ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/1 ojú ìwé 3-5
  • Mímú Àdììtú Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà Ṣe Kedere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Àdììtú Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà Ṣe Kedere
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà Kiri
  • Báwo ni Orúkọ náà Ṣe Di Àdììtú Kan?
  • Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà àti Ọjọ́-Ọ̀la Wa
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Bí O Ṣe Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2004
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Máa Gbé Orúkọ Ńlá Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/1 ojú ìwé 3-5

Mímú Àdììtú Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà Ṣe Kedere

Ó fani lọ́kàn mọ́ra láti rí i pé Kùránì àwọn Musulumi àti Bibeli àwọn Kristian tọ́ka sí orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà. Ìjíròrò yìí ṣàlàyé ìtumọ̀ àti ìjẹ́pàtàkì orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà. Ó tún fihàn bí orúkọ yẹn ṣe nípa lórí gbogbo aráyé àti ọjọ́-ọ̀la wa níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé.

ÀRÀÁDỌ́TA-Ọ̀KẸ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti gbé wọ́n sì ti kú lórí ilẹ̀-ayé yìí. Nínú àwọn ọ̀ràn púpọ̀ jùlọ orúkọ wọn ti kú pẹ̀lú wọn, ìrántí wọn sì ti di ìgbàgbé. Ṣùgbọ́n àwọn orúkọ ńlá díẹ̀—bíi Avicenna, Edison, Pasteur, Beethoven, Gandhi, àti Newton—ń wà nìṣó. Àwọn orúkọ wọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú àwọn àṣeyọrí, ìṣàwárí, àti ìhùmọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ orúkọ náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, orúkọ kan wà tí ó tóbi ju gbogbo orúkọ mìíràn lọ. Gbogbo àwọn ohun ìyanu àtijọ́ àti ti ìsinsìnyí ní gbogbo àgbáyé ní ó sopọ̀ mọ́ ọn. Họ́wù, ìrètí aráyé fún ìgbésí-ayé gígùn àti aláyọ̀ wémọ́ orúkọ yìí!

Ọ̀pọ̀ ti fẹ́ láti wá mọ orúkọ yìí. Wọ́n ti wá a kiri wọ́n sì ti béèrè nípa rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò tíì rí i. Fún wọn ó ṣì jẹ́ àdììtú kan síbẹ̀. Ní tòótọ́, kò sí ènìyàn kan tí ó lè ṣàwárí orúkọ yìí àyàfi bí Olórúkọ náà bá ṣípayá rẹ̀ fún un. A láyọ̀ pé, àdììtú orúkọ aláìlábàádọ́gba yìí ni a ti mú ṣe kedere. Ọlọrun fúnraarẹ̀ ni ó ti ṣe èyí kí àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ baà lè mọ̀ nípa rẹ̀. Ó ṣípayá orúkọ rẹ̀ fún Adamu, lẹ́yìn náà fún Abrahamu, fún Mose, àti fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ olùṣòtítọ́ mìíràn nígbà àtijọ́.

Wíwá Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà Kiri

Kùránì sọ nípa ẹnìkan tí “ó ní mímọ̀ tírà lọ́dọ̀.” (27:40, AL-KURÁNÌ TI A TUMỌ SI EDE YORUBA) Ní ṣíṣàlàyé ẹsẹ yìí, àlàyé-ọ̀rọ̀ kan tí a mọ̀ sí Tafsīr Jalālayn sọ pé: “Asaf ọmọkùnrin Barkhiyā jẹ́ ọkùnrin olódodo. Ó mọ orúkọ títóbilọ́lá jùlọ ti Ọlọrun, nígbàkigbà tí ó bá sì képè é, a ń dá a lóhùn.” Èyí rán wa létí Asafu òǹkọ̀wé Bibeli náà, tí ó sọ nínú Orin Dafidi 83:18 pé: “Kí àwọn ènìyàn kí ó lè mọ̀ pé ìwọ, orúkọ ẹni-kanṣoṣo tí í jẹ́ Jehofa, ìwọ ni Ọ̀gá-ògo lórí ayé gbogbo.”

Nínú Kùránì 17:2, a kà pé: “Àtipé Àwa fún Musa ní Tírà Àwa si ṣe é ní afinimọ̀nà fún àwọn ọmọ Israila.” Nínú àwọn Ìwé Mímọ́ [Tírà] wọnnì, Mose bá Ọlọrun sọ̀rọ̀, ní wíwí pé: “Nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israeli, tí èmi ó sì wí fún wọn pé, Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí yín; tí wọn ó sì bi mí pé, Orúkọ rẹ̀? kí ni èmi óò wí fún wọn?” Ọlọrun dá Mose lóhùn ní wíwí pé: “Báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún àwọn ọmọ Israeli; OLUWA, [“Jehofa,” NW] Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, àti Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán mi sí yín: èyí ni orúkọ mi títíláé.”—Eksodu 3:13, 15.

Ní àkókò ìgbàanì, àwọn ọmọ Israeli mọ orúkọ ńlá ti Ọlọrun yìí. Wọ́n tilẹ̀ ń lò ó gẹ́gẹ́ bí apákan orúkọ tiwọn fúnraawọn. Bí ó ti jẹ́ pé nísinsìnyí ẹnìkan lè rí orúkọ náà Abdullah, tí ó túmọ̀sí “Ìránṣẹ́ Ọlọrun,” àwọn ènìyàn Israeli ìgbàanì ní orúkọ náà Obadiah, tí ó túmọ̀sí “Ìránṣẹ́ Jehofa.” Ìyá wòlíì Mose ni a sọ ní Jokebedi, èyí tí ó ṣeéṣe kí ó túmọ̀sí “Ògo Ni Jehofa.” Orúkọ náà Johannu túmọ̀sí “Jehofa Ti Jẹ́ Olóore-Ọ̀fẹ́.” Orúkọ wòlíì Elija sì túmọ̀sí “Ọlọrun Mi Ni Jehofa.”

Àwọn wòlíì mọ orúkọ ńlá yìí wọ́n sì lò ó pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. A rí i níye ìgbà tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin lọ nínú Ìwé Mímọ́. Jesu Kristi, ọmọkùnrin Maria, tẹnumọ́ ọn nígbà tí ó sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọrun pé: “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fifún mi . . . Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mímọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn.” (Johannu 17:6, 26) Nínú àlàyé-ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó lókìkí lórí Kùránì, Bayḍāwī ṣàlàyé lórí Kùránì 2:87, ní wíwí pé Jesu a máa “sọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kú dalààyè nípasẹ̀ orúkọ títóbilọ́lá jùlọ ti Ọlọrun.”

Nígbà náà, kí ni ó ṣẹlẹ̀ láti mú kí orúkọ yẹn di àdììtú kan? Kí ni orúkọ yẹn níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́-ọ̀la ẹnìkọ̀ọ̀kan wa?

Báwo ni Orúkọ náà Ṣe Di Àdììtú Kan?

Àwọn kan ronú pé “Jehofa” ní èdè Heberu túmọ̀sí “Allah” (Ọlọrun). Ṣùgbọ́n “Allah” ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ʼElo·himʹ, èdè Heberu náà tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsọdipúpọ̀ ọláńlá ti ọ̀rọ̀ náà ʼelohʹah (ọlọrun). Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kan dìde láàárín àwọn Ju èyí tí ó ṣèdíwọ́ fún wọn láti máṣe pe orúkọ àtọ̀runwá náà, Jehofa. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá ń ka Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sì rí orúkọ náà Jehofa, ó di àṣà wọn láti sọ pé ʼAdho·naiʹ, èyí tí ó túmọ̀sí “Oluwa.” Ní àwọn ibìkan, wọ́n tilẹ̀ yí ojúlówó ọ̀rọ̀-ẹsẹ̀-ìwé Heberu náà padà láti “Jehofa” sí ʼAdho·naiʹ.

Àwọn aṣáájú ìsìn Kristẹndọm tẹ̀lé ipa ọ̀nà kan-náà. Wọ́n fi “Ọlọrun” (“Allah” ní èdè Lárúbáwá) àti “Oluwa” rọ́pò orúkọ náà Jehofa. Ìyẹn pakún ìgbèrú ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ èké ti Mẹ́talọ́kan, èyí tí kò ní ìpìlẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́. Nítorí èyí, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ń fi àṣìṣe jọ́sìn Jesu àti ẹ̀mí mímọ́ wọ́n sì kà wọ́n sí ọgba pẹ̀lú Ọlọrun.a

Fún ìdí yìí, ẹ̀bi náà fún àìmọ̀kan tí ó tànkálẹ̀ nípa orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà jẹ́ ti àwọn aṣáájú ìsìn Ju, àti ti Kristẹndọm. Ṣùgbọ́n Ọlọrun sọtẹ́lẹ̀ pé: “Èmi ó sì sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́, . . . àwọn [orílẹ̀-èdè, NW] yóò sì mọ̀ pé èmi ni [Jehofa, NW].” Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ láàárín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Èéṣe? Nítorí pé òun kìí wulẹ̀ ṣe Ọlọrun àwọn Ju tàbí ti orílẹ̀-èdè tàbí ti àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Jehofa ni Ọlọrun gbogbo aráyé pátá.—Esekieli 36:23; Genesisi 22:18; Orin Dafidi 145:21; Malaki 1:11.

Orúkọ Títóbilọ́lá Jùlọ náà àti Ọjọ́-Ọ̀la Wa

Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣáà pe orúkọ, [Jehofa, NW], ni a ó gbàlà.” (Romu 10:13) Ìgbàlà wa ní ọjọ́ ìdájọ́ yóò tanmọ́ mímọ̀ tí a mọ orúkọ Ọlọrun. Láti mọ orúkọ rẹ̀ ní nínú mímọ àwọn ànímọ́-ìwà, iṣẹ́, àti àwọn ète rẹ̀ àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà gíga rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Abrahamu mọ orúkọ Ọlọrun ó sì képe orúkọ yẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ó gbádùn ipò-ìbátan rere pẹ̀lú Ọlọrun, ó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú rẹ̀, ó gbáralé e, ó sì ṣègbọràn sí i. Abrahamu tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Bákan náà, mímọ orúkọ Ọlọrun ń fà wá súnmọ́ ọn ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú ipò-ìbátan ti ara-ẹni dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, ní dídìrọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ìfẹ́ rẹ̀.—Genesisi 12:8; Orin Dafidi 9:10; Owe 18:10; Jakọbu 2:23.

A kà nínú Bibeli pé: “Oluwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́, a sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa, tí wọ́n sì ń ṣe àṣàrò orúkọ rẹ̀.” (Malaki 3:16) Èéṣe tí ó fi yẹ kí a “ṣe àṣàrò” orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà? Lóréfèé, orúkọ náà Jehofa túmọ̀sí “Ó Ń Mú Kí Ó Wà.” Èyí fi Jehofa hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹni náà tí ń mú kí òun fúnraarẹ̀ alára di Olùmú àwọn ìlérí ṣẹ. Nígbà gbogbo ní ó máa ń mú kí àwọn ète rẹ̀ jásí èyí tí ó ní ìmúṣẹ. Òun ni Ọlọrun Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá kanṣoṣo náà, tí ó ní gbogbo ànímọ́-ìwà rere. Kò sí ẹyọ ọ̀rọ̀ kanṣoṣo tí ó lè ṣàkàwé bí Ọlọrun ti rí. Ṣùgbọ́n Ọlọrun yan orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà—Jehofa—fún araarẹ̀ ó sì ránnilétí gbogbo àwọn ànímọ́-ìwà, ànímọ́, àti ète rẹ̀.

Nínú Ìwé Mímọ́, Ọlọrun sọ fún wa nípa àwọn ète rẹ̀ fún ìran aráyé. Jehofa Ọlọrun dá ènìyàn láti gbádùn ìwàláàyè àìnípẹ̀kun, àti aláyọ̀ nínú Paradise. Ìfẹ́-inú rẹ̀ fún aráyé ni pé kí gbogbo ènìyàn parapọ̀ di ìdílé kanṣoṣo, tí ó sopọ̀ṣọ̀kan nínú ìfẹ́ àti àlàáfíà. Ọlọrun ìfẹ́ yóò mú ète yìí ṣẹ ní ọjọ́-ọ̀la tí kò pẹ́ mọ́.—Matteu 24:3-14, 32-42; 1 Johannu 4:14-21.

Ọlọrun ṣàlàyé àwọn ìdí fún ìjìyà aráyé ó sì fihàn pé ìgbàlà ṣeéṣe. (Ìfihàn 21:4) Ní Orin Dafidi 37:10, 11, a kà pé: “Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: nítòótọ́ ìwọ ó fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn-tútù ni yóò jogún ayé; wọ́n ó sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Wo Kùránì 21:105 pẹ̀lú.

Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun ni a ó fi orúkọ ńlá rẹ̀ mọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò níláti mọ̀ pé òun ni Jehofa. Àǹfààní àgbàyanu wo ni ó jẹ́ láti mọ orúkọ títóbilọ́lá jùlọ náà, láti jẹ́rìí sí i, àti láti dìrọ̀ mọ́ ọn! Ní ọ̀nà yẹn, ète aláyọ̀ ti Ọlọrun yóò ní ìmúṣẹ nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa: “Nítorí tí ó fẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ sí mi, nítorí náà ni èmi ó ṣe gbà á: èmi ó gbé e lékè, nítorí tí ó mọ orúkọ mi. Òun ó pe orúkọ mi, èmi ó sì dá a lóhùn. . . . Ẹ̀mí gígùn ni èmi ó fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi ó sì fi ìgbàlà mi hàn án.”—Orin Dafidi 91:14-16.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀rí pé Mẹ́talọ́kan kìí ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli, wo ìwé-pẹlẹbẹ náà Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? tí a tẹ̀ jáde ní 1991 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Níbi ìgbẹ́ tí ń jó, Ọlọrun fi ara rẹ̀ hàn fún Mose pé òun ni ‘Jehofa, Ọlọrun Abrahamu’

[Credit Line]

Mose àti Ìgbẹ́ tí Ń Jó, láti ọwọ́ W. Thomas, Sr.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́