Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó?
“Ènìyàn, tí a tipa obìnrin bí, ní ìwàláàyè kúkúrú, síbẹ̀ ó kún fún ìbànújẹ́ rẹ̀.”—JÓÒBÙ 14:1, THE JERUSALEM BIBLE.
O TI lè máa rò ó pé gbogbo ohun ẹlẹ́mìí ló máa gbó lọ́jọ́ kan dandan. Tá a bá ń lo ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ àti alùpùpù lójoojúmọ́, tó bá yá wọ́n á ṣíwọ́ iṣẹ́. Ó rọrùn láti gbà pé báwọn ẹranko náà ṣe máa darúgbó nìyẹn tí wọ́n á sì kú. Ṣùgbọ́n ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ẹranko tó ń jẹ́ Steven Austad ṣàlàyé pé: “Àwọn ohun ẹlẹ́mìí yàtọ̀ sí ẹ̀rọ. Ànímọ́ kan tí gbogbo ohun abẹ̀mí ní tó hàn jù lọ ni bí ẹ̀yà inú ara wọn ṣe máa ń tún ara rẹ̀ ṣe.”
Ọ̀nà tí ara ẹ gbà ń tún ara ẹ̀ ṣe lẹ́yìn tó o bá fara pa jẹ́ ohun àgbàyanu, àmọ́ àwọn àtúnṣe míì tó máa ń wáyé déédéé nínú ara, tiẹ̀ tún wá kàmàmà. Jẹ́ ká fi eegun rẹ ṣe àpẹẹrẹ. Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Téèyàn bá ń wo eegun láti ìta, ó lè dà bíi pé kò lẹ́mìí, ṣùgbọ́n ohun abẹ̀mí kan tó máa ń bà jẹ́ tó sì máa ń tún ara rẹ̀ ṣe téèyàn á fi dàgbà táá sì fi kú ni. Láàárín ọdún mẹ́wàá, gbogbo eegun inú ara èèyàn láá ti pààrọ̀ ara wọn.” Àwọn apá ibòmíì wà nínú ara ẹ tó máa ń tún ara ẹ̀ ṣe lemọ́lemọ́ jùyẹn lọ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan wà nínú awọ ara rẹ, ẹ̀dọ̀ rẹ àti ìfun rẹ tí wọ́n fẹ́ẹ̀ lè máa pààrọ̀ ara wọn lójoojúmọ́. Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, ara ẹ máa ń mú sẹ́ẹ̀lì mílíọ̀nù márùndínlọ́gbọ̀n jáde táá fi rọ́pò èyí tó ti bà jẹ́. Ká ní kì í ṣẹlẹ̀ báyẹn ni, ìyẹn ni pé ká ní gbogbo ẹ̀yà inú ara rẹ kì í pààrọ̀ ara wọn tàbí kí wọ́n tún ara wọn ṣe, àtikékeré lò bá ti darúgbó.
Nígbà táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí àwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì, wọ́n túbọ̀ wá rí i dájú lọ́nà pípabanbarì pé àwọn ẹ̀yà ara wa kì í gbó dà nù. Nígbà tí sẹ́ẹ̀lì kan bá rọ́pò òmíràn nínú ara rẹ, sẹ́ẹ̀lì tuntun kọ̀ọ̀kan máa ń ní èròjà DNA, ìyẹn èròjà tí ìsọfúnni nípa bí ara rẹ ṣe máa rí látòkèdélẹ̀ wà nínú rẹ̀. Ronú iye èròjà DNA tí sẹ́ẹ̀lì ti ṣe látìgbà tí wọ́n ti bí ọ, tàbí látìgbà tí Ẹlẹ́dàá ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá èèyàn! Láti lè lóye bí ohun tá à ń sọ yìí ṣe jẹ́ àgbàyanu tó, kíyè sí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá fi ẹ̀rọ tó ń ṣẹ̀dà ṣe ẹ̀dà ìwé kan, tó o sì wá fi ẹ̀dà tó o ṣe yẹn ṣe ẹ̀dà míì. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra, wàá rí i pé ìwé yẹn ò ní hàn rekete mọ́ tó bá sì yá kò ní í ṣeé kà mọ́. Àmọ́, ó dáa tó jẹ́ pé èròjà DNA inú ara wa kì í yí padà kì í sì í bà jẹ́ bó ti wù kó pín ara rẹ̀ tó. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara wa ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n gbà ń tún ohun tó bá bà jẹ́ nínú èròjà DNA ṣe. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni gbogbo èèyàn ì bá ti kú tán tipẹ́tipẹ́!
A ò lè sọ pàtó pé ẹ̀yà ara tó ń gbó ló fà á tá a fi ń darúgbó. Nítorí pé ó ti wá ṣe kedere pé lemọ́lemọ́ ni gbogbo ẹ̀yà ara wa máa ń pààrọ̀ ara wọn tàbí kí wọ́n tún ara wọn ṣe, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ẹ̀yà tó tóbi dórí àwọn kéékèèké. Ọ̀pọ̀ ohun tó dà bí ẹ̀rọ tó wà nínú ara, èyí tó pọ̀ jáǹrẹrẹ máa ń pààrọ̀ ara wọn tàbí kí wọn ṣàtúnṣe ara wọn láàárín ọ̀pọ̀ ọdún lóríṣiríṣi ọ̀nà, ó sì máa ń yá wọn ju ara wọn lọ. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, kí wá ló fà á tí gbogbo wọn fi máa ń daṣẹ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ kan náà?
Ṣé Ó Ti Wà Nínú Apilẹ̀ Àbùdá Pé Èèyàn Gbọ́dọ̀ Darúgbó Ni?
Kí ló dé tí ológìnní fi ń lò tó ogún ọdún láyé tí ẹranko opossum tí ò fí bẹ́ẹ̀ tóbi ju ológìnní lọ sì máa ń lo ọdún mẹ́ta péré?a Kí ló dé tí àdán fi máa ń lò tó ogún ọdún tàbí ọgbọ̀n ọdún àmọ́ tí èkúté kì í sì í lò ju ọdún mẹ́ta lọ? Kí ló dé tí ìjàpá ńlá fi máa ń gbé tó àádọ́jọ ọdún láyé àmọ́ tí erin kì í lò ju àádọ́rin ọdún lọ? Ohun tó mú kí ẹ̀mí àwọn ohun alààyè kan máa gùn ju ti òmíràn lọ kọjá irú oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ, bí wọ́n ṣe tóbi tó, ìtóbi ọpọlọ wọn, tàbí bí ara wọn ṣe ń yí padà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ìsọfúnni nípa ibi tí ọjọ́ orí ohun alààyè kan gbọ́dọ̀ dé dúró wà nínú apilẹ̀ àbùdá rẹ̀.” Ó dà bíi pé iye ọdún tí ohun alààyè kan lè gbé wà lákọọ́lẹ̀ nínú apilẹ̀ àbùdá rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀mí èèyàn bá ti ń lọ sópin rẹ̀, kí ló máa ń sọ fún ara pé kó ṣíwọ́ iṣẹ́?
Dókítà John Medina tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn ohun tíntìntín inú ara, kọ̀wé pé: “Ó dà bíi pé àmì abàmì kan wà nínú ara táá kàn dédé fara hàn lákòókò kan táá sì sọ fún àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n máa ṣe dúró.” Ó tún sọ pé: “Àwọn apilẹ̀ àbùdá kan wà tó lè sọ fáwọn sẹ́ẹ̀lì, tàbí gbogbo ẹ̀yà tó wà nínú ara pé kí wọ́n darúgbó kí wọ́n sì kú.”
A lè fi ara wa wé iléeṣẹ́ kan tó ti ń ṣòwò bọ̀ tó sì ń jèrè láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àfi lójijì táwọn alákòóso iléeṣẹ́ náà ò dédé gba òṣìṣẹ́ mọ́ tí wọ́n sì ṣíwọ́ fífún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́, wọn ò tún àwọn ẹ̀rọ tó yọnu ṣe wọn ò sì pààrọ̀ àwọn tó yẹ kí wọ́n pààrọ̀, wọn ò tún ilé àti ọgbà ilé iṣẹ́ náà ṣe wọn ò sì kọ́lé síbẹ̀ mọ́. Kò ní pẹ́ tí ọ̀pá ẹ̀bìtì iléeṣẹ́ náà ò fi ní í ré síwájú mọ́. Àmọ́ kí ló dé táwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ náà fi yí ìlànà tó ń gbè wọ́n tẹ́lẹ̀ yẹn padà? Irú ìbéèrè yìí jọ èyí tó ń dààmú àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tó ń mú kéèyàn darúgbó. Ìwé The Clock of Ages sọ pé: “Nínú ìwádìí tí wọ́n ń ṣe nípa ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó, ohun tó rú wọn lójú jù níbẹ̀ ni bí wọ́n ṣe fẹ́ mọ ohun tó ń mú káwọn sẹ́ẹ̀lì ṣíwọ́ pípààrọ̀ ara wọn kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú.”
Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Ká Má Darúgbó Mọ́?
Àwọn kan ti sọ pé ọjọ́ ogbó lèyí “tó le jù nínú ìṣòro tó ń kojú àwọn ohun alààyè.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń forí ṣe fọrùn ṣe, ìwádìí wọn ò tíì fi ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó hàn wọ́n ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bí wọ́n ṣe máa mú un kúrò. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ mọ́kànléláàádọ́ta tí wọ́n ṣèwádìí nípa ọjọ́ ogbó ṣèkìlọ̀ kan. Ìkìlọ̀ náà jáde lọ́dún 2004, nínú ìwé ìròyìn Scientific American pé: “Kò tíì sí oògùn náà lórí àtẹ báyìí, tó lè dín béèyàn ṣe ń darúgbó kù tàbí tó lè mú kéèyàn má darúgbó mọ́ tàbí tó lè mú kéèyàn máa lókun sí í bó ṣe ń dàgbà sí i.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tó dáa àti eré ìdárayá lè mú kí ara rẹ túbọ̀ le kó sì mú kó o jìnnà díẹ̀ sí ikú àìtọ́jọ́, kò tíì sí nǹkan tó lè fawọ́ aago ọjọ́ ogbó sẹ́yìn. Téèyàn bá ro gbogbo ẹ̀ lọ rò ó bọ̀, á rántí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Bíbélì pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”—Mátíù 6:27.
Dókítà Medina, ṣàkópọ̀ gbogbo àbárèbábọ̀ akitiyan láti mú hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó kúrò, ó kọ̀wé pé: “Ìdí tá a fi ń darúgbó gan-an ò tíì yé wa. . . . Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá bá a ṣe máa gbá àrùn jẹjẹrẹ wọlẹ̀, apá wa ò tíì ká a. Ọ̀ràn ti ọjọ́ ogbó sì wá rèé, kì í ṣẹgbẹ́ gbogbo ohun tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ lọ̀pọ̀ ọ̀nà.”
Ohun Pàtàkì Tá A Rí Dì Mú Látinú Ìwádìí
Ìwádìí tí wọ́n ṣe lórí bí ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ àti ìdí tára fi ń gbó ò fi hàn pé ẹ̀mí èèyàn ò lè gùn ju báyìí lọ. Látinú ìwádìí táwọn kan tún ṣe, wọ́n ti rí òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó. Onìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tó mọ̀ nípa èròjà inú ara Michael Behe, kọ̀wé pé: “Láti bí ogójì ọdún sẹ́yìn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa èròjà inú ara ti mọ báwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara ṣe ń ṣiṣẹ́. . . . Àbárèbábọ̀ ìwádìí tí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣe nípa sẹ́ẹ̀lì, ìyẹn ìwádìí láti mọ bí àwọn ohun tíntìntín inú ara ṣe ń ṣiṣẹ́, ti fi hàn láìṣeé jiyàn sí pé ẹnì kan ló ṣe wọ́n.” Ẹnì kan ló fi ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ dá àwọn ohun alààyè. Àmọ́ ṣá, Behe kọ́ lẹ́ni tó kọ́kọ́ dórí èrò yẹn o. Lẹ́yìn tí onísáàmù ìgbàanì kan ti ronú jinlẹ̀ lórí bí ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́, ó kọ̀wé pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:14.
Tó bá jẹ́ pé ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ ni Ọlọ́run, Ọba Adẹ́dàá fi dá gbogbo ohun alààyè, a lè béèrè nígbà náà pé, Ṣé ó dá ọmọ èèyàn láti máa lo iye ọdún kan náà táwọn ẹranko kan ń lò ni, àbí ó fẹ́ kí ẹ̀mí wa máa gùn ju tàwọn ẹranko lọ?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹran opossum tó wọ́pọ̀ jẹ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú tí wọ́n sábà máa ń rí ní Amẹ́ríkà Àríwá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
‘A ṣẹ̀dá wa tìyanu-tìyanu’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Ṣé gbígbó táwọn ẹ̀yà ara wa ń gbó ló ń fà á tá a fi ń darúgbó?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwòrán apilẹ̀ àbùdá DNA: Fọ́tò: Láti www.comstock.com