ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 11-12
  • Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I Láyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I Láyé
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọ̀kan Lára Àṣeyọrí Ńláǹlà Tí Aráyé Ṣe”
  • O Ní Láti Yí Ojú Ìwòye Rẹ Padà
  • Ǹjẹ́ O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Hẹ́gẹhẹ̀gẹ Ọjọ́ Ogbó?
    Jí!—2006
  • Kí Nìdí Tá A Fi Ń Darúgbó?
    Jí!—2006
  • Ǹjẹ́ O Lè Nírètí Àtiwàláàyè Títí Láé?
    Jí!—1999
  • Pẹ́ Láyé Kí Ara Rẹ Sì Tún Le Dáadáa
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 11-12

Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I Láyé

LỌ́DÚN 1513, Juan Ponce de León, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan báyìí tó ń ṣàyẹ̀wò kiri, gúnlẹ̀ sí etíkun kan tí kò mọ̀ ní Àríwá Amẹ́ríkà. Ìròyìn kan sọ pé nítorí pé òdòdó pọ̀ gan-an ní àgbègbè tó ṣàwárí náà, ó pe ibẹ̀ ní Florida, tó túmọ̀ sí “Ilẹ̀ Olódòdó” lédè Sípéènì. Rírí orúkọ sọ ọ́ rọrùn. Àmọ́, kò rí ṣẹ́lẹ̀rú tó ní oògùn àjídèwe tó ń wá kiri. Lẹ́yìn tí olùyẹ̀wòkiri náà forí jágbó káàkiri ilẹ̀ náà fún ọ̀pọ̀ oṣù, ó gbé jẹ́ẹ́ ara ẹ̀, kò wá ṣẹ́lẹ̀rú tókìkí rẹ̀ kàn pé ó lóògùn àjídèwe nínú náà kiri mọ́, ló bá ń bá tiẹ̀ lọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àwọn ṣẹ́lẹ̀rú olóògùn àjídèwe níbì kankan lóde òní bí kò ṣe sí nígbà ayé Ponce de León, ó jọ pé àwọn ènìyàn ti rí ohun tí òǹkọ̀wé Betty Friedan pè ní “ṣẹ́lẹ̀rú ogbó.” Nítorí pé àwọn arúgbó ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé lọ́nà gbígbàfiyèsí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń darúgbó lásìkò yìí tó fi jẹ́ pé ìsọ̀rí àwọn olùgbé ayé ń yí padà. Èyí tó wá já sí pé àwọn arúgbó ń pọ̀ sí i láyé.

“Ọ̀kan Lára Àṣeyọrí Ńláǹlà Tí Aráyé Ṣe”

Ìròyìn nípa iye àwọn olùgbé ayé ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ìwọ̀n ọdún tí a retí láti lò láyé nígbà ìbí kò tó àádọ́ta ọdún, kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù láyé. Lónìí, ó ti lé ní márùndínláàádọ́rin. Bákan náà, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà bíi China, Honduras, Indonesia, àti Vietnam, iye ọdún tí a retí láti lò láyé nígbà ìbí fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ju iye tó jẹ́ ní ogójì ọdún sẹ́yìn lọ. Níbi gbogbo láyé, àádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ń pé ẹni ọgọ́ta ọdún lóṣooṣù. Ó yani lẹ́nu pé kì í tún ṣe àwọn ọ̀dọ́ ló ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe àwọn tí wọ́n ti tó ẹni ọgọ́rin ọdún tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ‘àwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.’

Eileen Crimmins tó jẹ́ onímọ̀ nípa iye àwọn olùgbé ayé sọ nínú ìwé ìròyìn Science pé: “Gígùn tí iye ọdún tí a retí láti lò láyé ń gùn sí i ti jẹ́ ọ̀kan lára àṣeyọrí ńláǹlà tí aráyé ṣe.” Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbà pẹ̀lú èyí, àti pé láti pàfiyèsí sórí àṣeyọrí yìí, ó ti fi ọdún 1999 ṣe Ọdún Àwọn Arúgbó Lágbàáyé—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 11.

O Ní Láti Yí Ojú Ìwòye Rẹ Padà

Síbẹ̀síbẹ̀, àṣeyọrí yìí ju ìyípadà nínú iye ọdún tí a retí láti lò láyé lọ. Ó tún kan ìyípadà nínú ojú tí ènìyàn fi ń wo ọjọ́ ogbó. Lóòótọ́, èrò dídarúgbó ṣì ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn, ó tiẹ̀ máa ń bà wọ́n lẹ́rù nítorí pé wọ́n sábà máa ń ronú pé ara èèyàn á di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, á sì máa ṣarán tó bá ti ń darúgbó. Àmọ́, àwọn olùwádìí tí wọ́n ń wádìí nípa ọjọ́ ogbó ṣàlàyé pé dídarúgbó àti ṣíṣàìsàn jẹ́ ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ò tan mọ́ra. Bí àwọn èèyàn ṣe ń darúgbó yàtọ̀ síra gan-an. Àwọn olùwádìí sọ pé, ìyàtọ̀ wà láàárín iye ọjọ́ orí wa gangan àti bí ara wá ṣe gbó sí. (Wo àpótí “Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Jẹ́ Arúgbó?”) Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, gígòkè àgbà àti dídarúgbó kùjọ́kùjọ́ kì í ṣe ohun kan náà.

Ní ti gidi, bí o ṣe ń dàgbà sí i, o lè máa ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Lóòótọ́, kì í ṣe pé àwọn ohun wọ̀nyí á jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ kéré sí i, àmọ́ wọ́n lè mú kí ara rẹ máa ṣe kébékébé bí o ṣe ń dàgbà sí i. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tí o lè máa ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn nípa dídarúgbó kò jẹ ẹ́ lógún ní báyìí, máa ka ìwé yìí lọ, nítorí láìpẹ́, wàá rí pé ó kàn ẹ́ gbọ̀ngbọ̀n.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

ỌDÚN ÀWỌN ARÚGBÓ LÁGBÀÁYÉ

Kofi Annan tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà àjọ UN sọ láìpẹ́ yìí nígbà tí wọ́n ń ṣèfilọ́lẹ̀ ètò Ọdún Àwọn Arúgbó Lágbàáyé pé: “Níwọ̀n bí èmi alára ti pé ẹni ọgọ́ta ọdún . . . , mo wà lára àwọn tí mo sọ iye wọn lẹ́ẹ̀kan.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lọ̀ràn wọ́n dà bíi ti Ọ̀gbẹ́ni Annan. Àwọn olùwádìí sọ pé, tí ọ̀rúndún yìí bá fi máa parí, ẹnì kan lára àwọn márùn-ún ló ti máa pé ẹni ọgọ́ta ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn kan lára wọn yóò nílò ẹni tí yóò máa tọ́jú wọn, ṣùgbọ́n gbogbo wọn yóò nílò ọ̀nà tí wọ́n lè gbà máa ní òmìnira, iyì, àti ṣíṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe tó tẹ́lẹ̀. Láti ran àwọn elétò ìlú lọ́wọ́ láti kápá ìpèníjà tí ‘ìyípadà nínú ètò àwùjọ àgbáyé’ dá sílẹ̀ yìí àti láti túbọ̀ mọ “iyì ọjọ́ ogbó láwùjọ,” Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ ti Àjọ UN pinnu ní ọdún 1992 láti fi ọdún 1999 ṣe Ọdún Àwọn Arúgbó Lágbàáyé. “Ètò Ìrànwọ́ fún Àwùjọ Tọmọdétàgbà” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ọdún àkànṣe yìí.

[Àwòrán]

Kofi Annan

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò UN

Fọ́tò UN/DPI tí Milton Grant yà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ARÚGBÓ?

Olùwádìí kan sọ pé: “Sísàsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbésí ayé kì í ṣe kedere tọ́ràn ti ọjọ́ ogbó bá wọ̀ ọ́.” Òmíràn sọ pé: “Kò sẹ́ni tó yé dáadáa.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn onímọ̀ nípa ọjọ́ ogbó ti gbìyànjú láti ṣàlàyé rẹ̀. Wọ́n ní, ká sọ ọ́ lọ́nà tó yéni, dídarúgbó túmọ̀ sí iye àkókò tí ẹnì kan ti fi wà láyé. Ṣùgbọ́n ọjọ́ ogbó ní nínú ju bí ọdún ṣe ń kọjá lọ. A kì í sábà sọ pé ọmọdé kan ń darúgbó nítorí pé ọjọ́ ogbó ní í ṣe pẹ̀lú dídi kùjọ́kùjọ́ ní ìrísí. Dídarúgbó túmọ̀ sí ohun tí ọjọ́ orí ti sọni dà. Ó máa ń jọ pé àwọn èèyàn kan kéré sí ọjọ́ orí wọn gangan. Fún àpẹẹrẹ, ohun tí a ń sọ nìyí nígbà tí a bá wí fún ẹnì kan pé kò jọ pé “ó dàgbà tó ọjọ́ orí rẹ̀.” Láti fìyàtọ̀ sí ọjọ́ orí wa gangan àti bí ara wa ṣe gbó tó, àwọn olùwádìí sábà máa ń ṣàpèjúwe bí ara wa ṣe gbó sí (èyíinì ni dídarúgbó tí ń sọ ara di kùjọ́kùjọ́) bí “ìgbà ogbó.”

Steven N. Austad tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ẹranko ṣàpèjúwe ìgbà ogbó bí ìgbà tí gbogbo ẹ̀yà ara bẹ̀rẹ̀ sí di ẹ̀kùrẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Richard L. Sprott, tí ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Àpapọ̀ Tí A Ti Ń Kọ́ Nípa Ọjọ́ Ogbó, sọ pé ọjọ́ ogbó “jẹ́ ìgbà tí àwọn ẹ̀yà ètò inú ara wa tí ń jẹ́ ká fìrọ̀rùn gbéra sọ nígbà tí nǹkan kò bá rọgbọ ń di ẹ̀kùrẹ̀ díẹ̀díẹ̀.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ògbógi gbà pé ó ṣòro láti rí ìtumọ̀ tó ṣe kedere fún ohun tí ọjọ́ ogbó jẹ́. Dókítà John Medina tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè tín-tìn-tín ṣàlàyé ohun tó fà á pé: “Láti orí títí dé ẹsẹ̀, láti orí èròjà potéènì títí dé orí èròjà DNA, láti ìgbà ìbí títí di ìgbà ikú, ẹgbàágbèje ìyípadà ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ara láti mú kí ènìyàn tóun alára jẹ́ ọgọ́ta tírílíọ̀nù sẹ́ẹ̀lì máa darúgbó.” Abájọ tí ọ̀pọ̀ olùwádìí fi sọ pé ọjọ́ ogbó “ló díjú jù lọ lára gbogbo ìṣòro tí ẹ̀dá ń ní láyé”!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́