Ǹjẹ́ O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Hẹ́gẹhẹ̀gẹ Ọjọ́ Ogbó?
“Àádọ́rin ọdún ni gbogbo ohun tí a ní—ọgọ́rin ọdún, bí a bá lágbára; . . . láìpẹ́ ìwàláàyè yóò parí, a óò sì kọjá lọ.”—SÁÀMÙ 90:10, TODAY’S ENGLISH VERSION.
BÁWO ni ì bá ṣe rí ná ká ló ṣeé ṣe féèyàn láti máa gbádùn ọ̀ṣìngín ìgbà èwe rẹ̀ nìṣó. Kó wá lọ jẹ́ pé koko lara èèyàn máa ń le ní gbogbo ìgbà, tí iyè inú èèyàn á sì máa fìgbà gbogbo jí pépé láìsí pé èèyàn á máa gbàgbé nǹkan. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé èèyàn kàn ń dá ara ẹ̀ nínú dùn ni tó bá ń retí irú nǹkan báyìí? Ó dáa, ronú lórí ọ̀ràn tó gba àfiyèsí yìí: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ kan lè lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún láyé, agbára káká ni èkúté fi lè lò kọjá ọdún mẹ́ta. Torí irú ìyàtọ̀ báyìí tó máa ń wà nínú gígùn ọjọ́ orí àwọn ohun alààyè ló mú káwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé ó ní ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó àti pé tó bá lóhun tó ń fà á, a jẹ́ pé ojútùú lè wà fún un.
Àwọn iléeṣẹ́ oògùn ti náwó tó pọ̀ sórí ṣíṣe oògùn tí wọ́n fẹ́ fi ṣẹ́gun ọjọ́ ogbó. Bákan náà, ọjọ́ orí àwọn èèyàn tí wọ́n bí lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì ti lé ní ọgọ́ta ọdún báyìí olúkúlùkù wọn sì ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi ṣe é tí wọn ò fi ní tètè máa darúgbó.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣèwádìí nípa apilẹ̀ àbùdá, àwọn èròjà inú ara, àwọn ẹranko àti hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹpẹlẹ mọ́ ìwádìí nípa irú oògùn yìí báyìí. Ìwé Why We Age, látọwọ́ Steven Austad sọ pé: “Báwọn onímọ̀ nípa ọjọ́ ogbó bá ti forí korí báyìí, ńṣe làwọn èèyàn máa ń dánú dùn lábẹ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń retí ibi tọ́ràn máa já sí. A ti ń sún mọ́ bá a ṣe máa lóye àwọn ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó gan-an.”
Oríṣiríṣi àlàyé ló wà nípa ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó. Àwọn kan gbà gbọ́ pé ohun tó ń mú kéèyàn darúgbó ni ìgbà táwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara bá bà jẹ́ tí wọn ò sì lè ṣe iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n máa ṣe mọ́. Àwọn míì gbà pé ó ti wà nínú apilẹ̀ àbùdá àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara pé kí wọ́n gbó dà nù tó bá yá. Àwọn míì sọ pé nǹkan méjèèjì yẹn ló ń fà á. Báwo lọ̀rọ̀ dídarúgbó ṣe yéni tó? Ǹjẹ́ èrèdí kankan wà fún ríretí pé ìtọ́jú tó múná dóko á wà fún hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ kan lè lo ọgọ́rùn-ún ọdún láyé, àmọ́ nǹkan bí ọgọ́rin ọdún làwọn èèyàn máa ń lò. Àwọn olùṣèwádìí béèrè pé: “Kí ló ń fa ọjọ́ ogbó gan-an?”