ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/1 ojú ìwé 6
  • Ọ̀wọ̀ fún Ìjẹ́mímọ́ Ìwàláàyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀wọ̀ fún Ìjẹ́mímọ́ Ìwàláàyè
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Múni Dúró Ṣinṣin Lórí Ọ̀ràn Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìgbà Tí Mo Fọ́jú Lojú Mi Tó Là!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/1 ojú ìwé 6

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ọ̀wọ̀ fún Ìjẹ́mímọ́ Ìwàláàyè

BIBELI fihàn pé ẹ̀jẹ̀ ṣeyebíye ní ojú Ọlọrun àti pé òun dẹ́bi fún àṣìlò rẹ̀. (Lefitiku 17:14; Iṣe 15:19, 20, 28, 29) Nítorí àwọn ìtọ́ni Bibeli wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí gba ìfàjẹ̀sínilára.

Láti ran àwọn dókítà àti òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn lọ́wọ́ láti lóye ìdúró àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa níti ìsìn lórí ọ̀ràn yìí àti láti mọrírì pé àwọn Ẹlẹ́rìí yóò gba ìtọ́jú àfidípò, Watch Tower Society ti ṣètò àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé-Ìwòsàn (HLC) ní onírúurú ilẹ̀. Àwọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ wọ̀nyí ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé-ìwòsàn láti bá àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn sọ̀rọ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ní àwọn ìlú-ńlá méjìlá ní Poland, iye ìpàdé tí ó ju igba lọ ni a ti ṣe, èyí tí ó ní nínú àwọn dókítà ìṣègùn tí iye wọn ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ, tí wọ́n jẹ́ èkìdá àwọn olórí ilé-ìgbàtọ́jú tàbí wọ́ọ̀dù ilé-ìwòsàn. Ohun tí ó tẹ̀lé e yìí wáyé lákòókò ọ̀kan nínú irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀:

“Ìpàdé kan nínú Ilé-Ìtọ́jú Oníṣẹ́-Abẹ Ọkàn-Àyà ní Zabrze jẹ́ àṣeyọrí tí ó kẹ́sẹjárí jùlọ. Láti ọdún 1986 ẹgbẹ́ tí ó wà ní ilé-ìtọ́jú náà ti ń ṣiṣẹ́-abẹ fún àwọn ará wa láìlo ẹ̀jẹ̀. Títí di ìsinsìnyí, ogójì irú iṣẹ́-abẹ bẹ́ẹ̀ ni a ti ṣe. Ilé-ìtọ́jú náà ṣetán láti gba àwọn aláìsàn jákèjádò Poland àti láti àwọn ilu òkè-òkun bákan náà. Lẹ́yìn ìjíròrò aláàádọ́ta ìṣẹ́jú, adelé olórí wọ́ọ̀dù ilé-ìwòsàn kan fi àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé-Ìwòsàn hàn fún àwùjọ àwọn agbàtọ́jú kan ó sì sọ pé: ‘Ẹlẹ́rìí Jehofa ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé-ìtọ́jú wa, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́. Kìí ṣe kìkì àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nìkan ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olùgbàtọ́jú yòókù pẹ̀lú ń jàǹfààní láti inú ìrànlọ́wọ́ wọn. Ọpẹ́ ni fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó ti dá wa lójú pé iṣẹ́-abẹ ọkàn-àyà tí ó díjú ni a lè ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀.

“‘Fún àpẹẹrẹ, a ṣe iṣẹ́-abẹ fún obìnrin yìí [ní títọ́ka sí ọ̀kan lára àwọn olùgbàtọ́jú rẹ̀] láìlo ẹ̀jẹ̀, ọjọ́ Monday ni ó sì ń lọ sí ilé. Èmi yóò fẹ́ láti sọ pé a kìí lo ẹ̀jẹ̀ lemọ́lemọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó léwu. Ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú fáírọ́ọ̀sì HIV, àrùn mẹ́dọ̀wú, àti àìtètè jèrè okun padà.

“‘Katoliki ni mí, ṣùgbọ́n ní ilé wa a ti sábà máa ń fààyè gba ojú-ìwòye àwọn ẹlòmíràn. Ní ọjọ́ kan mo rin Pápá-Ìṣeré Slaski kiri pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, pápá-ìṣeré yìí ni a ti pa tì, ṣùgbọ́n a ṣàkíyèsí pé nísinsìnyí ó ti yípadà kọjá dídámọ̀. Mo béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ náà nípa bí ìyípadà yìí ti ṣe wáyé. Ó sọ pé àwọn olùṣàbójútó pápá-ìṣeré náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ìrètí títún pápá-ìṣeré náà ṣe padà, ṣùgbọ́n wọ́n fi háyà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àwọn ẹ̀wẹ̀ sì tún un ṣe.

“‘Nítorí náà àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ènìyàn tí gbogbo wa lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ lára wọn. Mo ronú pé nínú wọ́ọ̀dù yìí a níláti jẹ́ ẹni tí ó lè fààyè gba ojú-ìwòye àwọn ẹlòmíràn.’ Lẹ́yìn náà, ní títọ́ka sí Ẹlẹ́rìí kan tí a óò ṣe iṣẹ́-abẹ fún ní ọjọ́ díẹ̀ síi, ó sọ pé: ‘Obìnrin yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, a ó sì ṣe iṣẹ́-abẹ fún un láìlo ẹ̀jẹ̀.’”

Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí fipá mú àwọn ẹlòmíràn láti gba èrò ìgbàgbọ́ wọn gbọ́, wọ́n ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn aposteli wọ́n sì ń “gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.” (Iṣe 5:29) Èyí ní nínú níní ọ̀wọ̀ fún ẹ̀jẹ̀. Wọ́n mọrírì rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá bọ̀wọ̀ fún ìdánilójú wọn níti ìsìn lórí ọ̀ràn yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́