ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/15 ojú ìwé 3-4
  • Báwo ni Ìwọ Ṣe Lè Wàláàyè Pẹ́ Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo ni Ìwọ Ṣe Lè Wàláàyè Pẹ́ Tó?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkókò Ìgbésí-Ayé tí A Fàgùn Kẹ̀?
  • Èéṣe tí Ìwàláàyè fi Kúrú Tóbẹ́ẹ̀?
  • Báwo Ni Kìràkìtà Àtipẹ́láyé Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó?
    Jí!—2006
  • Pẹ́ Láyé Kí Ara Rẹ Sì Tún Le Dáadáa
    Jí!—1999
  • Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/15 ojú ìwé 3-4

Báwo ni Ìwọ Ṣe Lè Wàláàyè Pẹ́ Tó?

Ọ̀PỌ̀ jùlọ nínú wa ni yóò fi tinútinú gbà pé ìṣòro ń bẹ ní ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé. Síbẹ̀, a láyọ̀ láti wàláàyè. A kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú kìkì ìgbà ọmọdé wa tàbí àkókò ìgbésí-ayé kúkúrú kan; àwa yóò fẹ́ láti wàláàyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ikú dàbí ohun tí kò ṣeéyẹ̀sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ha ni bí?

Ó ha ṣeéṣe láti dá ikú dúró bí? A ha lè fa àkókò ìgbésí-ayé wa gùn síi bí?

Àkókò Ìgbésí-Ayé tí A Fàgùn Kẹ̀?

Ní 1990 àkọsílẹ̀ ìròyìn kan kéde ṣíṣeéṣe náà láti fa àkókò ìgbésí-ayé ènìyàn gùn dé “àádọ́fà ọdún.” Kò sí iyèméjì pé èyí jẹ́ ìtọ́ka tí kò ṣe tààràtà sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ẹnu olórin Bibeli náà Mose: “Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wa; bí ó sì ṣe pé nípa ti agbára, bí wọ́n bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára wọn làálàá òun ìbìnújẹ́ ni; nítorí pé a kì óò pẹ́ ké e kúrò, àwa a sì fò lọ.” (Orin Dafidi 90:10) Nítorí náà Bibeli fúnni ní àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún gẹ́gẹ́ bí ìpíndọ́gba àkókò ìgbésí-ayé ènìyàn. Ṣùgbọ́n kí ni iye ọdún náà tí ó ṣeéṣe kí ẹnìkan retí láti gbé lónìí?

Ìròyìn kan tí WHO (Ètò-Àjọ Ìlera Àgbáyé) tẹ̀ jáde ní 1992 fi ìpíndọ́gba bí ẹnìkan ṣe lè wàláàyè pẹ́ tó kárí-ayé sí ọdún márùndínláàádọ́rin. Gẹ́gẹ́ bí ètò-àjọ WHO ti sọ, èyí ni a “retí pé kí ó fi nǹkan bíi oṣù mẹ́rin ga síi lọ́dọọdún fún ọdún márùn-ún tí yóò tẹ̀lé e, ní pàtàkì nítorí ikú àwọn ọmọdé tí ń dínkù síi.” Kódà bí iṣẹ́-ìyanu ìṣègùn bá tilẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ikú ẹnikẹ́ni ṣáájú kí ó tó pé àádọ́ta ọdún, síbẹ̀síbẹ̀, ìwé-ìròyìn Time sọ pé ní United States, “ìbísí nínú ìpíndọ́gba bí ẹnìkan ṣe lè wàláàyé pẹ́ tó yóò wulẹ̀ jẹ́ ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀.”

Èéṣe tí Ìwàláàyè fi Kúrú Tóbẹ́ẹ̀?

Dókítà Jan Vijg ti Àjọ Aṣàyẹ̀wò Nípa Ọjọ́-Ogbó àti Àwọn Ìṣòro Arúgbó ní Netherlands fihàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gan-an bí irú àwọn àrùn kan ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn àbùkù nínú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì ara ènìyàn, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà tí a gbà ń dàgbà di arúgbó ṣe dàbí èyí tí àwọn kókó tí ó jẹmọ́ apilẹ̀-àbùdá ń nípa lé lórí. Àwọn olùwádìí-jinlẹ̀ kan gbàgbọ́ pé ẹ̀mí wa lè túbọ̀ gùn síi bí ó bá ṣeéṣe láti pààrọ̀ “ẹ̀kúnwọ́ lájorí apilẹ̀-àbùdá” bí a ti ń dàgbà síi. Àwọn mìíràn pe irú ìronúdábàá bẹ́ẹ̀ ní “ìmúrọrùn èké.”

Lọ́nàkọ́nà ṣáá, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé “ó dàbí ẹni pé gbèǹdéke àdámọ́ni kan wà nípa ìwàláàyé tí a ti wéwèé rẹ̀ sínú ṣẹ́ẹ̀lì ara ènìyàn,” ni ìwé-ìròyìn Time sọ. Àní àwọn wọnnì tí wọ́n ṣàríyànjiyàn pé a ti “wéwèé wa láti máa wàláàyè” pàápàá gbà pé “ìkùnà kan ti ṣẹlẹ̀.” Nítòótọ́, ní ọdún márùndínláàádọ́rin, àádọ́rin, tàbí ọgọ́rin ọdún tàbí ó lé díẹ̀ síi, ìwàláàyé wa á ‘ké kúrò’ nínú ikú, gẹ́gẹ́ bi Bibeli ti sọ.

Síbẹ̀, Kristian aposteli Paulu ti ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E. fi ìdánilójú sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun.” (1 Korinti 15:26) Báwo ni a ṣe lè mú òpin débá ikú? Àní bí a bá tilẹ̀ fi òpin síi, báwo ni ìwọ ṣe lè kojú ìṣòro nípa ikú àwọn tí o fẹ́ràn lónìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́