4, 5; Matteu 4:10) Ó tún mọ̀ pé àwọn Kristian níláti wà láìdásí tọ̀tún-tòsì nínú gbogbo àwọn àlàámọ̀rí òṣèlú ayé. (Danieli 3:1-30; Johannu 17:16) Nítorí náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rọ̀ ọ́ láti darapọ̀ mọ́ wọn, ó fi tìgboyàtìgboyà ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọ̀wọ̀ mú ìdúró rẹ̀. Kí ni ìwọ ìbá ti ṣe nínú irú ipò kan-náà?
Ìfẹ́-Ọkàn Láti Jẹ́ Apákan Agbo
Ìwé Mímọ́ fihàn pé àwọn ènìyàn ni Ọlọrun dá láti jẹ́ ẹni tí ń bẹ́gbẹ́ pé, ẹni tí ó ní àjọṣepọ̀ rere pẹ̀lú ẹnìkínní kejì, àti láti gbádùn ṣíṣe àwọn nǹkan papọ̀. Ó bá ìwà-ẹ̀dá mu láti fẹ́ láti wà pẹ̀lú ojúgbà ẹni, láti jẹ́ ẹni tí a tẹ́wọ́gbà, láti wà jẹ́ apákan agbo wọn. Irú àwọn ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ mú kí ìgbésí-ayé túbọ̀ gbádùnmọ́ni ó sì ń dákún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú àwọn ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Genesisi 2:18; Orin Dafidi 133:1; 1 Peteru 3:8.
Ìfẹ́-ọkàn àbínibí láti jẹ́ apákan agbo ni a gbéyọ nínú ìtẹnumọ́ lílágbára tí a gbékarí ìhùwà níbàámu pẹ̀lú àṣà tí ó lòde tí a rí nínú àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ kan lónìí pàápàá. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Japan, fún àpẹẹrẹ, ni a dálẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà àwọn ọdún wọn ìjímìjí láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí ọ̀pọ̀ jùlọ paláṣẹ kí wọ́n sì hùwà níbàámu pẹ̀lú rẹ̀. Àjogúnbá wọn kọ́ wọn pé ọ̀kan lára àwọn ojúṣe wọn títóbi jùlọ ni láti báradọ́gba pẹ̀lú àwùjọ. “Àwọn ará Japan lè fi púpọ̀ púpọ̀ ṣe nǹkan papọ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo kan ju àwọn ará Ìwọ̀-Oorùn lọ,” ni Edwin Reischauer, ikọ̀ United States sí Japan tẹ́lẹ̀rí àti olùṣàkíyèsí ìwà àwọn ará Japan kínníkínní. Ó fikún un pé: “Níbi tí àwọn ará Ìwọ̀-Oòrùn lè ti ṣàṣefihàn òmìnira àti jíjẹ́-ẹnìkan ní ìtagbangba, ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ará Japan yóò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn gidigidi láti hùwà níbàámu pẹ̀lú ọ̀pá-ìdíwọ̀n àwùjọ wọn nínú ìwọṣọ, ìwà, àṣà ìgbésí-ayé, àti nínú ìrònú pàápàá.” Ìfẹ́-ọkàn náà láti hùwà níbàámu pẹ̀lú àṣà tí ó lòde, bí ó ti wù kí ó rí, kò mọ sọ́dọ̀ àwọn ará Japan nìkan. Kárí-ayé ni.
Àwọn Ìkìmọ́lẹ̀ Láti Hùwà Níbàámu Pẹ̀lú Àṣà tí Ó Lòde
Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fanilọ́kànmọ́ra láti ṣe ohun tí ẹnìkan lè ṣe lọ́nà dídára jùlọ láti jẹ́ ẹni tí ó ní àjọṣepọ̀ rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ewu wà nínú híhùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó gbajúmọ̀ láìfọgbọ́nronú. Èéṣe? Ó jẹ́ nítorí pé ohun tí ó gbajúmọ̀ fún ogunlọ́gọ̀ sábà máa ń lòdìsí ohun tí ó ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun. “Gbogbo ayé ni ó wà ní agbára ẹni búburú nì,” ni Bibeli sọ fún wa. (1 Johannu 5:19) Satani ń fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí lo gbogbo ọ̀nà tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀—ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì, ìwàrere tí ó rẹlẹ̀, ẹ̀tanú ẹ̀yà-ìran, ìgbàgbọ́ aláìnírònú ti ìsìn, ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—láti nípa lórí àwọn ènìyàn àti láti yí wọn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Láti hùwà níbàámu pẹ̀lú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, ní ọ̀nà yẹn, yóò fi ẹnìkan sínú ìforígbárí pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun àti àwọn ète rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi gba àwọn Kristian nímọ̀ràn pé: “Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí: ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Romu 12:2.
Bí wọ́n ti ń gbé nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, àwọn Kristian wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ lemọ́lemọ́ láti hùwà níbàámu pẹ̀lú ohun tí ó gbajúmọ̀. Àwọn èwe ní pàtàkì ni ọwọ́ ṣìnkún lè tètè tẹ̀ ní ọ̀nà yìí. Ìfẹ́-ọkàn láti rí kí wọ́n sì hùwà bí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lágbára gidigidi. Ó gba ìgboyà gidi fún wọn láti ṣàlàyé ìdí tí wọn kìí fií lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan fún àwọn ojúgbà wọn. Ìkùnà láti fọhùn, bí ó ti wù kí ó rí, lè túmọ̀sí ìjábá tẹ̀mí fún wọn.—Owe 24:1, 19, 20.
Àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú ń dojúkọ irú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ibi iṣẹ́ wọn. A lè retí pé kí wọn kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kan lẹ́yìn àwọn wákàtí iṣẹ́ tàbí lákòókò họlidé kan. Kíkọ̀ láti darapọ̀ lè mú kí wọn dàbí ẹni tí ó takété tí kò sì fọwọ́sowọ́pọ̀, ní dídá ipò àyíká ṣíṣòro sílẹ̀ ní ibi iṣẹ́. Àwọn kan lè nímọ̀lára ìmúnilápàpàǹdodo láti ṣe iṣẹ́ àṣelé oníwákàtí gbọgbọrọ kìkì nítorí pé àwọn mìíràn ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí a sì retí rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Jíjuwọ́sílẹ̀ nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè ṣèpalára tẹ̀mí fún wọn kí ó sì tún dí wọn lọ́wọ́ láti máṣe mú àwọn iṣẹ́-àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mìíràn ṣẹ.—1 Korinti 15:33; 1 Timoteu 6:6-8.
Àwọn ìkìmọ́lẹ̀ láti hùwà níbàámu pẹ̀lú àṣà tí ó lòde tún wà níbòmíràn yàtọ̀ sí ilé-ẹ̀kọ́ tàbí ibi iṣẹ́. Ìyá kan tí ó jẹ́ Kristian sọ pé ní àkókò kan òun fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn lára ọmọ òun, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nílò rẹ̀ gidigidi kìkì nítorí pé òun nímọ̀lára pé àwọn ìyàwó-ilé mìíràn tí wọ́n wà níbẹ̀ kò ní tẹ́wọ́gbà á.—Owe 29:15, 17.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn Lè Ṣàìtọ̀nà
Bibeli fún wa ní ìmọ̀ràn púpọ̀ tí ó ṣe tààràtà nígbà tí ó bá kan títọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Israeli ni a sọ fún pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn láti ṣe ibi, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ ní ọ̀ràn kí o tẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ènìyàn láti yí ẹjọ́ po.” (Eksodu 23:2; fiwé Romu 6:16.) Ìmọ̀ràn yìí ni a kìí fìgbà gbogbo tẹ̀lé. Nígbà kan rí, kété lẹ́yìn tí wọ́n fi Egipti sílẹ̀, nígbà tí Mose kò sí níbẹ̀, àwọn ènìyàn kan lo àgbára-ìdarí lórí Aaroni àti àwọn ènìyàn láti ṣe àwòrán ẹgbọrọ màlúù oníwúrà kan àti láti jọ́sìn rẹ̀ nínú “àjọ fún Oluwa.” Àwọn ènìyàn náà jẹ wọ́n sì mu wọ́n sì gbádùn araawọn nínú orin àti ijó nígbà tí wọ́n ń rúbọ sí ẹgbọrọ màlúù oníwúrà náà. Fún ìgbésẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo aláìníjàánu àti olórìṣà yìí, nǹkan bíi ẹgbẹ́ẹ́dógún àwọn aṣáájú nínú ìwà-búburú náà ni a pa. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú àwọn yòókù ni Jehofa mú ìyọnu bá fún títọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn láìronújinlẹ̀.—Eksodu 32:1-35.
Àpẹẹrẹ mìíràn níti títọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn láti ṣe ibi wáyé ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ikú Jesu Kristi. Bí àwọn òjòwú aṣáájú ìsìn ti yí wọn lérò padà, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà darapọ̀ nínú bíbéèrè fún ìfìyà ikú jẹ Jesu. (Marku 15:11) Nígbà tí Peteru ṣàlàyé lórí àṣìṣe wọn wíwúworinlẹ̀ ní Pentekosti tẹ̀lé àjíǹde àti ìgòkè-re-ọ̀run Jesu, ọ̀pọ̀ ni “ọkàn wọ́n gbọgbẹ́” tí wọ́n sì wá mọ̀ ohun tí wọ́n ti ṣe ní títọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́yìn.—Iṣe 2:36, 37.
Àwọn Ìlànà Bibeli Dára Jù
Bí àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ti ṣàkàwé rẹ̀ ní kedere, títẹ̀lé ohun tí ó gbajúmọ̀ láìfọgbọ́nronú lè ṣamọ̀nà sí àbájáde búburú. Ó ti sàn jù tó láti tẹ̀lé Bibeli kí á sì jẹ́ kí àwọn ìlànà rẹ̀ jẹ́ atọ́nà nínú ìgbésí-ayé wa! “Bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ, àti èrò mi ju èrò yín lọ,” ni Jehofa wí. (Isaiah 55:9) Nínú àwọn ọ̀ràn ti ìwàrere àti àjọṣepọ̀ ti ẹ̀dá ènìyàn—nítòótọ́, nínú gbogbo ìpinnu ìgbésí-ayé—a ti fihàn léraléra pé títẹ̀lé àwọn ọ̀nà Jehofa dára fíìfíì ju títẹ̀lé ohun tí ó gbajúmọ̀ lọ. Ó jẹ́ kọ́kọ́rọ́ náà sí ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó láyọ̀ jù tí ó sì ń fúnni nílera jù.
Fún àpẹẹrẹ, gba ìrírí ti Kazuya yẹ̀wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fún àwọn àkókò kan, ó ń báa lọ láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà tí ó gbajúmọ̀—ní lílàkàkà láti di olówó kí ọwọ́ rẹ̀ sì tẹ àṣeyọrí. Àwọn ìsapá rẹ̀ láti wu àwọn ọ̀gá rẹ̀ àti láti di ẹni tí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ronú nípa rẹ̀ lọ́nà rere sábà máa ń ṣamọ̀nà sí ìjádelọ rẹ̀ fún ìdíje ọtí mímu títí di kùtùkùtù wákàtí òwúrọ̀. Ó di oníbèéérè dandangbọ̀n, aláìrí-ara-gba-nǹkan-sí, àti ẹlẹ́jàánú. Kò pẹ́ tí ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ yíyọyẹ́ fi jálẹ̀ sí àrùn rọlápá-rọlẹ́sẹ̀, èyí tí ó sọ ọ́ di arọ lápákan. Bí ara rẹ̀ ti ń yá bọ̀ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí lórí ibùsùn ilé-ìwòsàn kan, ó ní àkókò láti ronú síwá-sẹ́yìn lórí ohun tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti inú Bibeli àti ọ̀nà tí ó ń gbà gbé ìgbésí-ayé rẹ̀. Ó pinnu pé àkókò tó wàyí láti fi ohun tí òun ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílò. Ó kọ̀wé fi ipò alábòójútó-iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì yí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ padà. Ó tún ṣe àwọn ìsapá onífọkànsí láti gbé àkópọ̀ ànímọ́-ìwà Kristian wọ̀ ó sì tún ojú-ìwòye rẹ̀ ṣe nípa àwọn ohun-ìní ti ara. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, èrò ìdíyelé rẹ̀ yípadà, ìlera rẹ̀ sì sunwọ̀n síi. Níkẹyìn, ó ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa a sì baptisi rẹ̀.
Láti kẹ́sẹjárí nínú títọ ipa-ọ̀nà kan tí kò gbajúmọ̀, ẹnìkan gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìlànà tí ó wémọ́ ọn kí ó sì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú pé wọ́n tọ̀nà. Ohun tí Masaru nírìírí rẹ̀ fihàn pé bí ọ̀ràn ti rí nìyí. Nígbà tí ó wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kẹfà, ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, òun ni àwọn ọmọ kíláàsì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dámọ̀ràn pé kí ó jẹ́ olùnàgà fún àǹfààní ipò ààrẹ ìgbìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Pẹ̀lú àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn díẹ̀ ó padà rántí pé nítorí ṣíṣàìlóye àwọn ìlànà Bibeli tí ó wémọ́ ọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, òun kò lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọ kíláàsì òun ìdí tí òun kò fi lè díje fún ipò òṣèlú. Ìbẹ̀rù ènìyàn tí ó ní ti dí i lọ́wọ́ láti máṣe ṣí i payá pé Kristian kan ni òun jẹ́. Gbogbo ohun tí ó lè ṣe ni kí ó dorí kodò kí ó sì sọ ọ́ ní àsọtúnsọ pẹ̀lú omijé pé, “Èmi kò lè ṣe é.”
Ìrírí onírora yìí mú kí ó ṣèwádìí ìdí tí Kristian kan kìí fií lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò òṣèlú. (Fiwé Johannu 6:15.) Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó wà ní abala àkọ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, irú ipò bẹ́ẹ̀ tún wáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àkókò yìí, ó ti múratán láti ṣàlàyé ìdúró rẹ̀ fún olùkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú. Olùkọ́ náà tẹ́wọ́gba àlàyé rẹ̀, bákan náà sì ni àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ mélòókan tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí a gbékarí Bibeli.
Nígbà tí Gbogbo Ènìyàn Yóò Ṣe Ohun ti Ó Tọ̀nà
Nínú ayé titun tí ń bọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Kristi, nǹkan tí ó gbajúmọ̀ láti ṣe yóò jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà láti ṣe. Títí di ìgbà yẹn, àwa níláti máa wà ní ìṣọ́ra lòdìsí ìrọni náà láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó gbajúmọ̀. A lè rí ìṣírí gbà láti inú ìṣílétí Paulu pé: “Nítorí náà bí a ti fi àwọ̀sánmà tí ó kún tó báyìí fún àwọn ẹlẹ́rìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí á pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti dì mọ́ wa, kí á si máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—Heberu 12:1.
Nígbà tí àwọn ọ̀ràn àti ìpèníjà bá dojúkọ ọ́, kí ni ìwọ yóò ṣe? Ìwọ yóò ha juwọ́sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù ènìyàn kí o sì gbà láti ṣe ohun tí ó gbajúmọ̀ bí? Tàbí ìwọ yóò ha yíjú sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, kí o sì tẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ bí? Kìí ṣe pé títẹ̀lé ipa-ọnà tí ó kẹ́yìn yóò ṣàǹfààní fún ọ nísinsìnyí nìkan ni ṣùgbọ́n yóò tún fún ọ ní ìfojúsọ́nà wíwà lára àwọn wọnnì tí wọ́n “ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.”—Heberu 6:12.