ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 2-21
  • Ǹjẹ́ O Lè Nírètí Àtiwàláàyè Títí Láé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Nírètí Àtiwàláàyè Títí Láé?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú “Ìbéèrè Ńlá Náà Gan-an”
  • Ohun Náà Gan-an Tó Ń Fa Ikú
  • Ìdájọ́ Kan àti Ìlérí Kan
  • Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ẹ̀mí Rẹ Gùn Títí Láé
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ǹjẹ́ O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Hẹ́gẹhẹ̀gẹ Ọjọ́ Ogbó?
    Jí!—2006
  • Èé Ṣe Tí A Fi Ń Kú?
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Báwo Ni Kìràkìtà Àtipẹ́láyé Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 2-21

Ǹjẹ́ O Lè Nírètí Àtiwàláàyè Títí Láé?

Ọ̀MỌ̀WÉ James R. Smith, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa sẹ́ẹ̀lì inú ohun alààyè, sọ pé: “Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ nínú ara ènìyàn tó máa pinnu bóyá ènìyàn lè pẹ́ tó ọdún márùndínlọ́gọ́fà sí ọgọ́fà ọdún láyé. Ó níye ọdún tí a lè lò láyé—ṣùgbọ́n a ò mọ ohun tó ń pinnu ẹ̀.” Ọ̀mọ̀wé Roger Gosden tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé abájọ tí “àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tíì rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú kí ẹ̀mí ènìyàn túbọ̀ gùn sí i, agbára káká la sì fi rí èyí tó tilẹ̀ ń gbìyànjú rẹ̀.” Ìyípadà ha ti fẹ́ ṣẹlẹ̀ síyẹn bí?

Kíkojú “Ìbéèrè Ńlá Náà Gan-an”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbá èrò orí tí ń fojú àwọn ènìyàn sọ́nà fún yíyanjú ìṣòro ọjọ́ ogbó pọ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ògbógi fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí Dókítà Gene D. Cohen, ààrẹ Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ọjọ́ Ogbó ní Amẹ́ríkà, sọ pé, “òfo ni gbogbo ohun tí a rò pé yóò sàgbàdèwe yìí ń já sí.” Kí ló fà á? Nancy Shute, tó ń kọ nípa sáyẹ́ǹsì nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report, sọ pé, ohun kan ni pé “kò tíì sí ẹni tó mọ ohun tí ń fa dídarúgbó àti ikú tó ń gbẹ̀yìn rẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Lílòògùn sì àrùn tí a kò mọ ìdí ẹ̀ sì léwu.” Ọ̀mọ̀wé Gosden pẹ̀lú sọ pé ọ̀ràn ọjọ́ ogbó ṣì ṣòro láti lóye, ó wí pé: “Ó hàn kedere pé ó wà nínú olúkúlùkù wa àmọ́ bó ṣe jẹ́ gan-an kò tí ì yé èèyàn.” Ó sọ pé “ìbéèrè ńlá náà gan-an nípa ìdí tó tilẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ pàápàá” ni a kò kọbi ara sí dáadáa.a

Ẹ̀rí fi hàn pé bí ìwọ̀n eré tí èèyàn lè sá, bó ṣe lè fò tó, àti bó ṣe lè mòòkùn tó ṣe láàlà bẹ́ẹ̀ náà ni ààlà wà fún ibi tí ẹ̀dá èèyàn lè ronú dé láti ṣàlàyé nǹkan. Nítorí náà, dídáhùn “ìbéèrè ńlá náà gan-an nípa ohun tó fà á” ré kọjá ààlà yẹn dájúdájú. Nítorí náà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà rí ìdáhùn náà ni láti yíjú sí orísun kan tó ga ju àwọn ààlà ìmọ̀ ẹ̀dá. Ohun tí Bíbélì, ìwé àtayébáyé kan tó kún fún ọgbọ́n dábàá gẹ́lẹ́ pé kí o ṣe nìyẹn. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá, “orísun ìyè,” ó wí fún wa pé: “Bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun.” (Sáàmù 36:9; 2 Kíróníkà 15:2) Kí wá ni a óò rí, táa bá ṣàyẹ̀wò Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa ìdí náà gan-an tí ènìyàn fi ń kú?

Ohun Náà Gan-an Tó Ń Fa Ikú

Bíbélì wí fún wa pé nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ènìyàn àkọ́kọ́, ó fi “èrò wíwà títí ayérayé sí wọn lọ́kàn-àyà.” (Oníwàásù 3:11, Beck) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe kìkì ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé ni Ẹlẹ́dàá fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́; ó tún fún wọn láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá wọn pẹ̀lú ara àti èrò inú pípé, wọ́n sì gbádùn gbígbé ní àyíká alálàáfíà. Ẹlẹ́dàá pète pé kí àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ yìí wà láàyè títí láé àti pé bí àkókò ti ń lọ, kí àwọn ọmọ wọn pípé kún orí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15.

Ṣùgbọ́n, ìwàláàyè tí kò lópin wá sinmi lórí ipò kan. Ó sinmi lé ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. Bí Ádámù bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, òun yóò ‘kú dájúdájú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí pé “ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ìwà àìlófin.” (1 Jòhánù 3:4) Bí àbájáde rẹ̀, wọn ò tún ní àǹfààní ìyè ayérayé mọ́, nítorí pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Nítorí náà, nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ náà, ó wí pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ náà dẹ́ṣẹ̀, ipa tí a sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ yóò ní wá wọnú apilẹ̀ àbùdá wọn, bó ṣe wá di pé wọn ò lè máa wà láàyè títí lọ nìyẹn. Bí àbáyọrí rẹ̀, wọ́n di ẹni tí ń darúgbó, tí ikú sì ń pa níkẹyìn. Ní àfikún, lẹ́yìn tí a ti lé àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ náà dà nù kúrò nínú Párádísè ilé wọn àkọ́kọ́, tí a ń pè ní Édẹ́nì, ohun mìíràn tó ń nípa burúkú lórí ìwàláàyè wọn tún kojú wọn—àyíká tó dà bí ohun ìdènà lóde Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19, 23, 24) Àjọṣe tó wà láàárín àléébù àjogúnbá àti àyíká tí kò bára dé nípa lórí àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ náà, yóò sì nípa lórí àwọn ọmọ tí wọn yóò bí lọ́jọ́ iwájú.

Ìdájọ́ Kan àti Ìlérí Kan

Níwọ̀n bí àwọn ìyípadà tó ń pani lára yìí nínú ìgbésí ayé wọn ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́ náà kí wọ́n tó bímọ, kìkì àwọn ọmọ tó dà bí wọn nìkan ni wọ́n lè bí—aláìpé, ẹlẹ́ṣẹ̀, tó sì ń darúgbó. Bíbélì sọ pé: “Ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12; fi wé Sáàmù 51:5.) Ìwé The Body Machine—Your Health in Perspective sọ pé: “Ìwé àṣẹ ikú wa wà nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa.”

Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí fún ìwàláàyè tí kò lópin—ìwàláàyè láìsí ọjọ́ ogbó àti ikú. Lákọ̀ọ́kọ́, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá ènìyàn àti àwọn oríṣiríṣi ìṣẹ̀dá àgbàyanu mìíràn lè wo kùdìẹ̀-kudiẹ èyíkéyìí nínú apilẹ̀ àbùdá sàn kí ó sì pèsè agbára tí yóò mú kí ẹ̀dá máa wà nìṣó. Lọ́nà kejì, ohun tí Ẹlẹ́dàá ṣèlérí láti ṣe nìyí. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dájọ́ ikú fún àwọn ẹ̀dá àkọ́kọ́, ó fi hàn nígbà bíi mélòó kan pé ète rẹ̀ pé kí ènìyàn wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé kò tíì yí padà. Fún àpẹẹrẹ, ó mú un dáni lójú pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Kí ló yẹ kí o ṣe láti lè rí ìmúṣẹ ìlérí yìí?

Bí O Ṣe Lè Mú Kí Ẹ̀mí Rẹ Gùn Títí Láé

Lọ́nà tó dùn mọ́ni, lẹ́yìn tí Ronald Kotulak tó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fọ̀rọ̀ wá àwọn olùwádìí ìmọ̀ ìṣègùn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún lẹ́nu wò, ó sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé owó tí ń wọlé, iṣẹ́, àti ẹ̀kọ́ ló jẹ́ pàtàkì jù nínú pípinnu ìlera ènìyàn àti bí wọn yóò ṣe pẹ́ tó láyé. . . . Ṣùgbọ́n, ẹ̀kọ́ ló ń fara hàn bí èyí tó ṣe kókó jù lọ lára ohun tó ń pinnu bí ènìyàn yóò ṣe pẹ́ tó láyé.” Ó ṣàlàyé pé: “Bí oúnjẹ tí a ń jẹ ṣe ń fún ètò ìdènà àrùn wa lágbára láti lé àwọn kòkòrò àrùn tí ń wu ẹ̀mí léwu dà nù ni ẹ̀kọ́ ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ yíyan àwọn ohun tí kò dára.” Gẹ́gẹ́ bí olùwádìí kan ṣe sọ, “ẹ̀kọ́ ni a fi ń kọ́ bí a óò ṣe tukọ̀ ìgbésí ayé ẹni” àti bí a ṣe lè “borí àwọn ohun tó lè wá díni lọ́wọ́.” Nítorí náà, lọ́nà kan, bí òǹkọ̀wé Kotulak ṣe sọ, ẹ̀kọ́ ni “oògùn ara líle àti ẹ̀mí gígùn.”

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sípa jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú tún ni ẹ̀kọ́—ẹ̀kọ́ Bíbélì. Jésù Kristi sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Gbígba ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá, ìmọ̀ nípa Jésù Kristi, àti ìmọ̀ nípa ètò ìràpadà tí Ọlọ́run ṣe ni irú ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo tí yóò múra ẹnì kan sílẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń darí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ Bíbélì tí ń fúnni ní iyè yìí. Wá sí ọ̀kan lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa láti mọ̀ sí i nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀fẹ́ yìí, tàbí kí o ní kí a wá bẹ̀ ọ́ wò nígbà tó bá wọ̀ fún ọ. Wàá rí i pé Bíbélì ní ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ pé àkókò tí àwọn ohun ìdènà kò ní ṣèdíwọ́ fún ìwàláàyè ti sún mọ́lé tí ìwàláàyè kò sì ní lópin mọ́. Dájúdájú, ikú ti ń ṣàkóso fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àmọ́ láìpẹ́, a óò mú un kúrò títí ayérayé. Ìfojúsọ́nà tí ń mú tọmọdé tàgbà láyọ̀ gbáà lèyí!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn onímọ̀ nípa ọjọ́ ogbó ti gbé oríṣiríṣi àbá èrò orí kalẹ̀ (àwọn kan sọ pé ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún!) tó ń ṣàpèjúwe bí ọjọ́ ogbó ṣe lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́, àwọn àbá èrò orí wọ̀nyí kò ṣàlàyé ìdí tó tilẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìmọ̀ Bíbélì ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sípa jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́