Síṣàwárí Kọ́kọ́rọ́ Náà Sí Ìfẹ́ni Ará
“Ẹ fi . . . ìfẹ́ni ará kún ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run yín.”—2 PETERU 1:5-7, NW.
1. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìdí pàtàkì tí ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn Jehofa fi jẹ́ irú àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀?
NÍGBÀ kan rí oníṣègùn kan tí kìí ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá sí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́yege ọmọbìnrin rẹ̀ kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ Watch Tower Bible School of Gilead, níbi tí ó ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ míṣọ́nárì. Orí rẹ̀ wú gidigidi fún àwùjọ aláyọ̀ náà débi pé òun sọ èrò rẹ̀ jáde pé ìwọ̀nba àìsàn díẹ̀ ni ó gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Kí ni ó mú àwùjọ yẹn láyọ̀ tóbẹ́ẹ̀? Níti ìyẹn, kí ni ó ń mú gbogbo ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn Jehofa, nínú àwọn ìjọ, ní àpéjọ àyíká, àti ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè, jẹ́ àkókò aláyọ̀? Kìí ha ṣe ìfẹ́ni ará tí wọ́n fihàn sí araawọn ẹnìkínní kejì ni bí? Láìsí iyèméjì, ìfẹ́ni ará jẹ́ ìdí kan tí a fi sọ pé kò sí àwùjọ ìsìn mìíràn tí ó ní ìgbádùn, ayọ̀, àti ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú ìsìn bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ṣe.
2, 3. Àwọn ọ̀rọ̀ Griki méjì wo ni ó dá lórí bí a ṣe níláti nímọ̀lára nípa araawa ẹnìkínní kejì, ki ni àwọn ànímọ́ yíyàtọ̀ gédégédé wọn?
2 A níláti retí láti rí irú ìfẹ́ni ará bẹ́ẹ̀ ní ojú-ìwòye àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru ní 1 Peteru 1:22 (NW) pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará láìsí àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín ẹnìkínní kejì pẹ̀lú ìgbóná-ọkàn láti inú ọkàn-àyà.” Ọ̀kan lára àwọn apá pàtàkì ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ níhìn-ín sí “ìfẹ́ni ará” ni phi·liʹa (ìfẹ́ni). Ìtumọ̀ rẹ̀ tan pẹ́kípẹ́kí mọ́ ìtumọ̀ a·gaʹpe, ọ̀rọ̀ náà tí a sábà máa ń túmọ̀ sí “ìfẹ́.” (1 Johannu 4:8) Nígbà tí a sábà máa ń lo ìfẹ́ni ará àti ìfẹ́ ní pàṣípààrọ̀, wọ́n ní àwọn ànímọ́ pàtó. A kò níláti ṣì wọ́n mú fún araawọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn olùtúmọ̀ Bibeli ti ṣe. (Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí àti nínú èyí tí ó tẹ̀lé e, àwa yóò bójútó ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.)
3 Nípa ìyàtọ̀ náà tí ó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ Griki méjì wọ̀nyí, ọ̀mọ̀wé kan ṣàkíyèsí pé phi·liʹa jẹ́ “ọ̀rọ̀ ọ̀yàyà àti ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí àti ìfẹ́ni ní pàtó.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a·gaʹpe ní púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú èrò-inú. Nípa báyìí nígbà tí a sọ fún wá láti nífẹ̀ẹ́ (a·gaʹpe) àwọn ọ̀tá wa, a kò ní ìfẹ́ni fún wọn. Èéṣe tí a kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé “ẹgbẹ́ búburú ba ìwà rere jẹ́.” (1 Korinti 15:33) Èyí tí ń fihàn síwájú síi pé ìyàtọ̀ kan wà ni àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru pé: “Ẹ fi . . . ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín.”—2 Peteru 1:5-7, NW; fiwé Johannu 21:15-17.a
Àwọn Àpẹẹrẹ Àkànṣe Ìfẹ́ni Ará Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀
4. Èéṣe ti Jesu àti Johannu fi ní àkànṣe ìfẹ́ni fún araawọn ẹnìkínní kejì?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún wa ní iye àwọn àpẹẹrẹ rere nípa àkànṣe ìfẹ́ni ará ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀. Àkànṣe ìfẹ́ni yìí kìí ṣe àbájáde àwọn èrò òjijì kan ṣùgbọ́n a gbé e karí ìmọrírì àwọn ànímọ́ títayọ. Láìṣe àníàní àpẹẹrẹ dídára jùlọ tí a mọ̀ ni ti ìfẹ́ni tí Jesu Kristi ní fún aposteli Johannu. Dájúdájú, Jesu ní ìfẹ́ni ará fún gbogbo àwọn aposteli olùṣòtítọ́ rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ fún ìdí rere. (Luku 22:28) Ọ̀nà kan tí ó gbà fi èyí hàn ni nípa wíwẹ ẹsẹ̀ wọn, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn ní ẹ̀kọ́ kan nípa ìrẹ̀lẹ̀. (Johannu 13:3-16) Ṣùgbọ́n Jesu ní àkànṣe ìfẹ́ni fún Johannu, èyí tí Johannu mẹ́nukàn léraléra. (Johannu 13:23; 19:26; 20:2) Àní gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní ìdí láti fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti àwọn aposteli rẹ̀, ó ṣeéṣe jùlọ kí Johannu ti fún Jesu ní ìdí láti ní àkànṣe ìfẹ́ni fún un nítorí ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí ó ní fún Jesu. A lè rí èyí láti inú àwọn ìkọ̀wé Johannu, Ìhìnrere rẹ̀ àti àwọn lẹ́tà onímìísí rẹ̀. Ẹ wo bí òun ti sábà máa ń mẹ́nukan ìfẹ́ nínú ìkọ̀wé wọnnì tó! Ìmọrírì giga jù tí Johannu ní fún àwọn ànímọ́ tẹ̀mí ti Jesu ni a rí nínú ohun tí ó kọ ní Johannu ori 1 àti 13 sí 17, àti nípa àwọn ìtọ́ka àṣetúnṣe tí ó ṣe sí wíwà Jesu ṣáájú kí ó tó di ènìyàn.—Johannu 1:1-3; 3:13; 6:38, 42, 58; 17:5; 18:37.
5. Kí ni a lé sọ nípa àkànṣe ìfẹ́ni ará tí Paulu àti Timoteu ní fún araawọn ẹnìkínní kejì?
5 Bákan náà, àwa kò ní fẹ́ láti gbójú fo àkànṣe ìfẹ́ni ará ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ tí aposteli Paulu àti Kristian alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ Timoteu ní fún araawọn ẹnìkínní kejì, èyí tí ó dájú pé a gbékarí mímọrírì àwọn ànímọ́ rere ẹnìkínní kejì. Àwọn ìkọ̀wé Paulu ní nínú àwọn ọ̀rọ̀ rere nípa Timoteu, irú bíi: “Èmi kò ní ẹni onínú kan-náà tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. . . . Ẹ̀yin ti mọ̀ ọ́n dájúdájú, pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ìhìnrere.” (Filippi 2:20-22) Ọ̀pọ̀ ni àwọn ìtọ́ka ti ara-ẹni nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀ sí Timoteu tí ó fi ìfẹ́ni ọlọ́yàyà Paulu fún Timoteu hàn. Fún àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí 1 Timoteu 6:20: “Timoteu, ṣọ́ ohun nì tí a fi sí ìtọ́jú rẹ.” (Tún wo 1 Timoteu 4:12-16; 5:23; 2 Timoteu 1:5; 3:14, 15.) Ní pàtàkì ni ìfiwéra àwọn lẹ́tà Paulu sí Timoteu pẹ̀lú lẹ́tà rẹ̀ sí Titu gbé ìtẹnumọ́ karí àkànṣe ìfẹ́ni Paulu fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí. Timoteu gbọ́dọ̀ ti nímọ̀lára ní ọ̀nà kan-náà nípa ipò ọ̀rẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti lè ṣàkíyèsí rẹ̀ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní 2 Timoteu 1:3, 4: “Ní àìsinmi ni èmi ń ṣe ìrántí rẹ nínú mi, . . . èmi ń [yánhànhàn, NW] àti rí ọ, ti mo ń rántí omijé rẹ, kí á lè fi ayọ̀ kún mi ní ọkàn.”
6, 7. Ìmọ̀lára wo ni Dafidi àti Jonatani ní fún araawọn ẹnìkínní kejì, èésìtiṣe?
6 Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu tún pèsè àwọn àpẹẹrẹ rere, irú bíi ti Dafidi àti Jonatani. A kà pé lẹ́yìn tí Dafidi pa Goliati, “ọkàn Jonatani sì fà mọ́ ọkàn Dafidi, Jonatani sì fẹ́ ẹ bí òun tìkaraarẹ̀.” (1 Samueli 18:1) Ìmọrírì fún àpẹẹrẹ Dafidi nípa ìtara fún orúkọ Jehofa àti àìbẹ̀rù rẹ̀ nínú jíjáde lọ láti lọ pàdé Goliati òmìrán láìṣiyèméjì mú kí Jonatani ní àkànṣe ìfẹ́ni fún Dafidi.
7 Jonatani ní irú ìfẹ́ni bẹ́ẹ̀ fún Dafidi débi pé ó wu ìwàláàyè tirẹ̀ fúnraarẹ̀ léwu nínú gbígbèjà Dafidi kúrò lọ́wọ́ Ọba Saulu. Kò sí ìgbà tí Jonatani tíì bínú sí yíyàn tí Jehofa yan Dafidi láti jẹ́ ọba Israeli tí yóò jẹ tẹ̀lé Saulu. (1 Samueli 23:17) Lọ́nà kan-náà Dafidi ní ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ fún Jonatani, èyí tí ó ṣe kedere nínú ohun tí ó sọ nígbà tí ó ń ṣọ̀fọ̀ ikú Jonatani: “Wàhálà bá mi nítorí rẹ, Jonatani, arákùnrin mi: dídùn jọjọ ni ìwọ jẹ́ fún mi: ìfẹ́ rẹ sí mi jásí ìyanu, ó ju ìfẹ́ obìnrin lọ.” Lóòótọ́, ìmọrírì mímúná ni ó sàmì sí ipò-ìbátan wọn.—2 Samueli 1:26.
8. Àwọn obìnrin méjì wo ni wọ́n fi àkànṣe ìfẹ́ni hàn fún araawọn ẹnìkínní kejì, èésìtiṣe?
8 A tún ní àpẹẹrẹ rere nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nípa àkànṣe ìfẹ́ni nípa ti àwọn obìnrin méjì, Naomi àti Rutu opó aya ọmọ rẹ̀. Padà rántí àwọn ọ̀rọ̀ Rutu sí Naomi: “Máṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀, tàbí láti padà kúrò lẹ́yìn rẹ: nítorí ibi tí ìwọ bá lọ, ni èmi ó lọ; ibi tí ìwọ bá sì wọ̀, ni èmi ó wọ̀: àwọn ènìyàn rẹ ni yóò máa ṣe ènìyàn mi, Ọlọrun rẹ ni yóò sì máa ṣe Ọlọrun mi.” (Rutu 1:16) Àwa kò ha gbọ́dọ̀ parí-èrò pé Naomi, nípa ìwà rẹ̀ àti nípa sísọ̀rọ̀ tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Jehofa, ṣèrànwọ́ láti ru ìdáhùnpadà onímọrírì yìí sókè nínú Rutu bí?—Fiwé Luku 6:40.
Àpẹẹrẹ Aposteli Paulu
9. Kí ni ó fihàn pé Paulu jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ níti ìfẹ́ni ará?
9 Gẹ́gẹ́ bí a ti ríi, aposteli Paulu ní àkànṣe ìfẹ́ni ará ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ fún Timoteu. Ṣùgbọ́n ó tún fi àgbàyanu àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa fífi ìfẹ́ni ará ọlọ́yàyà hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní gbogbogbòò. Ó sọ fún àwọn alàgbà láti Efesu pé “fún ọdún mẹ́ta, [òun] kò dẹ́kun àti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.” Ọ̀yàyà ìfẹ́ni ará ha kọ́ ni èyí bí? Kò sí iyèméjì kankan nípa rẹ̀! Wọn sì nímọ̀lára lọ́nà kan-náà nípa Paulu. Nìgbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn kò ní ríi mọ́, “gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu ní ọrùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.” (Iṣe 20:31, 37) Ìfẹ́ni ará tí a gbékarí ìmọrírì ha kọ́ nìyí bí? Bẹ́ẹ̀ni! Ìfẹ́ni ará rẹ̀ ni a tún rí láti inú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní 2 Korinti 6:11-13 (NW): “A ti la ẹnu wa sí yín, ẹ̀yin ará Korinti, ọkàn-àyà wa ni a ti mú gbòòrò. Ààyè kò há fún yín ní inú wa, ṣùgbọ́n ààyè há fún yín nínú ìfẹ́ni oníkẹ̀ẹ́ ti ẹ̀yin tìkáraayín. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ìdápadà—mo ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀—ẹ̀yin, pẹ̀lú, ẹ gbòòrò síwájú.”
10. Àìní ìfẹ́ni wo ni o ṣamọ̀nà sí ríròyìn tí Paulu ròyìn àwọn àdánwò rẹ̀ ní 2 Korinti orí 11?
10 Ní kedere, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Korinti ń ṣaláìní ìfẹ́ni ará tí ó jẹ́ ti ìmọrírì fún aposteli Paulu. Nípa báyìí, díẹ̀ nínú wọn ṣàròyé pé: “Ìwé rẹ̀ wúwo, wọ́n sì lágbára; ṣùgbọ́n ìrísí rẹ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò níláárí.” (2 Korinti 10:10) Ìdí nìyẹn tí Paulu fi tọ́ka sí “àwọn aposteli gígagíga” wọn sì sún un láti sọ nípa àwọn àdánwò tí ó ti faradà, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní 2 Korinti 11:5, 22-33.
11. Ẹ̀rí wo ni ó wà níbẹ̀ nípa ìfẹ́ni Paulu fún àwọn Kristian ní Tessalonika?
11 Ìfẹ́ni ọlọ́yàyà Paulu fún àwọn wọnnì tí ó jíṣẹ́ fún hàn gbangba ní pàtàkì láti inú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní 1 Tessalonika 2:8: “Ní níní ìfẹ́ni oníkẹ̀ẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa dáradára láti fún yín, kìí ṣe kìkì ìhìnrere Ọlọrun nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn tiwa fúnraawa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yin di àyànfẹ́ fún wa.” Ní tòótọ́, ó ní irú ìfẹ́ni bẹ́ẹ̀ fún àwọn arákùnrin titun wọnyí débi pé nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́—ó ní ìháragàgà tóbẹ́ẹ̀ láti mọ bí wọ́n ti ń farada inúnibíni—ó rán Timoteu sí wọn, ẹni tí ó fúnni ní ìròyìn rere tí ó tu Paulu lára gidigidi. (1 Tessalonika 3:1, 2, 6, 7) Ìwé Insight on the Scriptures ṣàkíyèsí dáradára pé: “Ìdè ìfẹ́ni ará wà láàárín Paulu àti àwọn wọnnì tí òun jíṣẹ́ fún.”
Ìmọrírì—Kọ́kọ́rọ́ náà sí Ìfẹ́ni Ará
12. Àwọn ìdí wo ni ó wà níbẹ̀ fún fífi ìfẹ́ni ọlọ́yàyà hàn fún àwọn arákùnrin wa?
12 Lọ́nà tí kò níyèméjì nínú, kọ́kọ́rọ́ náà sí ìfẹ́ni ará jẹ́ ìmọrírì. Gbogbo àwọn ìráńṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ ti Jehofa kò ha ní àwọn ànímọ́ tí a mọrírì, tí ó béèrè fún ìfẹ́ni wa, tí ó sì ń mú kí a kúndùn wọn bí? Gbogbo wa ni a ń wá Ìjọba Ọlọrun àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Gbogbo wa ni a ń fàyà rán ìjà alágbára lòdì sí àwọn ọ̀tá wa ìgbà gbogbo mẹ́ta: Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀, ayé búburú tí ó wà lábẹ́ ìdarí Satani, àti àwọn ìtẹ̀sí ìmọtara-ẹni-nìkan ti ẹran-ara abẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogúnbá. Àwa kò ha níláti máa fìgbà gbogbo mú ìdúró náà pé àwọn arákùnrin wa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ní ojú-ìwòye àwọn ipò-àyíká bí? Olúkúlùkù nínú ayé ni ó wà yálà níhà ọ̀dọ̀ Jehofa tàbí níhà ọ̀dọ̀ Satani. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa olùṣèyàsímímọ́ wà níhà ọ̀dọ̀ Jehofa, bẹ́ẹ̀ni, níhà ọ̀dọ̀ wa, àti nítorí náà wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí ìfẹ́ni ará wa.
13. Èéṣe tí a fi níláti ní ìfẹ́ni ọlọ́yàyà fún àwọn alàgbà?
13 Kí ni nípa mímọrírì àwọn alàgbà wa? Kò ha yẹ kí á ní ìmọ̀lára ọlọ́yàyà nínú ọkàn-àyà wa fún wọn ní ojú-ìwòye ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe làálàá nítorí àwọn ire ìjọ? Bíi gbogbo wa, wọ́n níláti pèsè fún araawọn àti ìdílé wọn. Wọ́n tún ní àwọn iṣẹ́-àìgbọdọ̀máṣe kan-náà gẹ́gẹ́ bí àwa yòókù láti ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, kí wọ́n sì ṣàjọpín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá. Ní àfikún, wọ́n ní iṣẹ́-àìgbọdọ̀máṣe náà láti múra àwọn apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún àwọn ìpàdé sílẹ̀, sọ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé fún gbogbo ènìyàn, kí wọ́n sì bójútó àwọn ìṣòro tí ń dìde nínú ìjọ, èyí tí ó máa ń ní ọ̀pọ̀ wákàtí ìgbẹ́jọ́ ìdájọ́ nínú nígbà mìíràn. Lóòótọ́, a fẹ́ láti “máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”—Filippi 2:29.
Fífi Ìfẹ́ni Ará Hàn
14. Àwọn ìwé mímọ́ wo ni ó pàṣẹ fún wa láti fi ìfẹ́ni ará hàn?
14 Láti wu Jehofa, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀lára ọlọ́yàyà ti ìfẹ́ni ará hàn fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, àní gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi àti Paulu ti ṣe. A kà pé: “Nínú [ìfẹ́ni ará] ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún araayín ẹnìkínní kejì.” (Romu 12:10, Kingdom Interlinear) “Níti ìtọ́ka sí [ìfẹ́ni ará], ẹ̀yin kò nílò wa láti máa kọ̀wé sí yín, nítorí ẹ̀yin fúnraayín ni a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun láti fẹ́ràn ẹnìkínní kejì.” (1 Tessalonika 4:9, Int) “Ẹ jẹ́ kí [ìfẹ́ni ará] yín máa báa lọ.” (Heberu 13:1, Int) Dájúdájú ó tẹ́ Bàbá wa ọ̀run lọ́rùn nígbà tí a bá fi ìfẹ́ni ará hàn fún àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé!
15. Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a lè gbà fi ìfẹ́ni ará hàn?
15 Ní àkókò àwọn aposteli, àwọn Kristian ni ó jẹ́ àṣà wọn láti máa kí araawọn ẹnìkínní kejì pẹ̀lú “ìfẹnukonu mímọ́” tàbí “ìfẹnukonu ìfẹ́.” (Romu 16:16; 1 Peteru 5:14) Nítòótọ́ ìfihàn ìfẹ́ni ará ni ó jẹ́! Lónìí, ní apá ibi tí ó pọ̀ jùlọ lórí ilẹ̀-ayé, ìfihàn tí ó túbọ̀ yẹ yóò jẹ́ ẹ̀rín músẹ́ pẹ̀lú òtítọ́-inú bíi ti ọ̀rẹ́ àti ìgbanilọ́wọ́ gírígírí. Ní àwọn ilẹ̀ Latin, irú bíi Mexico, ìkíni lọ́nà ti fífọwọ́ gbánimọ́ra wà, tí ó jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ni nítòótọ́. Ìfẹ́ni ọlọ́yàyà yìí ní ipa ti àwọn ará wọ̀nyí lè jẹ́ apákan ìdí fún ìbísí ńlá tí ń wáyé ní àwọn ilẹ̀ wọn.
16. Àwọn àǹfààní wo ni a ní láti fi ìfẹ́ni ará hàn ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
16 Nígbà tí a bá wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwa ha ń ṣe àkànṣe ìsapá láti fi ìfẹ́ni ará hàn bí? Ó lè jẹ́ kí á ní àwọn ọ̀rọ̀ oníṣìírí láti sọ, ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí ó jọ pé wọ́n soríkọ́. A sọ fún wa láti “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí wọ́n soríkọ́.” (1 Tessalonika 5:14, NW) Dájúdájú ìyẹn jẹ́ ọ̀nà kan nínú èyí tí a lè gbà ta àtaré ọ̀yàyà ìfẹ́ni ará. Ọ̀nà rere mìíràn ni láti fi ìmọrírì hàn fún ọ̀rọ̀-àsọyé dáradára kan fún gbogbo ènìyàn, apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí a bójútó dáradára, ìsapá rere tí akẹ́kọ̀ọ́ olùbánisọ̀rọ̀ kan lò nínú Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
17. Báwo ni alàgbà kan ṣe jèrè ìfẹ́ni ìjọ?
17 Kí ni nípa kíkésí àwọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sínú ilé wa fún oúnjẹ kan tàbí bóyá ìpápánu kan lẹ́yìn ìpàdé bí kò bá pẹ́ jù? Kò ha yẹ kí á jẹ́ kí ìmọ̀ràn Jesu ní Luku 14:12-14 darí wa bí? Lẹ́ẹ̀kan rí míṣọ́nárì tẹ́lẹ̀rí kan ni a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága nínú ìjọ kan níbi tí gbogbo àwọn tí ó kù ti wá láti inú ẹ̀yà-ìran ọ̀tọ̀. Ó fòye mọ àìsí ìfẹ́ni ará, nítorí náà ó ṣe ìwéwèé kan láti yanjú ipò-ọ̀ràn náà. Báwo? Ní gbogbo ọjọ́ Sunday, ó ń késí ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún oúnjẹ. Nígbà tí ó fi máa di òpin ọdún kan, gbogbo wọn ń fi ọ̀yàyà ìfẹ́ni ará hàn sí i.
18. Báwo ni a ṣe lè fi ìfẹ́ni ará hàn fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí ń ṣàìsàn?
18 Nígbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ń ṣàìsàn, ní ilé tàbí ní ilé-ìwòsàn, ìfẹ́ni ará yóò mú kí á jẹ́ kí ẹni yẹn mọ̀ pé a bìkítà. Tàbí kí ni nípa ti àwọn wọnnì tí wọ́n ń gbé nínú ilé ìtọ́jú-aláìsàn? Èéṣe tí o kò fi ṣe ìbẹ̀wò fúnraàrẹ, ṣe ìkésíni orí tẹlifóònù, tàbí fi káàdì kan tí ń fi èrò ọ̀yàyà hàn ránṣẹ́?
19, 20. Báwo ni a ṣe lè fihàn pé ìfẹ́ni ará wa ti gbòòrò jáde?
19 Nígbà tí a bá ń fi irú ìfẹ́ni ará bẹ́ẹ̀ hàn, a lè béèrè lọ́wọ́ araawa pé, ‘Ìfẹ́ni ará mi ha jẹ́ ti olójúṣàájú bí? Ǹjẹ́ irú àwọn okùnfà bẹ́ẹ̀ bíi àwọ̀-ara, ẹ̀kọ́-ìwé, tàbí àwọn ohun-ìní ti ara ha ń nípa lórí ìfihànjáde ìfẹ́ni ará mi bí? Mo ha níláti gbòòrò jáde nínú ìfẹ́ni ará mi, gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti rọ àwọn Kristian ní Korinti láti ṣe bí?’ Ìfẹ́ni ará yóò mú kí á wo àwọn arákùnrin wa lọ́nà tí ń gbéniró, ní mímọrírì wọn fún àwọn ànímọ́ rere wọn. Ìfẹ́ni ará yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti yọ̀ fún ìlọsíwájú arákùnrin wa dípò ṣíṣe ìlara rẹ̀.
20 Ìfẹ́ni ará tún níláti mú wa wà lójúfò láti ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Ó níláti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn orin wa (Nọmba 92) ti sọ ọ́:
“Ran àwọn aláìlera lọ́wọ́,
Kí wọ́n baà lè fì ‘gboyà sọ̀rọ̀.
Máṣe gbàgbé àwọn ọ̀dọ́ láé,
Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti d’alágbára.”
21. Ìdáhùnpadà wo ni a lè retí nígbà tí a bá fi ìfẹ́ni ará hàn?
21 Nítorí náà ẹ máṣe jẹ́ kí á gbàgbé pé nínú fífi ìfẹ́ni ará hàn, ìlànà náà tí Jesu sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè ṣeéfisílò pé: “Ẹ fifúnni, a ó sì fifún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n sí àyà yín; nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.” (Luku 6:38) A ń ṣàǹfààní fún araawa nígbà tí a bá fi ìfẹ́ni ará hàn, ní fífi ìgbéníyì hàn fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ìráńṣẹ́ Jehofa bí àwa náà ti jẹ́. Àwọn wọnnì tí wọ́n ní inúdídùn nínú fífi ìfẹ́ni ará hàn jẹ́ aláyọ̀ nítòótọ́!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e: “Ìfẹ́ (Agape)—Ohun tí Kò Jẹ́ àti Ohun tí Ó Jẹ́.”
Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Àwọn ọ̀rọ̀ Griki wo ni ó dá lórí àwọn èrò-ìmọ̀lára wa, báwo ni wọ́n sì ṣe yàtọ̀ síra?
◻ Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí ìfẹ́ni ará?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni a ní nípa àkànṣe ìfẹ́ni ará?
◻ Èéṣe tí a fi níláti ní ìfẹ́ni ọlọ́yàyà fún àwọn arákùnrin wa àti fún àwọn alàgbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Aposteli Peteru rọ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti fi ìfẹ́ni ará kún ìgbàgbọ́ àti àwọn ànímọ́ Kristian wọn mìíràn