ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/1 ojú ìwé 23-27
  • Ìgbà Tí Mo Fọ́jú Lojú Mi Tó Là!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tí Mo Fọ́jú Lojú Mi Tó Là!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Èrò Tí Mo Kọ́kọ́ Ní Nígbà Tí Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Ìṣègùn
  • “Ríràn Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ fún Mi Láyọ̀”
  • Títọ́jú Àwọn Aláìsàn Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí
  • Àjálù Kan Dé Bá Mi
  • Láti Ìbẹ̀rẹ̀ Ni Mo Ti Lérò Òdì Nípa Wọn
  • Mo Tún Dẹni Tó Wúlò Padà
  • Jíjẹ́ Olóòótọ́ Nígbà Wàhálà
  • Ìwà Àwọn Dókítà Yí Padà
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
  • Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìtọ́jú àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Laráyé Ń Gba Tiẹ̀ Báyìí
    Jí!—2000
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/1 ojú ìwé 23-27

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìgbà Tí Mo Fọ́jú Lojú Mi Tó Là!

GẸ́GẸ́ BÍ EGON HAUSER ṢE SỌ Ọ́

Lẹ́yìn oṣù méjì tójú mi ti fọ́, ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí òtítọ́ Bíbélì tí mo ti pa tì ní gbogbo ìgbésí ayé mi.

NÍGBÀ tí mo bojú wẹ̀yìn wo àádọ́rin ọdún tí mo ti lò nínú ìgbésí ayé mi, èyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ló tẹ́ mi lọ́rùn gan-an. Ṣùgbọ́n, ká sọ pé mo lè yí apá kan padà nínú rẹ̀ ni, ì bá wù mí kí n ti mọ Jèhófà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò tí mo wá mọ̀ ọ́n yìí.

Ọdún 1927 ni wọ́n bí mi ní orílẹ̀-èdè Uruguay tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Ajẹntínà àti Brazil, Olódùmarè sì fi àyíká rírẹwà tó pọ̀ gan-an jíǹkí orílẹ̀-èdè ọ̀hún ní apá Etíkun Àtìláńtíìkì. Àtọmọdọ́mọ àwọn tó ṣí wá láti orílẹ̀-èdè Ítálì àti Sípéènì ló pọ̀ jù lórílẹ̀-èdè yìí. Àmọ́ ṣá o, orílẹ̀-èdè Hungary làwọn òbí mi ti ṣí wá, ilé kékeré kan táwọn olùgbé ibẹ̀ kì í yara wọn lẹ́sẹ̀ kan là ń gbé nígbà tí mo ṣì kéré. A kì í tilẹ̀kùn bẹ́ẹ̀ ni a kì í gbé irin dábùú ojú fèrèsé. Kò sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín wa. Àtàwọn ọmọ onílẹ̀ àtàwọn àjèjì, àtòyìnbó àtaláwọ̀ dúdú, ọ̀rẹ́ ni gbogbo wa ń bára wa ṣe.

Onísìn Kátólíìkì paraku làwọn òbí mi, èmi náà si di ọmọ ìdí pẹpẹ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá. Nígbà tí mo wá dàgbà, mo ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò, mo sì jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ tó ń gba bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò yẹn nímọ̀ràn. Níwọ̀n bó ṣe jẹ́ pé iṣẹ́ ìṣègùn ni iṣẹ́ mi, wọ́n pè mí láti kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣètò ní orílẹ̀-èdè Venezuela. Nítorí pé dókítà tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú àìsàn àwọn obìnrin ni wá, ìwádìí nípa àwọn oògùn máà-lóyún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí àtẹ nígbà yẹn ni wọ́n yàn fún àwùjọ wa.

Àwọn Èrò Tí Mo Kọ́kọ́ Ní Nígbà Tí Mò Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Ìṣègùn

Nígbà tí mo ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn nípa ara èèyàn, mo mọyì ọgbọ́n tá a fi dá ara èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, agbára tí ara ní láti bọ̀ sípò kó sì wo ara rẹ̀ sàn lẹ́yìn tí wàhálà bá ti bá a ṣì máa ń jọ mi lójú, irú bí ìgbà tí ẹ̀dọ̀ tàbí egungun ìhà bá padà bọ̀ sípò lẹ́yìn tá a gé apá kan lára wọn kúrò.

Bákan náà, mo máa ń rí àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí, ó sì máa ń bà mí nínú jẹ́ bí wọ́n bá kú látàrí pé wọ́n gbẹ̀jẹ̀ sára. Mò ṣì ń rántí títí dòní olónìí yìí bó ṣe máa ń nira tó láti sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹnì kan tó kú nítorí ìṣòro tó jẹ yọ látinú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà si irú ẹni bẹ́ẹ̀ lára. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ò kì í sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí yẹn pé ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí èèyàn wọn lára ló ṣekú pa á. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun mìíràn la máa ń sọ fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti kọjá, síbẹ̀ mo ṣì máa ń rántí bí ìfàjẹ̀sínilára ṣe máa ń dọkàn mi láàmú, ìyẹn ló wá jẹ́ kí n parí èrò sí pé nǹkan kan wà tí kò dáa nínú ìfàjẹ̀sínilára. Ì bá ti lọ dáa jù ká sọ pé mo ti mọ ohun tí òfin Jèhófà sọ lórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ nígbà yẹn ni! Ká sọ pé mo ti mọ òfin yẹn ni, ǹ bá ti mọ ìdí tọ́kàn mi fi ń dààmú nítorí ìfàjẹ̀sínilára.—Ìṣe 15:19, 20.

“Ríràn Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ fún Mi Láyọ̀”

Bí àkókò ti ń lọ, mo di dókítà oníṣẹ́-abẹ tó ní ìwé àṣẹ, mo sì di olùdarí ọsibítù kan ní ìlú Santa Lucía. Mo tún bá Àjọ Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí Àwọn Ohun Abẹ̀mí ṣiṣẹ́. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ló fún mi láyọ̀ gan-an. Mo ti bá ọ̀pọ̀ èèyàn tọ́jú àìsàn wọn, mo ti yọ wọ́n nínú wàhálà tó dé bá wọn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì ti ṣèrànwọ́ láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là, mo sì ti ṣèrànwọ́ láti mú kí ọ̀pọ̀ ọmọ wà láàyè nípa ríran ìyá wọn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń rọbí. Nítorí àwọn ìrírí tí mo ti ní tẹ́lẹ̀ nípa ìfàjẹ̀sínilára, mi ò kì í fà á síni lára, ẹgbẹẹgbẹ̀rún iṣẹ́ abẹ ni mo sì ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀. Mo lè sọ pé bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń ya jáde lára èèyàn dà bí ìgbà tí omi ń jò nínú àgbá. Ojútùú kan ṣoṣo tó wà ni pé kí á dí ibi tó ń jò lára àgbá yẹn, kì í ṣe ká tún wá máa pọn omi sínú ẹ̀.

Títọ́jú Àwọn Aláìsàn Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí

Àwọn ọdún 1960 ni mo mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n máa ń wá sí ọsibítù wa fún iṣẹ́ abẹ tí ko la ẹ̀jẹ̀ lọ. Mi ò lè gbàgbé obìnrin kan báyìí, aṣáájú ọ̀nà (òjíṣẹ́ alákòókò kíkún) ni, Mercedes Gonzalez sì lorúkọ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ tó wà lára rẹ̀ kéré débi pé àwọn dókítà tó wà ní ọsibítù yunifásítì ò fẹ́ dáwọ́ lé ṣíṣe iṣẹ́ abẹ fún un, wọ́n ti gbà pé kò lè yè é. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ tó wà lára rẹ̀ kò pọ̀ mọ́, a ṣe iṣẹ́ abẹ fún un ní ọsibítù wa. Iṣẹ́ abẹ náà kẹ́sẹ járí, ó sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ lọ fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tá a ṣe iṣẹ́ abẹ yẹn, kó tó wá kú láìpẹ́ yìí lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún.

Kò sígbà tí ìfẹ́ àti aájò táwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi hàn sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tó ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ wa kì í wú mi lórí. Nígbà tí mo bá ń bẹ àwọn aláìsàn wò, mo máa ń gbádùn bí wọ́n ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, mo sì máa ń gba àwọn ìwé tí wọ́n bá fún mi. Mi ò tiẹ̀ rò ó rí pé láìpẹ́, kì í ṣe dókítà wọn nìkan ni màá jẹ́, ṣùgbọ́n pé màá tún di arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí.

Mo túbọ̀ wá sún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí sí i nígbà tí mo fẹ́ Beatriz tó jẹ́ ọmọ ọkùnrin kan tó wá gbàtọ́jú. Àwọn tó pọ̀ jù nínú ìdílé rẹ̀ ló ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, lẹ́yìn tá a sì fẹ́ra tán, òun náà di Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé. Ṣùgbọ́n ní tèmi, iṣẹ́ mi kò fún mi láyè rárá, mò si dẹni tó lókìkí dé àyè kan nídìí iṣẹ́ ìṣègùn. Nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún mi nígbà yẹn. Mì o mọ̀ pé kò ní pẹ́ sígbà yẹn tí àjálù fi máa yí ayé mi padà.

Àjálù Kan Dé Bá Mi

Ọ̀kan nínú àwọn aburú tó lè bá oníṣẹ́-abẹ kan ni kójú ẹ̀ fọ́. Ìyẹn gan-an ló ṣẹlẹ̀ sí mi. Lójijì ni awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó máa ń gba ìmọ́lẹ̀ sára nínú ojú daṣẹ́ sílẹ̀, bí mo ṣe dafọ́jú nìyẹn, mi ò sì mọ̀ bóyá mo tún lè fojú mi ríran. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi tán, mo dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn, wọ́n sì fi ọ̀já di ojú mi méjèèjì, ìbànújẹ́ dorí mi kodò. Mo ti gbà pé mi ò lè wúlò mọ́ mo sì ti sọ̀rètí nù pátápátá débi pé mo pinnu láti gbẹ̀mí ara mi. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àjà kẹrin ni mo wà, mo bọ́ sílẹ̀ kúrò lórí ibùsùn mi, mo sì fọwọ́ tá ràrà lára ògiri, mò ń wá ojú fèrèsé. Mo fẹ́ fò bọ́ sílẹ̀ kí n sì kú dànù. Àmọ́ ọ̀dẹ̀dẹ̀ ọsibítù náà ni mo já sí, nọ́ọ̀sì kan sì mú mi padà sórí ibùsùn mi.

Mi ò tún dá irú ẹ̀ láṣà mọ́. Bí mo ṣe fọ́jú yẹn máa ń mú mi soríkọ́, ó sì tún máa ń múnú bí mi. Nígbà tí mo fọ́jú yìí, mo ṣèlérí fún Ọlọ́run pé bí mo bá tún lè ríran padà, màá ka gbogbo Bíbélì tán látòkèdélẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí ríran díẹ̀díẹ̀, mo sì lè kàwé. Ṣùgbọ́n mi ò lè ṣe ìṣẹ́ abẹ́ fáwọn èèyàn mọ́. Síbẹ̀ wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ kan ní orílẹ̀-èdè Uruguay pé: “No hay mal que por bien no venga,” “Kò sí bí nǹkan ṣe lè burú tó kí àyè ọpẹ́ má wà níbẹ̀.” Mo máa tó mọ bọ́rọ̀ yẹn ṣe jóòótọ́ tó.

Láti Ìbẹ̀rẹ̀ Ni Mo Ti Lérò Òdì Nípa Wọn

Mo fẹ́ ra ẹ̀dà Bíbélì The Jerusalem Bible, tó jẹ́ onílẹ́tà gàdàgbà, ṣùgbọ́n mo gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bíbélì tí kò wọ́n, èyí tí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan sọ pé òun á wá fún mi nílé. Ọmọkùnrin náà mú Bíbélì yẹn wá fún mi lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì. Ìyàwó mi ṣílẹ̀kùn fún un, ó sì ń bá a sọ̀rọ̀, ni mo pariwo lé e lórí, mo sì sọ pé bí ìyàwó mi bá ti sanwó Bíbélì yẹn fún un, kò sí ohun tó tún ń wá mọ́, nítorí náà kó yá a máa lọ. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́ mọ́, ojú ẹsẹ̀ ló filé wa sílẹ̀. Mi o mọ̀ pé ẹni yìí gan-an ló máa wá kópa pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi.

Lọ́jọ́ kan, mo ṣèlérí kan fún ìyàwó mi tí mi ò lè múṣẹ́. Kí n bàa lè múnú ẹ̀ dùn, mo sọ pé màá bá a lọ sí Ìrántí ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Nígbà tọ́jọ́ yẹn kò, mo rántí ìlérí tí mo ṣe, mo sì tẹ̀ lé e lọ sí Ìṣe Ìrántí yẹn. Ọ̀yàyà àti inú rere táwọn èèyàn náà fi kí mi káàbọ̀ wú mi lórí gan-an. Nígbà tí ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀, ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé ọkùnrin kan náà tí mo ti kàn lábùkù, tí mo sì lé jáde kúrò nílé mi ni olùbánisọ̀rọ̀ yẹn. Ọ̀rọ̀ tó sọ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo sì kábàámọ̀ pé mo hùwà sí i lọ́nà tí kò bójú mu. Kí wá ni mo lè ṣe báyìí tí màá fi padà bá a rẹ́?

Mo ní kí ìyàwó mi pè é fún oúnjẹ alẹ́ nílé wa, ṣùgbọ́n ó dábàá pé: “Ṣé o kò rò pé ohun tó bójú mu jù lọ ni kí ìwọ fúnra rẹ pè é? Dúró síbí, yóò wá sọ́dọ̀ wa.” Ohun to sọ rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ọkùnrin náà wá kí wa, tayọ̀tayọ̀ ló sì fi gbà láti wá.

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ tó wá yẹn ló jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìyípadà tí mo ṣe. Ó fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiyea hàn mí, èmi náà sì fi ẹ̀dà mẹ́fà ìwé yìí kan náà hàn án. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá gbàtọ́jú ní ọsibítù ló fún mi, ṣùgbọ́n mi ò kà wọ́n rí. Nígbà tá a ń jẹun àtìgbà tá a jẹun tán, àní títí di ọ̀gànjọ́ òru, ni mo fi ń béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè, gbogbo àwọn ìbéèrè yẹn pátá ló sì fi Bíbélì dáhùn. A fọ̀rọ̀ wérọ̀ títí tó fi di ìdájí ọjọ́ kejì. Kó tó lọ, ọkùnrin náà sọ pé òun á fi ìwé Otitọ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mẹ́ta la fi parí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé yẹn, a sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ nínú ìwé “Babylon the Great Has Fallen!” God’s Kingdom Rules!b Lẹ́yìn ìyẹn, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run mo sì ṣèrìbọmi.

Mo Tún Dẹni Tó Wúlò Padà

Nítorí pé ojúyòójú mi fọ́, ‘ojú ọkàn mi’ là sí òtítọ́ Bíbélì tí mo ti ń pa tì kó tó dìgbà yẹn! (Éfésù 1:18) Mímọ Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ fìfẹ́ pèsè ló yí ìgbésí ayé mi padà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo dẹni tó wúlò mo sì láyọ̀. Mo ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, mo sì ń fi bí wọ́n ṣe lè mú káyé wọn gùn díẹ̀ sí i nínú ètò àwọn nǹkan yìí hàn wọ́n, àti bí wọ́n á ṣe gbé títí láé nínú ètò tuntun.

Mo ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ìtẹ̀síwájú tó wà nínú ìmọ̀ ìṣègùn, mo ń ṣèwádìí lórí àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀, ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ, ẹ̀tọ́ olùgbàtọ́jú àti ìlànà tó rọ̀ mọ́ títọ́jú aláìsàn. Mo ti ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí fáwọn dókítà tó wà nítòsí nígbà tí wọ́n ké sí mi nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ìṣègùn. Ní ọdún 1994, mo lọ sí àpérò àkọ́kọ́ lórí ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ ní ìlú Rio de Janeiro lórílẹ̀-èdè Brazil, mo sì sọ̀rọ̀ lórí bá a ṣe lè tọ́jú aláìsàn tí ẹ̀jẹ̀ ò dá bọ̀rọ̀ lára rẹ̀. Díẹ̀ lára ìsọfúnni náà wà nínú àpilẹ̀kọ kan tí mo kọ, “Una propuesta: Estrategias para el Tratamiento de las Hemorragias” (“Àwọn Àbá Pàtàkì Lórí Títọ́jú Àìdá Ẹ̀jẹ̀”) tó jáde nínú ìwé ìròyìn ìmọ̀ ìṣègùn kan tí wọ́n ń pè ní Hemoterapia.

Jíjẹ́ Olóòótọ́ Nígbà Wàhálà

Níbẹ̀rẹ̀, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí mo ní nípa ìfàjẹ̀sínilára nìkan ló jẹ́ kí n máa ṣiyèméjì nípa rẹ̀. Àmọ́, nígbà témi gan-an wá lọ gbàtọ́jú ní ọsibítù, mo wá rí i pé kò rọrùn fẹ́nì kan láti sọ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀ kó sí di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú nígbà táwọn dókítà bá ń fúngun mọ́ ọn. Ohun tó lé ní wákàtí méjì gbáko ni mo fi ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi fẹ́ gbẹ̀jẹ̀ fún dókítà oníṣẹ́-abẹ kan nígbà tí àìsàn ọkàn lílágbára kan kọ lù mí. Ọmọ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kan ni dókítà ọ̀hún, ó sì sọ pé òun kò lè lajú sílẹ̀ kí n kú tó bá jẹ́ pé ìfàjẹ̀sínilára lè mú kí n yè é. Mo gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí dókítà yìí lóye kó sì bọ̀wọ̀ fún ohun tí mo sọ bí kò tiẹ̀ fara mọ́ ọn. Níkẹyìn, dókítà náà gbà láti ṣe ohun tí mo fẹ́.

Ìgbà kan tún wà tí wọ́n yọ kókó kan nínú ẹṣẹ́ tí ń pèsè omi àtọ̀ nínú ara mi. Ẹ̀jẹ̀ tó dà lára mi kò kéré. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún ní láti máa ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi lè gbẹ̀jẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ẹ̀jẹ̀ tó wà lára mi ti ṣòfò, síbẹ̀ àwọn dókítà náà ṣe ohun tí mo fẹ́.

Ìwà Àwọn Dókítà Yí Padà

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọmọ Àjọ Àgbáyé Tí Ń Bójú Tó Òfin Ìtọ́jú Aláìsàn, inú mi dùn láti rí i pé àwọn dókítà àtàwọn amòfin ti yí ìwà wọn padà lórí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ẹni tó ń gbàtọ́jú. Àwọn dókítà tí yí bí wọ́n ṣe máa ń pàṣẹ wàá tẹ́lẹ̀ padà, wọ́n sì ti ń bọ̀wọ̀ fún ohun tẹ́ni tó ń gbàtọ́jú bá fẹ́. Wọ́n ti wá ń gbà báyìí pé kí aláìsàn yan irú ìtọ́jú tó wù ú. Wọn ò wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí agbawèrèmẹ́sìn tí kò yẹ káwọn tọ́jú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí olùgbàtọ́jú tó lóye, táwọn ò sì gbọ́dọ̀ fojú ẹ̀tọ́ wọn gbolẹ̀. Nínú àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìmọ̀ ìṣègùn àti lórí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn gbajúgbajà ọ̀jọ̀gbọ́n máa ń sọ àwọn gbólóhùn bí: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ kó wá yé wa báyìí pé . . . ” “A ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé . . . ” àti “Wọ́n ti kọ́ wa láti mọṣẹ́ wa dunjú sí i.”

Gbogbo èèyàn ló gbà pé ìwàláàyè ṣe pàtàkì ju ohunkóhun lọ, nítorí òtúbáńtẹ́ ni òmìnira, àti iyì ọmọ ènìyàn tí kò bá sí ìwàláàyè. Ọ̀pọ̀ dókítà ló ti wá fara mọ́ òfin tó ga jù lọ pé olúkúlùkù ló ní ẹ̀tọ́ tirẹ̀, olúkúlùkù ló sì lè ṣèpinnu lórí èyí tó yẹ́ kó gbawájú nínú ẹ̀tọ́ rẹ̀ lábẹ́ ipò èyíkéyìí. Nípa bẹ́ẹ̀, iyì ọmọ ènìyàn, òmìnira láti yan ohun tó bá wuni àti ìgbàgbọ́ ẹni ló ṣe pàtàkì jù. Aláìsàn kan lómìnira láti yan irú ìtọ́jú tó bá wù ú. Iṣẹ́ Ìpèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti ran ọ̀pọ̀ dókítà lọ́wọ́ láti mú kí òye wọn túbọ̀ kún sí i lórí àwọn kókó wọ̀nyí.

Bí ìdílé mi ṣe ń tì mí lẹ́yìn látìgbàdégbà ti jẹ́ kí n lè wúlò nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì ti jẹ́ kí n lè máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ohun tó dùn mí jù lọ ni pé mi ò tètè mọ Jèhófà nínú ìgbésí ayé mi. Àmọ́ ṣá ó, mo dúpẹ́ pé ó ti la ojú mi sí àgbàyanu ìrètí gbígbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run níbi tí ‘kò ti ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’—Aísáyà 33:24.c

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.

c Nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́ ni Arákùnrin Egon Hauser gbẹ́mìí mì. Ó ṣe olóòótọ́ dójú ikú, a sì bá a yọ̀ pé ìrètí rẹ̀ dájú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi rèé nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ ní ọsibítù tó wà nílùú Santa Lucía, mo ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún nígbà yẹn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Beatriz ìyàwó mi rèé lọ́dún 1995

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́